Millat al-Islam

Chapter 51 · 60 verses · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Surah Adh-Dhariyat in Yoruba

Arabic with tafsir Listen to Surah Adh-Dhariyat (1246 reciters)

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

وَٱلذَّٰرِيَٰتِ ذَرۡوًا ١(Allāhu búra pẹ̀lú) atẹ́gùn t’ó ń tu erùpẹ̀ jáde nílẹ̀ tààrà فَٱلۡحَٰمِلَٰتِ وِقۡرًا ٢(Ó búra pẹ̀lú) àwọn ẹ̀ṣújò t’ó wúwo rinrin فَٱلۡجَٰرِيَٰتِ يُسۡرًا ٣(Ó búra pẹ̀lú) àwọn ọkọ̀ ojú-omi t’ó ń rìn pẹ̀lú ìrọ̀rùn فَٱلۡمُقَسِّمَٰتِ أَمۡرًا ٤(Ó búra pẹ̀lú) àwọn mọlāika t’ó ń pín n̄ǹkan (tí Ó ti pín fún ẹ̀dá) إِنَّمَا تُوعَدُونَ لَصَادِقٌ ٥Òdodo mà ni ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fun yín وَإِنَّ ٱلدِّينَ لَوَٰقِعٌ ٦Àti pé dájúdájú Ọjọ́ Ẹ̀san máa ṣẹlẹ̀ وَٱلسَّمَآءِ ذَاتِ ٱلۡحُبُكِ ٧(Allāhu tún búra pẹ̀lú) sánmọ̀ ọlọ́ṣọ̀ọ́ إِنَّكُمۡ لَفِي قَوۡلٍ مُّخۡتَلِفٍ ٨Dájúdájú ẹ̀yin wà lórí ọ̀rọ̀ t’ó ń takora wọn (nípa al-Ƙur’ān) يُؤۡفَكُ عَنۡهُ مَنۡ أُفِكَ ٩Ẹni tí wọ́n ń ṣẹ́ lórí kúrò níbi al-Ƙur’ān ni ẹni tí Wọ́n ti ṣẹ́ lórí kúrò níbẹ̀ (láti inú Laohul-Mahfūṭḥ) قُتِلَ ٱلۡخَرَّٰصُونَ ١٠Ègbé ni fún àwọn òpùrọ́ ٱلَّذِينَ هُمۡ فِي غَمۡرَةٍ سَاهُونَ ١١àwọn ni wọ́n wà nínú àìmọ̀kan, àwọn onígbàgbé يَسۡـَٔلُونَ أَيَّانَ يَوۡمُ ٱلدِّينِ ١٢tí wọ́n ń bèèrè ìgbà tí Ọjọ́ Ẹ̀san máa ṣẹlẹ̀ يَوۡمَ هُمۡ عَلَى ٱلنَّارِ يُفۡتَنُونَ ١٣Ní ọjọ́ náà sì ni wọn yóò máa fi Iná jẹ wọ́n níyà ذُوقُواْ فِتۡنَتَكُمۡ هَٰذَا ٱلَّذِي كُنتُم بِهِۦ تَسۡتَعۡجِلُونَ ١٤Ẹ tọ́ ìyà yín wò. Èyí ni n̄ǹkan tí ẹ ti ń wá pẹ̀lú ìkánjú إِنَّ ٱلۡمُتَّقِينَ فِي جَنَّٰتٍ وَعُيُونٍ ١٥Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) yóò wà nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra pẹ̀lú àwọn omi odò (ní ìsàlẹ̀ rẹ̀) ءَاخِذِينَ مَآ ءَاتَىٰهُمۡ رَبُّهُمۡۚ إِنَّهُمۡ كَانُواْ قَبۡلَ ذَٰلِكَ مُحۡسِنِينَ ١٦Wọn yóò máa gba n̄ǹkan tí Olúwa wọn bá fún wọn. Dájúdájú wọ́n ti jẹ́ olùṣe-rere ṣíwájú ìyẹn كَانُواْ قَلِيلًا مِّنَ ٱلَّيۡلِ مَا يَهۡجَعُونَ ١٧Wọ́n máa ń sun oorun díẹ̀ nínú òru وَبِٱلۡأَسۡحَارِ هُمۡ يَسۡتَغۡفِرُونَ ١٨Wọ́n máa ń tọrọ àforíjìn ní àfẹ̀mọ́júmọ́ وَفِيٓ أَمۡوَٰلِهِمۡ حَقٌّ لِّلسَّآئِلِ وَٱلۡمَحۡرُومِ ١٩Nínú dúkìá wọn, wọ́n ní ojúṣe tí wọ́n ń ṣe fún alágbe àti ẹni tí A ṣe arísìkí ní èèwọ̀ fún وَفِي ٱلۡأَرۡضِ ءَايَٰتٌ لِّلۡمُوقِنِينَ ٢٠Àwọn àmì wà ní orí ilẹ̀ fún àwọn alámọ̀dájú وَفِيٓ أَنفُسِكُمۡۚ أَفَلَا تُبۡصِرُونَ ٢١Nínú ẹ̀mí ara yín gan-an (àmì ìyanu wà nínú rẹ̀). Ṣé ẹ ò ríran ni وَفِي ٱلسَّمَآءِ رِزۡقُكُمۡ وَمَا تُوعَدُونَ ٢٢Arísìkí yín àti ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fun yín wà nínú sánmọ̀ فَوَرَبِّ ٱلسَّمَآءِ وَٱلۡأَرۡضِ إِنَّهُۥ لَحَقٌّ مِّثۡلَ مَآ أَنَّكُمۡ تَنطِقُونَ ٢٣Nítorí náà, Mó fi Olúwa sánmọ̀ àti ilẹ̀ búra, dájúdájú òdodo ni (ọ̀rọ̀ náà) gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ òdodo pé ẹ̀ ń fẹnu sọ̀rọ̀ هَلۡ أَتَىٰكَ حَدِيثُ ضَيۡفِ إِبۡرَٰهِيمَ ٱلۡمُكۡرَمِينَ ٢٤Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ àwọn àlejò (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, àwọn alápọ̀n-ọ́nlé, ti dé ọ̀dọ̀ rẹ إِذۡ دَخَلُواْ عَلَيۡهِ فَقَالُواْ سَلَٰمًاۖ قَالَ سَلَٰمٌ قَوۡمٌ مُّنكَرُونَ ٢٥(Rántí) nígbà tí wọ́n wọlé tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì sọ pé: "Àlàáfíà (fún ọ)." Òun náà sọ pé: "Àlàáfíà (fun yín), ẹ̀yin àjòjì ènìyàn فَرَاغَ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِۦ فَجَآءَ بِعِجۡلٍ سَمِينٍ ٢٦Ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará ilé rẹ̀, ó sì dé pẹ̀lú ọmọ màálù ọlọ́ràá (àyangbẹ) فَقَرَّبَهُۥٓ إِلَيۡهِمۡ قَالَ أَلَا تَأۡكُلُونَ ٢٧Ó gbé e súnmọ́ ọ̀dọ̀ wọn. Ó sì sọ pé: "Ṣé ẹ ò níí jẹun ni فَأَوۡجَسَ مِنۡهُمۡ خِيفَةًۖ قَالُواْ لَا تَخَفۡۖ وَبَشَّرُوهُ بِغُلَٰمٍ عَلِيمٍ ٢٨Nígbà náà, ó ní ìpáyà wọn nínú ọkàn. Wọ́n sọ pé: "Má ṣe páyà." Wọ́n sì fún un ní ìró ìdùnnú nípa bíbí ọmọkùnrin onímọ̀ kan فَأَقۡبَلَتِ ٱمۡرَأَتُهُۥ فِي صَرَّةٍ فَصَكَّتۡ وَجۡهَهَا وَقَالَتۡ عَجُوزٌ عَقِيمٌ ٢٩Nígbà náà, ìyàwó rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ igbe, ó sì gbára rẹ̀ lójú, ó sọ pé: "Arúgbó, àgàn (mà ni mí) قَالُواْ كَذَٰلِكِ قَالَ رَبُّكِۖ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلۡحَكِيمُ ٱلۡعَلِيمُ ٣٠Wọ́n sọ pé: "Báyẹn ni Olúwa rẹ sọ. Dájúdájú Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀

Juz 27

۞ قَالَ فَمَا خَطۡبُكُمۡ أَيُّهَا ٱلۡمُرۡسَلُونَ ٣١(Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: "Kí tún ni ọ̀rọ̀ tí ẹ bá wá, ẹ̀yin Òjíṣẹ́ قَالُوٓاْ إِنَّآ أُرۡسِلۡنَآ إِلَىٰ قَوۡمٍ مُّجۡرِمِينَ ٣٢Wọ́n sọ pé: "Dájúdájú Wọ́n rán wa níṣẹ́ sí ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ ni لِنُرۡسِلَ عَلَيۡهِمۡ حِجَارَةً مِّن طِينٍ ٣٣nítorí kí á lè fi òkúta amọ̀ (sísun) ránṣẹ́ sí wọn مُّسَوَّمَةً عِندَ رَبِّكَ لِلۡمُسۡرِفِينَ ٣٤Wọ́n ti fàmì sí i lára lọ́dọ̀ Olúwa rẹ fún àwọn alákọyọ فَأَخۡرَجۡنَا مَن كَانَ فِيهَا مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ٣٥Nítorí náà, A mú àwọn t’ó jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo jáde kúrò nínú (ìlú náà) فَمَا وَجَدۡنَا فِيهَا غَيۡرَ بَيۡتٍ مِّنَ ٱلۡمُسۡلِمِينَ ٣٦A ò sì rí nínú (ìlú náà) tayọ ilé kan t’ó jẹ́ ti àwọn mùsùlùmí وَتَرَكۡنَا فِيهَآ ءَايَةً لِّلَّذِينَ يَخَافُونَ ٱلۡعَذَابَ ٱلۡأَلِيمَ ٣٧A sì fi àmì kan sílẹ̀ nínú (ìlú náà) fún àwọn t’ó ń páyà ìyà ẹlẹ́ta-eléro وَفِي مُوسَىٰٓ إِذۡ أَرۡسَلۡنَٰهُ إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ بِسُلۡطَٰنٍ مُّبِينٍ ٣٨(Àmì tún wà) lára (Ànábì) Mūsā. Nígbà tí A fi ẹ̀rí pọ́nńbélé rán an níṣẹ́ sí Fir‘aon فَتَوَلَّىٰ بِرُكۡنِهِۦ وَقَالَ سَٰحِرٌ أَوۡ مَجۡنُونٌ ٣٩Ṣùgbọ́n (Fir‘aon) gbúnrí pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ó sì wí pé: "Òpìdán tàbí wèrè kan (nìyí) فَأَخَذۡنَٰهُ وَجُنُودَهُۥ فَنَبَذۡنَٰهُمۡ فِي ٱلۡيَمِّ وَهُوَ مُلِيمٌ ٤٠Nítorí náà, A mú òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀. A sì jù wọ́n sínú agbami odò nígbà tí ó jẹ́ alábùkù وَفِي عَادٍ إِذۡ أَرۡسَلۡنَا عَلَيۡهِمُ ٱلرِّيحَ ٱلۡعَقِيمَ ٤١(Àmì tún wà) lára ìjọ ‘Ād. (Rántí) nígbà tí A rán atẹ́gùn ìparun sí wọn مَا تَذَرُ مِن شَيۡءٍ أَتَتۡ عَلَيۡهِ إِلَّا جَعَلَتۡهُ كَٱلرَّمِيمِ ٤٢kò fi kiní kan tó fẹ́ sí lára sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ àfi kó sọ ọ́ di bí èso rírún túútú وَفِي ثَمُودَ إِذۡ قِيلَ لَهُمۡ تَمَتَّعُواْ حَتَّىٰ حِينٍ ٤٣(Àmì tún wà) lára ìjọ Thamūd. (Rántí) nígbà tí A sọ fún wọn pé: "Ẹ jayé fún ìgbà díẹ̀ ná فَعَتَوۡاْ عَنۡ أَمۡرِ رَبِّهِمۡ فَأَخَذَتۡهُمُ ٱلصَّٰعِقَةُ وَهُمۡ يَنظُرُونَ ٤٤Wọ́n ṣègbéraga sí àṣẹ Olúwa wọn. Nítorí náà, igbe ìparun mú wọ́n; wọ́n sì ń wò bọ̀ọ̀ فَمَا ٱسۡتَطَٰعُواْ مِن قِيَامٍ وَمَا كَانُواْ مُنتَصِرِينَ ٤٥Wọn kò lè dìde nàró. Wọn kò sì lè ran ara wọn lọ́wọ́ وَقَوۡمَ نُوحٍ مِّن قَبۡلُۖ إِنَّهُمۡ كَانُواْ قَوۡمًا فَٰسِقِينَ ٤٦Àti ìjọ Nūh tí ó ṣíwájú (wọn), dájúdájú Àwa sì ni olùgbòòrò وَٱلسَّمَآءَ بَنَيۡنَٰهَا بِأَيۡيْدٍ وَإِنَّا لَمُوسِعُونَ ٤٧Àti pé sánmọ̀, A mọ ọ́n (sí òkè yín) pẹ̀lú agbára. Dájúdájú Àwa sì ni olùgbòòrò وَٱلۡأَرۡضَ فَرَشۡنَٰهَا فَنِعۡمَ ٱلۡمَٰهِدُونَ ٤٨Àti ilẹ̀, A ṣe é ní ìtẹ́. Àwọn olùtẹ́lẹ̀-sílẹ̀ sì dára وَمِن كُلِّ شَيۡءٍ خَلَقۡنَا زَوۡجَيۡنِ لَعَلَّكُمۡ تَذَكَّرُونَ ٤٩Àti pé gbogbo n̄ǹkan ni A ṣẹ̀dá ní oríṣi méjì-méjì nítorí kí ẹ lè lo ìrántí فَفِرُّوٓاْ إِلَى ٱللَّهِۖ إِنِّي لَكُم مِّنۡهُ نَذِيرٌ مُّبِينٌ ٥٠Nítorí náà, ẹ sá lọ sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípa ìronúpìwàdà). Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fun yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ وَلَا تَجۡعَلُواْ مَعَ ٱللَّهِ إِلَٰهًا ءَاخَرَۖ إِنِّي لَكُم مِّنۡهُ نَذِيرٌ مُّبِينٌ ٥١Ẹ má ṣe mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fun yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ كَذَٰلِكَ مَآ أَتَى ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِم مِّن رَّسُولٍ إِلَّا قَالُواْ سَاحِرٌ أَوۡ مَجۡنُونٌ ٥٢Báyẹn ni (ọ̀rọ̀ ṣe rí)! Òjíṣẹ́ kan kò wá bá àwọn t’ó ṣíwájú wọn àfi kí wọ́n wí pé: "Òpìdán tàbí wèrè ni أَتَوَاصَوۡاْ بِهِۦۚ بَلۡ هُمۡ قَوۡمٌ طَاغُونَ ٥٣Ṣé wọn sọ àsọọ́lẹ̀ nípa rẹ̀ láààrin ara wọn ni? Rárá o! Ìjọ olùtayọ-ẹnu-àlà ni wọ́n ni فَتَوَلَّ عَنۡهُمۡ فَمَآ أَنتَ بِمَلُومٍ ٥٤Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn ná. Ìwọ kì í ṣe alábùkù وَذَكِّرۡ فَإِنَّ ٱلذِّكۡرَىٰ تَنفَعُ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ٥٥Ṣèrántí nítorí pé, dájúdájú ìrántí máa wúlò fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo وَمَا خَلَقۡتُ ٱلۡجِنَّ وَٱلۡإِنسَ إِلَّا لِيَعۡبُدُونِ ٥٦Àti pé Èmi kò ṣẹ̀dá àlùjànnú àti ènìyàn bí kò ṣe pé kí wọ́n lè jọ́sìn fún Mi مَآ أُرِيدُ مِنۡهُم مِّن رِّزۡقٍ وَمَآ أُرِيدُ أَن يُطۡعِمُونِ ٥٧Èmi kò gbèrò arísìkí kan láti ọ̀dọ̀ wọn. Èmi kò sì gbèrò pé kí wọ́n máa bọ́ Mi إِنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلرَّزَّاقُ ذُو ٱلۡقُوَّةِ ٱلۡمَتِينُ ٥٨Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùpèsè, Alágbára líle فَإِنَّ لِلَّذِينَ ظَلَمُواْ ذَنُوبًا مِّثۡلَ ذَنُوبِ أَصۡحَٰبِهِمۡ فَلَا يَسۡتَعۡجِلُونِ ٥٩Dájúdájú ìpín ìyà tí ó máa jẹ àwọn t’ó ṣàbòsí (wọ̀nyí) ni irú ìpín ìyà tí ó jẹ ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ (irú) wọn. Nítorí náà, kí wọ́n má ṣe kán Mi lójú (nípa ìyà wọn) فَوَيۡلٌ لِّلَّذِينَ كَفَرُواْ مِن يَوۡمِهِمُ ٱلَّذِي يُوعَدُونَ ٦٠Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ní ọjọ́ wọn tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn

Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.