Millat al-Islam

Chapter 85 · 22 verses · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Surah Al-Burooj in Yoruba

Arabic with tafsir Listen to Surah Al-Burooj (1318 reciters)
Meccanسورة البروج22 verses

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

وَٱلسَّمَآءِ ذَاتِ ٱلۡبُرُوجِ ١(Allāhu) búra pẹ̀lú sánmọ̀ tí àwọn ibùsọ̀ (òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀) wà nínú rẹ̀ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡمَوۡعُودِ ٢Ó tún búra pẹ̀lú ọjọ́ tí wọ́n ṣe ní àdéhùn وَشَاهِدٍ وَمَشۡهُودٍ ٣Ó tún búra pẹ̀lú olùjẹ́rìí àti ohun t’ó jẹ́rìí sí قُتِلَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡأُخۡدُودِ ٤A ṣẹ́bi lé àwọn t’ó gbẹ́ kòtò (iná) ٱلنَّارِ ذَاتِ ٱلۡوَقُودِ ٥(ìyẹn) iná tí wọ́n ń fi igi kò (nínú kòtò) إِذۡ هُمۡ عَلَيۡهَا قُعُودٌ ٦(Rántí) nígbà tí wọ́n jókòó sí ìtòsí rẹ̀ وَهُمۡ عَلَىٰ مَا يَفۡعَلُونَ بِٱلۡمُؤۡمِنِينَ شُهُودٌ ٧Wọ́n sì ń wo ohun tí wọ́n ń ṣe fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo وَمَا نَقَمُواْ مِنۡهُمۡ إِلَّآ أَن يُؤۡمِنُواْ بِٱللَّهِ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡحَمِيدِ ٨Kò sì sí kiní kan tí wọ́n torí rẹ̀ jẹ wọ́n níyà bí kò ṣe pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu, Alágbára, Ọlọ́pẹ́ ٱلَّذِي لَهُۥ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٍ شَهِيدٌ ٩Ẹni tí Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ni Ẹlẹ́rìí lórí gbogbo n̄ǹkan إِنَّ ٱلَّذِينَ فَتَنُواْ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ وَٱلۡمُؤۡمِنَٰتِ ثُمَّ لَمۡ يَتُوبُواْ فَلَهُمۡ عَذَابُ جَهَنَّمَ وَلَهُمۡ عَذَابُ ٱلۡحَرِيقِ ١٠Dájúdájú àwọn t’ó fi ìnira kan àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, lẹ́yìn náà tí wọn kò ronú pìwàdà, ìyà iná Jahanamọ ń bẹ fún wọn. Ìyà iná t’ó ń jò sì wà fún wọn إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ لَهُمۡ جَنَّٰتٌ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُۚ ذَٰلِكَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡكَبِيرُ ١١Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tiwọn ni àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá إِنَّ بَطۡشَ رَبِّكَ لَشَدِيدٌ ١٢Dájúdájú ìgbámú ti Olúwa rẹ mà le إِنَّهُۥ هُوَ يُبۡدِئُ وَيُعِيدُ ١٣Dájúdájú Òun ni Ó pìlẹ̀ (ẹ̀dá), Ó sì máa dá (ẹ̀dá) padà (fún àjíǹde) وَهُوَ ٱلۡغَفُورُ ٱلۡوَدُودُ ١٤Òun ni Aláforíjìn, Olólùfẹ́ (ẹ̀dá) ذُو ٱلۡعَرۡشِ ٱلۡمَجِيدُ ١٥Òun l’Ó ni Ìtẹ́-ọlá, Ẹni-ọ̀wọ̀ jùlọ فَعَّالٌ لِّمَا يُرِيدُ ١٦Olùṣe-ohun-t’Ó-bá-fẹ́ هَلۡ أَتَىٰكَ حَدِيثُ ٱلۡجُنُودِ ١٧Ṣebí ìró àwọn ọmọ ogun ti dé ọ̀dọ̀ rẹ فِرۡعَوۡنَ وَثَمُودَ ١٨(ọmọ ogun) Fir‘aon àti (ìjọ) Thamūd بَلِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ فِي تَكۡذِيبٍ ١٩Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ sì ń pe òdodo nírọ́ وَٱللَّهُ مِن وَرَآئِهِم مُّحِيطُۢ ٢٠Allāhu sì yí wọn ká lẹ́yìn wọn بَلۡ هُوَ قُرۡءَانٌ مَّجِيدٌ ٢١Àmọ́ sá, ohun (tí A fi ránṣẹ́ sí ọ ni) al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé فِي لَوۡحٍ مَّحۡفُوظِۭ ٢٢tí ó wà nínú wàláà tí À ń ṣọ́

Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.