بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
وَٱلۡفَجۡرِ ١Allāhu búra pẹ̀lú àfẹ̀mọ́júmọ́ وَلَيَالٍ عَشۡرٍ ٢Ó tún búra pẹ̀lú àwọn òru mẹ́wàá kan وَٱلشَّفۡعِ وَٱلۡوَتۡرِ ٣Ó tún búra pẹ̀lú méjì àti ẹyọ وَٱلَّيۡلِ إِذَا يَسۡرِ ٤Ó tún búra pẹ̀lú òru nígbà tí ó bá lọ (tí ó bá dé) هَلۡ فِي ذَٰلِكَ قَسَمٌ لِّذِي حِجۡرٍ ٥Ǹjẹ́ ìbúra wà nínú ìyẹn fún onílàákàyè أَلَمۡ تَرَ كَيۡفَ فَعَلَ رَبُّكَ بِعَادٍ ٦Ṣé o ò rí bí Olúwa rẹ ti ṣe ọ̀rọ̀ ará ‘Ād إِرَمَ ذَاتِ ٱلۡعِمَادِ ٧(ìyẹn àwọn ìran) ’Irọm, àwọn òmìrán ٱلَّتِي لَمۡ يُخۡلَقۡ مِثۡلُهَا فِي ٱلۡبِلَٰدِ ٨àwọn tí A ò dá irú wọn mọ́ sínú ìlú وَثَمُودَ ٱلَّذِينَ جَابُواْ ٱلصَّخۡرَ بِٱلۡوَادِ ٩Àti àwọn Thamūd tí wọ́n gbẹ́ (ilé ìgbé) sínú àpáta nínú àfonífojì وَفِرۡعَوۡنَ ذِي ٱلۡأَوۡتَادِ ١٠àti Fir‘aon eléèkàn (ìyà) ٱلَّذِينَ طَغَوۡاْ فِي ٱلۡبِلَٰدِ ١١(Àwọn wọ̀nyí ni) àwọn t’ó tayọ ẹnu-àlà nínú ìlú فَأَكۡثَرُواْ فِيهَا ٱلۡفَسَادَ ١٢Wọ́n sì ṣe ìbàjẹ́ púpọ̀ sínú rẹ̀ فَصَبَّ عَلَيۡهِمۡ رَبُّكَ سَوۡطَ عَذَابٍ ١٣Olúwa rẹ sì rọ̀jò ìyà lé wọn lórí إِنَّ رَبَّكَ لَبِٱلۡمِرۡصَادِ ١٤Dájúdájú Olúwa rẹ wà ní ibùṣọ́ (iṣẹ́ ẹ̀dá) فَأَمَّا ٱلۡإِنسَٰنُ إِذَا مَا ٱبۡتَلَىٰهُ رَبُّهُۥ فَأَكۡرَمَهُۥ وَنَعَّمَهُۥ فَيَقُولُ رَبِّيٓ أَكۡرَمَنِ ١٥Nítorí náà, ní ti ènìyàn, nígbà tí Olúwa rẹ̀ bá dán an wò, tí Ó pọ́n ọn lé, tí Ó sì ṣe ìdẹ̀ra fún un, nígbà náà ó máa wí pé: "Olúwa mi ti pọ́n mi lé وَأَمَّآ إِذَا مَا ٱبۡتَلَىٰهُ فَقَدَرَ عَلَيۡهِ رِزۡقَهُۥ فَيَقُولُ رَبِّيٓ أَهَٰنَنِ ١٦Ṣùgbọ́n nígbà tí Ó bá dán an wò, tí Ó gán arísìkí rẹ̀ lé e lọ́wọ́, nígbà náà ó máa wí pé: "Olúwa mi ti yẹpẹrẹ mi كـَلَّاۖ بَل لَّا تُكۡرِمُونَ ٱلۡيَتِيمَ ١٧Rárá, kò rí bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ẹ̀yin kò ṣàpọ́nlé ọmọ-òrukàn وَلَا تَحَٰٓضُّونَ عَلَىٰ طَعَامِ ٱلۡمِسۡكِينِ ١٨Àti pé ẹ̀yin kò gbẹra yín lóǹgbẹ láti fún mẹ̀kúnnù ní oúnjẹ وَتَأۡكُلُونَ ٱلتُّرَاثَ أَكۡلًا لَّمًّا ١٩Ẹ tún ń jẹ ogún ní ìjẹkújẹ وَتُحِبُّونَ ٱلۡمَالَ حُبًّا جَمًّا ٢٠Àti pé ẹ nífẹ̀ẹ́ sí dúkìá ní ìfẹ́ púpọ̀ كـَلَّآۖ إِذَا دُكَّتِ ٱلۡأَرۡضُ دَكًّا دَكًّا ٢١Rárá, (kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀). Nígbà tí wọ́n bá mi ilẹ̀ tìtì ní mímì tìtì (t’ó rún wómúwómú, tí kò sí kòtò, tí kò sí gelemọ) وَجَآءَ رَبُّكَ وَٱلۡمَلَكُ صَفًّا صَفًّا ٢٢(tí) Olúwa rẹ dé pẹ̀lú àwọn mọlāika ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ وَجِاْيٓءَ يَوۡمَئِذِۭ بِجَهَنَّمَۚ يَوۡمَئِذٍ يَتَذَكَّرُ ٱلۡإِنسَٰنُ وَأَنَّىٰ لَهُ ٱلذِّكۡرَىٰ ٢٣ní ọjọ́ yẹn ni wọ́n máa mú iná Jahanamọ wá. Ní ọjọ́ yẹn, ènìyàn yóò rántí (ọ̀rọ̀ ara rẹ̀). Báwo sì ni ìrántí náà ṣe lè wúlò fún un يَقُولُ يَٰلَيۡتَنِي قَدَّمۡتُ لِحَيَاتِي ٢٤Ó máa wí pé: "Yéè, èmi ìbá ti ti (iṣẹ́ rere) síwájú fún ìṣẹ̀mí mi فَيَوۡمَئِذٍ لَّا يُعَذِّبُ عَذَابَهُۥٓ أَحَدٌ ٢٥Ní ọjọ́ yẹn, ẹnì kan kò lè fi ìyà jẹ (ẹ̀dá) bí irú ìyà (tí) Allāhu (yóò fi jẹ ẹ́) وَلَا يُوثِقُ وَثَاقَهُۥٓ أَحَدٌ ٢٦Ẹnì kan kò sì lè de (ẹ̀dá) ní ìgbèkùn bí irú ìgbèkùn (tí) Allāhu (yóò fi dè é) يَٰٓأَيَّتُهَا ٱلنَّفۡسُ ٱلۡمُطۡمَئِنَّةُ ٢٧Ìwọ ẹ̀mí olùfọ̀kànbalẹ̀ ٱرۡجِعِيٓ إِلَىٰ رَبِّكِ رَاضِيَةً مَّرۡضِيَّةً ٢٨padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ní olùyọ́nú, ẹni ìyọ́nú فَٱدۡخُلِي فِي عِبَٰدِي ٢٩Nítorí náà, wọlé sáààrin àwọn ẹrúsìn Mi وَٱدۡخُلِي جَنَّتِي ٣٠Wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra Mi