Millat al-Islam

Chapter 17 · 111 verses · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Surah Al-Israa in Yoruba

Arabic with tafsir Listen to Surah Al-Israa (1338 reciters)
Meccanسورة الإسراء111 verses

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

سُبۡحَٰنَ ٱلَّذِيٓ أَسۡرَىٰ بِعَبۡدِهِۦ لَيۡلًا مِّنَ ٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡحَرَامِ إِلَى ٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡأَقۡصَا ٱلَّذِي بَٰرَكۡنَا حَوۡلَهُۥ لِنُرِيَهُۥ مِنۡ ءَايَٰتِنَآۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡبَصِيرُ ١Mímọ́ ni fún Ẹni tí Ó mú ẹrúsìn Rẹ̀ ṣe ìrìn-àjò ní alẹ́ láti Mọ́sálásí Haram sí Mọ́sálásí Aƙsọ̄ tí A fi ìbùkún yí ká, nítorí kí Á lè fi nínú àwọn àmì Wa hàn án. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Olùríran وَءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡكِتَٰبَ وَجَعَلۡنَٰهُ هُدًى لِّبَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ أَلَّا تَتَّخِذُواْ مِن دُونِي وَكِيلًا ٢A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. A sì ṣe é ní ìmọ̀nà fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl. (A sì sọ) pé: “Ẹ má ṣe mú aláàbò kan lẹ́yìn Mi.” ذُرِّيَّةَ مَنۡ حَمَلۡنَا مَعَ نُوحٍۚ إِنَّهُۥ كَانَ عَبۡدًا شَكُورًا ٣(Ẹ jẹ́) àrọ́mọdọ́mọ àwọn tí A gbé gun ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú (Ànábì) Nūh. Dájúdájú (Nūh) jẹ́ ẹrúsìn, olùdúpẹ́ وَقَضَيۡنَآ إِلَىٰ بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ فِي ٱلۡكِتَٰبِ لَتُفۡسِدُنَّ فِي ٱلۡأَرۡضِ مَرَّتَيۡنِ وَلَتَعۡلُنَّ عُلُوًّا كَبِيرًا ٤A sì fi mọ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl nínú Tírà pé: “Dájúdájú ẹ máa ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀ nígbà mejì. Dájúdájú ẹ tún máa ṣègbéraga t’ó tóbi.” فَإِذَا جَآءَ وَعۡدُ أُولَىٰهُمَا بَعَثۡنَا عَلَيۡكُمۡ عِبَادًا لَّنَآ أُوْلِي بَأۡسٍ شَدِيدٍ فَجَاسُواْ خِلَٰلَ ٱلدِّيَارِۚ وَكَانَ وَعۡدًا مَّفۡعُولًا ٥Nítorí náà, nígbà tí àdéhùn fún àkọ́kọ́ nínú méjèèjì bá ṣẹlẹ̀, A máa gbé àwọn ẹrúsìn Wa kan, tí wọ́n lágbára gan-an, dìde si yín. Wọn yóò dá rògbòdìyàn sílẹ̀ láààrin ìlú (yín). Ó jẹ́ àdéhùn kan tí A máa mú ṣẹ ثُمَّ رَدَدۡنَا لَكُمُ ٱلۡكَرَّةَ عَلَيۡهِمۡ وَأَمۡدَدۡنَٰكُم بِأَمۡوَٰلٍ وَبَنِينَ وَجَعَلۡنَٰكُمۡ أَكۡثَرَ نَفِيرًا ٦Lẹ́yìn náà, A dá ìṣẹ́gun lórí wọn padà fun yín. A sì fi àwọn dúkìá àti àwọn ọmọ ṣe ìdẹ̀ra fun yín. A sì ṣe yín ní ìjọ t’ó pọ̀ jùlọ إِنۡ أَحۡسَنتُمۡ أَحۡسَنتُمۡ لِأَنفُسِكُمۡۖ وَإِنۡ أَسَأۡتُمۡ فَلَهَاۚ فَإِذَا جَآءَ وَعۡدُ ٱلۡأٓخِرَةِ لِيَسُـُٔواْ وُجُوهَكُمۡ وَلِيَدۡخُلُواْ ٱلۡمَسۡجِدَ كَمَا دَخَلُوهُ أَوَّلَ مَرَّةٍ وَلِيُتَبِّرُواْ مَا عَلَوۡاْ تَتۡبِيرًا ٧Tí ẹ bá ṣe rere, ẹ ṣe rere fún ẹ̀mí ara yín. Tí ẹ bá sì ṣe aburú, fún ẹ̀mí ara yín ni. Nígbà tí àdéhùn ìkẹ́yìn bá dé, (A óò gbé ọmọ ogun mìíràn dìde) nítorí kí wọ́n lè kó ìbànújẹ́ ba yín àti nítorí kí wọ́n lè wọ inú Mọ́sálásí gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe wọ̀ ọ́ nígbà àkọ́kọ́ àti nítorí kí wọ́n lè pa ohun tí (àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl) jọba lórí rẹ̀ run pátápátá عَسَىٰ رَبُّكُمۡ أَن يَرۡحَمَكُمۡۚ وَإِنۡ عُدتُّمۡ عُدۡنَاۚ وَجَعَلۡنَا جَهَنَّمَ لِلۡكَٰفِرِينَ حَصِيرًا ٨Ó lè jẹ́ pé Olúwa yín máa ṣàánú yín. Tí ẹ bá sì padà (síbi ẹ̀ṣẹ̀), A máa padà (síbi ẹ̀san). A sì ṣe iná Jahanamọ ní ẹ̀wọ̀n fún àwọn aláìgbàgbọ́ إِنَّ هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانَ يَهۡدِي لِلَّتِي هِيَ أَقۡوَمُ وَيُبَشِّرُ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ٱلَّذِينَ يَعۡمَلُونَ ٱلصَّٰلِحَٰتِ أَنَّ لَهُمۡ أَجۡرًا كَبِيرًا ٩Dájúdájú al-Ƙur’ān yìí, ó ń fini mọ̀nà sí ọ̀nà tààrà, ó sì ń fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo t’ó ń ṣe àwọn iṣẹ́ rere ní ìró ìdùnnú pé dájúdájú ẹ̀san t’ó tóbi wà fún wọn وَأَنَّ ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡأٓخِرَةِ أَعۡتَدۡنَا لَهُمۡ عَذَابًا أَلِيمًا ١٠Dájúdájú àwọn tí kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́, A ti pèsè ìyà ẹlẹ́ta-eléro sílẹ̀ dè wọ́n وَيَدۡعُ ٱلۡإِنسَٰنُ بِٱلشَّرِّ دُعَآءَهُۥ بِٱلۡخَيۡرِۖ وَكَانَ ٱلۡإِنسَٰنُ عَجُولًا ١١Ènìyàn ń tọrọ aburú bí ó ṣe ń tọrọ ohun rere; ènìyàn sì jẹ́ olùkánjú وَجَعَلۡنَا ٱلَّيۡلَ وَٱلنَّهَارَ ءَايَتَيۡنِۖ فَمَحَوۡنَآ ءَايَةَ ٱلَّيۡلِ وَجَعَلۡنَآ ءَايَةَ ٱلنَّهَارِ مُبۡصِرَةً لِّتَبۡتَغُواْ فَضۡلًا مِّن رَّبِّكُمۡ وَلِتَعۡلَمُواْ عَدَدَ ٱلسِّنِينَ وَٱلۡحِسَابَۚ وَكُلَّ شَيۡءٍ فَصَّلۡنَٰهُ تَفۡصِيلًا ١٢A ṣe alẹ́ àti ọ̀sán ní àmì méjì; A pa àmì alẹ́ rẹ́, A sì ṣe àmì ọ̀sán ní ìríran1 nítorí kí ẹ lè wá oore àjùlọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín àti nítorí kí ẹ lè mọ òǹkà àwọn ọdún àti ìṣírò. Gbogbo n̄ǹkan ni A ti ṣàlàyé rẹ̀ ní ìfọ́síwẹ́wẹ́ وَكُلَّ إِنسَٰنٍ أَلۡزَمۡنَٰهُ طَٰٓئِرَهُۥ فِي عُنُقِهِۦۖ وَنُخۡرِجُ لَهُۥ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ كِتَٰبًا يَلۡقَىٰهُ مَنشُورًا ١٣Ènìyàn kọ̀ọ̀kan ni A ti la àyànmọ́ àti ìwé iṣẹ́ rẹ̀ bọ̀ lọ́rùn. A sì máa mú ìwé kan jáde fún un ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ó máa pàdé rẹ̀ ní ṣíṣí sílẹ̀ ٱقۡرَأۡ كِتَٰبَكَ كَفَىٰ بِنَفۡسِكَ ٱلۡيَوۡمَ عَلَيۡكَ حَسِيبًا ١٤Ka ìwé (iṣẹ́) rẹ. Ìwọ ti tó ní olùṣírò fún ẹ̀mí ara rẹ lónìí مَّنِ ٱهۡتَدَىٰ فَإِنَّمَا يَهۡتَدِي لِنَفۡسِهِۦۖ وَمَن ضَلَّ فَإِنَّمَا يَضِلُّ عَلَيۡهَاۚ وَلَا تَزِرُ وَازِرَةٌ وِزۡرَ أُخۡرَىٰۗ وَمَا كُنَّا مُعَذِّبِينَ حَتَّىٰ نَبۡعَثَ رَسُولًا ١٥Ẹnikẹ́ni t’ó bá mọ̀nà, ó mọ̀nà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni t’ó bá sì ṣìnà, ó ń ṣìnà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹlẹ́rù-ẹ̀ṣẹ̀ kan kò níí ru ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn. A ò sì níí jẹ àwọn ẹ̀dá níyà títí A fi máa gbé òjíṣẹ́ kan dìde (sí wọn) وَإِذَآ أَرَدۡنَآ أَن نُّهۡلِكَ قَرۡيَةً أَمَرۡنَا مُتۡرَفِيهَا فَفَسَقُواْ فِيهَا فَحَقَّ عَلَيۡهَا ٱلۡقَوۡلُ فَدَمَّرۡنَٰهَا تَدۡمِيرًا ١٦Nígbà tí A bá sì gbèrò láti pa ìlú kan run, A máa pa àwọn onígbẹdẹmukẹ ìlú náà láṣẹ (rere). Àmọ́ wọ́n máa ṣèbàjẹ́ sínú ìlú. Ọ̀rọ̀ náà yó sì kò lé wọn lórí. A ó sì pa wọ́n rẹ́ pátápátá وَكَمۡ أَهۡلَكۡنَا مِنَ ٱلۡقُرُونِ مِنۢ بَعۡدِ نُوحٍۗ وَكَفَىٰ بِرَبِّكَ بِذُنُوبِ عِبَادِهِۦ خَبِيرَۢا بَصِيرًا ١٧Mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parun lẹ́yìn (Ànábì) Nūh! Olúwa rẹ tó ní Alámọ̀tán, Olùríran nípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹrúsìn Rẹ̀ مَّن كَانَ يُرِيدُ ٱلۡعَاجِلَةَ عَجَّلۡنَا لَهُۥ فِيهَا مَا نَشَآءُ لِمَن نُّرِيدُ ثُمَّ جَعَلۡنَا لَهُۥ جَهَنَّمَ يَصۡلَىٰهَا مَذۡمُومًا مَّدۡحُورًا ١٨Ẹni tí ó bá ń gbèrò (oore) ayé yìí (nìkan), A máa taari ohun tí A bá fẹ́ sí i nínú rẹ̀ ní kíákíá fún ẹni tí A bá fẹ́. Lẹ́yìn náà, A máa ṣe iná Jahanamọ fún un; ó máa wọ inú rẹ̀ ní ẹni yẹpẹrẹ, ẹni ẹ̀kọ̀ وَمَنۡ أَرَادَ ٱلۡأٓخِرَةَ وَسَعَىٰ لَهَا سَعۡيَهَا وَهُوَ مُؤۡمِنٌ فَأُوْلَٰٓئِكَ كَانَ سَعۡيُهُم مَّشۡكُورًا ١٩Ẹni tí ó bá sì gbèrò (oore) ọ̀run, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rẹ̀, ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, àwọn wọ̀nyẹn, iṣẹ́ wọn máa jẹ́ àtẹ́wọ́gbà (pẹ̀lú ẹ̀san rere) كُلًّا نُّمِدُّ هَٰٓؤُلَآءِ وَهَٰٓؤُلَآءِ مِنۡ عَطَآءِ رَبِّكَۚ وَمَا كَانَ عَطَآءُ رَبِّكَ مَحۡظُورًا ٢٠Àwọn wọ̀nyí (t’ó ń gbèrò oore ayé) àti àwọn wọ̀nyí (t’ó ń gbèrò oore ọ̀run), gbogbo wọn ni À ń ṣe oore ayé fún láti inú ọrẹ Olúwa rẹ. Wọn kò níí dí ọrẹ Olúwa rẹ lọ́wọ́ (fún ìkíní kejì nílé ayé) ٱنظُرۡ كَيۡفَ فَضَّلۡنَا بَعۡضَهُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٍۚ وَلَلۡأٓخِرَةُ أَكۡبَرُ دَرَجَٰتٍ وَأَكۡبَرُ تَفۡضِيلًا ٢١Wo bí A ṣe fún apá kan wọn lóore àjùlọ lórí apá kan (nílé ayé). Dájúdájú tọ̀run tún tóbi jùlọ ní ipò, ó sì tóbi jùlọ lóore àjùlọ لَّا تَجۡعَلۡ مَعَ ٱللَّهِ إِلَٰهًا ءَاخَرَ فَتَقۡعُدَ مَذۡمُومًا مَّخۡذُولًا ٢٢Má ṣe mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu nítorí kí o má baà jókòó (sínú Iná) ní ẹni àbùkù, ẹni tí wọ́n máa dá ìṣòro rẹ̀ dá ۞ وَقَضَىٰ رَبُّكَ أَلَّا تَعۡبُدُوٓاْ إِلَّآ إِيَّاهُ وَبِٱلۡوَٰلِدَيۡنِ إِحۡسَٰنًاۚ إِمَّا يَبۡلُغَنَّ عِندَكَ ٱلۡكِبَرَ أَحَدُهُمَآ أَوۡ كِلَاهُمَا فَلَا تَقُل لَّهُمَآ أُفٍّ وَلَا تَنۡهَرۡهُمَا وَقُل لَّهُمَا قَوۡلًا كَرِيمًا ٢٣Olúwa rẹ pàṣẹ pé: “Ẹ má ṣe jọ́sìn fún ẹnì kan àyàfi Òun. Kí ẹ sì ṣe dáadáa sí àwọn òbí (yín) méjèèjì. Tí ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì tàbí ìkíní kejì wọn bá dàgbà sí ọ lọ́dọ̀, má ṣe ṣíọ̀ sí wọn, má ṣe jágbe mọ́ wọn. Máa bá àwọn méjèèjì sọ ọ̀rọ̀ àpọ́nlé وَٱخۡفِضۡ لَهُمَا جَنَاحَ ٱلذُّلِّ مِنَ ٱلرَّحۡمَةِ وَقُل رَّبِّ ٱرۡحَمۡهُمَا كَمَا رَبَّيَانِي صَغِيرًا ٢٤Kí ó sì rẹ apá rẹ nílẹ̀ láti fi bọ̀wọ̀ fún àwọn méjèèjì nípa ṣíṣe àánú wọn. Kí o sì sọ pé: "Olúwa Ẹlẹ́dàá mi, kẹ́ àwọn méjèèjì gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe rè mí ní kékeré رَّبُّكُمۡ أَعۡلَمُ بِمَا فِي نُفُوسِكُمۡۚ إِن تَكُونُواْ صَٰلِحِينَ فَإِنَّهُۥ كَانَ لِلۡأَوَّٰبِينَ غَفُورًا ٢٥Olúwa yín nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ń bẹ nínú ẹ̀mí yín, tí ẹ bá jẹ́ ẹni rere. Dájúdájú Ó ń jẹ́ Aláforíjìn fún àwọn olùronúpìwàdà وَءَاتِ ذَا ٱلۡقُرۡبَىٰ حَقَّهُۥ وَٱلۡمِسۡكِينَ وَٱبۡنَ ٱلسَّبِيلِ وَلَا تُبَذِّرۡ تَبۡذِيرًا ٢٦Ẹ fún ẹbí ní ẹ̀tọ́ rẹ̀. (Ẹ fún) mẹ̀kúnnù àti onírìn-àjò tí agara dá (ní n̄ǹkan). Kí ẹ sì má ṣe ná dúkìá yín ní ìná-àpà إِنَّ ٱلۡمُبَذِّرِينَ كَانُوٓاْ إِخۡوَٰنَ ٱلشَّيَٰطِينِۖ وَكَانَ ٱلشَّيۡطَٰنُ لِرَبِّهِۦ كَفُورًا ٢٧Dájúdájú àwọn àpà, wọ́n jẹ́ ọmọ ìyá Èṣù. Aláìmoore sì ni Èṣù jẹ́ sí Olúwa rẹ̀ وَإِمَّا تُعۡرِضَنَّ عَنۡهُمُ ٱبۡتِغَآءَ رَحۡمَةٍ مِّن رَّبِّكَ تَرۡجُوهَا فَقُل لَّهُمۡ قَوۡلًا مَّيۡسُورًا ٢٨Tí o bá ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn (ìyẹn àwọn aláìní) láti wá ìkẹ́ kan tí ò ń retí láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, bá wọn sọ̀rọ̀ ẹ̀lẹ̀ وَلَا تَجۡعَلۡ يَدَكَ مَغۡلُولَةً إِلَىٰ عُنُقِكَ وَلَا تَبۡسُطۡهَا كُلَّ ٱلۡبَسۡطِ فَتَقۡعُدَ مَلُومًا مَّحۡسُورًا ٢٩Má di ọwọ́ rẹ mọ́ ọrùn rẹ (má ya ahun), má sì tẹ́ ẹ sílẹ̀ tán pátápátá (má ya àpà), kí o má baà jókòó kalẹ̀ ní ẹni èébú (tí o bá jẹ́ ahun), ẹni tí kò níí sí lọ́wọ́ rẹ̀ mọ́ (tí o bá jẹ́ àpà) إِنَّ رَبَّكَ يَبۡسُطُ ٱلرِّزۡقَ لِمَن يَشَآءُ وَيَقۡدِرُۚ إِنَّهُۥ كَانَ بِعِبَادِهِۦ خَبِيرَۢا بَصِيرًا ٣٠Dájúdájú Olúwa rẹ l’Ó ń tẹ́ arísìkí sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹlòmíìràn). Dájúdájú Ó ń jẹ́ Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀, Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ وَلَا تَقۡتُلُوٓاْ أَوۡلَٰدَكُمۡ خَشۡيَةَ إِمۡلَٰقٍۖ نَّحۡنُ نَرۡزُقُهُمۡ وَإِيَّاكُمۡۚ إِنَّ قَتۡلَهُمۡ كَانَ خِطۡـًٔا كَبِيرًا ٣١Ẹ má pa àwọn ọmọ yín nítorí ìpáyà òṣì. Àwa l’À ń pèsè fún àwọn àti ẹ̀yin. Dájúdájú pípa wọ́n jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ t’ó tóbi وَلَا تَقۡرَبُواْ ٱلزِّنَىٰٓۖ إِنَّهُۥ كَانَ فَٰحِشَةً وَسَآءَ سَبِيلًا ٣٢Ẹ má ṣe súnmọ́ àgbèrè. Dájúdájú ó jẹ́ ìwà burúkú. Ó sì burú ní ojú ọ̀nà وَلَا تَقۡتُلُواْ ٱلنَّفۡسَ ٱلَّتِي حَرَّمَ ٱللَّهُ إِلَّا بِٱلۡحَقِّۗ وَمَن قُتِلَ مَظۡلُومًا فَقَدۡ جَعَلۡنَا لِوَلِيِّهِۦ سُلۡطَٰنًا فَلَا يُسۡرِف فِّي ٱلۡقَتۡلِۖ إِنَّهُۥ كَانَ مَنصُورًا ٣٣Ẹ má pa ẹ̀mí tí Allāhu ṣe (pípa rẹ̀) ní èèwọ̀ àyàfi ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Ẹni tí wọ́n bá pa ní ìpa àbòsí, dájúdájú A ti fún alámòjúútó rẹ̀ ní agbára (láti gbẹ̀san). Nítorí náà, kí ẹnikẹ́ni má ṣe tayọ ẹnu- àlà níbi ìpànìyàn (nítorí pé) dájúdájú A máa ran (ẹbí òkú) lọ́wọ́ (láti gbẹ̀san) وَلَا تَقۡرَبُواْ مَالَ ٱلۡيَتِيمِ إِلَّا بِٱلَّتِي هِيَ أَحۡسَنُ حَتَّىٰ يَبۡلُغَ أَشُدَّهُۥۚ وَأَوۡفُواْ بِٱلۡعَهۡدِۖ إِنَّ ٱلۡعَهۡدَ كَانَ مَسۡـُٔولًا ٣٤Ẹ má ṣe súnmọ́ dúkìá ọmọ òrukàn, àyàfi ní ọ̀nà t’ó dára jùlọ, títí ó fi máa dàgbà. Kí ẹ sì mú àdéhùn ṣẹ. Dájúdájú àdéhùn jẹ́ ohun tí A ó bèèrè nípa rẹ̀ وَأَوۡفُواْ ٱلۡكَيۡلَ إِذَا كِلۡتُمۡ وَزِنُواْ بِٱلۡقِسۡطَاسِ ٱلۡمُسۡتَقِيمِۚ ذَٰلِكَ خَيۡرٌ وَأَحۡسَنُ تَأۡوِيلًا ٣٥Ẹ wọn òṣùwọ̀n kún nígbà tí ẹ bá wọ̀n ọ́n. Ẹ fi ìwọ̀n t’ó tọ́ wọ̀n ọ́n. Ìyẹn lóore jùlọ, ó sì dára jùlọ ní ìkángun وَلَا تَقۡفُ مَا لَيۡسَ لَكَ بِهِۦ عِلۡمٌۚ إِنَّ ٱلسَّمۡعَ وَٱلۡبَصَرَ وَٱلۡفُؤَادَ كُلُّ أُوْلَٰٓئِكَ كَانَ عَنۡهُ مَسۡـُٔولًا ٣٦Má ṣe tẹ̀lé ohun tí ìwọ kò nímọ̀ nípa rẹ̀. Dájúdájú ìgbọ́rọ̀, ìríran àti ọkàn; ìkọ̀ọ̀kan ìwọ̀nyẹn ni A óò bèèrè nípa rẹ̀ وَلَا تَمۡشِ فِي ٱلۡأَرۡضِ مَرَحًاۖ إِنَّكَ لَن تَخۡرِقَ ٱلۡأَرۡضَ وَلَن تَبۡلُغَ ٱلۡجِبَالَ طُولًا ٣٧Má ṣe rìn lórí ilẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga; dájúdájú ìwọ kò lè dá ilẹ̀ lu, ìwọ kò sì lè ga tó àpáta كُلُّ ذَٰلِكَ كَانَ سَيِّئُهُۥ عِندَ رَبِّكَ مَكۡرُوهًا ٣٨Gbogbo ìyẹn, aburú rẹ̀ jẹ́ ohun ìkórira lọ́dọ̀ Olúwa rẹ ذَٰلِكَ مِمَّآ أَوۡحَىٰٓ إِلَيۡكَ رَبُّكَ مِنَ ٱلۡحِكۡمَةِۗ وَلَا تَجۡعَلۡ مَعَ ٱللَّهِ إِلَٰهًا ءَاخَرَ فَتُلۡقَىٰ فِي جَهَنَّمَ مَلُومًا مَّدۡحُورًا ٣٩Ìyẹn wà nínú ohun tí Olúwa rẹ fi ránṣẹ́ sí ọ nínú ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n (al-Ƙur’ān). Má ṣe mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu kí wọ́n má baà jù ọ́ sínú iná Jahanamọ ní ẹni àbùkù, ẹni ẹ̀kọ̀ أَفَأَصۡفَىٰكُمۡ رَبُّكُم بِٱلۡبَنِينَ وَٱتَّخَذَ مِنَ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةِ إِنَٰثًاۚ إِنَّكُمۡ لَتَقُولُونَ قَوۡلًا عَظِيمًا ٤٠Ṣé Olúwa yín fi àwọn ọmọkùnrin ṣà yín lẹ́ṣà, Òun wá mú àwọn ọmọbìnrin nínú àwọn mọlāika (ní tiRẹ̀)? Dájúdájú ẹ mà ń sọ ọ̀rọ̀ ńlá (t’ó burú) وَلَقَدۡ صَرَّفۡنَا فِي هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانِ لِيَذَّكَّرُواْ وَمَا يَزِيدُهُمۡ إِلَّا نُفُورًا ٤١Dájúdájú A ti ṣe àlàyé sínú al- Ƙur’ān yìí nítorí kí wọ́n lè lo ìṣítí. Síbẹ̀síbẹ̀ kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe sísá (fún ìrántí) قُل لَّوۡ كَانَ مَعَهُۥٓ ءَالِهَةٌ كَمَا يَقُولُونَ إِذًا لَّٱبۡتَغَوۡاْ إِلَىٰ ذِي ٱلۡعَرۡشِ سَبِيلًا ٤٢Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé àwọn ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń wí, wọn ìbá wá ọ̀nà láti súnmọ́ (Allāhu) Onítẹ̀ẹ́-ọlá ni.” سُبۡحَٰنَهُۥ وَتَعَٰلَىٰ عَمَّا يَقُولُونَ عُلُوًّا كَبِيرًا ٤٣Mímọ́ ni fún Un. Ó sì ga ní gíga t’ó tóbi tayọ ohun tí wọ́n ń wí (ní àìda nípa Rẹ̀) تُسَبِّحُ لَهُ ٱلسَّمَٰوَٰتُ ٱلسَّبۡعُ وَٱلۡأَرۡضُ وَمَن فِيهِنَّۚ وَإِن مِّن شَيۡءٍ إِلَّا يُسَبِّحُ بِحَمۡدِهِۦ وَلَٰكِن لَّا تَفۡقَهُونَ تَسۡبِيحَهُمۡۚ إِنَّهُۥ كَانَ حَلِيمًا غَفُورًا ٤٤Àwọn sánmọ̀ méjèèje, ilẹ̀ àti àwọn tí wọ́n wà nínú wọn ń ṣe àfọ̀mọ́ fún Un. Kò sì sí kiní kan àfi kí ó ṣe àfọ̀mọ́ àti ìdúpẹ́ fún Un. Ṣùgbọ́n ẹ kò lè gbọ́ àgbọ́yé àfọ̀mọ́ wọn. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Aláfaradà, Aláforíjìn وَإِذَا قَرَأۡتَ ٱلۡقُرۡءَانَ جَعَلۡنَا بَيۡنَكَ وَبَيۡنَ ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡأٓخِرَةِ حِجَابًا مَّسۡتُورًا ٤٥Nígbà tí o bá ń ké al-Ƙur’ān, A máa fi gàgá ààbò sáààrin ìwọ àti àwọn tí kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́ وَجَعَلۡنَا عَلَىٰ قُلُوبِهِمۡ أَكِنَّةً أَن يَفۡقَهُوهُ وَفِيٓ ءَاذَانِهِمۡ وَقۡرًاۚ وَإِذَا ذَكَرۡتَ رَبَّكَ فِي ٱلۡقُرۡءَانِ وَحۡدَهُۥ وَلَّوۡاْ عَلَىٰٓ أَدۡبَٰرِهِمۡ نُفُورًا ٤٦A fi èbìbò bo ọkàn wọn nítorí kí wọ́n má baà gbọ́ ọ yé. (A tún fi) èdídí sínú etí wọn. Nígbà tí o bá sì dárúkọ Olúwa rẹ nìkan ṣoṣo nínú al-Ƙur’ān, wọ́n máa pẹ̀yìn wọn dà láti sá lọ نَّحۡنُ أَعۡلَمُ بِمَا يَسۡتَمِعُونَ بِهِۦٓ إِذۡ يَسۡتَمِعُونَ إِلَيۡكَ وَإِذۡ هُمۡ نَجۡوَىٰٓ إِذۡ يَقُولُ ٱلظَّٰلِمُونَ إِن تَتَّبِعُونَ إِلَّا رَجُلًا مَّسۡحُورًا ٤٧Àwa nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń gbọ́ nígbà tí wọ́n bá ń tẹ́tí sí ọ àti nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, nígbà tí àwọn alábòsí bá ń wí pé: “Ẹ kò tẹ̀lé ẹnì kan bí kò ṣe ọkùnrin eléèdì kan.” ٱنظُرۡ كَيۡفَ ضَرَبُواْ لَكَ ٱلۡأَمۡثَالَ فَضَلُّواْ فَلَا يَسۡتَطِيعُونَ سَبِيلًا ٤٨Wo bí wọ́n ṣe fún ọ ní àwọn àfiwé (burúkú)! Nítorí náà, wọ́n ti ṣìnà; wọn kò sì lè mọ̀nà وَقَالُوٓاْ أَءِذَا كُنَّا عِظَٰمًا وَرُفَٰتًا أَءِنَّا لَمَبۡعُوثُونَ خَلۡقًا جَدِيدًا ٤٩Wọ́n wí pé: “Ṣé nígbà tí a bá ti di egungun, tí a ti jẹrà, ṣé Wọ́n máa gbé wa dìde ní ẹ̀dá titun ni?” ۞ قُلۡ كُونُواْ حِجَارَةً أَوۡ حَدِيدًا ٥٠Sọ pé: "Ẹ di òkúta tàbí irin أَوۡ خَلۡقًا مِّمَّا يَكۡبُرُ فِي صُدُورِكُمۡۚ فَسَيَقُولُونَ مَن يُعِيدُنَاۖ قُلِ ٱلَّذِي فَطَرَكُمۡ أَوَّلَ مَرَّةٍۚ فَسَيُنۡغِضُونَ إِلَيۡكَ رُءُوسَهُمۡ وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هُوَۖ قُلۡ عَسَىٰٓ أَن يَكُونَ قَرِيبًا ٥١Tàbí (kí ẹ di) ẹ̀dá kan nínú ohun tí ó tóbi nínú ọkàn yín." Síbẹ̀síbẹ̀ wọn yóò wí pé: “Ta ni Ó máa dá wa padà (fún àjíǹde)?” Sọ pé: “Ẹni tí Ó pilẹ̀ ìṣẹ̀dá yín ní ìgbà àkọ́kọ́ ni.” Síbẹ̀síbẹ̀ wọn yóò mi orí wọn sí ọ (ní ti àbùkù) Nígbà náà, wọn yóò wí pé: “Ìgbà wo ni?” Sọ pé: “Ó lè jẹ́ pé ó ti súnmọ́.” يَوۡمَ يَدۡعُوكُمۡ فَتَسۡتَجِيبُونَ بِحَمۡدِهِۦ وَتَظُنُّونَ إِن لَّبِثۡتُمۡ إِلَّا قَلِيلًا ٥٢Ọjọ́ tí Allāhu yóò pè yín. Ẹ sì máa jẹ́pè pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Un. Ẹ sì máa rò pé ẹ kò gbé ilé ayé bí kò ṣe fún ìgbà díẹ̀ وَقُل لِّعِبَادِي يَقُولُواْ ٱلَّتِي هِيَ أَحۡسَنُۚ إِنَّ ٱلشَّيۡطَٰنَ يَنزَغُ بَيۡنَهُمۡۚ إِنَّ ٱلشَّيۡطَٰنَ كَانَ لِلۡإِنسَٰنِ عَدُوًّا مُّبِينًا ٥٣Sọ fún àwọn ẹrúsìn Mi pé kí wọ́n sọ ọ̀rọ̀ èyí t’ó dára jùlọ. Dájúdájú Èṣù yóò máa dá yánpọn-yánrin sílẹ̀ láààrin wọn. Dájúdájú Èṣù jẹ́ ọ̀tá pọ́nńbélé fún ènìyàn رَّبُّكُمۡ أَعۡلَمُ بِكُمۡۖ إِن يَشَأۡ يَرۡحَمۡكُمۡ أَوۡ إِن يَشَأۡ يُعَذِّبۡكُمۡۚ وَمَآ أَرۡسَلۡنَٰكَ عَلَيۡهِمۡ وَكِيلًا ٥٤Olúwa yín nímọ̀ jùlọ nípa yín. Tí Ó bá fẹ́, Ó máa kẹ yín. Tàbí tí Ó bá sì fẹ́, Ó máa jẹ yín níyà. A kò rán ọ pé kí o jẹ́ olùṣọ́ lórí wọn وَرَبُّكَ أَعۡلَمُ بِمَن فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۗ وَلَقَدۡ فَضَّلۡنَا بَعۡضَ ٱلنَّبِيِّـۧنَ عَلَىٰ بَعۡضٍۖ وَءَاتَيۡنَا دَاوُۥدَ زَبُورًا ٥٥Olúwa rẹ nímọ̀ jùlọ nípa àwọn t’ó ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Dájúdájú A ti ṣe oore àjùlọ fún apá kan àwọn Ànábì lórí apá kan. A sì fún (Ànábì) Dāwūd ní Zabūr قُلِ ٱدۡعُواْ ٱلَّذِينَ زَعَمۡتُم مِّن دُونِهِۦ فَلَا يَمۡلِكُونَ كَشۡفَ ٱلضُّرِّ عَنكُمۡ وَلَا تَحۡوِيلًا ٥٦Sọ pé: "Ẹ pe àwọn tí ẹ sọ nípa wọn láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ pé wọ́n jẹ́ ọlọ́hun lẹ́yìn Rẹ̀, (ẹ máa rí i pé) wọn kò ní ìkápá láti gbé ìnira kúrò tàbí láti ṣe ìyípadà kan fun yín أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ يَدۡعُونَ يَبۡتَغُونَ إِلَىٰ رَبِّهِمُ ٱلۡوَسِيلَةَ أَيُّهُمۡ أَقۡرَبُ وَيَرۡجُونَ رَحۡمَتَهُۥ وَيَخَافُونَ عَذَابَهُۥٓۚ إِنَّ عَذَابَ رَبِّكَ كَانَ مَحۡذُورًا ٥٧Àwọn wọ̀nyẹn tí wọ́n ń pè (lẹ́yìn Rẹ̀) ń wá àtẹ̀gùn sọ́dọ̀ Olúwa wọn ni! - Èwo nínú wọn l’ó súnmọ́ (Allāhu) jùlọ (báyìí)? – Àwọn náà ń retí ìkẹ́ Allāhu, wọ́n sì ń páyà ìyà Rẹ̀. Dájúdájú ìyà Olúwa rẹ jẹ́ ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún وَإِن مِّن قَرۡيَةٍ إِلَّا نَحۡنُ مُهۡلِكُوهَا قَبۡلَ يَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِ أَوۡ مُعَذِّبُوهَا عَذَابًا شَدِيدًاۚ كَانَ ذَٰلِكَ فِي ٱلۡكِتَٰبِ مَسۡطُورًا ٥٨Kò sí ìlú kan (t’ó ṣàbòsí) àfi kí Àwa pa á rẹ́ ṣíwájú Ọjọ́ Àjíǹde tàbí kí Á jẹ ẹ́ níyà líle. Ìyẹn wà ní kíkọ sílẹ̀ nínú Tírà (Laohul-Mahfūṭḥ) وَمَا مَنَعَنَآ أَن نُّرۡسِلَ بِٱلۡأٓيَٰتِ إِلَّآ أَن كَذَّبَ بِهَا ٱلۡأَوَّلُونَۚ وَءَاتَيۡنَا ثَمُودَ ٱلنَّاقَةَ مُبۡصِرَةً فَظَلَمُواْ بِهَاۚ وَمَا نُرۡسِلُ بِٱلۡأٓيَٰتِ إِلَّا تَخۡوِيفًا ٥٩Àti pé kò sí ohun tí ó dí Wa lọ́wọ́ láti fi àwọn àmì (iṣẹ́ ìyanu) ránṣẹ́ bí kò ṣe pé àwọn ẹni àkọ́kọ́ ti pè é nírọ́. A fún ìjọ Thamūd ní abo ràkúnmí; (àmì) t’ó fojú hàn kedere ni. Àmọ́ wọ́n ṣàbòsí sí i. A ò sì níí fi àwọn àmì ránṣẹ́ bí kò ṣe fún ìdẹ́rùbà وَإِذۡ قُلۡنَا لَكَ إِنَّ رَبَّكَ أَحَاطَ بِٱلنَّاسِۚ وَمَا جَعَلۡنَا ٱلرُّءۡيَا ٱلَّتِيٓ أَرَيۡنَٰكَ إِلَّا فِتۡنَةً لِّلنَّاسِ وَٱلشَّجَرَةَ ٱلۡمَلۡعُونَةَ فِي ٱلۡقُرۡءَانِۚ وَنُخَوِّفُهُمۡ فَمَا يَزِيدُهُمۡ إِلَّا طُغۡيَٰنًا كَبِيرًا ٦٠(Rántí) nígbà tí A sọ fún ọ pé: “Dájúdájú Olúwa rẹ yí àwọn ènìyàn po (pẹ̀lú agbára Rẹ̀). Àti pé A kò ṣe ìran (wíwò) tí A fi hàn ọ́ àti igi (zaƙūm) tí A ṣẹ́bi lé nínú al-Ƙur’ān ní kiní kan bí kò ṣe pé (ó jẹ́) àdánwò fún àwọn ènìyàn. À ń dẹ́rù bà wọ́n, àmọ́ kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe ìwà àgbéré t’ó tóbi وَإِذۡ قُلۡنَا لِلۡمَلَٰٓئِكَةِ ٱسۡجُدُواْ لِأٓدَمَ فَسَجَدُوٓاْ إِلَّآ إِبۡلِيسَ قَالَ ءَأَسۡجُدُ لِمَنۡ خَلَقۡتَ طِينًا ٦١(Rántí) nígbà tí A sọ fún àwọn mọlāika pé: "Ẹ forí kanlẹ̀ kí (Ànábì) Ādam." Wọ́n sì forí kanlẹ̀ kí i àfi ’Iblīs. Ó wí pé: “Ṣé kí n̄g forí kanlẹ̀ kí ẹni tí O fi amọ̀ ṣẹ̀dá rẹ̀ ni?” قَالَ أَرَءَيۡتَكَ هَٰذَا ٱلَّذِي كَرَّمۡتَ عَلَيَّ لَئِنۡ أَخَّرۡتَنِ إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِ لَأَحۡتَنِكَنَّ ذُرِّيَّتَهُۥٓ إِلَّا قَلِيلًا ٦٢Ó wí pé: "Sọ fún mi nípa èyí tí O gbé àpọ́nlé fún lórí mí, (nítorí kí ni?) Dájúdájú tí O bá lè lọ́ mi lára di Ọjọ́ Àjíǹde, dájúdájú mo máa jẹgàba lórí àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ àfi àwọn díẹ̀ قَالَ ٱذۡهَبۡ فَمَن تَبِعَكَ مِنۡهُمۡ فَإِنَّ جَهَنَّمَ جَزَآؤُكُمۡ جَزَآءً مَّوۡفُورًا ٦٣(Allāhu) sọ pé: "Máa lọ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ọ nínú wọn, dájúdájú iná Jahanamọ ni ẹ̀san yín. (Ó sì jẹ́) ẹ̀san t’ó kún kẹ́kẹ́ وَٱسۡتَفۡزِزۡ مَنِ ٱسۡتَطَعۡتَ مِنۡهُم بِصَوۡتِكَ وَأَجۡلِبۡ عَلَيۡهِم بِخَيۡلِكَ وَرَجِلِكَ وَشَارِكۡهُمۡ فِي ٱلۡأَمۡوَٰلِ وَٱلۡأَوۡلَٰدِ وَعِدۡهُمۡۚ وَمَا يَعِدُهُمُ ٱلشَّيۡطَٰنُ إِلَّا غُرُورًا ٦٤Fi ohùn rẹ kó ẹni tí agbára rẹ bá ká nínú wọn láyà jẹ. Fi àwọn ọmọ ogun ẹlẹ́sin rẹ àti ọmọ ogun ẹlẹ́sẹ̀ rẹ pè wọ́n (sínú ìṣìnà). Kópa pẹ̀lú wọn nínú àwọn dúkìá àti àwọn ọmọ. Kí o sì ṣe ìlérí fún wọn." Èṣù kò sì níí ṣe ìlérí fún wọn bí kò ṣe ẹ̀tàn إِنَّ عِبَادِي لَيۡسَ لَكَ عَلَيۡهِمۡ سُلۡطَٰنٌۚ وَكَفَىٰ بِرَبِّكَ وَكِيلًا ٦٥Dájúdájú àwọn ẹrúsìn Mi, kò sí agbára kan fún ọ lórí wọn. Olúwa rẹ sì tó ní Olùṣọ́ رَّبُّكُمُ ٱلَّذِي يُزۡجِي لَكُمُ ٱلۡفُلۡكَ فِي ٱلۡبَحۡرِ لِتَبۡتَغُواْ مِن فَضۡلِهِۦٓۚ إِنَّهُۥ كَانَ بِكُمۡ رَحِيمًا ٦٦Olúwa yín ni Ẹni t’Ó ń mú ọkọ̀ ojú-omi rìn fun yín nítorí kí ẹ lè wá nínú oore àjùlọ Rẹ̀. Dájúdájú Ó ń jẹ́ Aláàánú fun yín وَإِذَا مَسَّكُمُ ٱلضُّرُّ فِي ٱلۡبَحۡرِ ضَلَّ مَن تَدۡعُونَ إِلَّآ إِيَّاهُۖ فَلَمَّا نَجَّىٰكُمۡ إِلَى ٱلۡبَرِّ أَعۡرَضۡتُمۡۚ وَكَانَ ٱلۡإِنسَٰنُ كَفُورًا ٦٧Nígbà tí ìnira bá fọwọ́ bà yín lójú omi, ẹni tí ẹ̀ ń pè yó sì dòfo (mọ yín lọ́wọ́) àfi Òun nìkan (Allāhu). Nígbà ti Ó bá sì gbà yín là (tí ẹ) gúnlẹ̀, ẹ̀ ń gbúnrí (kúrò lọ́dọ̀ Rẹ̀). Ènìyàn sì jẹ́ aláìmoore أَفَأَمِنتُمۡ أَن يَخۡسِفَ بِكُمۡ جَانِبَ ٱلۡبَرِّ أَوۡ يُرۡسِلَ عَلَيۡكُمۡ حَاصِبًا ثُمَّ لَا تَجِدُواْ لَكُمۡ وَكِيلًا ٦٨Ṣé ẹ fọkàn balẹ̀ pé (Allāhu) kò lè mú apá kan ilẹ̀ ri mọ yín lẹ́sẹ̀ ni? Tàbí pé kò lè fi òkúta iná ránṣẹ́ si yín? Lẹ́yìn náà, ẹ̀ o sì níí rí olùṣọ́ kan tí ó máa gbà yín là أَمۡ أَمِنتُمۡ أَن يُعِيدَكُمۡ فِيهِ تَارَةً أُخۡرَىٰ فَيُرۡسِلَ عَلَيۡكُمۡ قَاصِفًا مِّنَ ٱلرِّيحِ فَيُغۡرِقَكُم بِمَا كَفَرۡتُمۡ ثُمَّ لَا تَجِدُواْ لَكُمۡ عَلَيۡنَا بِهِۦ تَبِيعًا ٦٩Tàbí ẹ fọkàn balẹ̀ pé (Allāhu) kò níí padà mu yín wá sí (orí omi) nígbà mìíràn ni; tí Ó máa rán ìjì atẹ́gùn si yín, tí Ó sì máa tẹ̀ yín rì (sínú omi) nítorí pé ẹ ṣàì moore? Lẹ́yìn náà, ẹ ò sì níí rí olùrànlọ́wọ́ kan t’ó máa ba yín gbẹ̀san lára Wa ۞ وَلَقَدۡ كَرَّمۡنَا بَنِيٓ ءَادَمَ وَحَمَلۡنَٰهُمۡ فِي ٱلۡبَرِّ وَٱلۡبَحۡرِ وَرَزَقۡنَٰهُم مِّنَ ٱلطَّيِّبَٰتِ وَفَضَّلۡنَٰهُمۡ عَلَىٰ كَثِيرٍ مِّمَّنۡ خَلَقۡنَا تَفۡضِيلًا ٧٠Dájúdájú A ṣe àpọ́nlé fún àwọn ọmọ (Ànábì) Ādam; A gbé wọn rìn lórí ilẹ̀ àti lórí omi; A fún wọn ní ìjẹ-ìmu nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa; A sì ṣoore àjùlọ fún wọn gan-an lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn tí A dá يَوۡمَ نَدۡعُواْ كُلَّ أُنَاسِۭ بِإِمَٰمِهِمۡۖ فَمَنۡ أُوتِيَ كِتَٰبَهُۥ بِيَمِينِهِۦ فَأُوْلَٰٓئِكَ يَقۡرَءُونَ كِتَٰبَهُمۡ وَلَا يُظۡلَمُونَ فَتِيلًا ٧١Ní ọjọ́ tí A óò máa pe gbogbo ènìyàn pẹ̀lú aṣíwájú wọn . Nígbà náà, ẹnikẹ́ni tí A bá fún ní ìwé (iṣẹ́) rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni wọn yóò máa ka ìwé (iṣẹ́) wọn. A ò sì níí ṣàbòsí bín-íntín sí wọn وَمَن كَانَ فِي هَٰذِهِۦٓ أَعۡمَىٰ فَهُوَ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ أَعۡمَىٰ وَأَضَلُّ سَبِيلًا ٧٢Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ afọ́jú (nípa ’Islām) nílé ayé yìí, òun ni afọ́jú ní ọ̀run. Ó sì (ti) ṣìnà jùlọ وَإِن كَادُواْ لَيَفۡتِنُونَكَ عَنِ ٱلَّذِيٓ أَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡكَ لِتَفۡتَرِيَ عَلَيۡنَا غَيۡرَهُۥۖ وَإِذًا لَّٱتَّخَذُوكَ خَلِيلًا ٧٣Wọ́n fẹ́ẹ̀ kó ìyọnu bá ọ nípa n̄ǹkan tí A mú wá fún ọ ní ìmísí nítorí kí o lè hun n̄ǹkan mìíràn t’ó yàtọ̀ sí i nípa Wa. Nígbà náà, wọn ìbá mú ọ ní ọ̀rẹ́ àyò وَلَوۡلَآ أَن ثَبَّتۡنَٰكَ لَقَدۡ كِدتَّ تَرۡكَنُ إِلَيۡهِمۡ شَيۡـًٔا قَلِيلًا ٧٤Tí kò bá jẹ́ pé A fi ẹsẹ̀ rẹ rinlẹ̀ ni, dájúdájú o fẹ́ẹ̀ fi n̄ǹkan díẹ̀ tẹ̀ sí ọ̀dọ̀ wọn إِذًا لَّأَذَقۡنَٰكَ ضِعۡفَ ٱلۡحَيَوٰةِ وَضِعۡفَ ٱلۡمَمَاتِ ثُمَّ لَا تَجِدُ لَكَ عَلَيۡنَا نَصِيرًا ٧٥Nígbà náà, Àwa ìbá jẹ́ kí o tọ́ ìlọ́po (ìyà) ìṣẹ̀mí ayé àti ìlọ́po (ìyà lẹ́yìn) ikú wò. Lẹ́yìn náà, ìwọ kò níí rí olùrànlọ́wọ́ kan tí ó máa gbà ọ́ sílẹ̀ níbi ìyà Wa وَإِن كَادُواْ لَيَسۡتَفِزُّونَكَ مِنَ ٱلۡأَرۡضِ لِيُخۡرِجُوكَ مِنۡهَاۖ وَإِذًا لَّا يَلۡبَثُونَ خِلَٰفَكَ إِلَّا قَلِيلًا ٧٦Wọ́n fẹ́ẹ̀ kó ọ láyà jẹ nínú ìlú nítorí kí wọ́n lè lé ọ jáde kúrò nínú rẹ̀. Nígbà náà, àwọn náà kò níí wà nínú rẹ̀ lẹ́yìn rẹ tayọ ìgbà díẹ̀ سُنَّةَ مَن قَدۡ أَرۡسَلۡنَا قَبۡلَكَ مِن رُّسُلِنَاۖ وَلَا تَجِدُ لِسُنَّتِنَا تَحۡوِيلًا ٧٧(Èyí jẹ́) ìṣe (Allāhu) lórí àwọn tí A ti rán níṣẹ́ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Wa ṣíwájú rẹ. O ò sì níí rí ìyípadà kan fún ìṣe Wa أَقِمِ ٱلصَّلَوٰةَ لِدُلُوكِ ٱلشَّمۡسِ إِلَىٰ غَسَقِ ٱلَّيۡلِ وَقُرۡءَانَ ٱلۡفَجۡرِۖ إِنَّ قُرۡءَانَ ٱلۡفَجۡرِ كَانَ مَشۡهُودًا ٧٨Gbé ìrun kíkí dúró ní (ìgbà tí) òòrùn bá yẹ̀tàrí títí di ìgbà tí alẹ́ yóò fi lẹ́. Àti pé ìrun Subh, dájúdájú ìrun Subh jẹ́ ohun tí (àwọn mọlāika alẹ́ àti ọ̀sán) yóò jẹ́rìí sí وَمِنَ ٱلَّيۡلِ فَتَهَجَّدۡ بِهِۦ نَافِلَةً لَّكَ عَسَىٰٓ أَن يَبۡعَثَكَ رَبُّكَ مَقَامًا مَّحۡمُودًا ٧٩Àti pé nínú òru, fi kíké al-Ƙur’ān (lórí ìrun) ṣàì sùn. (Èyí jẹ́) iṣẹ́ àṣegbọrẹ fún ọ. Láìpẹ́, Olúwa rẹ yóò gbé ọ sí àyè ọpẹ́ وَقُل رَّبِّ أَدۡخِلۡنِي مُدۡخَلَ صِدۡقٍ وَأَخۡرِجۡنِي مُخۡرَجَ صِدۡقٍ وَٱجۡعَل لِّي مِن لَّدُنكَ سُلۡطَٰنًا نَّصِيرًا ٨٠Sọ pé: “Olúwa mi, mú mi wọ inú ìlú ní ìwọ̀lú ọ̀nà òdodo. Mú mi jáde kúrò nínú ìlú ní ìjáde ọ̀nà òdodo. Kí O sì fún mi ní àrànṣe t’ó lágbára láti ọ̀dọ̀ Rẹ وَقُلۡ جَآءَ ٱلۡحَقُّ وَزَهَقَ ٱلۡبَٰطِلُۚ إِنَّ ٱلۡبَٰطِلَ كَانَ زَهُوقًا ٨١Sọ pé: “Òdodo dé. Irọ́ sì sá lọ. Dájúdájú irọ́ jẹ́ ohun tí ó máa sá lọ.” وَنُنَزِّلُ مِنَ ٱلۡقُرۡءَانِ مَا هُوَ شِفَآءٌ وَرَحۡمَةٌ لِّلۡمُؤۡمِنِينَ وَلَا يَزِيدُ ٱلظَّٰلِمِينَ إِلَّا خَسَارًا ٨٢À ń sọ ohun tí ó jẹ́ ìwòsàn àti ìkẹ́ kalẹ̀ sínú al-Ƙur’ān fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo. (al-Ƙur’ān) kò sì ṣàlékún fún àwọn alábòsí bí kò ṣe òfò وَإِذَآ أَنۡعَمۡنَا عَلَى ٱلۡإِنسَٰنِ أَعۡرَضَ وَنَـَٔا بِجَانِبِهِۦ وَإِذَا مَسَّهُ ٱلشَّرُّ كَانَ يَـُٔوسًا ٨٣Nígbà tí A bá ṣèdẹ̀ra fún ènìyàn, ó máa gbúnrí (kúrò níbi òdodo), ó sì máa ṣègbéraga. Nígbà tí aburú bá sì fọwọ́ bà á, ó máa di olùsọ̀rètínù قُلۡ كُلٌّ يَعۡمَلُ عَلَىٰ شَاكِلَتِهِۦ فَرَبُّكُمۡ أَعۡلَمُ بِمَنۡ هُوَ أَهۡدَىٰ سَبِيلًا ٨٤Sọ pé: "Ẹnì kọ̀ọ̀kan ń ṣiṣẹ́ lórí àdámọ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n Olúwa yín nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tí ó mọ̀nà وَيَسۡـَٔلُونَكَ عَنِ ٱلرُّوحِۖ قُلِ ٱلرُّوحُ مِنۡ أَمۡرِ رَبِّي وَمَآ أُوتِيتُم مِّنَ ٱلۡعِلۡمِ إِلَّا قَلِيلًا ٨٥Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa ẹ̀mí. Sọ pé: “Ẹ̀mí ń bẹ nínú àṣẹ Olúwa mi. A ò sì fun yín nínú ìmọ̀ bí kò ṣe díẹ̀.” وَلَئِن شِئۡنَا لَنَذۡهَبَنَّ بِٱلَّذِيٓ أَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡكَ ثُمَّ لَا تَجِدُ لَكَ بِهِۦ عَلَيۡنَا وَكِيلًا ٨٦Àti pé dájúdájú tí A bá fẹ́ ni, A ìbá kúkú gba ìmísí tí A fi ránṣẹ́ sí ọ (kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ). Lẹ́yìn náà, ìwọ kò níí rí aláàbò kan tí ó máa là ọ́ lọ́dọ̀ Wa إِلَّا رَحۡمَةً مِّن رَّبِّكَۚ إِنَّ فَضۡلَهُۥ كَانَ عَلَيۡكَ كَبِيرًا ٨٧Àyàfi ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ (ni kò fi ṣe bẹ́ẹ̀). Dájúdájú oore àjùlọ Rẹ̀ lórí rẹ tóbi قُل لَّئِنِ ٱجۡتَمَعَتِ ٱلۡإِنسُ وَٱلۡجِنُّ عَلَىٰٓ أَن يَأۡتُواْ بِمِثۡلِ هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانِ لَا يَأۡتُونَ بِمِثۡلِهِۦ وَلَوۡ كَانَ بَعۡضُهُمۡ لِبَعۡضٍ ظَهِيرًا ٨٨Sọ pé: “Dájúdájú tí àwọn ènìyàn àti àlùjànnú bá para pọ̀ láti mú irú al-Ƙur’ān yìí wá, wọn kò lè mú irú rẹ̀ wá, apá kan wọn ìbáà jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún apá kan وَلَقَدۡ صَرَّفۡنَا لِلنَّاسِ فِي هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانِ مِن كُلِّ مَثَلٍ فَأَبَىٰٓ أَكۡثَرُ ٱلنَّاسِ إِلَّا كُفُورًا ٨٩Dájúdájú A ti fi àkàwé kọ̀ọ̀kan ṣàlàyé (oríṣiríṣi) fún àwọn ènìyàn sínú al-Ƙur’ān yìí. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn kọ̀ láti gbà àfi àtakò sá وَقَالُواْ لَن نُّؤۡمِنَ لَكَ حَتَّىٰ تَفۡجُرَ لَنَا مِنَ ٱلۡأَرۡضِ يَنۢبُوعًا ٩٠Wọ́n sì wí pé: “A kò níí gbà ọ́ gbọ́ títí o máa fi mú omi ìṣẹ́lẹ̀rú ṣẹ́ yọ fún wa أَوۡ تَكُونَ لَكَ جَنَّةٌ مِّن نَّخِيلٍ وَعِنَبٍ فَتُفَجِّرَ ٱلۡأَنۡهَٰرَ خِلَٰلَهَا تَفۡجِيرًا ٩١Tàbí kí o ní ọgbà oko dàbínù àti ọgbà oko àjàrà, tí o sì máa jẹ́ kí àwọn odò ṣàn kọ já dáadáa láààrin wọn أَوۡ تُسۡقِطَ ٱلسَّمَآءَ كَمَا زَعَمۡتَ عَلَيۡنَا كِسَفًا أَوۡ تَأۡتِيَ بِٱللَّهِ وَٱلۡمَلَٰٓئِكَةِ قَبِيلًا ٩٢Tàbí kí o jẹ́ kí sánmọ̀ já lù wá ní kélekèle gẹ́gẹ́ bí o ṣe sọ (pé Allāhu lè ṣe bẹ́ẹ̀). Tàbí kí o mú Allāhu àti àwọn mọlāika wá (bá wa) ní ojúkojú أَوۡ يَكُونَ لَكَ بَيۡتٌ مِّن زُخۡرُفٍ أَوۡ تَرۡقَىٰ فِي ٱلسَّمَآءِ وَلَن نُّؤۡمِنَ لِرُقِيِّكَ حَتَّىٰ تُنَزِّلَ عَلَيۡنَا كِتَٰبًا نَّقۡرَؤُهُۥۗ قُلۡ سُبۡحَانَ رَبِّي هَلۡ كُنتُ إِلَّا بَشَرًا رَّسُولًا ٩٣Tàbí kí o ní ilé wúrà kan, tàbí kí o gun òkè sánmọ̀ lọ. A kò sì níí gba gígun-sánmọ̀ rẹ gbọ́ títí o fi máa sọ tírà kan tí a óò máa ké kalẹ̀ fún wa.” Sọ pé: “Mímọ́ ni fún Olúwa mi, ǹjẹ́ mo jẹ́ kiní kan bí kò ṣe Òjíṣẹ́ abara?” وَمَا مَنَعَ ٱلنَّاسَ أَن يُؤۡمِنُوٓاْ إِذۡ جَآءَهُمُ ٱلۡهُدَىٰٓ إِلَّآ أَن قَالُوٓاْ أَبَعَثَ ٱللَّهُ بَشَرًا رَّسُولًا ٩٤Kò sí ohun tí ó kọ̀ fún àwọn ènìyàn láti gbàgbọ́ ní òdodo nígbà tí ìmọ̀nà dé bá wọn àfi kí wọ́n wí pé: “Ṣé Allāhu rán Òjíṣẹ́ abara níṣẹ́ ni?” قُل لَّوۡ كَانَ فِي ٱلۡأَرۡضِ مَلَٰٓئِكَةٌ يَمۡشُونَ مُطۡمَئِنِّينَ لَنَزَّلۡنَا عَلَيۡهِم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ مَلَكًا رَّسُولًا ٩٥Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé àwọn mọlāika wà lórí ilẹ̀ ayé, tí wọ́n ń rìn kiri, (tí wọ́n ń gbé lórí ilẹ̀) pẹ̀lú ìfàyàbalẹ̀, A ìbá sọ mọlāika kan kalẹ̀ fún wọn láti inú sánmọ̀ (láti jẹ́) Òjíṣẹ́.” قُلۡ كَفَىٰ بِٱللَّهِ شَهِيدَۢا بَيۡنِي وَبَيۡنَكُمۡۚ إِنَّهُۥ كَانَ بِعِبَادِهِۦ خَبِيرَۢا بَصِيرًا ٩٦Sọ pé: “Allāhu tó ní Ẹlẹ́rìí láààrin èmi àti ẹ̀yin. Dájúdájú Ó ń jẹ́ Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀, Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn Rẹ̀.” وَمَن يَهۡدِ ٱللَّهُ فَهُوَ ٱلۡمُهۡتَدِۖ وَمَن يُضۡلِلۡ فَلَن تَجِدَ لَهُمۡ أَوۡلِيَآءَ مِن دُونِهِۦۖ وَنَحۡشُرُهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ عَلَىٰ وُجُوهِهِمۡ عُمۡيًا وَبُكۡمًا وَصُمًّاۖ مَّأۡوَىٰهُمۡ جَهَنَّمُۖ كُلَّمَا خَبَتۡ زِدۡنَٰهُمۡ سَعِيرًا ٩٧Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fi mọ̀nà (’Islām), òun ni olùmọ̀nà. Ẹnikẹ́ni tí Ó bá ṣì lọ́nà, o ò níí rí àwọn olùrànlọ́wọ́ kan fún wọn lẹ́yìn Rẹ̀. Àti pé A máa kó wọn jọ ní Ọjọ́ Àjíǹde ní ìdojúbolẹ̀. (Wọn yóò di) afọ́jú, ayaya àti odi. Iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn. Nígbàkígbà tí Iná bá jó lọọlẹ̀, A máa ṣàlékún jíjò (rẹ̀) fún wọn ذَٰلِكَ جَزَآؤُهُم بِأَنَّهُمۡ كَفَرُواْ بِـَٔايَٰتِنَا وَقَالُوٓاْ أَءِذَا كُنَّا عِظَٰمًا وَرُفَٰتًا أَءِنَّا لَمَبۡعُوثُونَ خَلۡقًا جَدِيدًا ٩٨Ìyẹn ni ẹ̀san wọn nítorí pé, wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa. Wọ́n sì wí pé: “Ṣé nígbà tí a bá ti di egungun, tí a sì ti jẹrà, ṣé wọ́n tún máa gbé wa dìde ní ẹ̀dá titun ni?” ۞ أَوَلَمۡ يَرَوۡاْ أَنَّ ٱللَّهَ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ قَادِرٌ عَلَىٰٓ أَن يَخۡلُقَ مِثۡلَهُمۡ وَجَعَلَ لَهُمۡ أَجَلًا لَّا رَيۡبَ فِيهِ فَأَبَى ٱلظَّٰلِمُونَ إِلَّا كُفُورًا ٩٩Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ lágbára láti ṣẹ̀dá irú wọn (mìíràn)? Ó sì máa fún wọn ní gbèdéke àkókò kan, tí kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn alábòsí kọ̀ láti gbà àfi àtakò sá قُل لَّوۡ أَنتُمۡ تَمۡلِكُونَ خَزَآئِنَ رَحۡمَةِ رَبِّيٓ إِذًا لَّأَمۡسَكۡتُمۡ خَشۡيَةَ ٱلۡإِنفَاقِۚ وَكَانَ ٱلۡإِنسَٰنُ قَتُورًا ١٠٠Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé ẹ̀yin l’ẹ ni ìkápá lórí àwọn ilé ọrọ̀ ìkẹ́ Olúwa mi ni, nígbà náà ẹ̀yin ìbá diwọ́ mọ́ ọn ní ti ìbẹ̀rù òṣì. Ènìyàn sì jẹ́ ahun وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَىٰ تِسۡعَ ءَايَٰتِۭ بَيِّنَٰتٍۖ فَسۡـَٔلۡ بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ إِذۡ جَآءَهُمۡ فَقَالَ لَهُۥ فِرۡعَوۡنُ إِنِّي لَأَظُنُّكَ يَٰمُوسَىٰ مَسۡحُورًا ١٠١Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní àwọn àmì mẹ́sàn-án t’ó yanjú. Bi àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl léèrè wò. Rántí, nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ wọn, Fir‘aon wí fún un pé: “Dájúdájú èmi lérò pé eléèdì ni ọ́, Mūsā.” قَالَ لَقَدۡ عَلِمۡتَ مَآ أَنزَلَ هَٰٓؤُلَآءِ إِلَّا رَبُّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ بَصَآئِرَ وَإِنِّي لَأَظُنُّكَ يَٰفِرۡعَوۡنُ مَثۡبُورًا ١٠٢(Ànábì Mūsā) sọ pé: “O kúkú mọ̀ pé kò sí ẹni tí ó sọ àwọn (àmì) wọ̀nyí kalẹ̀ bí kò ṣe Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀; (ó sì jẹ́) àmì t’ó yanjú. Dájúdájú èmi náà lérò pé ẹni ìparun ni ọ́, Fir‘aon.” فَأَرَادَ أَن يَسۡتَفِزَّهُم مِّنَ ٱلۡأَرۡضِ فَأَغۡرَقۡنَٰهُ وَمَن مَّعَهُۥ جَمِيعًا ١٠٣Nítorí náà, (Fir‘aon) fẹ́ kó wọn láyà jẹ lórí ilẹ̀. A sì tẹ òun àti àwọn t’ó wà pẹ̀lú rẹ̀ rì pátápátá وَقُلۡنَا مِنۢ بَعۡدِهِۦ لِبَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ ٱسۡكُنُواْ ٱلۡأَرۡضَ فَإِذَا جَآءَ وَعۡدُ ٱلۡأٓخِرَةِ جِئۡنَا بِكُمۡ لَفِيفًا ١٠٤A sì sọ fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl lẹ́yìn (ikú) rẹ̀ pé: “Ẹ máa gbé orí ilẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n nígbà tí Àdéhùn Ìkẹ́yìn bá dé, A óò mú gbogbo yín wá ní àpapọ̀ (ní ọjọ́ ẹ̀san) وَبِٱلۡحَقِّ أَنزَلۡنَٰهُ وَبِٱلۡحَقِّ نَزَلَۗ وَمَآ أَرۡسَلۡنَٰكَ إِلَّا مُبَشِّرًا وَنَذِيرًا ١٠٥A sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Ó sì sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú òdodo. A kò sì rán ọ níṣẹ́ bí kò ṣe pé (kí o jẹ́) oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀ وَقُرۡءَانًا فَرَقۡنَٰهُ لِتَقۡرَأَهُۥ عَلَى ٱلنَّاسِ عَلَىٰ مُكۡثٍ وَنَزَّلۡنَٰهُ تَنزِيلًا ١٠٦Àti pé al-Ƙur’ān, A ṣàlàyé rẹ̀ (fún ọ) nítorí kí o lè ké e fún àwọn ènìyàn pẹ̀lú pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́. A sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ díẹ̀díẹ̀. oríṣi ìsọ̀kalẹ̀ méjì l’ó wà fún al-Ƙur’ān. Ìsọ̀kalẹ̀ kìíní ni ìsọ̀kalẹ̀ olódidi láti inú Laohul-Mahfuṭḥ sínú sánmọ̀ ilé ayé. Ìsọ̀kalẹ̀ yìí l’ó ṣẹlẹ̀ nínú òru Laelatul-ƙọdr. Èyí l’ó jẹyọ nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:185 sūrah ad-Dukān; 44:3 àti sūrah al-Ƙọdr’ 97:1. Ìsọ̀kalẹ̀ kejì ni ìsọ̀kalẹ̀ onídíẹ̀díẹ̀ láti inú sánmọ̀ ilé ayé sórí ilẹ̀ ayé. Èyí ṣẹlẹ̀ fún òǹkà ọdún mẹ́tàlélógún. Ìsọ̀kalẹ̀ yìí ni āyah yìí ń sọ nípa rẹ̀ قُلۡ ءَامِنُواْ بِهِۦٓ أَوۡ لَا تُؤۡمِنُوٓاْۚ إِنَّ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡعِلۡمَ مِن قَبۡلِهِۦٓ إِذَا يُتۡلَىٰ عَلَيۡهِمۡ يَخِرُّونَۤ لِلۡأَذۡقَانِۤ سُجَّدًاۤ ١٠٧Sọ pé: “Ẹ gba al-Ƙur’ān gbọ́ tàbí ẹ ò gbà á gbọ́, dájúdájú àwọn tí A fún ní ìmọ̀ ṣíwájú (ìsọ̀kalẹ̀) rẹ̀, nígbà tí wọ́n bá ń ké e fún wọn, wọn yóò dojú bolẹ̀, tí wọ́n ń forí kanlẹ̀ (fún Allāhu) وَيَقُولُونَ سُبۡحَٰنَ رَبِّنَآ إِن كَانَ وَعۡدُ رَبِّنَا لَمَفۡعُولًا ١٠٨Wọ́n ń sọ pé: “Mímọ́ ni fún Olúwa wa. Dájúdájú àdéhùn Olúwa wa máa wá sí ìmúṣẹ ni.” وَيَخِرُّونَ لِلۡأَذۡقَانِ يَبۡكُونَ وَيَزِيدُهُمۡ خُشُوعًا ۩ ١٠٩Wọ́n ń dojú bolẹ̀, tí wọ́n ń sunkún (fún Allāhu. Al-Ƙur’ān) sì ń ṣàlékún ìtẹríba fún wọn قُلِ ٱدۡعُواْ ٱللَّهَ أَوِ ٱدۡعُواْ ٱلرَّحۡمَٰنَۖ أَيًّا مَّا تَدۡعُواْ فَلَهُ ٱلۡأَسۡمَآءُ ٱلۡحُسۡنَىٰۚ وَلَا تَجۡهَرۡ بِصَلَاتِكَ وَلَا تُخَافِتۡ بِهَا وَٱبۡتَغِ بَيۡنَ ذَٰلِكَ سَبِيلًا ١١٠Sọ pé: “Ẹ pe Allāhu tàbí ẹ pe ar-Rahmọ̄n (Àjọkẹ́-ayé).” Èyíkéyìí tí ẹ bá fi pè É (nínú rẹ̀), ṣebí tiRẹ̀ ni àwọn orúkọ t’ó dára jùlọ. Má ṣe kígbe lórí ìrun (àti àdúà) rẹ. Má sì ṣe wà ní ìdákẹ́ rọ́rọ́. Wá ọ̀nà sáààrin méjèèjì yẹn وَقُلِ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ ٱلَّذِي لَمۡ يَتَّخِذۡ وَلَدًا وَلَمۡ يَكُن لَّهُۥ شَرِيكٌ فِي ٱلۡمُلۡكِ وَلَمۡ يَكُن لَّهُۥ وَلِيٌّ مِّنَ ٱلذُّلِّۖ وَكَبِّرۡهُ تَكۡبِيرَۢا ١١١Kí o sì sọ pé: "Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí kò fi ẹnì kan ṣe ọmọ. Kò sì ní akẹgbẹ́ nínú ìjọba. Kò yẹpẹrẹ áḿbọ̀sìbọ́sí pé Ó máa wá bùkátà sí olùrànlọ́wọ́.” Gbé títóbi fún Un gan-an

Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.