Millat al-Islam

Chapter 97 · 5 verses · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Surah Al-Qadr in Yoruba

Arabic with tafsir Listen to Surah Al-Qadr (1300 reciters)
Meccanسورة القدر5 verses

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

إِنَّآ أَنزَلۡنَٰهُ فِي لَيۡلَةِ ٱلۡقَدۡرِ ١Dájúdájú Àwa sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ nínú Òru Abiyì وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا لَيۡلَةُ ٱلۡقَدۡرِ ٢Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Òru Abiyì لَيۡلَةُ ٱلۡقَدۡرِ خَيۡرٌ مِّنۡ أَلۡفِ شَهۡرٍ ٣Òru Abiyì lóore ju ẹgbẹ̀rún oṣù lọ تَنَزَّلُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ وَٱلرُّوحُ فِيهَا بِإِذۡنِ رَبِّهِم مِّن كُلِّ أَمۡرٍ ٤Àwọn mọlāika àti Jibrīl yó sì máa sọ̀kalẹ̀ nínú òru náà pẹ̀lú àṣẹ Olúwa wọn fún gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan سَلَٰمٌ هِيَ حَتَّىٰ مَطۡلَعِ ٱلۡفَجۡرِ ٥Àlàáfíà ni òru náà títí di àsìkò àfẹ̀mọ́júmọ́

Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.