بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
الٓمٓ ١’Alif lām mīm تَنزِيلُ ٱلۡكِتَٰبِ لَا رَيۡبَ فِيهِ مِن رَّبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ ٢Ìsọ̀kalẹ̀ Tírà náà, kò sí iyèméjì nínú rẹ̀ (pé ó wá) láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá أَمۡ يَقُولُونَ ٱفۡتَرَىٰهُۚ بَلۡ هُوَ ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّكَ لِتُنذِرَ قَوۡمًا مَّآ أَتَىٰهُم مِّن نَّذِيرٍ مِّن قَبۡلِكَ لَعَلَّهُمۡ يَهۡتَدُونَ ٣Tàbí wọ́n ń wí pé: “Ó dá àdápa irọ́ rẹ̀ ni.” Rárá o! Òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ nítorí kí o lè fi ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn kan, tí olùkìlọ̀ kan kò wá bá wọn rí ṣíwájú rẹ, nítorí kí wọ́n lè mọ̀nà ٱللَّهُ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ وَمَا بَيۡنَهُمَا فِي سِتَّةِ أَيَّامٍ ثُمَّ ٱسۡتَوَىٰ عَلَى ٱلۡعَرۡشِۖ مَا لَكُم مِّن دُونِهِۦ مِن وَلِيٍّ وَلَا شَفِيعٍۚ أَفَلَا تَتَذَكَّرُونَ ٤Allāhu ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan t’ó wà láààrin méjèèjì láààrin ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sórí Ìtẹ́-ọlá. Kò sí aláàbò àti olùṣìpẹ̀ kan fun yín lẹ́yìn Rẹ̀. Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni يُدَبِّرُ ٱلۡأَمۡرَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ إِلَى ٱلۡأَرۡضِ ثُمَّ يَعۡرُجُ إِلَيۡهِ فِي يَوۡمٍ كَانَ مِقۡدَارُهُۥٓ أَلۡفَ سَنَةٍ مِّمَّا تَعُدُّونَ ٥Ó ń ṣètò ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá) láti sánmọ̀ wá sórí ilẹ̀. Lẹ́yìn náà, (àbọ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀dá) yóò gùnkè tọ̀ Ọ́ lọ láààrin ọjọ́ kan tí òdiwọ̀n rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún ọdún nínú òǹkà tí ẹ̀ ń kà ذَٰلِكَ عَٰلِمُ ٱلۡغَيۡبِ وَٱلشَّهَٰدَةِ ٱلۡعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ ٦Ìyẹn ni Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba, Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run ٱلَّذِيٓ أَحۡسَنَ كُلَّ شَيۡءٍ خَلَقَهُۥۖ وَبَدَأَ خَلۡقَ ٱلۡإِنسَٰنِ مِن طِينٍ ٧Ẹni t’ó ṣe gbogbo n̄ǹkan tí Ó dá ní dáadáa. Ó sì bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ènìyàn láti inú erùpẹ̀ amọ̀ ثُمَّ جَعَلَ نَسۡلَهُۥ مِن سُلَٰلَةٍ مِّن مَّآءٍ مَّهِينٍ ٨Lẹ́yìn náà, Ó ṣe àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ láti ara ohun tí A mú jáde láti ara omi lílẹ yẹpẹrẹ ثُمَّ سَوَّىٰهُ وَنَفَخَ فِيهِ مِن رُّوحِهِۦۖ وَجَعَلَ لَكُمُ ٱلسَّمۡعَ وَٱلۡأَبۡصَٰرَ وَٱلۡأَفۡـِٔدَةَۚ قَلِيلًا مَّا تَشۡكُرُونَ ٩Lẹ́yìn náà, Ó to (oríkèéríkèé) rẹ̀ dọ́gba. Ó sì fẹ́ (ẹ̀mí) sí i lára nínú ẹ̀mí Rẹ̀ (tí Ó dá). Ó tún ṣe ìgbọ́rọ̀, ìríran àti ọkàn fun yín. Díẹ̀ ni ọpẹ́ tí ẹ̀ ń dá وَقَالُوٓاْ أَءِذَا ضَلَلۡنَا فِي ٱلۡأَرۡضِ أَءِنَّا لَفِي خَلۡقٍ جَدِيدِۭۚ بَلۡ هُم بِلِقَآءِ رَبِّهِمۡ كَٰفِرُونَ ١٠Wọ́n sì wí pé: “Ǹjẹ́ nígbà tí a bá ti pòórá sínú ilẹ̀, ǹjẹ́ àwa tún lè wà ní ẹ̀dá titun mọ́? Àní sẹ́, àwọn ni aláìgbàgbọ́ nínú ìpàdé Olúwa wọn ۞ قُلۡ يَتَوَفَّىٰكُم مَّلَكُ ٱلۡمَوۡتِ ٱلَّذِي وُكِّلَ بِكُمۡ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّكُمۡ تُرۡجَعُونَ ١١Sọ pé: “Mọlāika ikú èyí tí A fi tì yín máa gba ẹ̀mí yín. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni wọn máa da yín padà sí.” gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe jẹ́ Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo. Kò sí ẹ̀dá kan tí ó máa tọ́ ìṣẹ̀mí wò àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Kò sì sí ẹ̀dá kan tí ó máa tọ́ ikú wò àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Nípa èyí Allāhu l’Ó ń fi àṣẹ Rẹ̀ gba ẹ̀mí kúrò lára ẹ̀dá Rẹ̀ ní àkókò tí Ó ti kọ mọ́ ọn nínú kádàrá. Ìyẹn ni ó jẹyọ nínú sūrah az-Zumọr; 39:42. Bákan náà وَلَوۡ تَرَىٰٓ إِذِ ٱلۡمُجۡرِمُونَ نَاكِسُواْ رُءُوسِهِمۡ عِندَ رَبِّهِمۡ رَبَّنَآ أَبۡصَرۡنَا وَسَمِعۡنَا فَٱرۡجِعۡنَا نَعۡمَلۡ صَٰلِحًا إِنَّا مُوقِنُونَ ١٢(Ìwọ ìbá rí èèmọ̀) tí ó bá jẹ́ pé o rí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ nígbà tí wọ́n bá sorí kọ́ ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn, (wọ́n sì máa wí pé): “Olúwa wa, a ti ríran, a sì ti gbọ́ràn (báyìí), nítorí náà, dá wa padà (sí ilé ayé) nítorí kí á lè lọ ṣe iṣẹ́ rere; dájúdájú àwa ni alámọ̀dájú.” وَلَوۡ شِئۡنَا لَأٓتَيۡنَا كُلَّ نَفۡسٍ هُدَىٰهَا وَلَٰكِنۡ حَقَّ ٱلۡقَوۡلُ مِنِّي لَأَمۡلَأَنَّ جَهَنَّمَ مِنَ ٱلۡجِنَّةِ وَٱلنَّاسِ أَجۡمَعِينَ ١٣Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́ ni, dájúdájú A ìbá fún gbogbo ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ìmọ̀nà rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà ti ṣẹ láti ọ̀dọ̀ Mi (báyìí pé): “Dájúdájú Mo máa mú nínú àwọn àlùjànnú àti ènìyàn ní àpapọ̀ kún inú iná Jahanamọ.” فَذُوقُواْ بِمَا نَسِيتُمۡ لِقَآءَ يَوۡمِكُمۡ هَٰذَآ إِنَّا نَسِينَٰكُمۡۖ وَذُوقُواْ عَذَابَ ٱلۡخُلۡدِ بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ ١٤Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà wò nítorí pé ẹ ti gbàgbé ìpàdé ọjọ́ yín (òní) yìí. Dájúdájú Àwa náà yóò gbàgbé yín sínú Iná. Ẹ tọ́ ìyà gbére wò nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ إِنَّمَا يُؤۡمِنُ بِـَٔايَٰتِنَا ٱلَّذِينَ إِذَا ذُكِّرُواْ بِهَا خَرُّواْۤ سُجَّدًاۤ وَسَبَّحُواْ بِحَمۡدِ رَبِّهِمۡ وَهُمۡ لَا يَسۡتَكۡبِرُونَ ۩ ١٥Àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa ni àwọn tí ó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá fi ṣe ìṣítí fún wọn, wọn yóò dojú bolẹ̀ ní olùforíkanlẹ̀, wọn yó sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa wọn. Wọn kò sì níí ṣègbéraga تَتَجَافَىٰ جُنُوبُهُمۡ عَنِ ٱلۡمَضَاجِعِ يَدۡعُونَ رَبَّهُمۡ خَوۡفًا وَطَمَعًا وَمِمَّا رَزَقۡنَٰهُمۡ يُنفِقُونَ ١٦Wọ́n ń gbé ẹ̀gbẹ́ wọn kúrò lórí ibùsùn. Wọ́n sì ń pe Olúwa wọn ní ti ìpáyà àti ìrètí. Wọ́n sì ń ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn فَلَا تَعۡلَمُ نَفۡسٌ مَّآ أُخۡفِيَ لَهُم مِّن قُرَّةِ أَعۡيُنٍ جَزَآءَۢ بِمَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ ١٧Kò sí ẹ̀mí kan tí ó mọ ohun tí A fi pamọ́ fún wọn nínú àwọn n̄ǹkan ìtutù ojú. (Ó jẹ́) ẹ̀san ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (rere) أَفَمَن كَانَ مُؤۡمِنًا كَمَن كَانَ فَاسِقًاۚ لَّا يَسۡتَوُۥنَ ١٨Ǹjẹ́ ẹni t’ó jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo dà bí ẹni t’ó jẹ́ òbìlẹ̀jẹ́ bí? Wọn kò dọ́gba أَمَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ فَلَهُمۡ جَنَّٰتُ ٱلۡمَأۡوَىٰ نُزُلَۢا بِمَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ ١٩Ní ti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, àwọn ibùgbé (nínú) Ọ̀gbà Ìdẹ̀ra ń bẹ fún wọn. (Ó jẹ́) ohun tí A pèsè sílẹ̀ (dè wọ́n) nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (rere) وَأَمَّا ٱلَّذِينَ فَسَقُواْ فَمَأۡوَىٰهُمُ ٱلنَّارُۖ كُلَّمَآ أَرَادُوٓاْ أَن يَخۡرُجُواْ مِنۡهَآ أُعِيدُواْ فِيهَا وَقِيلَ لَهُمۡ ذُوقُواْ عَذَابَ ٱلنَّارِ ٱلَّذِي كُنتُم بِهِۦ تُكَذِّبُونَ ٢٠Ní ti àwọn t’ó balẹ̀jẹ́, Iná ni ibùgbé wọn. Ìgbàkígbà tí wọ́n bá fẹ́ jáde kúrò nínú rẹ̀, A ó sì máa dá wọn padà sínú rẹ̀. A sì máa sọ fún wọn pé: “Ẹ tọ́ ìyà Iná tí ẹ̀ ń pè nírọ́ wò.” وَلَنُذِيقَنَّهُم مِّنَ ٱلۡعَذَابِ ٱلۡأَدۡنَىٰ دُونَ ٱلۡعَذَابِ ٱلۡأَكۡبَرِ لَعَلَّهُمۡ يَرۡجِعُونَ ٢١Dájúdájú A máa fún wọn tọ́ wò nínú ìyà t’ó kéré jùlọ (nílé ayé) yàtọ̀ sí ìyà t’ó tóbi jùlọ (lọ́run) nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo ṣíwájú ikú wọn) وَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّن ذُكِّرَ بِـَٔايَٰتِ رَبِّهِۦ ثُمَّ أَعۡرَضَ عَنۡهَآۚ إِنَّا مِنَ ٱلۡمُجۡرِمِينَ مُنتَقِمُونَ ٢٢Àti pé ta l’ó ṣe àbòsí t’ó tayọ ẹni tí wọn fi àwọn āyah Wa ṣe ìṣítí fún, lẹ́yìn náà, tí ó gbúnrí kúrò níbẹ̀? Dájúdájú Àwa máa gbẹ̀san lára àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡكِتَٰبَ فَلَا تَكُن فِي مِرۡيَةٍ مِّن لِّقَآئِهِۦۖ وَجَعَلۡنَٰهُ هُدًى لِّبَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ ٢٣Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. Nítorí náà, má ṣe wà nínú iyèméjì nípa bí ó ṣe pàdé rẹ̀ (ìyẹn, nínú ìrìn-àjò òru àti gígun sánmọ̀). A sì ṣe Tírà náà ní ìmọ̀nà fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl وَجَعَلۡنَا مِنۡهُمۡ أَئِمَّةً يَهۡدُونَ بِأَمۡرِنَا لَمَّا صَبَرُواْۖ وَكَانُواْ بِـَٔايَٰتِنَا يُوقِنُونَ ٢٤Àti pé A ṣe àwọn aṣíwájú kan nínú wọn ní afinimọ̀nà pẹ̀lú àṣẹ Wa nígbà tí wọ́n ṣe sùúrù. Wọ́n sì ń ní àmọ̀dájú nípa àwọn āyah Wa إِنَّ رَبَّكَ هُوَ يَفۡصِلُ بَيۡنَهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ فِيمَا كَانُواْ فِيهِ يَخۡتَلِفُونَ ٢٥Dájúdájú Olúwa rẹ, Ó máa ṣe ìdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí أَوَلَمۡ يَهۡدِ لَهُمۡ كَمۡ أَهۡلَكۡنَا مِن قَبۡلِهِم مِّنَ ٱلۡقُرُونِ يَمۡشُونَ فِي مَسَٰكِنِهِمۡۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٍۚ أَفَلَا يَسۡمَعُونَ ٢٦Ṣé kò fojú hàn sí wọn pé, mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn. Àwọn náà sì ń rìn kọjá nínú àwọn ibùgbé wọn! Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn. Nítorí náà, ṣé wọn kò níí tẹ́tí gbọ́rọ̀ (òdodo ni) أَوَلَمۡ يَرَوۡاْ أَنَّا نَسُوقُ ٱلۡمَآءَ إِلَى ٱلۡأَرۡضِ ٱلۡجُرُزِ فَنُخۡرِجُ بِهِۦ زَرۡعًا تَأۡكُلُ مِنۡهُ أَنۡعَٰمُهُمۡ وَأَنفُسُهُمۡۚ أَفَلَا يُبۡصِرُونَ ٢٧Tàbí wọn kò rí i pé dájúdájú Àwa l’À ń wa omi òjò lọ sórí ilẹ̀ gbígbẹ, tí A sì ń fi mú irúgbìn jáde? Àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn àti àwọn náà sì ń jẹ nínú rẹ̀. Nítorí náà, ṣé wọn kò ríran ni وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا ٱلۡفَتۡحُ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ ٢٨Wọ́n sì ń wí pé: “Ìgbà wo ni Ìdájọ́ yìí tí ẹ bá jẹ́ olódodo?” قُلۡ يَوۡمَ ٱلۡفَتۡحِ لَا يَنفَعُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ إِيمَٰنُهُمۡ وَلَا هُمۡ يُنظَرُونَ ٢٩Sọ pé: “Ní Ọjọ́ Ìdájọ́, ìgbàgbọ́ wọn kò níí ṣàǹfààní fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ (nínú Allāhu). A ò sì níí fún wọn ní ìsinmi (nínú Iná).” فَأَعۡرِضۡ عَنۡهُمۡ وَٱنتَظِرۡ إِنَّهُم مُّنتَظِرُونَ ٣٠Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn, kí o sì máa retí (Ọjọ́ Ìdájọ́). Dájúdájú àwọn náà ń retí (rẹ̀)