Millat al-Islam

Chapter 99 · 8 verses · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Surah Az-Zalzala in Yoruba

Arabic with tafsir Listen to Surah Az-Zalzala (1306 reciters)

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

إِذَا زُلۡزِلَتِ ٱلۡأَرۡضُ زِلۡزَالَهَا ١Nígbà tí wọ́n bá mi ilẹ̀ tìtì ní ìmìtìtì rẹ̀ وَأَخۡرَجَتِ ٱلۡأَرۡضُ أَثۡقَالَهَا ٢àti (nígbà) tí ilẹ̀ bá tú àwọn ẹrù t’ó wúwo nínú rẹ̀ jáde وَقَالَ ٱلۡإِنسَٰنُ مَا لَهَا ٣ènìyàn yó sì wí pé: "Kí l’ó mú un يَوۡمَئِذٍ تُحَدِّثُ أَخۡبَارَهَا ٤Ní ọjọ́ yẹn ni (ilẹ̀) yóò sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìró rẹ̀ (tí ẹ̀dá gbé orí ilẹ̀ ṣe) بِأَنَّ رَبَّكَ أَوۡحَىٰ لَهَا ٥Nítorí pé dájúdájú Olúwa rẹ l’Ó fún un ní àṣẹ (láti sọ̀rọ̀) يَوۡمَئِذٍ يَصۡدُرُ ٱلنَّاسُ أَشۡتَاتًا لِّيُرَوۡاْ أَعۡمَٰلَهُمۡ ٦Ní ọjọ́ yẹn, àwọn ènìyàn yóò máa gba ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ nítorí kí wọ́n lè fi àwọn iṣẹ́ wọn hàn wọ́n فَمَن يَعۡمَلۡ مِثۡقَالَ ذَرَّةٍ خَيۡرًا يَرَهُۥ ٧Nítorí náà, ẹni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere ní òdíwọ̀n ọmọ iná-igún, ó máa rí i وَمَن يَعۡمَلۡ مِثۡقَالَ ذَرَّةٍ شَرًّا يَرَهُۥ ٨Ẹni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ aburú ní òdíwọ̀n ọmọ iná-igún, ó máa rí i

Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.