Millat al-Islam

Chapter 10 · 109 verses · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Surah Yunus in Yoruba

Arabic with tafsir Listen to Surah Yunus (1195 reciters)
Meccanسورة يونس109 verses

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

الٓرۚ تِلۡكَ ءَايَٰتُ ٱلۡكِتَٰبِ ٱلۡحَكِيمِ ١’Alif Lām Rọ̄. Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà ọgbọ́n أَكَانَ لِلنَّاسِ عَجَبًا أَنۡ أَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰ رَجُلٍ مِّنۡهُمۡ أَنۡ أَنذِرِ ٱلنَّاسَ وَبَشِّرِ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ أَنَّ لَهُمۡ قَدَمَ صِدۡقٍ عِندَ رَبِّهِمۡۗ قَالَ ٱلۡكَٰفِرُونَ إِنَّ هَٰذَا لَسَٰحِرٌ مُّبِينٌ ٢Ṣé ó jẹ́ kàyéfì fún àwọn ènìyàn pé A fi ìmísí ránṣẹ́ sí arákùnrin kan nínú wọn, pé: “Ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn, kí o sì fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní ìró ìdùnnú pé ẹ̀san rere (iṣẹ́ tí wọ́n ṣe) ṣíwájú ti wà ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn.”? Àwọn aláìgbàgbọ́ wí pé: “Dájúdájú òpìdán pọ́nńbélé mà ni (Ànábì) yìí.” إِنَّ رَبَّكُمُ ٱللَّهُ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ فِي سِتَّةِ أَيَّامٍ ثُمَّ ٱسۡتَوَىٰ عَلَى ٱلۡعَرۡشِۖ يُدَبِّرُ ٱلۡأَمۡرَۖ مَا مِن شَفِيعٍ إِلَّا مِنۢ بَعۡدِ إِذۡنِهِۦۚ ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبُّكُمۡ فَٱعۡبُدُوهُۚ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ ٣Dájúdájú Olúwa yín ni Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sí orí Ìtẹ́-ọlá. Ó ń ṣètò ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá). Kò sí olùṣìpẹ̀ kan àfi lẹ́yìn ìyọ̀ǹda Rẹ̀. Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni إِلَيۡهِ مَرۡجِعُكُمۡ جَمِيعًاۖ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقًّاۚ إِنَّهُۥ يَبۡدَؤُاْ ٱلۡخَلۡقَ ثُمَّ يُعِيدُهُۥ لِيَجۡزِيَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ بِٱلۡقِسۡطِۚ وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَهُمۡ شَرَابٌ مِّنۡ حَمِيمٍ وَعَذَابٌ أَلِيمُۢ بِمَا كَانُواْ يَكۡفُرُونَ ٤Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ibùpadàsí gbogbo yín. (Ó jẹ́) àdéhùn Allāhu ní òdodo. Dájúdájú Òun l’Ó ń pilẹ̀ dídá ẹ̀dá. Lẹ́yìn náà, Ó máa da á padà (sọ́dọ̀ Rẹ̀) nítorí kí Ó lè fi déédé san ẹ̀san fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere. Àwọn t’ó sì ṣàì gbàgbọ́, ohun mímu gbígbóná àti ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún wọn nítorí pé wọ́n ṣàì gbàgbọ́ هُوَ ٱلَّذِي جَعَلَ ٱلشَّمۡسَ ضِيَآءً وَٱلۡقَمَرَ نُورًا وَقَدَّرَهُۥ مَنَازِلَ لِتَعۡلَمُواْ عَدَدَ ٱلسِّنِينَ وَٱلۡحِسَابَۚ مَا خَلَقَ ٱللَّهُ ذَٰلِكَ إِلَّا بِٱلۡحَقِّۚ يُفَصِّلُ ٱلۡأٓيَٰتِ لِقَوۡمٍ يَعۡلَمُونَ ٥(Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó ṣe òòrùn ní ìtànsán. (Ó ṣe) òṣùpá ní ìmọ́lẹ̀. Ó sì díwọ̀n (ìrísí) rẹ̀ sínú àwọn ibùsọ̀ nítorí kí ẹ lè mọ òǹkà àwọn ọdún àti ìṣírò (ọjọ́). Allāhu kò dá ìyẹn bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo. Ó ń ṣàlàyé àwọn āyah fún ìjọ t’ó nímọ̀ إِنَّ فِي ٱخۡتِلَٰفِ ٱلَّيۡلِ وَٱلنَّهَارِ وَمَا خَلَقَ ٱللَّهُ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ لَأٓيَٰتٍ لِّقَوۡمٍ يَتَّقُونَ ٦Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìtẹ̀léǹtẹ̀lé àti ìyàtọ̀ òru àti ọ̀sán àti ohun tí Allāhu dá sínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀; (àmì wà nínú wọn) fún ìjọ t’ó ń bẹ̀rù (Allāhu) إِنَّ ٱلَّذِينَ لَا يَرۡجُونَ لِقَآءَنَا وَرَضُواْ بِٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا وَٱطۡمَأَنُّواْ بِهَا وَٱلَّذِينَ هُمۡ عَنۡ ءَايَٰتِنَا غَٰفِلُونَ ٧Dájúdájú àwọn tí kò retí ìpàdé Wa (ní ọ̀run), tí wọ́n yọ́nú sí ìṣẹ̀mí ayé, tí ọkàn wọn sì balẹ̀ dódó sí (ìṣẹ̀mí ayé yìí) àti àwọn afọ́nú-fọ́ra nípa àwọn āyah Wa أُوْلَٰٓئِكَ مَأۡوَىٰهُمُ ٱلنَّارُ بِمَا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ ٨àwọn wọ̀nyẹn, ibùgbé wọn ni Iná nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ يَهۡدِيهِمۡ رَبُّهُم بِإِيمَٰنِهِمۡۖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهِمُ ٱلۡأَنۡهَٰرُ فِي جَنَّٰتِ ٱلنَّعِيمِ ٩Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, Olúwa wọn yóò fi ìgbàgbọ́ òdodo wọn tọ́ wọn sọ́nà. Àwọn odò yó sì máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ ọ̀dọ̀ wọn nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra دَعۡوَىٰهُمۡ فِيهَا سُبۡحَٰنَكَ ٱللَّهُمَّ وَتَحِيَّتُهُمۡ فِيهَا سَلَٰمٌۚ وَءَاخِرُ دَعۡوَىٰهُمۡ أَنِ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ ١٠Àdúà wọn nínú rẹ̀ ni “mímọ́ ni fún Ọ, Allāhu”. Ìkíni wọn nínú rẹ̀ ni “àlàáfíà”. Ìparí àdúà wọn sì ni pé “gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá” ۞ وَلَوۡ يُعَجِّلُ ٱللَّهُ لِلنَّاسِ ٱلشَّرَّ ٱسۡتِعۡجَالَهُم بِٱلۡخَيۡرِ لَقُضِيَ إِلَيۡهِمۡ أَجَلُهُمۡۖ فَنَذَرُ ٱلَّذِينَ لَا يَرۡجُونَ لِقَآءَنَا فِي طُغۡيَٰنِهِمۡ يَعۡمَهُونَ ١١Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu ń kánjú mú aburú bá àwọn ènìyàn (nípasẹ̀ èpè ẹnu wọn, gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe ń) tètè mú oore bá wọn (nípasẹ̀ àdúà), A ìbá ti mú òpin ba ìṣẹ́mí wọn. Nítorí náà, A máa fi àwọn tí kò retí ìpàdé Wa sílẹ̀ sínú àgbéré wọn, tí wọn yóò máa pa rìdàrìdà وَإِذَا مَسَّ ٱلۡإِنسَٰنَ ٱلضُّرُّ دَعَانَا لِجَنۢبِهِۦٓ أَوۡ قَاعِدًا أَوۡ قَآئِمًا فَلَمَّا كَشَفۡنَا عَنۡهُ ضُرَّهُۥ مَرَّ كَأَن لَّمۡ يَدۡعُنَآ إِلَىٰ ضُرٍّ مَّسَّهُۥۚ كَذَٰلِكَ زُيِّنَ لِلۡمُسۡرِفِينَ مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ ١٢Nígbà tí ìnira bá kan ènìyàn, ó máa pè Wá lórí ìdùbúlẹ̀ rẹ̀ tàbí ní ìjókòó tàbí ní ìnàró. Nígbà tí A bá mú ìnira rẹ̀ kúrò fún un, ó máa tẹ̀ síwájú (nínú àìgbàgbọ́) bí ẹni pé kò pè Wá sí ìnira tí ó mú un. Báyẹn ni wọ́n ṣe ní ọ̀ṣọ́ fún àwọn alákọyọ ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ وَلَقَدۡ أَهۡلَكۡنَا ٱلۡقُرُونَ مِن قَبۡلِكُمۡ لَمَّا ظَلَمُواْ وَجَآءَتۡهُمۡ رُسُلُهُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِ وَمَا كَانُواْ لِيُؤۡمِنُواْۚ كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلۡمُجۡرِمِينَ ١٣A kúkú ti pa àwọn ìran kan rẹ́ ṣíwájú yín nígbà tí wọ́n ṣe àbòsí. Àwọn Òjíṣẹ́ wọn mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá bá wọn. Wọn kò sì gbàgbọ́. Báyẹn ni A ṣe ń san ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ẹ̀san ثُمَّ جَعَلۡنَٰكُمۡ خَلَٰٓئِفَ فِي ٱلۡأَرۡضِ مِنۢ بَعۡدِهِمۡ لِنَنظُرَ كَيۡفَ تَعۡمَلُونَ ١٤Lẹ́yìn náà, A ṣe yín ní àrólé lórí ilẹ̀ lẹ́yìn wọn nítorí kí Á lè wo bí ẹ̀yin náà yóò ṣe máa ṣe وَإِذَا تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِمۡ ءَايَاتُنَا بَيِّنَٰتٍ قَالَ ٱلَّذِينَ لَا يَرۡجُونَ لِقَآءَنَا ٱئۡتِ بِقُرۡءَانٍ غَيۡرِ هَٰذَآ أَوۡ بَدِّلۡهُۚ قُلۡ مَا يَكُونُ لِيٓ أَنۡ أُبَدِّلَهُۥ مِن تِلۡقَآيِٕ نَفۡسِيٓۖ إِنۡ أَتَّبِعُ إِلَّا مَا يُوحَىٰٓ إِلَيَّۖ إِنِّيٓ أَخَافُ إِنۡ عَصَيۡتُ رَبِّي عَذَابَ يَوۡمٍ عَظِيمٍ ١٥Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa, t’ó yanjú fún wọn, àwọn tí kò retí ìpàdé Wa (ní ọ̀run) yóò máa wí pé: “Mú Ƙur’ān kan wá yàtọ̀ sí èyí tàbí kí o yí i padà.” Sọ pé: “Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún mi láti yí i padà láti ọ̀dọ̀ ara mi. Èmi kò tẹ̀lé kiní kan àyàfi ohun tí Wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi ní ìmísí. Dájúdájú èmi ń páyà ìyà Ọjọ́ ńlá tí mo bá fi lè yapa Olúwa mi.” قُل لَّوۡ شَآءَ ٱللَّهُ مَا تَلَوۡتُهُۥ عَلَيۡكُمۡ وَلَآ أَدۡرَىٰكُم بِهِۦۖ فَقَدۡ لَبِثۡتُ فِيكُمۡ عُمُرًا مِّن قَبۡلِهِۦٓۚ أَفَلَا تَعۡقِلُونَ ١٦Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́ ni, èmi ìbá tí lè ké al-Ƙur’ān fun yín, àti pé Allāhu ìbá tí fi ìmọ̀ rẹ̀ mọ̀ yín. Mo kúkú ti lo àwọn ọdún kan láààrin yín ṣíwájú (ìsọ̀kalẹ̀) rẹ̀, ṣé ẹ ò ṣe làákàyè ni?” فَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّنِ ٱفۡتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبًا أَوۡ كَذَّبَ بِـَٔايَٰتِهِۦٓۚ إِنَّهُۥ لَا يُفۡلِحُ ٱلۡمُجۡرِمُونَ ١٧Nítorí náà, ta l’ó ṣàbòsí ju ẹni t’ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu tàbí t’ó pe àwọn āyah Rẹ̀ nírọ́? Dájúdájú àwọn ọ̀daràn kò níí jèrè وَيَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَا لَا يَضُرُّهُمۡ وَلَا يَنفَعُهُمۡ وَيَقُولُونَ هَٰٓؤُلَآءِ شُفَعَٰٓؤُنَا عِندَ ٱللَّهِۚ قُلۡ أَتُنَبِّـُٔونَ ٱللَّهَ بِمَا لَا يَعۡلَمُ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَلَا فِي ٱلۡأَرۡضِۚ سُبۡحَٰنَهُۥ وَتَعَٰلَىٰ عَمَّا يُشۡرِكُونَ ١٨Wọ́n ń jọ́sìn fún ohun tí kò lè kó ìnira bá wọn, tí kò sì lè ṣe wọ́n ní àǹfààní lẹ́yìn Allāhu. Wọ́n sì ń wí pé: “Àwọn wọ̀nyí ni olùṣìpẹ̀ wa lọ́dọ̀ Allāhu.” Sọ pé: “Ṣé ẹ máa fún Allāhu ní ìró ohun tí kò mọ̀ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ni?” Mímọ́ ni fún Un, Ó ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I وَمَا كَانَ ٱلنَّاسُ إِلَّآ أُمَّةً وَٰحِدَةً فَٱخۡتَلَفُواْۚ وَلَوۡلَا كَلِمَةٌ سَبَقَتۡ مِن رَّبِّكَ لَقُضِيَ بَيۡنَهُمۡ فِيمَا فِيهِ يَخۡتَلِفُونَ ١٩Kí ni àwọn ènìyàn jẹ́ (ní ìpìlẹ̀) bí kò ṣe ìjọ ẹyọ kan (ìjọ ’Islām). Lẹ́yìn náà ni wọ́n yapa ẹnu. Tí kò bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kan t’ó ti ṣíwájú lọ́dọ̀ Olúwa rẹ, Àwa ìbá ti yanjú ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí láààrin ara wọn وَيَقُولُونَ لَوۡلَآ أُنزِلَ عَلَيۡهِ ءَايَةٌ مِّن رَّبِّهِۦۖ فَقُلۡ إِنَّمَا ٱلۡغَيۡبُ لِلَّهِ فَٱنتَظِرُوٓاْ إِنِّي مَعَكُم مِّنَ ٱلۡمُنتَظِرِينَ ٢٠Wọ́n ń wí pé: “Kí ni kò jẹ́ kí àmì kan sọ̀kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?” Nítorí náà, sọ pé: “Ti Allāhu ni ìkọ̀kọ̀. Nítorí náà, ẹ máa retí. Dájúdájú èmi náà wà pẹ̀lú yín nínú àwọn olùretí.” وَإِذَآ أَذَقۡنَا ٱلنَّاسَ رَحۡمَةً مِّنۢ بَعۡدِ ضَرَّآءَ مَسَّتۡهُمۡ إِذَا لَهُم مَّكۡرٌ فِيٓ ءَايَاتِنَاۚ قُلِ ٱللَّهُ أَسۡرَعُ مَكۡرًاۚ إِنَّ رُسُلَنَا يَكۡتُبُونَ مَا تَمۡكُرُونَ ٢١Nígbà tí A bá fún àwọn ènìyàn ní ìdẹ̀ra kan tọ́wò lẹ́yìn tí ìnira ti fọwọ́ bà wọ́n, nígbà náà ni wọ́n máa dète sí àwọn āyah Wa. Sọ pé: “Allāhu yára jùlọ níbi ète. Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ Wa ń ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí ẹ̀ ń dá léte.” هُوَ ٱلَّذِي يُسَيِّرُكُمۡ فِي ٱلۡبَرِّ وَٱلۡبَحۡرِۖ حَتَّىٰٓ إِذَا كُنتُمۡ فِي ٱلۡفُلۡكِ وَجَرَيۡنَ بِهِم بِرِيحٍ طَيِّبَةٍ وَفَرِحُواْ بِهَا جَآءَتۡهَا رِيحٌ عَاصِفٌ وَجَآءَهُمُ ٱلۡمَوۡجُ مِن كُلِّ مَكَانٍ وَظَنُّوٓاْ أَنَّهُمۡ أُحِيطَ بِهِمۡ دَعَوُاْ ٱللَّهَ مُخۡلِصِينَ لَهُ ٱلدِّينَ لَئِنۡ أَنجَيۡتَنَا مِنۡ هَٰذِهِۦ لَنَكُونَنَّ مِنَ ٱلشَّٰكِرِينَ ٢٢(Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó mu yín rìn lórí ilẹ̀ àti ní ojú omi, títí di ìgbà tí ẹ bá wà nínú ọkọ̀ ojú-omi, tí atẹ́gùn t’ó dára sì ń tukọ̀ wọn lọ, inú wọn yó sì máa dùn sí i. (Àmọ́) atẹ́gùn líle kọ lù ú, ìgbì omi dé bá wọn ní gbogbo àyè, wọ́n sì lérò pé dájúdájú wọ́n ti fi (àdánwò) yí àwọn po, wọ́n sì pe Allāhu pẹ̀lú ṣíṣe àfọ̀mọ́-àdúà fún Un pé: “Dájúdájú tí O bá fi lè gbà wá là níbi èyí, dájúdájú a máa wà nínú àwọn olùdúpẹ́.” فَلَمَّآ أَنجَىٰهُمۡ إِذَا هُمۡ يَبۡغُونَ فِي ٱلۡأَرۡضِ بِغَيۡرِ ٱلۡحَقِّۗ يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ إِنَّمَا بَغۡيُكُمۡ عَلَىٰٓ أَنفُسِكُمۖ مَّتَٰعَ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۖ ثُمَّ إِلَيۡنَا مَرۡجِعُكُمۡ فَنُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ ٢٣Ṣùgbọ́n nígbà tí Ó gbà wọ́n là tán ìgbà náà ni wọ́n tún ń ṣe ìbàjẹ́ kiri lórí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́. Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú ìbàjẹ́ yín ń bẹ lórí yín. (Ìbàjẹ́ yín sì jẹ́) ìgbádùn ìṣẹ̀mí ayé. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Wa ni ibùpadàsí yín. A sì máa fun yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ إِنَّمَا مَثَلُ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا كَمَآءٍ أَنزَلۡنَٰهُ مِنَ ٱلسَّمَآءِ فَٱخۡتَلَطَ بِهِۦ نَبَاتُ ٱلۡأَرۡضِ مِمَّا يَأۡكُلُ ٱلنَّاسُ وَٱلۡأَنۡعَٰمُ حَتَّىٰٓ إِذَآ أَخَذَتِ ٱلۡأَرۡضُ زُخۡرُفَهَا وَٱزَّيَّنَتۡ وَظَنَّ أَهۡلُهَآ أَنَّهُمۡ قَٰدِرُونَ عَلَيۡهَآ أَتَىٰهَآ أَمۡرُنَا لَيۡلًا أَوۡ نَهَارًا فَجَعَلۡنَٰهَا حَصِيدًا كَأَن لَّمۡ تَغۡنَ بِٱلۡأَمۡسِۚ كَذَٰلِكَ نُفَصِّلُ ٱلۡأٓيَٰتِ لِقَوۡمٍ يَتَفَكَّرُونَ ٢٤Àpèjúwe ìṣẹ̀mí ayé dà bí omi kan tí A sọ̀kalẹ̀ láti sánmọ̀, tí àwọn irúgbìn nínú ohun tí ènìyàn àti àwọn ẹran-ọ̀sìn ń jẹ sì gbà á sára, títí di ìgbà tí ilẹ̀ yóò fi lọ́ràá. Ó sì mú ọ̀ṣọ́ (ara) rẹ̀ jáde. Àwọn t’ó ni í sì lérò pé àwọn ni alágbára lórí rẹ̀, (nígbà náà ni) àṣẹ Wa dé bá a ní òru tàbí ní ọ̀sán. A sì sọ ọ́ di oko tí wọ́n fà tu dànù bí ẹni pé kò sí níbẹ̀ rárá rí ní àná. Báyẹn ni A ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah fún ìjọ aláròjinlẹ̀ وَٱللَّهُ يَدۡعُوٓاْ إِلَىٰ دَارِ ٱلسَّلَٰمِ وَيَهۡدِي مَن يَشَآءُ إِلَىٰ صِرَٰطٍ مُّسۡتَقِيمٍ ٢٥Allāhu ń pèpè sí ilé Àlàáfíà. Ó sì ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sí ọ̀nà tààrà (’Islām) ۞ لِّلَّذِينَ أَحۡسَنُواْ ٱلۡحُسۡنَىٰ وَزِيَادَةٌۖ وَلَا يَرۡهَقُ وُجُوهَهُمۡ قَتَرٌ وَلَا ذِلَّةٌۚ أُوْلَٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡجَنَّةِۖ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ ٢٦Rere àti àlékún (oore) wà fún àwọn t’ó ṣe rere. Eruku tàbí ìyẹpẹrẹ kan kò níí bò wọ́n lójú mọ́lẹ̀. Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ وَٱلَّذِينَ كَسَبُواْ ٱلسَّيِّـَٔاتِ جَزَآءُ سَيِّئَةِۭ بِمِثۡلِهَا وَتَرۡهَقُهُمۡ ذِلَّةٌۖ مَّا لَهُم مِّنَ ٱللَّهِ مِنۡ عَاصِمٍۖ كَأَنَّمَآ أُغۡشِيَتۡ وُجُوهُهُمۡ قِطَعًا مِّنَ ٱلَّيۡلِ مُظۡلِمًاۚ أُوْلَٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِۖ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ ٢٧Àwọn t’ó sì ṣ’iṣẹ́ aburú, ẹ̀san aburú bí irú rẹ̀ (ni ẹ̀san wọn). Ìyẹpẹrẹ sì máa bò wọ́n mọ́lẹ̀. Kò sí aláàbò kan fún wọn lọ́dọ̀ Allāhu. (Wọ́n máa dà bí) ẹni pé wọ́n fi apá kan òru t’ó ṣókùnkùn bò wọ́n lójú pa. Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ وَيَوۡمَ نَحۡشُرُهُمۡ جَمِيعًا ثُمَّ نَقُولُ لِلَّذِينَ أَشۡرَكُواْ مَكَانَكُمۡ أَنتُمۡ وَشُرَكَآؤُكُمۡۚ فَزَيَّلۡنَا بَيۡنَهُمۡۖ وَقَالَ شُرَكَآؤُهُم مَّا كُنتُمۡ إِيَّانَا تَعۡبُدُونَ ٢٨Àti pé (rántí) Ọjọ́ tí A óò kó gbogbo wọn jọ, lẹ́yìn náà A óò sọ fún àwọn t’ó bá Allāhu wá akẹgbẹ́ pé: “Ẹ dúró pa sí àyè yín, ẹ̀yin àti àwọn òrìṣà yín.” Nítorí náà, A yà wọ́n sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àwọn òrìṣà wọn sì wí pé: “Àwa kọ́ ni ẹ̀ ń jọ́sìn fún فَكَفَىٰ بِٱللَّهِ شَهِيدَۢا بَيۡنَنَا وَبَيۡنَكُمۡ إِن كُنَّا عَنۡ عِبَادَتِكُمۡ لَغَٰفِلِينَ ٢٩Nítorí náà, Allāhu tó ní Ẹlẹ́rìí láààrin àwa àti ẹ̀yin pé àwa jẹ́ aláìmọ̀ nípa ìjọ́sìn yín (tí ẹ̀ ṣe fún wa).” هُنَالِكَ تَبۡلُواْ كُلُّ نَفۡسٍ مَّآ أَسۡلَفَتۡۚ وَرُدُّوٓاْ إِلَى ٱللَّهِ مَوۡلَىٰهُمُ ٱلۡحَقِّۖ وَضَلَّ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَفۡتَرُونَ ٣٠Níbẹ̀ yẹn, ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan máa dá ohun t’ó ṣe síwájú mọ̀. Wọn yó sì da wọ́n padà sọ́dọ̀ Allāhu, Olúwa wọn, Òdodo. Ohun tí wọ́n sì ń dá ní àdápa irọ́ sì máa dòfò mọ́ wọn lọ́wọ́ قُلۡ مَن يَرۡزُقُكُم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ وَٱلۡأَرۡضِ أَمَّن يَمۡلِكُ ٱلسَّمۡعَ وَٱلۡأَبۡصَٰرَ وَمَن يُخۡرِجُ ٱلۡحَيَّ مِنَ ٱلۡمَيِّتِ وَيُخۡرِجُ ٱلۡمَيِّتَ مِنَ ٱلۡحَيِّ وَمَن يُدَبِّرُ ٱلۡأَمۡرَۚ فَسَيَقُولُونَ ٱللَّهُۚ فَقُلۡ أَفَلَا تَتَّقُونَ ٣١Sọ pé: “Ta ni Ó ń pèsè fun yín láti inú sánmọ̀ àti ilẹ̀? Ta ni Ó ní ìkápá lórí ìgbọ́rọ̀ àti ìríran? Ta ni Ó ń mú alààyè jáde láti ara òkú, tí Ó tún ń mú òkú jáde láti ara alààyè? Ta sì ni Ó ń ṣe ètò ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá)?” Wọn yóò wí pé: "Allāhu" Nígbà náà, sọ pé: "Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni فَذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبُّكُمُ ٱلۡحَقُّۖ فَمَاذَا بَعۡدَ ٱلۡحَقِّ إِلَّا ٱلضَّلَٰلُۖ فَأَنَّىٰ تُصۡرَفُونَ ٣٢Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín, Òdodo. Kí sì ni ó ń bẹ lẹ́yìn Òdodo bí kò ṣe ìṣìnà? Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí yín kúrò níbi òdodo كَذَٰلِكَ حَقَّتۡ كَلِمَتُ رَبِّكَ عَلَى ٱلَّذِينَ فَسَقُوٓاْ أَنَّهُمۡ لَا يُؤۡمِنُونَ ٣٣Báyẹn ni ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ ṣe wá sí ìmúṣẹ lórí àwọn t’ó ṣèbàjẹ́ pé dájúdájú wọn kò níí gbàgbọ́ قُلۡ هَلۡ مِن شُرَكَآئِكُم مَّن يَبۡدَؤُاْ ٱلۡخَلۡقَ ثُمَّ يُعِيدُهُۥۚ قُلِ ٱللَّهُ يَبۡدَؤُاْ ٱلۡخَلۡقَ ثُمَّ يُعِيدُهُۥۖ فَأَنَّىٰ تُؤۡفَكُونَ ٣٤Sọ pé: "Ǹjẹ́ ó wà nínú àwọn òrìṣà yín ẹni tí ó lè pilẹ̀ dídá ẹ̀dá, lẹ́yìn náà, tí ó máa dá a padà (sí ìpìlẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn ikú)?" Sọ pé: "Allāhu l’Ó ń pilẹ̀ dídá ẹ̀dá. Lẹ́yìn náà, Ó máa dá a padà (sí ìpìlẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn ikú). Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí yín kúrò níbi òdodo قُلۡ هَلۡ مِن شُرَكَآئِكُم مَّن يَهۡدِيٓ إِلَى ٱلۡحَقِّۚ قُلِ ٱللَّهُ يَهۡدِي لِلۡحَقِّۗ أَفَمَن يَهۡدِيٓ إِلَى ٱلۡحَقِّ أَحَقُّ أَن يُتَّبَعَ أَمَّن لَّا يَهِدِّيٓ إِلَّآ أَن يُهۡدَىٰۖ فَمَا لَكُمۡ كَيۡفَ تَحۡكُمُونَ ٣٥Sọ pé: "Ǹjẹ́ ó wà nínú àwọn òrìṣà yín ẹni t’ó ń fini mọ̀nà síbi òdodo?" Sọ pé: “Allāhu l’Ó ń fini mọ̀nà síbi òdodo. Nígbà náà, ṣé Ẹni t’Ó ń fini mọ̀nà síbi òdodo l’ó lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ sí pé kí wọ́n máa tẹ̀lé ni tàbí ẹni tí kò lè dá ọ̀nà mọ̀ fúnra rẹ̀ àfi tí A bá fi mọ̀nà?” Nítorí náà, kí l’ó ń ṣe yín tí ẹ fi ń dájọ́ báyìí وَمَا يَتَّبِعُ أَكۡثَرُهُمۡ إِلَّا ظَنًّاۚ إِنَّ ٱلظَّنَّ لَا يُغۡنِي مِنَ ٱلۡحَقِّ شَيۡـًٔاۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمُۢ بِمَا يَفۡعَلُونَ ٣٦Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò sì rí kiní kan tẹ̀lé bí kò ṣe àròsọ. Dájúdájú àròsọ kò sì lè rọrọ̀ kiní kan níwájú òdodo. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ وَمَا كَانَ هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانُ أَن يُفۡتَرَىٰ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَلَٰكِن تَصۡدِيقَ ٱلَّذِي بَيۡنَ يَدَيۡهِ وَتَفۡصِيلَ ٱلۡكِتَٰبِ لَا رَيۡبَ فِيهِ مِن رَّبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ ٣٧Al-Ƙur’ān yìí kì í ṣe n̄ǹkan tí ó ṣe é dáhun (láti ọ̀dọ̀ ẹlòmíìràn) lẹ́yìn Allāhu, ṣùgbọ́n ó ń jẹ́rìí sí èyí t’ó jẹ́ òdodo nínú èyí t’ó ṣíwájú rẹ̀, ó ń ṣe àlàyé (àwọn) Tírà náà. Kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. (Ó wá) láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá أَمۡ يَقُولُونَ ٱفۡتَرَىٰهُۖ قُلۡ فَأۡتُواْ بِسُورَةٍ مِّثۡلِهِۦ وَٱدۡعُواْ مَنِ ٱسۡتَطَعۡتُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ ٣٨Tàbí wọ́n ń wí pé: "Ó hun ún ni? Sọ pé: "Ẹ mú sūrah kan bí irú rẹ̀ wá. Kí ẹ sì pe ẹnikẹ́ni tí ẹ bá lè pè lẹ́yìn Allāhu, tí ẹ bá jẹ́ olódodo بَلۡ كَذَّبُواْ بِمَا لَمۡ يُحِيطُواْ بِعِلۡمِهِۦ وَلَمَّا يَأۡتِهِمۡ تَأۡوِيلُهُۥۚ كَذَٰلِكَ كَذَّبَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۖ فَٱنظُرۡ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلظَّٰلِمِينَ ٣٩Kò rí bẹ́è, wọ́n pe ohun tí wọn kò ní ìmọ̀ rẹ̀ nírọ́ ni. Àti pé ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ Rẹ̀ kò tí ì dé bá wọn (ni wọ́n fi pè é nírọ́). Báyẹn ni àwọn t’ó ṣíwájú wọn ṣe pe (ọ̀rọ̀ Allāhu) nírọ́. Nítorí náà, wo bí àtubọ̀tán àwọn alábòsí ṣe rí وَمِنۡهُم مَّن يُؤۡمِنُ بِهِۦ وَمِنۡهُم مَّن لَّا يُؤۡمِنُ بِهِۦۚ وَرَبُّكَ أَعۡلَمُ بِٱلۡمُفۡسِدِينَ ٤٠Ó sì ń bẹ nínú wọn ẹni t’ó gbà á gbọ́ ní òdodo. Ó tún ń bẹ́ nínú wọn ẹni tí kò gbà á gbọ́. Olúwa rẹ sì ni Onímọ̀-jùlọ nípa àwọn òbìlẹ̀jẹ́ وَإِن كَذَّبُوكَ فَقُل لِّي عَمَلِي وَلَكُمۡ عَمَلُكُمۡۖ أَنتُم بَرِيٓـُٔونَ مِمَّآ أَعۡمَلُ وَأَنَا۠ بَرِيٓءٌ مِّمَّا تَعۡمَلُونَ ٤١Tí wọ́n bá pè ọ́ ní òpùrọ́, sọ pé: “Tèmi ni iṣẹ́ mi. Tiyín ni iṣẹ́ yín. Ẹ̀yin yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí mò ń ṣe níṣẹ́. Èmi náà sì yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.” وَمِنۡهُم مَّن يَسۡتَمِعُونَ إِلَيۡكَۚ أَفَأَنتَ تُسۡمِعُ ٱلصُّمَّ وَلَوۡ كَانُواْ لَا يَعۡقِلُونَ ٤٢Ó sì wà nínú wọn, àwọn t’ó ń tẹ́tí sí ọ. Ṣé ìwọ l’o máa mú adití gbọ́rọ̀ ni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe làákàyè وَمِنۡهُم مَّن يَنظُرُ إِلَيۡكَۚ أَفَأَنتَ تَهۡدِي ٱلۡعُمۡيَ وَلَوۡ كَانُواْ لَا يُبۡصِرُونَ ٤٣Ó tún ń bẹ nínú wọn ẹni t’ó ń wò ọ́. Ṣé ìwọ l’o máa fi afọ́jú mọ̀nà ni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ríran إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَظۡلِمُ ٱلنَّاسَ شَيۡـًٔا وَلَٰكِنَّ ٱلنَّاسَ أَنفُسَهُمۡ يَظۡلِمُونَ ٤٤Dájúdájú Allāhu kò níí fí kiní kan ṣàbòsí sí ènìyàn. Ṣùgbọ́n ènìyàn ń ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn وَيَوۡمَ يَحۡشُرُهُمۡ كَأَن لَّمۡ يَلۡبَثُوٓاْ إِلَّا سَاعَةً مِّنَ ٱلنَّهَارِ يَتَعَارَفُونَ بَيۡنَهُمۡۚ قَدۡ خَسِرَ ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بِلِقَآءِ ٱللَّهِ وَمَا كَانُواْ مُهۡتَدِينَ ٤٥Àti pé (rántí) Ọjọ́ tí (Allāhu) yóò kó wọn jọ àfi bí ẹni pé wọn kò gbé ilé ayé ju àkókò kan nínú ọ̀sán. Wọn yó sì dára wọn mọ̀. Dájúdájú àwọn t’ó pe ìpàdé Allāhu nírọ́ ti ṣòfò; wọn kò sì jẹ́ olùmọ̀nà وَإِمَّا نُرِيَنَّكَ بَعۡضَ ٱلَّذِي نَعِدُهُمۡ أَوۡ نَتَوَفَّيَنَّكَ فَإِلَيۡنَا مَرۡجِعُهُمۡ ثُمَّ ٱللَّهُ شَهِيدٌ عَلَىٰ مَا يَفۡعَلُونَ ٤٦Ó ṣeé ṣe kí A fi apá kan èyí tí A ṣe ní ìlérí fún wọn hàn ọ́ tàbí kí A ti gba ẹ̀mí rẹ (ṣíwájú àsìkò náà), ọ̀dọ̀ Wa kúkú ni ibùpadàsí wọn. Lẹ́yìn náà, Allāhu ni Arínú-róde ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ وَلِكُلِّ أُمَّةٍ رَّسُولٌۖ فَإِذَا جَآءَ رَسُولُهُمۡ قُضِيَ بَيۡنَهُم بِٱلۡقِسۡطِ وَهُمۡ لَا يُظۡلَمُونَ ٤٧Òjíṣẹ́ ti wà fún ìjọ kọ̀ọ̀kan. Nítorí náà, nígbà tí Òjíṣẹ́ wọn bá dé, A óò ṣèdájọ́ láààrin wọn pẹ̀lú déédé; A ò sì níí ṣàbòsí sí wọn وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا ٱلۡوَعۡدُ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ ٤٨Wọ́n ń wí pé: “Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?” قُل لَّآ أَمۡلِكُ لِنَفۡسِي ضَرًّا وَلَا نَفۡعًا إِلَّا مَا شَآءَ ٱللَّهُۗ لِكُلِّ أُمَّةٍ أَجَلٌۚ إِذَا جَآءَ أَجَلُهُمۡ فَلَا يَسۡتَـٔۡخِرُونَ سَاعَةً وَلَا يَسۡتَقۡدِمُونَ ٤٩Sọ pé: “Èmi kò ní ìkápá ìnira tàbí oore kan fún ẹ̀mí ara mi àfi ohun tí Allāhu bá fẹ́. Gbèdéke àkókò ti wà fún ìjọ kọ̀ọ̀kan. Nígbà tí àkókò náà bá dé, wọn kò níí sún un ṣíwájú di àkókò kan, wọn kò sì níí fà á sẹ́yìn.” قُلۡ أَرَءَيۡتُمۡ إِنۡ أَتَىٰكُمۡ عَذَابُهُۥ بَيَٰتًا أَوۡ نَهَارًا مَّاذَا يَسۡتَعۡجِلُ مِنۡهُ ٱلۡمُجۡرِمُونَ ٥٠Sọ pé: "Ẹ sọ fún mi, tí ìyà Rẹ̀ bá dé ba yín ní òru tàbí ní ọ̀sán? Èwo nínú rẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń wá pẹ̀lú ìkánjú?” أَثُمَّ إِذَا مَا وَقَعَ ءَامَنتُم بِهِۦٓۚ ءَآلۡـَٰٔنَ وَقَدۡ كُنتُم بِهِۦ تَسۡتَعۡجِلُونَ ٥١Ṣé lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ṣẹlẹ̀ tán ni ẹ máa gbà á gbọ́? Ṣé nísinsìn yìí (ni ẹ óò gbà á gbọ́), tí ẹ sì kúkú ti ń wá a pẹ̀lú ìkánjú ثُمَّ قِيلَ لِلَّذِينَ ظَلَمُواْ ذُوقُواْ عَذَابَ ٱلۡخُلۡدِ هَلۡ تُجۡزَوۡنَ إِلَّا بِمَا كُنتُمۡ تَكۡسِبُونَ ٥٢Lẹ́yìn náà, A óò sọ fún àwọn t’ó ṣàbòsí pé: “Ẹ tọ́ ìyà gbére wò.” Ṣé A óò san yín ní ẹ̀san kan bí kò ṣe ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ ۞ وَيَسۡتَنۢبِـُٔونَكَ أَحَقٌّ هُوَۖ قُلۡ إِي وَرَبِّيٓ إِنَّهُۥ لَحَقٌّۖ وَمَآ أَنتُم بِمُعۡجِزِينَ ٥٣Wọ́n sì ń bèèrè fún ìró rẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “ṣé òdodo ni?” Sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni. Mo fi Olúwa mi búra. Dájúdájú òdodo ni. Ẹ̀yin kò sì níí mórí bọ́.” وَلَوۡ أَنَّ لِكُلِّ نَفۡسٍ ظَلَمَتۡ مَا فِي ٱلۡأَرۡضِ لَٱفۡتَدَتۡ بِهِۦۗ وَأَسَرُّواْ ٱلنَّدَامَةَ لَمَّا رَأَوُاْ ٱلۡعَذَابَۖ وَقُضِيَ بَيۡنَهُم بِٱلۡقِسۡطِ وَهُمۡ لَا يُظۡلَمُونَ ٥٤Àti pé tí ó bá jẹ́ pé gbogbo n̄ǹkan tí ń bẹ lórí ilẹ̀ jẹ́ ti ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan t’ó ṣàbòsí, ìbá fi ṣèràpadà (fún ẹ̀mí ara wọn níbi ìyà). Wọn yóò fi igbe àbámọ̀ pamọ́ nígbà tí wọ́n bá rí Ìyà. A ó ṣe ìdájọ́ láààrin wọn pẹ̀lú déédé; Wọn kò sì níí ṣàbòsí sí wọn أَلَآ إِنَّ لِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۗ أَلَآ إِنَّ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقٌّ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ ٥٥Gbọ́, dájúdájú ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Gbọ́! Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò nímọ̀ هُوَ يُحۡيِۦ وَيُمِيتُ وَإِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ ٥٦Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ قَدۡ جَآءَتۡكُم مَّوۡعِظَةٌ مِّن رَّبِّكُمۡ وَشِفَآءٌ لِّمَا فِي ٱلصُّدُورِ وَهُدًى وَرَحۡمَةٌ لِّلۡمُؤۡمِنِينَ ٥٧Èyin ènìyàn, ìṣítí kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín ti dé ba yín. Ìwòsàn ni fún n̄ǹkan t’ó wà nínú àwọn igbá-àyà ẹ̀dá. Ìmọ̀nà àti ìkẹ́ ni fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo قُلۡ بِفَضۡلِ ٱللَّهِ وَبِرَحۡمَتِهِۦ فَبِذَٰلِكَ فَلۡيَفۡرَحُواْ هُوَ خَيۡرٌ مِّمَّا يَجۡمَعُونَ ٥٨Sọ pé: “Pẹ̀lú àjùlọ oore Allāhu (ìyẹn, al-Ƙur’ān) àti àánú Rẹ̀ (ìyẹn, ’Islām), nítorí ìyẹn ni kí wọ́n máa fi dunnú; ó sì lóore jùlọ sí ohun tí àwọn (aláìgbàgbọ́) ń kó jọ (nínú oore ayé).” قُلۡ أَرَءَيۡتُم مَّآ أَنزَلَ ٱللَّهُ لَكُم مِّن رِّزۡقٍ فَجَعَلۡتُم مِّنۡهُ حَرَامًا وَحَلَٰلًا قُلۡ ءَآللَّهُ أَذِنَ لَكُمۡۖ أَمۡ عَلَى ٱللَّهِ تَفۡتَرُونَ ٥٩Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi nípa àwọn n̄ǹkan tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ fun yín nínú arísìkí, tí ẹ̀yin fúnra yín ṣe àwọn kan ní èèwọ̀ àti ẹ̀tọ́. Ṣé Allāhu l’Ó yọ̀ǹda fun yín ni tàbí ẹ̀ ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu?” وَمَا ظَنُّ ٱلَّذِينَ يَفۡتَرُونَ عَلَى ٱللَّهِ ٱلۡكَذِبَ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۗ إِنَّ ٱللَّهَ لَذُو فَضۡلٍ عَلَى ٱلنَّاسِ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَهُمۡ لَا يَشۡكُرُونَ ٦٠Kí ni èrò-ọkàn àwọn t’ó ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu ní Ọjọ́ Àjíǹde ná? Dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́lá-jùlọ lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kì í dúpẹ́ (fún Un) وَمَا تَكُونُ فِي شَأۡنٍ وَمَا تَتۡلُواْ مِنۡهُ مِن قُرۡءَانٍ وَلَا تَعۡمَلُونَ مِنۡ عَمَلٍ إِلَّا كُنَّا عَلَيۡكُمۡ شُهُودًا إِذۡ تُفِيضُونَ فِيهِۚ وَمَا يَعۡزُبُ عَن رَّبِّكَ مِن مِّثۡقَالِ ذَرَّةٍ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَا فِي ٱلسَّمَآءِ وَلَآ أَصۡغَرَ مِن ذَٰلِكَ وَلَآ أَكۡبَرَ إِلَّا فِي كِتَٰبٍ مُّبِينٍ ٦١Ìwọ kò níí wà nínú ìṣe kan, ìwọ kò sì níí ké (āyah kan) nínú al-Ƙur’ān, ẹ̀yin kò níí ṣe iṣẹ́ kan àfi kí Àwa jẹ́ Ẹlẹ́rìí lórí yín nígbà tí ẹ bá ń ṣe é. Kiní kan kò pamọ́ fún Olúwa rẹ; tí ó mọ ní òdiwọ̀n iná-igún nínú ilẹ̀ àti nínú sánmọ̀, kí ó tún kéré jú ìyẹn lọ tàbí kí ó tóbi jù ú lọ àfi kí ó wà nínú àkọsílẹ̀ t’ó yanjú أَلَآ إِنَّ أَوۡلِيَآءَ ٱللَّهِ لَا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ ٦٢Gbọ́, dájúdájú àwọn ọ̀rẹ́ Allāhu, kò níí sí ìbẹ̀rù (ìyà ọ̀run) fún wọn, wọn kò sì níí banújẹ́ (lórí oore ayé) ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَكَانُواْ يَتَّقُونَ ٦٣(Àwọn ni) àwọn t’ó gbàgbọ́ lódodo, wọ́n sì máa ń bẹ̀rù (Allāhu) لَهُمُ ٱلۡبُشۡرَىٰ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا وَفِي ٱلۡأٓخِرَةِۚ لَا تَبۡدِيلَ لِكَلِمَٰتِ ٱللَّهِۚ ذَٰلِكَ هُوَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡعَظِيمُ ٦٤Ti wọn ni ìró ìdùnnú nínú ìṣẹ̀mí ayé (yìí) àti ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Kò sí ìyípadà kan fún àwọn ọ̀rọ̀ Allāhu. Ìyẹn, òhun ni èrèǹjẹ ńlá وَلَا يَحۡزُنكَ قَوۡلُهُمۡۘ إِنَّ ٱلۡعِزَّةَ لِلَّهِ جَمِيعًاۚ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡعَلِيمُ ٦٥Má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ (ẹnu) wọn bà ọ́ nínú jẹ́. Dájúdájú gbogbo agbára pátápátá ń jẹ́ ti Allāhu. Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀ أَلَآ إِنَّ لِلَّهِ مَن فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَن فِي ٱلۡأَرۡضِۗ وَمَا يَتَّبِعُ ٱلَّذِينَ يَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ شُرَكَآءَۚ إِن يَتَّبِعُونَ إِلَّا ٱلظَّنَّ وَإِنۡ هُمۡ إِلَّا يَخۡرُصُونَ ٦٦Gbọ́, dájúdájú ti Allāhu ni ẹnikẹ́ni t’ó ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti ẹnikẹ́ni t’ó ń bẹ lórí ilẹ̀. Kí ni àwọn t’ó ń pe àwọn òrìṣà lẹ́yìn Allāhu ń tẹ̀lé ná? Wọn kò tẹ̀lé (kiní kan) bí kò ṣe àròsọ. Wọn kò sì ṣe kiní kan bí kò ṣe pé wọ́n ń parọ́ هُوَ ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُمُ ٱلَّيۡلَ لِتَسۡكُنُواْ فِيهِ وَٱلنَّهَارَ مُبۡصِرًاۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٍ لِّقَوۡمٍ يَسۡمَعُونَ ٦٧Òun ni Ẹni t’Ó ṣe òru fun yín nítorí kí ẹ lè sinmi nínú rẹ̀. (Ó ṣe) ọ̀sán ní (àsìkò) tí ẹ óò ríran (kedere). Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ń gbọ́rọ̀ (òdodo) قَالُواْ ٱتَّخَذَ ٱللَّهُ وَلَدًاۗ سُبۡحَٰنَهُۥۖ هُوَ ٱلۡغَنِيُّۖ لَهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۚ إِنۡ عِندَكُم مِّن سُلۡطَٰنِۭ بِهَٰذَآۚ أَتَقُولُونَ عَلَى ٱللَّهِ مَا لَا تَعۡلَمُونَ ٦٨Wọ́n wí pé: “Allāhu sọ ẹ̀dá di ọmọ.” - Mímọ́ ni fún Un. Òun ní Olùrọrọ̀. TiRẹ̀ ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. – Kò sí ẹ̀rí kan lọ́dọ̀ yín fún èyí. Ṣé ẹ fẹ́ ṣàfitì ohun tí ẹ ò nímọ̀ nípa rẹ̀ sọ́dọ̀ Allāhu ni قُلۡ إِنَّ ٱلَّذِينَ يَفۡتَرُونَ عَلَى ٱللَّهِ ٱلۡكَذِبَ لَا يُفۡلِحُونَ ٦٩Sọ pé: “Dájúdájú àwọn t’ó ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu, wọn kò níí jèrè.” مَتَٰعٌ فِي ٱلدُّنۡيَا ثُمَّ إِلَيۡنَا مَرۡجِعُهُمۡ ثُمَّ نُذِيقُهُمُ ٱلۡعَذَابَ ٱلشَّدِيدَ بِمَا كَانُواْ يَكۡفُرُونَ ٧٠Ìgbádùn bín-íntín (lè wà fún wọn) nílé ayé. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Wa ni ibùpadàsí wọn. Lẹ́yìn náà, A óò fún wọn ní ìyà líle tọ́ wò nítorí pé wọ́n ń ṣàì gbàgbọ́ ۞ وَٱتۡلُ عَلَيۡهِمۡ نَبَأَ نُوحٍ إِذۡ قَالَ لِقَوۡمِهِۦ يَٰقَوۡمِ إِن كَانَ كَبُرَ عَلَيۡكُم مَّقَامِي وَتَذۡكِيرِي بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ فَعَلَى ٱللَّهِ تَوَكَّلۡتُ فَأَجۡمِعُوٓاْ أَمۡرَكُمۡ وَشُرَكَآءَكُمۡ ثُمَّ لَا يَكُنۡ أَمۡرُكُمۡ عَلَيۡكُمۡ غُمَّةً ثُمَّ ٱقۡضُوٓاْ إِلَيَّ وَلَا تُنظِرُونِ ٧١Ka ìròyìn (Ànábì) Nūh fún wọn. Nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, tí ó bá jẹ́ pé ìdúró mi (pẹ̀lú yín) àti bí mo ṣe ń fi àwọn āyah Allāhu ṣe ìṣítí fun yín bá lágbara lára yín, nígbà náà Allāhu ni mo gbáralé. Nítorí náà, ẹ pa ìmọ̀ràn yín pọ̀, (kí ẹ sì ké pe) àwọn òrìṣà yín. Lẹ́yìn náà, kí ìpinnu ọ̀rọ̀ yín má ṣe wà ní bòńkẹ́lẹ́ láààrin yín. Lẹ́yìn náà, kí ẹ yanjú ọ̀rọ̀ mi. Kí ẹ sì má ṣe lọ́ mi lára mọ́ فَإِن تَوَلَّيۡتُمۡ فَمَا سَأَلۡتُكُم مِّنۡ أَجۡرٍۖ إِنۡ أَجۡرِيَ إِلَّا عَلَى ٱللَّهِۖ وَأُمِرۡتُ أَنۡ أَكُونَ مِنَ ٱلۡمُسۡلِمِينَ ٧٢Tí ẹ bá sì kọ̀yìn (sí ìrántí), èmi kò kúkú tọrọ owó-ọ̀yà kan lọ́wọ́ yín. Kò sí ẹ̀san kan fún mi (níbì kan) bí kò ṣe lọ́dọ̀ Allāhu. Wọ́n sì ti pa mí láṣẹ pé kí n̄g wà nínú àwọn mùsùlùmí.” فَكَذَّبُوهُ فَنَجَّيۡنَٰهُ وَمَن مَّعَهُۥ فِي ٱلۡفُلۡكِ وَجَعَلۡنَٰهُمۡ خَلَٰٓئِفَ وَأَغۡرَقۡنَا ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَاۖ فَٱنظُرۡ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلۡمُنذَرِينَ ٧٣Nígbà náà, wọ́n pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, A gbà á là, òun àti àwọn t’ó ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú-omí. A sì ṣe wọ́n ní àrólé (lórí ilẹ̀). A sì tẹ àwọn t’ó pe āyah Wa nírọ́ rì sínú agbami. Nítorí náà, wo bí ìkángun àwọn ẹni-akìlọ̀-fún ṣe rí ثُمَّ بَعَثۡنَا مِنۢ بَعۡدِهِۦ رُسُلًا إِلَىٰ قَوۡمِهِمۡ فَجَآءُوهُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِ فَمَا كَانُواْ لِيُؤۡمِنُواْ بِمَا كَذَّبُواْ بِهِۦ مِن قَبۡلُۚ كَذَٰلِكَ نَطۡبَعُ عَلَىٰ قُلُوبِ ٱلۡمُعۡتَدِينَ ٧٤Lẹ́yìn náà, A gbé àwọn Òjíṣẹ́ kan dìde sí àwọn ìjọ wọn. Wọ́n sì mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá bá wọn. Àwọn náà kò kúkú gbàgbọ́ nínú ohun tí (ijọ́ Ànábì Nūh) pè nírọ́ ṣíwájú (wọn, ìyẹn ni pé, irú kan-ùn ni wọ́n). Báyẹn ni A ṣe ń fi èdídí bo ọkàn àwọn alákọyọ ثُمَّ بَعَثۡنَا مِنۢ بَعۡدِهِم مُّوسَىٰ وَهَٰرُونَ إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ وَمَلَإِيْهِۦ بِـَٔايَٰتِنَا فَٱسۡتَكۡبَرُواْ وَكَانُواْ قَوۡمًا مُّجۡرِمِينَ ٧٥Lẹ́yìn náà, lẹ́yìn wọn A fi àwọn àmì Wa rán (Ànábì) Mūsā àti Hārūn níṣẹ́ sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Nígbà náà, wọ́n ṣègbéraga. Wọ́n sì jẹ́ ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ فَلَمَّا جَآءَهُمُ ٱلۡحَقُّ مِنۡ عِندِنَا قَالُوٓاْ إِنَّ هَٰذَا لَسِحۡرٌ مُّبِينٌ ٧٦Nígbà tí òdodo dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Wa, wọ́n wí pé: “Dájúdájú èyí ni idán pọ́nńbélé.” قَالَ مُوسَىٰٓ أَتَقُولُونَ لِلۡحَقِّ لَمَّا جَآءَكُمۡۖ أَسِحۡرٌ هَٰذَا وَلَا يُفۡلِحُ ٱلسَّٰحِرُونَ ٧٧(Ànábì) Mūsā sọ pé: "Ṣé n̄ǹkan tí ẹ̀yin yóò máa wí nípa òdodo ni pé idán ni nígbà tí ó dé ba yín? Ṣé idán sì ni èyí bí? Àwọn òpìdán kò sì níí jèrè قَالُوٓاْ أَجِئۡتَنَا لِتَلۡفِتَنَا عَمَّا وَجَدۡنَا عَلَيۡهِ ءَابَآءَنَا وَتَكُونَ لَكُمَا ٱلۡكِبۡرِيَآءُ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَمَا نَحۡنُ لَكُمَا بِمُؤۡمِنِينَ ٧٨Wọ́n wí pé: “Ṣé o wá bá wa nítorí kí o lè ṣẹ́rí wa kúrò níbi ohun tí a bá àwọn bàbá wa lórí rẹ̀ (nínú ìbọ̀rìṣà) àti nítorí kí títóbi sì lè jẹ́ tẹ̀yin méjèèjì lórí ilẹ̀? Àwa kò sì níí gba ẹ̀yin méjèèjì gbọ́.” وَقَالَ فِرۡعَوۡنُ ٱئۡتُونِي بِكُلِّ سَٰحِرٍ عَلِيمٍ ٧٩Fir‘aon wí pé: “Ẹ lọ mú gbogbo àwọn onímọ̀ nípa idán pípa wá fún mi.” فَلَمَّا جَآءَ ٱلسَّحَرَةُ قَالَ لَهُم مُّوسَىٰٓ أَلۡقُواْ مَآ أَنتُم مُّلۡقُونَ ٨٠Nígbà tí àwọn òpìdán sì dé, (Ànábì) Mūsā sọ fún wọn pé: “Ẹ ju ohun tí ẹ máa jù sílẹ̀.” فَلَمَّآ أَلۡقَوۡاْ قَالَ مُوسَىٰ مَا جِئۡتُم بِهِ ٱلسِّحۡرُۖ إِنَّ ٱللَّهَ سَيُبۡطِلُهُۥٓ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُصۡلِحُ عَمَلَ ٱلۡمُفۡسِدِينَ ٨١Nígbà tí wọ́n jù ú sílẹ̀, (Ànábì) Mūsā sọ pé: “Idán ni ohun tí ẹ mú wá. Dájúdájú Allāhu sì máa bà á jẹ́. Dájúdájú Allāhu kò sì níí ṣàtúnṣe iṣẹ́ àwọn òbìlẹ̀jẹ́ وَيُحِقُّ ٱللَّهُ ٱلۡحَقَّ بِكَلِمَٰتِهِۦ وَلَوۡ كَرِهَ ٱلۡمُجۡرِمُونَ ٨٢Allāhu sì máa mú òdodo ṣẹ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ìbáà kórira rẹ̀ فَمَآ ءَامَنَ لِمُوسَىٰٓ إِلَّا ذُرِّيَّةٌ مِّن قَوۡمِهِۦ عَلَىٰ خَوۡفٍ مِّن فِرۡعَوۡنَ وَمَلَإِيْهِمۡ أَن يَفۡتِنَهُمۡۚ وَإِنَّ فِرۡعَوۡنَ لَعَالٍ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَإِنَّهُۥ لَمِنَ ٱلۡمُسۡرِفِينَ ٨٣Nítorí náà, kò sí ẹni t’ó gba (Ànábì) Mūsā gbọ́ àfi àwọn àrọ́mọdọ́mọ kan nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú ìbẹ̀rù-bojo (wọn) sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè wọn pé ó máa fòòró àwọn. Dájúdájú Fir‘aon kúkú ṣègbéraga lórí ilẹ̀. Àti pé, dájúdájú ó wà nínú àwọn alákọyọ وَقَالَ مُوسَىٰ يَٰقَوۡمِ إِن كُنتُمۡ ءَامَنتُم بِٱللَّهِ فَعَلَيۡهِ تَوَكَّلُوٓاْ إِن كُنتُم مُّسۡلِمِينَ ٨٤(Ànábì) Mūsā sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, tí ẹ bá jẹ́ ẹni t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu, Òun náà ni kí ẹ gbáralé tí ẹ bá jẹ́ mùsùlùmí.” فَقَالُواْ عَلَى ٱللَّهِ تَوَكَّلۡنَا رَبَّنَا لَا تَجۡعَلۡنَا فِتۡنَةً لِّلۡقَوۡمِ ٱلظَّٰلِمِينَ ٨٥Nítorí náà, wọ́n sọ pé: "Allāhu la gbáralé. Olúwa wa, má ṣe wá ní àdánwò fún ìjọ alábòsí وَنَجِّنَا بِرَحۡمَتِكَ مِنَ ٱلۡقَوۡمِ ٱلۡكَٰفِرِينَ ٨٦Kí Ó sì fi àánú Rẹ gbà wá là lọ́wọ́ ìjọ aláìgbàgbọ́ وَأَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰ مُوسَىٰ وَأَخِيهِ أَن تَبَوَّءَا لِقَوۡمِكُمَا بِمِصۡرَ بُيُوتًا وَٱجۡعَلُواْ بُيُوتَكُمۡ قِبۡلَةً وَأَقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَۗ وَبَشِّرِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ٨٧A sì ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā àti arákùnrin rẹ̀ pé: “Kí ẹ̀yin méjèèjì mú àwọn ibùgbé fún àwọn ènìyàn yín sí ìlú Misrọ. Kí ẹ sì sọ ibùgbé yín di ibùkírun. Kí ẹ sì máa kírun. Àti pé, fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ìró ìdùnnú.” وَقَالَ مُوسَىٰ رَبَّنَآ إِنَّكَ ءَاتَيۡتَ فِرۡعَوۡنَ وَمَلَأَهُۥ زِينَةً وَأَمۡوَٰلًا فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا رَبَّنَا لِيُضِلُّواْ عَن سَبِيلِكَۖ رَبَّنَا ٱطۡمِسۡ عَلَىٰٓ أَمۡوَٰلِهِمۡ وَٱشۡدُدۡ عَلَىٰ قُلُوبِهِمۡ فَلَا يُؤۡمِنُواْ حَتَّىٰ يَرَوُاْ ٱلۡعَذَابَ ٱلۡأَلِيمَ ٨٨(Ànábì) Mūsā sọ pé: "Olúwa wa, dájúdájú Ìwọ l’O fún Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀ ní ọ̀ṣọ́ àti dúkìá nínú ìṣẹ̀mí ayé. Olúwa wa, (O fún wọn) nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Rẹ. Olúwa wa, pa dúkìá wọn rẹ́, kí O sì mú ọkàn wọn le, kí wọ́n má gbàgbọ́ mọ́ títí wọn fi máa rí ìyà ẹlẹ́ta-eléro قَالَ قَدۡ أُجِيبَت دَّعۡوَتُكُمَا فَٱسۡتَقِيمَا وَلَا تَتَّبِعَآنِّ سَبِيلَ ٱلَّذِينَ لَا يَعۡلَمُونَ ٨٩(Allāhu) sọ pé: "Dájúdájú Mo ti gba àdúà ẹ̀yin méjèèjì. Nítorí náà, kí ẹ̀yin méjèèjì dúró ṣinṣin. Ẹ má ṣe tẹ̀lé ojú ọ̀nà àwọn tí kò nímọ̀ ۞ وَجَٰوَزۡنَا بِبَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ ٱلۡبَحۡرَ فَأَتۡبَعَهُمۡ فِرۡعَوۡنُ وَجُنُودُهُۥ بَغۡيًا وَعَدۡوًاۖ حَتَّىٰٓ إِذَآ أَدۡرَكَهُ ٱلۡغَرَقُ قَالَ ءَامَنتُ أَنَّهُۥ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا ٱلَّذِيٓ ءَامَنَتۡ بِهِۦ بَنُوٓاْ إِسۡرَٰٓءِيلَ وَأَنَا۠ مِنَ ٱلۡمُسۡلِمِينَ ٩٠A mú àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl la agbami odò já. Fir‘aon àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì gbá tọ̀ wọ́n lẹ́yìn, ní ti àbòsí àti ìtayọ ẹnu-àlà, títí ìtẹ̀rì sínú agbami òkun fi bá a. Ó sì wí pé: “Mo gbàgbọ́ pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Ẹni tí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl gbàgbọ́. Mo sì wà nínú àwọn mùsùlùmí.” ءَآلۡـَٰٔنَ وَقَدۡ عَصَيۡتَ قَبۡلُ وَكُنتَ مِنَ ٱلۡمُفۡسِدِينَ ٩١Ṣé nísinsìn yìí, tí ìwọ ti yapa ṣíwájú, tí o sì wà nínú àwọn òbìlẹ̀jẹ́ فَٱلۡيَوۡمَ نُنَجِّيكَ بِبَدَنِكَ لِتَكُونَ لِمَنۡ خَلۡفَكَ ءَايَةًۚ وَإِنَّ كَثِيرًا مِّنَ ٱلنَّاسِ عَنۡ ءَايَٰتِنَا لَغَٰفِلُونَ ٩٢Nítorí náà, ní òní ní A óò gbé òkú rẹ jáde sí orí ilẹ̀ téńté nítorí kí o lè jẹ́ àmì (fèyíkọ́gbọ́n) fún àwọn t’ó ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ. Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn ènìyàn mà ni afọ́nú-fọ́ra nípa àwọn āyah Wa وَلَقَدۡ بَوَّأۡنَا بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ مُبَوَّأَ صِدۡقٍ وَرَزَقۡنَٰهُم مِّنَ ٱلطَّيِّبَٰتِ فَمَا ٱخۡتَلَفُواْ حَتَّىٰ جَآءَهُمُ ٱلۡعِلۡمُۚ إِنَّ رَبَّكَ يَقۡضِي بَيۡنَهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ فِيمَا كَانُواْ فِيهِ يَخۡتَلِفُونَ ٩٣A kúkú ṣe ibùgbé fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl ní ibùgbé alápọ̀n-ọ́nlé. A sì pèsè fún wọn nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa. Nígbà náà, wọn kò yapa ẹnu (sí ’Islām) títí ìmọ̀ fi dé bá wọn. Dájúdájú Olúwa rẹ yóò ṣèdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí فَإِن كُنتَ فِي شَكٍّ مِّمَّآ أَنزَلۡنَآ إِلَيۡكَ فَسۡـَٔلِ ٱلَّذِينَ يَقۡرَءُونَ ٱلۡكِتَٰبَ مِن قَبۡلِكَۚ لَقَدۡ جَآءَكَ ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّكَ فَلَا تَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡمُمۡتَرِينَ ٩٤Tí o bá wà nínú iyèméjì nípa n̄ǹkan tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ (pé orúkọ rẹ àti àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ wà nínú Taorāt àti ’Injīl), bi àwọn t’ó ń ka Tírà ṣíwájú rẹ léèrè wò. Dájúdájú òdodo ti dé bá ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ wà lára àwọn oníyèméjì وَلَا تَكُونَنَّ مِنَ ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ فَتَكُونَ مِنَ ٱلۡخَٰسِرِينَ ٩٥O ò gbọdọ̀ wà lára àwọn t’ó pe àwọn āyah Allāhu nírọ́, nítorí kí o má baà wà lára àwọn ẹni òfò إِنَّ ٱلَّذِينَ حَقَّتۡ عَلَيۡهِمۡ كَلِمَتُ رَبِّكَ لَا يُؤۡمِنُونَ ٩٦Dájúdájú àwọn tí ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ ti kò lé lórí, wọn kò níí gbàgbọ́ وَلَوۡ جَآءَتۡهُمۡ كُلُّ ءَايَةٍ حَتَّىٰ يَرَوُاْ ٱلۡعَذَابَ ٱلۡأَلِيمَ ٩٧gbogbo āyah ìbáà dé bá wọn, títí wọ́n máa fi rí ìyà ẹlẹ́ta-eléro فَلَوۡلَا كَانَتۡ قَرۡيَةٌ ءَامَنَتۡ فَنَفَعَهَآ إِيمَٰنُهَآ إِلَّا قَوۡمَ يُونُسَ لَمَّآ ءَامَنُواْ كَشَفۡنَا عَنۡهُمۡ عَذَابَ ٱلۡخِزۡيِ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا وَمَتَّعۡنَٰهُمۡ إِلَىٰ حِينٍ ٩٨Kò kúkú sí ìlú kàn, t’ó gbàgbọ́ (lásìkò ìyà), tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ sì ṣe é ní àǹfààní àfi ìjọ (Ànábì) Yūnus. Nígbà tí wọ́n gbàgbọ́, A mú àbùkù ìyà kúrò fún wọn nínú ìṣẹ̀mí ayé. A sì jẹ́ kí wọ́n jẹ ìgbádùn ayé fún ìgbà díẹ̀ وَلَوۡ شَآءَ رَبُّكَ لَأٓمَنَ مَن فِي ٱلۡأَرۡضِ كُلُّهُمۡ جَمِيعًاۚ أَفَأَنتَ تُكۡرِهُ ٱلنَّاسَ حَتَّىٰ يَكُونُواْ مُؤۡمِنِينَ ٩٩Tí ó bá jẹ́ pé Olúwa rẹ bá fẹ́, àwọn tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ìbá gbàgbọ́, gbogbo wọn pátápátá. Nítorí náà, ṣé ìwọ l’o máa jẹ wọ́n nípá ni títí wọn yóò fi di onígbàgbọ́ òdodo وَمَا كَانَ لِنَفۡسٍ أَن تُؤۡمِنَ إِلَّا بِإِذۡنِ ٱللَّهِۚ وَيَجۡعَلُ ٱلرِّجۡسَ عَلَى ٱلَّذِينَ لَا يَعۡقِلُونَ ١٠٠Ẹ̀mí kan kò lè gbàgbọ́ àfi pẹ̀lú àṣẹ Allāhu. Ó sì máa fi ìyà jẹ àwọn tí kò ṣe làákàyè قُلِ ٱنظُرُواْ مَاذَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ وَمَا تُغۡنِي ٱلۡأٓيَٰتُ وَٱلنُّذُرُ عَن قَوۡمٍ لَّا يُؤۡمِنُونَ ١٠١Sọ pé: "Ẹ wòye sí n̄ǹkan tí ń bẹ nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àwọn āyah àti ìkìlọ̀ kò sì níí rọ ìjọ aláìgbàgbọ́ lọ́rọ̀ فَهَلۡ يَنتَظِرُونَ إِلَّا مِثۡلَ أَيَّامِ ٱلَّذِينَ خَلَوۡاْ مِن قَبۡلِهِمۡۚ قُلۡ فَٱنتَظِرُوٓاْ إِنِّي مَعَكُم مِّنَ ٱلۡمُنتَظِرِينَ ١٠٢Nítorí náà, ṣé wọ́n tún ń retí (n̄ǹkan mìíràn) ni bí kò ṣe (ìparun) irú ti ìgbà àwọn t’ó ré kọjá lọ ṣíwájú wọn. Sọ pé: “Ẹ máa retí nígbà náà. Dájúdájú èmi náà wà pẹ̀lú yín nínú àwọn olùretí.” ثُمَّ نُنَجِّي رُسُلَنَا وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْۚ كَذَٰلِكَ حَقًّا عَلَيۡنَا نُنجِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ١٠٣Lẹ́yìn náà, A óò gba àwọn Òjíṣẹ́ Wa àti àwọn t’ó gbàgbọ́ là. Báyẹn ní ó ṣe jẹ́ ojúṣe Wa láti gba àwọn onígbàgbọ́ òdodo là قُلۡ يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ إِن كُنتُمۡ فِي شَكٍّ مِّن دِينِي فَلَآ أَعۡبُدُ ٱلَّذِينَ تَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَلَٰكِنۡ أَعۡبُدُ ٱللَّهَ ٱلَّذِي يَتَوَفَّىٰكُمۡۖ وَأُمِرۡتُ أَنۡ أَكُونَ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ١٠٤Sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, tí ẹ bá wà nínú iyèméjì nípa ẹ̀sìn mi. Nígbà náà, èmi kò níí jọ́sìn fún àwọn tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu. Ṣùgbọ́n èmi yóò máa jọ́sìn fún Allāhu, Ẹni tí Ó máa gba ẹ̀mí yín. Wọ́n sì pa mí ní àṣẹ pé kí n̄g wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo وَأَنۡ أَقِمۡ وَجۡهَكَ لِلدِّينِ حَنِيفًا وَلَا تَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ ١٠٥(Wọ́n tún pa mí láṣẹ pé): “Dojú rẹ kọ ẹ̀sìn náà, (kí o jẹ́) olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn. Ìwọ kò sì gbọdọ̀ wà nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ وَلَا تَدۡعُ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَا لَا يَنفَعُكَ وَلَا يَضُرُّكَۖ فَإِن فَعَلۡتَ فَإِنَّكَ إِذًا مِّنَ ٱلظَّٰلِمِينَ ١٠٦Àti pé má ṣe pè lẹ́yìn Allāhu n̄ǹkan tí kò lè ṣe ọ́ ní àǹfààní, tí kò sì lè kó ìnira bá ọ. Tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà náà, dájúdájú ìwọ ti wà nínú àwọn alábòsí.” وَإِن يَمۡسَسۡكَ ٱللَّهُ بِضُرٍّ فَلَا كَاشِفَ لَهُۥٓ إِلَّا هُوَۖ وَإِن يُرِدۡكَ بِخَيۡرٍ فَلَا رَآدَّ لِفَضۡلِهِۦۚ يُصِيبُ بِهِۦ مَن يَشَآءُ مِنۡ عِبَادِهِۦۚ وَهُوَ ٱلۡغَفُورُ ٱلرَّحِيمُ ١٠٧Tí Allāhu bá mú ìnira bá ọ, kò sí ẹni tí ó lè mú un kúrò àfi Òun. Tí Ó bá sì gbèrò oore kan pẹ̀lú rẹ, kò sí ẹni tí ó lè dá oore Rẹ̀ padà. Ó ń ṣoore fún ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run قُلۡ يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ قَدۡ جَآءَكُمُ ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّكُمۡۖ فَمَنِ ٱهۡتَدَىٰ فَإِنَّمَا يَهۡتَدِي لِنَفۡسِهِۦۖ وَمَن ضَلَّ فَإِنَّمَا يَضِلُّ عَلَيۡهَاۖ وَمَآ أَنَا۠ عَلَيۡكُم بِوَكِيلٍ ١٠٨Sọ pé: "Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú òdodo ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀nà, ó mọ̀nà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣìnà, ó ṣìnà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Èmi sì kọ́ ni olùṣọ́ fun yín وَٱتَّبِعۡ مَا يُوحَىٰٓ إِلَيۡكَ وَٱصۡبِرۡ حَتَّىٰ يَحۡكُمَ ٱللَّهُۚ وَهُوَ خَيۡرُ ٱلۡحَٰكِمِينَ ١٠٩Tẹ̀lé ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ nínú ìmísí. Kí o sì ṣe sùúrù títí Allāhu yóò fi ṣe ìdájọ́. Òun sì lóore julọ nínú àwọn olùdájọ́

Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.