بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
وَٱلضُّحَىٰ ١(Allāhu búra pẹ̀lú) ìyálẹ̀ta وَٱلَّيۡلِ إِذَا سَجَىٰ ٢Ó tún búra pẹ̀lú alẹ́ nígbà tí (ilẹ̀) bá ṣú مَا وَدَّعَكَ رَبُّكَ وَمَا قَلَىٰ ٣Olúwa rẹ kò pa ọ́ tì, kò sì bínú sí ọ وَلَلۡأٓخِرَةُ خَيۡرٌ لَّكَ مِنَ ٱلۡأُولَىٰ ٤Dájúdájú ọ̀run lóore fún ọ ju ayé lọ وَلَسَوۡفَ يُعۡطِيكَ رَبُّكَ فَتَرۡضَىٰٓ ٥Dájúdájú láìpẹ́ Olúwa rẹ máa fún ọ ní (oore púpọ̀ ní ọ̀run). Nítorí náà, o sì máa yọ́nú sí i أَلَمۡ يَجِدۡكَ يَتِيمًا فَـَٔاوَىٰ ٦Ṣé (Allāhu) kò rí ọ ní ọmọ-òrukàn ni? Ó sì fún ọ ní ibùgbé وَوَجَدَكَ ضَآلًّا فَهَدَىٰ ٧Ó sì rí ọ ní aláìmọ̀nà (ìyẹn ṣíwájú ìsọ̀kalẹ̀ ìmísí). Ó sì fi ọ̀nà mọ̀ ọ́ وَوَجَدَكَ عَآئِلًا فَأَغۡنَىٰ ٨Ó tún rí ọ ní aláìní, Ó sì rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ فَأَمَّا ٱلۡيَتِيمَ فَلَا تَقۡهَرۡ ٩Nítorí náà, ní ti ọmọ-òrukàn, má ṣe jẹ gàba (lé e lórí) وَأَمَّا ٱلسَّآئِلَ فَلَا تَنۡهَرۡ ١٠Ní ti alágbe, má sì ṣe jágbe (mọ́ ọn) وَأَمَّا بِنِعۡمَةِ رَبِّكَ فَحَدِّثۡ ١١Ní ti ìdẹ̀ra Olúwa rẹ, sọ ọ́ jáde