بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
وَٱلۡعَٰدِيَٰتِ ضَبۡحًا ١Allāhu búra pẹ̀lú àwọn ẹṣin t’ó ń sáré t’ó ń mí hẹlẹhẹlẹ ní ojú-ogun فَٱلۡمُورِيَٰتِ قَدۡحًا ٢Ó tún búra pẹ̀lú àwọn ẹṣin tí pátákò ẹsẹ̀ wọn ń ṣáná (níbi eré sísá) فَٱلۡمُغِيرَٰتِ صُبۡحًا ٣Ó tún búra pẹ̀lú àwọn ẹṣin t’ó ń kọlu ọ̀tá ẹ̀sìn ní òwúrọ̀ kùtùkùtù فَأَثَرۡنَ بِهِۦ نَقۡعًا ٤Wọ́n sì fi (pátákò ẹsẹ̀ wọn) tu eruku (ilẹ̀ ọ̀tá) sókè فَوَسَطۡنَ بِهِۦ جَمۡعًا ٥Wọ́n tún bẹ́ gìjà papọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ sáààrin àkójọ ọ̀tá إِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ لِرَبِّهِۦ لَكَنُودٌ ٦Dájúdájú ènìyàn ni aláìmoore sí Olúwa rẹ̀ وَإِنَّهُۥ عَلَىٰ ذَٰلِكَ لَشَهِيدٌ ٧Dájúdájú Allāhu sì ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí lórí ìyẹn وَإِنَّهُۥ لِحُبِّ ٱلۡخَيۡرِ لَشَدِيدٌ ٨Àti pé dájúdájú ènìyàn le gan-an níbi ìfẹ́ oore ayé ۞ أَفَلَا يَعۡلَمُ إِذَا بُعۡثِرَ مَا فِي ٱلۡقُبُورِ ٩Ṣé kò mọ̀ pé nígbà tí wọ́n bá tú ohun t’ó wà nínú sàréè jáde (fún àjíǹde) وَحُصِّلَ مَا فِي ٱلصُّدُورِ ١٠tí wọ́n sì tú ohun t’ó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá síta pátápátá إِنَّ رَبَّهُم بِهِمۡ يَوۡمَئِذٍ لَّخَبِيرُۢ ١١dájúdájú Olúwa wọn ni Alámọ̀tán nípa wọn ní Ọjọ́ yẹn