ملة الإسلام

السورة 96 · 19 آية · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

سورة العلق باللغة اليوروبا

السورة بالعربية مع التفسير استمع إلى سورة العلق (1,283 قارئاً)
مكيةسورة العلق١٩ آية

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

ٱقۡرَأۡ بِٱسۡمِ رَبِّكَ ٱلَّذِي خَلَقَ ١Ké (al-Ƙur’ān) pẹ̀lú orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá خَلَقَ ٱلۡإِنسَٰنَ مِنۡ عَلَقٍ ٢Ó ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara ẹ̀jẹ̀ dídì ٱقۡرَأۡ وَرَبُّكَ ٱلۡأَكۡرَمُ ٣Ké e. Olúwa rẹ ni Alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ ٱلَّذِي عَلَّمَ بِٱلۡقَلَمِ ٤Ẹni tí Ó fi ìmọ̀ nípa gègé ìkọ̀wé mọ ènìyàn عَلَّمَ ٱلۡإِنسَٰنَ مَا لَمۡ يَعۡلَمۡ ٥Ó fi ìmọ̀ tí ènìyàn kò mọ̀ mọ̀ ọ́n كـَلَّآ إِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ لَيَطۡغَىٰٓ ٦Ní ti òdodo, dájúdájú ènìyàn kúkú ń tayọ ẹnu-àlà أَن رَّءَاهُ ٱسۡتَغۡنَىٰٓ ٧nítorí pé ó ríra rẹ̀ ní ọlọ́rọ̀ إِنَّ إِلَىٰ رَبِّكَ ٱلرُّجۡعَىٰٓ ٨Dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni àbọ̀ ẹ̀dá أَرَءَيۡتَ ٱلَّذِي يَنۡهَىٰ ٩Sọ fún mi nípa ẹni t’ó ń kọ̀ عَبۡدًا إِذَا صَلَّىٰٓ ١٠fún ẹrúsìn kan nígbà tí (ẹrúsìn náà) kírun أَرَءَيۡتَ إِن كَانَ عَلَى ٱلۡهُدَىٰٓ ١١Sọ fún mi (nípa ẹ̀san rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó wà lórí ìmọ̀nà (’Islām) أَوۡ أَمَرَ بِٱلتَّقۡوَىٰٓ ١٢tàbí pé ó pàṣẹ ìbẹ̀rù (Allāhu) أَرَءَيۡتَ إِن كَذَّبَ وَتَوَلَّىٰٓ ١٣Sọ fún mi (nípa ìyà rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó pe òdodo nírọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i أَلَمۡ يَعۡلَم بِأَنَّ ٱللَّهَ يَرَىٰ ١٤Ṣé kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ń rí (òun ni) كـَلَّا لَئِن لَّمۡ يَنتَهِ لَنَسۡفَعَۢا بِٱلنَّاصِيَةِ ١٥Bẹ́ẹ̀ ni (Allāhu ń rí i.) Dájúdájú tí kò bá jáwọ́ (níbi dídí i lọ́wọ́), dájúdájú A máa fi àásó orí rẹ̀ wọ́ ọ (sínú Iná) نَاصِيَةٍ كَٰذِبَةٍ خَاطِئَةٍ ١٦àásó orí òpùrọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀ فَلۡيَدۡعُ نَادِيَهُۥ ١٧Nítorí náà, kí ó pe àwọn olùbájókòó rẹ̀ سَنَدۡعُ ٱلزَّبَانِيَةَ ١٨Àwa máa pe àwọn mọlāika ẹ̀ṣọ́ Iná كـَلَّا لَا تُطِعۡهُ وَٱسۡجُدۡۤ وَٱقۡتَرِب ۩ ١٩Rárá o, má ṣe tẹ̀lé tirẹ̀. Forí kanlẹ̀ (kí o kírun), kí o súnmọ́ (Allāhu)

الترجمة: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.