بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
لَآ أُقۡسِمُ بِهَٰذَا ٱلۡبَلَدِ ١Èmi (Allāhu) búra pẹ̀lú ìlú yìí وَأَنتَ حِلُّۢ بِهَٰذَا ٱلۡبَلَدِ ٢Ìwọ sì ní ẹ̀tọ́ sí ìlú yìí (láti jagun nínú rẹ̀) وَوَالِدٍ وَمَا وَلَدَ ٣(Mo tún) búra pẹ̀lú òbí àti ohun t’ó bí لَقَدۡ خَلَقۡنَا ٱلۡإِنسَٰنَ فِي كَبَدٍ ٤Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn sínú ìṣòro أَيَحۡسَبُ أَن لَّن يَقۡدِرَ عَلَيۡهِ أَحَدٌ ٥Ṣé ó ń lérò pé ẹnì kan kò ní agbára lórí òun ni يَقُولُ أَهۡلَكۡتُ مَالًا لُّبَدًا ٦Ó (sì) ń wí pé: "Èmi ti bàná dúkìá ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ (láti fi tako Ànábì s.a.w) أَيَحۡسَبُ أَن لَّمۡ يَرَهُۥٓ أَحَدٌ ٧Ṣé ó ń lérò pé ẹnì kan kò rí òun ni أَلَمۡ نَجۡعَل لَّهُۥ عَيۡنَيۡنِ ٨Ṣé A kò ṣe ojú méjì fún un وَلِسَانًا وَشَفَتَيۡنِ ٩Àti ahọ́n pẹ̀lú ètè méjì (tí A ṣe fún un) وَهَدَيۡنَٰهُ ٱلنَّجۡدَيۡنِ ١٠A sì fi ọ̀nà méjì mọ̀ ọ́n فَلَا ٱقۡتَحَمَ ٱلۡعَقَبَةَ ١١Kò sì mú àkàbà ìgbàlà gùn وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا ٱلۡعَقَبَةُ ١٢Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ àkàbà ìgbàlà فَكُّ رَقَبَةٍ ١٣(Òhun ni) títú ẹrú sílẹ̀ lóko ẹrú أَوۡ إِطۡعَٰمٌ فِي يَوۡمٍ ذِي مَسۡغَبَةٍ ١٤Tàbí fífún ènìyàn ní oúnjẹ ní ọjọ́ ebi يَتِيمًا ذَا مَقۡرَبَةٍ ١٥(Ó lè jẹ́) ọmọ-òrukàn nínú ẹbí أَوۡ مِسۡكِينًا ذَا مَتۡرَبَةٍ ١٦tàbí mẹ́kùnnú, ẹni ilẹ̀ẹ́lẹ̀ ثُمَّ كَانَ مِنَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَتَوَاصَوۡاْ بِٱلصَّبۡرِ وَتَوَاصَوۡاْ بِٱلۡمَرۡحَمَةِ ١٧Lẹ́yìn náà, kí ó wà nínú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ń gbara wọn níyànjú sùúrù ṣíṣe, tí wọ́n sì tún ń gbara wọn níyànjú àánú ṣíṣe أُوْلَٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡمَيۡمَنَةِ ١٨Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò ọwọ́ ọ̀tún وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِـَٔايَٰتِنَا هُمۡ أَصۡحَٰبُ ٱلۡمَشۡـَٔمَةِ ١٩Àwọn t’ó sì ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, àwọn ni èrò ọwọ́ òsì عَلَيۡهِمۡ نَارٌ مُّؤۡصَدَةُۢ ٢٠A máa ti àwọn ìlẹ̀kùn Iná pa mọ́ wọn lórí pátápátá