ملة الإسلام

السورة 59 · 24 آية · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

سورة الحشر باللغة اليوروبا

السورة بالعربية مع التفسير استمع إلى سورة الحشر (1,236 قارئاً)
مدنيةسورة الحشر٢٤ آية

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

سَبَّحَ لِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۖ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ ١Ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀ ń ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n هُوَ ٱلَّذِيٓ أَخۡرَجَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ مِنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ مِن دِيَٰرِهِمۡ لِأَوَّلِ ٱلۡحَشۡرِۚ مَا ظَنَنتُمۡ أَن يَخۡرُجُواْۖ وَظَنُّوٓاْ أَنَّهُم مَّانِعَتُهُمۡ حُصُونُهُم مِّنَ ٱللَّهِ فَأَتَىٰهُمُ ٱللَّهُ مِنۡ حَيۡثُ لَمۡ يَحۡتَسِبُواْۖ وَقَذَفَ فِي قُلُوبِهِمُ ٱلرُّعۡبَۚ يُخۡرِبُونَ بُيُوتَهُم بِأَيۡدِيهِمۡ وَأَيۡدِي ٱلۡمُؤۡمِنِينَ فَٱعۡتَبِرُواْ يَٰٓأُوْلِي ٱلۡأَبۡصَٰرِ ٢Òun ni Ẹni tí Ó mú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn ahlu-l-kitāb jáde kúrò nínú ilé wọn fún ìkójọ àkọ́kọ́. Ẹ̀yin kò lérò pé wọn yóò jáde. Àwọn náà sì lérò pé dájúdájú àwọn odi ilé wọn yóò dáàbò bo àwọn lọ́dọ̀ Allāhu. Ṣùgbọ́n Allāhu wá bá wọn ní ibi tí wọn kò lérò; Allāhu sì ju ìbẹ̀rù sínú ọkàn wọn. Wọ́n ń fi ọwọ́ ara wọn àti ọwọ́ àwọn onígbàgbọ́ òdodo wó àwọn ilé wọn. Nítorí náà, ẹ wòye, ẹ̀yin tí ẹ ní ojú ìríran وَلَوۡلَآ أَن كَتَبَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِمُ ٱلۡجَلَآءَ لَعَذَّبَهُمۡ فِي ٱلدُّنۡيَاۖ وَلَهُمۡ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ عَذَابُ ٱلنَّارِ ٣Àti pé tí kò bá jẹ́ pé Allāhu ti kọ ìjáde kúrò nínú ìlú Mọdīnah lé àwọn ahlu-l-kitāb lórí ni, dájúdájú (Allāhu) ìbá jẹ wọ́n níyà nílé ayé. Ìyà Iná sì tún wà fún wọn ní ọ̀run ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ شَآقُّواْ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥۖ وَمَن يُشَآقِّ ٱللَّهَ فَإِنَّ ٱللَّهَ شَدِيدُ ٱلۡعِقَابِ ٤Ìyẹn nítorí pé dájúdájú wọ́n yapa (àṣẹ) Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá yapa (àṣẹ) Allāhu, dájúdájú Allāhu le níbi ìyà مَا قَطَعۡتُم مِّن لِّينَةٍ أَوۡ تَرَكۡتُمُوهَا قَآئِمَةً عَلَىٰٓ أُصُولِهَا فَبِإِذۡنِ ٱللَّهِ وَلِيُخۡزِيَ ٱلۡفَٰسِقِينَ ٥Ẹ̀yin kò níí ge igi dàbínù kan tàbí kí ẹ fi sílẹ̀ kí ó dúró sórí gbòǹgbò rẹ̀, (àfi) pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. (Ó rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Ó lè dójú ti àwọn òbìlẹ̀jẹ́ ni وَمَآ أَفَآءَ ٱللَّهُ عَلَىٰ رَسُولِهِۦ مِنۡهُمۡ فَمَآ أَوۡجَفۡتُمۡ عَلَيۡهِ مِنۡ خَيۡلٍ وَلَا رِكَابٍ وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ يُسَلِّطُ رُسُلَهُۥ عَلَىٰ مَن يَشَآءُۚ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٍ قَدِيرٌ ٦Ohunkóhun tí Allāhu bá dá padà láti ọ̀dọ̀ wọn fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀, tí ẹ ò gbé ẹṣin àti ràkúnmí sáré fún (ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ni). Ṣùgbọ́n Allāhu yóò máa fún àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ní agbára lórí ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan مَّآ أَفَآءَ ٱللَّهُ عَلَىٰ رَسُولِهِۦ مِنۡ أَهۡلِ ٱلۡقُرَىٰ فَلِلَّهِ وَلِلرَّسُولِ وَلِذِي ٱلۡقُرۡبَىٰ وَٱلۡيَتَٰمَىٰ وَٱلۡمَسَٰكِينِ وَٱبۡنِ ٱلسَّبِيلِ كَيۡ لَا يَكُونَ دُولَةَۢ بَيۡنَ ٱلۡأَغۡنِيَآءِ مِنكُمۡۚ وَمَآ ءَاتَىٰكُمُ ٱلرَّسُولُ فَخُذُوهُ وَمَا نَهَىٰكُمۡ عَنۡهُ فَٱنتَهُواْۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَۖ إِنَّ ٱللَّهَ شَدِيدُ ٱلۡعِقَابِ ٧Ohunkóhun tí Allāhu bá dá padà láti ọ̀dọ̀ àwọn ará ìlú fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀, (ó jẹ́) ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ àti ti àwọn ìbátan, àwọn ọmọ òrukàn, àwọn tálíkà àti onírìn-àjò tí agara dá nítorí kí ó má baá jẹ́ àdápín láààrin àwọn ọlọ́rọ̀ nínú yín. Ohunkóhun tí Òjíṣẹ́ bá fun yín, ẹ gbà á. Ohunkóhun tí ó bá sì kọ̀ fun yín, ẹ jáwọ́ nínú rẹ. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu le níbi ìyà لِلۡفُقَرَآءِ ٱلۡمُهَٰجِرِينَ ٱلَّذِينَ أُخۡرِجُواْ مِن دِيَٰرِهِمۡ وَأَمۡوَٰلِهِمۡ يَبۡتَغُونَ فَضۡلًا مِّنَ ٱللَّهِ وَرِضۡوَٰنًا وَيَنصُرُونَ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥٓۚ أُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلصَّٰدِقُونَ ٨(Ìkógun náà tún wà fún) àwọn aláìní, (ìyẹn,) al-Muhājirūn, àwọn tí wọ́n lé jáde kúrò nínú ilé wọn àti níbi dúkìá wọn, tí wọ́n sì ń wá oore àjùlọ àti ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Allāhu, tí wọ́n sì ń ṣàrànṣe fún (ẹ̀sìn) Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olódodo وَٱلَّذِينَ تَبَوَّءُو ٱلدَّارَ وَٱلۡإِيمَٰنَ مِن قَبۡلِهِمۡ يُحِبُّونَ مَنۡ هَاجَرَ إِلَيۡهِمۡ وَلَا يَجِدُونَ فِي صُدُورِهِمۡ حَاجَةً مِّمَّآ أُوتُواْ وَيُؤۡثِرُونَ عَلَىٰٓ أَنفُسِهِمۡ وَلَوۡ كَانَ بِهِمۡ خَصَاصَةٌۚ وَمَن يُوقَ شُحَّ نَفۡسِهِۦ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡمُفۡلِحُونَ ٩Àwọn t’ó ń gbé nínú ìlú Mọdīnah, tí wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ òdodo ṣíwájú wọn, wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn t’ó fi ìlú Mọkkah sílẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wọn (ní ìlú Mọdīnah). Wọn kò sì ní bùkátà kan nínú igbá-àyà wọn sí n̄ǹkan tí wọ́n fún wọn. Wọ́n sì ń gbé àjùlọ fún wọn lórí ẹ̀mí ara wọn, kódà kí ó jẹ́ pé àwọn gan-an ní bùkátà (sí ohun tí wọ́n fún wọn). Ẹnikẹ́ni tí A bá ṣọ́ níbi ahun àti ọ̀kánjúà inú ẹ̀mí rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni olùjèrè وَٱلَّذِينَ جَآءُو مِنۢ بَعۡدِهِمۡ يَقُولُونَ رَبَّنَا ٱغۡفِرۡ لَنَا وَلِإِخۡوَٰنِنَا ٱلَّذِينَ سَبَقُونَا بِٱلۡإِيمَٰنِ وَلَا تَجۡعَلۡ فِي قُلُوبِنَا غِلًّا لِّلَّذِينَ ءَامَنُواْ رَبَّنَآ إِنَّكَ رَءُوفٌ رَّحِيمٌ ١٠Àwọn t’ó dé lẹ́yìn wọn ń sọ pé: "Olúwa wa, foríjin àwa àti àwọn ọmọ ìyá wa t’ó ṣíwájú wa nínú ìgbàgbọ́ òdodo. Má ṣe jẹ́ kí inúnibíni wà nínú ọkàn wa sí àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo. Olúwa wa, dájúdájú Ìwọ ni Aláàánú, Àṣàkẹ́-ọ̀run ۞ أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ نَافَقُواْ يَقُولُونَ لِإِخۡوَٰنِهِمُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ مِنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ لَئِنۡ أُخۡرِجۡتُمۡ لَنَخۡرُجَنَّ مَعَكُمۡ وَلَا نُطِيعُ فِيكُمۡ أَحَدًا أَبَدًا وَإِن قُوتِلۡتُمۡ لَنَنصُرَنَّكُمۡ وَٱللَّهُ يَشۡهَدُ إِنَّهُمۡ لَكَٰذِبُونَ ١١Ṣé o ò rí àwọn t’ó ṣọ̀bẹ-ṣèlu tí wọ́n ń wí fún àwọn ọmọ ìyá wọn, àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn ahlul-kitāb, pé "Dájúdájú tí wọ́n bá le yín jáde (kúrò nínú ìlú), àwa náà gbọ́dọ̀ jáde pẹ̀lú yín ni. Àwa kò sì níí tẹ̀lé àṣẹ ẹnì kan lórí yín láéláé. Tí wọ́n bá sì gbé ogun dìde si yín, àwa gbọ́dọ̀ ṣe ìrànlọ́wọ́ fun yín ni." Allāhu sì ń jẹ́rìí pé dájúdájú òpùrọ́ ni wọ́n لَئِنۡ أُخۡرِجُواْ لَا يَخۡرُجُونَ مَعَهُمۡ وَلَئِن قُوتِلُواْ لَا يَنصُرُونَهُمۡ وَلَئِن نَّصَرُوهُمۡ لَيُوَلُّنَّ ٱلۡأَدۡبَٰرَ ثُمَّ لَا يُنصَرُونَ ١٢Dájúdájú tí wọ́n bá lé wọn jáde, wọn kò níí jáde pẹ̀lú wọn. Dájúdájú tí wọ́n bá sì gbógun tì wọ́n, wọn kò níí ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn. Tí wọ́n bá sì wá ìrànlọ́wọ́ wọn, dájúdájú wọn yóò pẹ̀yìn dà (láti fẹsẹ̀ fẹ́ẹ). Lẹ́yìn náà, wọn kò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́ لَأَنتُمۡ أَشَدُّ رَهۡبَةً فِي صُدُورِهِم مِّنَ ٱللَّهِۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ قَوۡمٌ لَّا يَفۡقَهُونَ ١٣Dájúdájú ẹ̀yin ni ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ t’ó lágbára ju Allāhu lọ nínú igbá-àyà wọn. Ìyẹn nítorí pé dájúdájú àwọn ni ìjọ tí kò gbọ́ àgbọ́yé لَا يُقَٰتِلُونَكُمۡ جَمِيعًا إِلَّا فِي قُرًى مُّحَصَّنَةٍ أَوۡ مِن وَرَآءِ جُدُرِۭۚ بَأۡسُهُم بَيۡنَهُمۡ شَدِيدٌۚ تَحۡسَبُهُمۡ جَمِيعًا وَقُلُوبُهُمۡ شَتَّىٰۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ قَوۡمٌ لَّا يَعۡقِلُونَ ١٤Wọn kò lè parapọ̀ dojú ìjà kọ yín àfi (kí wọ́n) wà nínú odi ìlú tàbí (kí wọ́n wà) lẹ́yìn àwọn ògiri. Ogun ààrin ara wọn gan-an le. Ò ń lérò pé wọ́n wà ní ìrẹ́pọ̀ ni, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sì ni ọkàn wọn wà. Ìyẹn nítorí pé dájúdájú àwọn ni ìjọ tí kò ní làákàyè كَمَثَلِ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡ قَرِيبًاۖ ذَاقُواْ وَبَالَ أَمۡرِهِمۡ وَلَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٌ ١٥Àpẹẹrẹ wọn dà bí àwọn t’ó ṣíwájú wọn tí kò tí ì pẹ́ lọ títí. Wọ́n tọ́ aburú ọ̀rọ̀ ara wọn wò. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn كَمَثَلِ ٱلشَّيۡطَٰنِ إِذۡ قَالَ لِلۡإِنسَٰنِ ٱكۡفُرۡ فَلَمَّا كَفَرَ قَالَ إِنِّي بَرِيٓءٌ مِّنكَ إِنِّيٓ أَخَافُ ٱللَّهَ رَبَّ ٱلۡعَٰلَمِينَ ١٦Àpẹẹrẹ wọn dà bí Èṣù nígbà tí ó bá wí fún ènìyàn pé: "Ṣàì gbàgbọ́." Nígbà tí ó bá ṣàì gbàgbọ́ (tán), ó máa wí pé: "Dájúdájú èmi yọwọ́-yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ rẹ. Dájúdájú èmi ń páyà Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá فَكَانَ عَٰقِبَتَهُمَآ أَنَّهُمَا فِي ٱلنَّارِ خَٰلِدَيۡنِ فِيهَاۚ وَذَٰلِكَ جَزَٰٓؤُاْ ٱلظَّٰلِمِينَ ١٧Nítorí náà, ìkángun àwọn méjèèjì ni pé, dájúdájú àwọn méjèèjì yóò wà nínú Iná. Olùṣegbére ni àwọn méjèèjì nínú rẹ̀. Ìyẹn sì ni ẹ̀san àwọn alábòsí يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَلۡتَنظُرۡ نَفۡسٌ مَّا قَدَّمَتۡ لِغَدٍۖ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَۚ إِنَّ ٱللَّهَ خَبِيرُۢ بِمَا تَعۡمَلُونَ ١٨Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ̀mí kan sì wòye sí ohun tí ó tì ṣíwájú fún ọ̀la (àlùkìyáámọ̀). Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ وَلَا تَكُونُواْ كَٱلَّذِينَ نَسُواْ ٱللَّهَ فَأَنسَىٰهُمۡ أَنفُسَهُمۡۚ أُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡفَٰسِقُونَ ١٩Kí ẹ sì má ṣe dà bí àwọn t’ó gbàgbé Allāhu. (Allāhu) sì mú wọn gbàgbé ẹ̀mí ara wọn. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni òbìlẹ̀jẹ́ لَا يَسۡتَوِيٓ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِ وَأَصۡحَٰبُ ٱلۡجَنَّةِۚ أَصۡحَٰبُ ٱلۡجَنَّةِ هُمُ ٱلۡفَآئِزُونَ ٢٠Àwọn èrò inú Iná àti àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra kò dọ́gba. Àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, àwọn ni olùjèrè لَوۡ أَنزَلۡنَا هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانَ عَلَىٰ جَبَلٍ لَّرَأَيۡتَهُۥ خَٰشِعًا مُّتَصَدِّعًا مِّنۡ خَشۡيَةِ ٱللَّهِۚ وَتِلۡكَ ٱلۡأَمۡثَٰلُ نَضۡرِبُهَا لِلنَّاسِ لَعَلَّهُمۡ يَتَفَكَّرُونَ ٢١Tí ó bá jẹ́ pé A sọ al-Ƙur’ān yìí kalẹ̀ sórí àpáta ni, dájúdájú o máa rí i tí ó máa wálẹ̀, tí ó máa fọ́ pẹ́tẹpẹ̀tẹ fún ìpáyà Allāhu. Ìwọ̀nyí ni àwọn àpẹẹrẹ tí À ń fi lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn nítorí kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀ هُوَ ٱللَّهُ ٱلَّذِي لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ عَٰلِمُ ٱلۡغَيۡبِ وَٱلشَّهَٰدَةِۖ هُوَ ٱلرَّحۡمَٰنُ ٱلرَّحِيمُ ٢٢Òun ni Allāhu, kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Onímọ̀ ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba. Òun ni Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run هُوَ ٱللَّهُ ٱلَّذِي لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ٱلۡمَلِكُ ٱلۡقُدُّوسُ ٱلسَّلَٰمُ ٱلۡمُؤۡمِنُ ٱلۡمُهَيۡمِنُ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡجَبَّارُ ٱلۡمُتَكَبِّرُۚ سُبۡحَٰنَ ٱللَّهِ عَمَّا يُشۡرِكُونَ ٢٣Òun ni Allāhu, kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Ọba (ẹ̀dá), Ẹni-mímọ́ jùlọ, Aláìlábùkù, Olùjẹ́rìí-Òjíṣẹ́-Rẹ̀, Olùjẹ́rìí-ẹ̀dá Alágbára, Olùjẹni-nípá, Atóbi. Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ ohun tí wọ́n fi ń ṣẹbọ sí I هُوَ ٱللَّهُ ٱلۡخَٰلِقُ ٱلۡبَارِئُ ٱلۡمُصَوِّرُۖ لَهُ ٱلۡأَسۡمَآءُ ٱلۡحُسۡنَىٰۚ يُسَبِّحُ لَهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ ٢٤Òun ni Allāhu, Ẹlẹ́dàá, Olùpilẹ̀-ẹ̀dá, Olùyàwòrán-ẹ̀dá. TiRẹ̀ ni àwọn orúkọ t’ó dára jùlọ. Ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ń ṣàfọ̀mọ́ fún Un. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

الترجمة: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.