ملة الإسلام

السورة 77 · 50 آية · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

سورة المرسلات باللغة اليوروبا

السورة بالعربية مع التفسير استمع إلى سورة المرسلات (1,226 قارئاً)
مكيةسورة المرسلات٥٠ آية

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

وَٱلۡمُرۡسَلَٰتِ عُرۡفًا ١Allāhu búra pẹ̀lú àwọn atẹ́gùn t’ó ń sáré ní tẹ̀léǹtẹ̀lé فَٱلۡعَٰصِفَٰتِ عَصۡفًا ٢Ó búra pẹ̀lú àwọn ìjì atẹ́gùn t’ó ń jà وَٱلنَّٰشِرَٰتِ نَشۡرًا ٣Ó búra pẹ̀lú àwọn atẹ́gùn t’ó ń tú èṣújò ká فَٱلۡفَٰرِقَٰتِ فَرۡقًا ٤Ó búra pẹ̀lú àwọn t’ó ń ṣèpínyà láààrin òdodo àti irọ́ فَٱلۡمُلۡقِيَٰتِ ذِكۡرًا ٥Ó tún búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó ń mú ìrántí wá (bá àwọn Òjíṣẹ́) عُذۡرًا أَوۡ نُذۡرًا ٦(Ìrántí náà jẹ́) àwíjàre tàbí ìkìlọ̀ إِنَّمَا تُوعَدُونَ لَوَٰقِعٌ ٧Dájúdájú ohun tí A ṣe ní àdéhùn fun yín kúkú máa ṣẹlẹ̀ فَإِذَا ٱلنُّجُومُ طُمِسَتۡ ٨Nítorí náà, nígbà tí wọ́n bá pa (ìmọ́lẹ̀) ìràwọ̀ rẹ́ وَإِذَا ٱلسَّمَآءُ فُرِجَتۡ ٩àti nígbà tí wọ́n bá ṣí sánmọ̀ sílẹ̀ gbagada وَإِذَا ٱلۡجِبَالُ نُسِفَتۡ ١٠àti nígbà tí wọ́n bá ku àwọn àpáta dànù وَإِذَا ٱلرُّسُلُ أُقِّتَتۡ ١١àti nígbà tí wọ́n bá fún àwọn Òjíṣẹ́ ní àsìkò láti kójọ, (Àkókò náà ti dé nìyẹn) لِأَيِّ يَوۡمٍ أُجِّلَتۡ ١٢Ọjọ́ wo ni wọ́n so (àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí) rọ̀ fún ná لِيَوۡمِ ٱلۡفَصۡلِ ١٣Fún ọjọ́ ìpínyà (láààrin àwọn ẹ̀dá) ni وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا يَوۡمُ ٱلۡفَصۡلِ ١٤Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Ọjọ́ ìpínyà وَيۡلٌ يَوۡمَئِذٍ لِّلۡمُكَذِّبِينَ ١٥Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́ أَلَمۡ نُهۡلِكِ ٱلۡأَوَّلِينَ ١٦Ǹjẹ́ Àwa kò ti pa àwọn ẹni àkọ́kọ́ rẹ́ bí ثُمَّ نُتۡبِعُهُمُ ٱلۡأٓخِرِينَ ١٧Lẹ́yìn náà, A sì máa fi àwọn ẹni Ìkẹ́yìn tẹ̀lé wọn (nínú ìparun) كَذَٰلِكَ نَفۡعَلُ بِٱلۡمُجۡرِمِينَ ١٨Báyẹn ni A ó ti ṣe pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ وَيۡلٌ يَوۡمَئِذٍ لِّلۡمُكَذِّبِينَ ١٩Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́ أَلَمۡ نَخۡلُقكُّم مِّن مَّآءٍ مَّهِينٍ ٢٠Ṣé A ò ṣẹ̀dá yin láti inú omi lílẹ yẹpẹrẹ bí فَجَعَلۡنَٰهُ فِي قَرَارٍ مَّكِينٍ ٢١Lẹ́yìn náà, A fi sínú àyè ààbò (ìyẹn, ilé-ọmọ) إِلَىٰ قَدَرٍ مَّعۡلُومٍ ٢٢títí di gbèdéke àkókò kan tí A ti mọ̀ (ìyen, ọjọ́ ìbímọ) فَقَدَرۡنَا فَنِعۡمَ ٱلۡقَٰدِرُونَ ٢٣A sì ní ìkápá àti àyànmọ́ (lórí rẹ̀). (Àwa sì ni) Olùkápá àti Olùpèbùbù ẹ̀dá t’ó dára وَيۡلٌ يَوۡمَئِذٍ لِّلۡمُكَذِّبِينَ ٢٤Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́ أَلَمۡ نَجۡعَلِ ٱلۡأَرۡضَ كِفَاتًا ٢٥Ǹjẹ́ Àwa kò ṣe ilẹ̀ ní ohun t’ó ń kó ẹ̀dá jọ mọ́ra wọn أَحۡيَآءً وَأَمۡوَٰتًا ٢٦(ìyẹn) àwọn alààyè àti àwọn òkú وَجَعَلۡنَا فِيهَا رَوَٰسِيَ شَٰمِخَٰتٍ وَأَسۡقَيۡنَٰكُم مَّآءً فُرَاتًا ٢٧A sì fi àwọn àpáta gbagidi gíga-gíga sínú rẹ̀. A sì fun yín ní omi dídùn mu وَيۡلٌ يَوۡمَئِذٍ لِّلۡمُكَذِّبِينَ ٢٨Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́ ٱنطَلِقُوٓاْ إِلَىٰ مَا كُنتُم بِهِۦ تُكَذِّبُونَ ٢٩Ẹ máa lọ sí ibi tí ẹ̀ ń pè nírọ́ ٱنطَلِقُوٓاْ إِلَىٰ ظِلٍّ ذِي ثَلَٰثِ شُعَبٍ ٣٠Ẹ máa lọ sí ibi èéfín ẹlẹ́ka mẹ́ta لَّا ظَلِيلٍ وَلَا يُغۡنِي مِنَ ٱللَّهَبِ ٣١Kì í ṣe ibòji tútù. Kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ìjòfòfò Iná إِنَّهَا تَرۡمِي بِشَرَرٍ كَٱلۡقَصۡرِ ٣٢Dájúdájú (Iná náà) yóò máa ju ẹ̀tapàrà (rẹ̀ sókè t’ó máa dà) bí pẹ̀tẹ́ẹ̀sì كَأَنَّهُۥ جِمَٰلَتٌ صُفۡرٌ ٣٣(Ó máa dà) bí àwọn ràkúnmí aláwọ̀ omi ọsàn وَيۡلٌ يَوۡمَئِذٍ لِّلۡمُكَذِّبِينَ ٣٤Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́ هَٰذَا يَوۡمُ لَا يَنطِقُونَ ٣٥Èyí ni ọjọ́ tí wọn kò níí sọ̀rọ̀ وَلَا يُؤۡذَنُ لَهُمۡ فَيَعۡتَذِرُونَ ٣٦A ò sì níí yọ̀ǹda (ọ̀rọ̀ sísọ) fún wọn, áḿbọ̀sìbọ́sí pé wọ́n yóò mú àwáwí wá وَيۡلٌ يَوۡمَئِذٍ لِّلۡمُكَذِّبِينَ ٣٧Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́ هَٰذَا يَوۡمُ ٱلۡفَصۡلِۖ جَمَعۡنَٰكُمۡ وَٱلۡأَوَّلِينَ ٣٨Èyí ni ọjọ́ ìpínyà. Àwa yó sì kó ẹ̀yin àti àwọn ẹni àkọ́kọ́ jọ فَإِن كَانَ لَكُمۡ كَيۡدٌ فَكِيدُونِ ٣٩Tí ẹ bá ní ète kan lọ́wọ́, ẹ déte sí Mi wò وَيۡلٌ يَوۡمَئِذٍ لِّلۡمُكَذِّبِينَ ٤٠Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́ إِنَّ ٱلۡمُتَّقِينَ فِي ظِلَٰلٍ وَعُيُونٍ ٤١Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù Allāhu yóò wà níbi ibòji àti àwọn omi ìṣẹ́lẹ̀rú وَفَوَٰكِهَ مِمَّا يَشۡتَهُونَ ٤٢àti àwọn èso èyí tí wọ́n bá ń fẹ́ كُلُواْ وَٱشۡرَبُواْ هَنِيٓـَٔۢا بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ ٤٣Ẹ jẹ, kí ẹ sì mu pẹ̀lú ìgbádùn nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ ٤٤Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere) وَيۡلٌ يَوۡمَئِذٍ لِّلۡمُكَذِّبِينَ ٤٥Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́ كُلُواْ وَتَمَتَّعُواْ قَلِيلًا إِنَّكُم مُّجۡرِمُونَ ٤٦Ẹ jẹ, kí ẹ sì gbádùn fún ìgbà díẹ̀. Dájúdájú ẹlẹ́ṣẹ̀ ni yín وَيۡلٌ يَوۡمَئِذٍ لِّلۡمُكَذِّبِينَ ٤٧Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́ وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ ٱرۡكَعُواْ لَا يَرۡكَعُونَ ٤٨Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé kí wọ́n kírun, wọn kò níí kírun وَيۡلٌ يَوۡمَئِذٍ لِّلۡمُكَذِّبِينَ ٤٩Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́ فَبِأَيِّ حَدِيثِۭ بَعۡدَهُۥ يُؤۡمِنُونَ ٥٠Nígbà náà, ọ̀rọ̀ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn rẹ̀

الترجمة: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.