ملة الإسلام

السورة 56 · 96 آية · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

سورة الواقعة باللغة اليوروبا

السورة بالعربية مع التفسير استمع إلى سورة الواقعة (1,362 قارئاً)
مكيةسورة الواقعة٩٦ آية

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

إِذَا وَقَعَتِ ٱلۡوَاقِعَةُ ١Nígbà tí Ìṣẹ̀lẹ̀ (Àjíǹde) bá ṣẹlẹ̀ لَيۡسَ لِوَقۡعَتِهَا كَاذِبَةٌ ٢kò sí irọ́ kan nípa ìṣẹ̀lẹ̀ rẹ̀-E خَافِضَةٌ رَّافِعَةٌ ٣ó máa mú (àwọn kan) wálẹ̀ (sínú Iná), ó sì máa gbé (àwọn kan) sókè (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra) إِذَا رُجَّتِ ٱلۡأَرۡضُ رَجًّا ٤Nígbà tí wọ́n bá mi ilẹ̀ tìtì ní mímìtìtì وَبُسَّتِ ٱلۡجِبَالُ بَسًّا ٥àti nígbà tí Wọ́n bá fọ́ àwọn àpáta ní fífọ́ wómúwómú فَكَانَتۡ هَبَآءً مُّنۢبَثًّا ٦wọ́n sì máa di eruku àfẹ́dànù - E وَكُنتُمۡ أَزۡوَٰجًا ثَلَٰثَةً ٧ẹ̀yin sì máa jẹ́ oríṣi mẹ́ta فَأَصۡحَٰبُ ٱلۡمَيۡمَنَةِ مَآ أَصۡحَٰبُ ٱلۡمَيۡمَنَةِ ٨ìjọ òsì àti ìjọ aṣíwájú. Àmọ́ nínú sūrah al-Balad; 90:18-19 àti sūrah az-Zalzalah; 99:6-8 Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) pín wọn sí ìjọ méjì. Ìjọ méjì kúkú ni gbogbo ẹ̀dá ní ọ̀run 8 Àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún, kí ni (ó máa ti dára tó fún) àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún وَأَصۡحَٰبُ ٱلۡمَشۡـَٔمَةِ مَآ أَصۡحَٰبُ ٱلۡمَشۡـَٔمَةِ ٩Àwọn èrò ọwọ́ òsì, kí ni (ó máa ti burú tó fún) àwọn èrò ọwọ́ òsì وَٱلسَّٰبِقُونَ ٱلسَّٰبِقُونَ ١٠Àwọn aṣíwájú sì ni àwọn aṣíwájú أُوْلَٰٓئِكَ ٱلۡمُقَرَّبُونَ ١١Àwọn wọ̀nyẹn ni alásùn-únmọ́ (Allāhu) فِي جَنَّٰتِ ٱلنَّعِيمِ ١٢nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra ثُلَّةٌ مِّنَ ٱلۡأَوَّلِينَ ١٣Wọ́n pọ̀ nínú àwọn ẹni àkọ́kọ́ وَقَلِيلٌ مِّنَ ٱلۡأٓخِرِينَ ١٤Wọ́n sì kéré nínú àwọn ẹni Ìkẹ́yìn عَلَىٰ سُرُرٍ مَّوۡضُونَةٍ ١٥(Wọn yóò wà) lórí ìtẹ́ tí wọ́n fi góòlù hun مُّتَّكِـِٔينَ عَلَيۡهَا مُتَقَٰبِلِينَ ١٦Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú sórí rẹ̀, wọn sì máa dojú kọra wọn يَطُوفُ عَلَيۡهِمۡ وِلۡدَٰنٌ مُّخَلَّدُونَ ١٧Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí kò níí darúgbó yó sì máa lọ bọ̀ láààrin wọn بِأَكۡوَابٍ وَأَبَارِيقَ وَكَأۡسٍ مِّن مَّعِينٍ ١٨pẹ̀lú àwọn ife omi, ohun ìrọmi fẹ̀ǹfẹ̀ àti ife ọtí aládùn لَّا يُصَدَّعُونَ عَنۡهَا وَلَا يُنزِفُونَ ١٩Kò níí fọ́ wọn lórí; kò sì níí mú wọn húnrìrà وَفَٰكِهَةٍ مِّمَّا يَتَخَيَّرُونَ ٢٠Èso tí wọn yóò máa ṣẹ̀ṣà nínú rẹ̀ (tún wà fún wọn) وَلَحۡمِ طَيۡرٍ مِّمَّا يَشۡتَهُونَ ٢١Àti ẹran ẹyẹ, èyí tí wọ́n ń fẹ́ (yó wà fún wọn) وَحُورٌ عِينٌ ٢٢Àwọn obìnrin ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́ (tún wà fún wọn) كَأَمۡثَٰلِ ٱللُّؤۡلُوِٕ ٱلۡمَكۡنُونِ ٢٣Wọ́n dà bí òkúta olówó-iyebíye tí wọ́n fi pamọ́ جَزَآءَۢ بِمَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ ٢٤(Ìwọ̀nyí ni) ẹ̀san fún ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ لَا يَسۡمَعُونَ فِيهَا لَغۡوًا وَلَا تَأۡثِيمًا ٢٥Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ àti ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra إِلَّا قِيلًا سَلَٰمًا سَلَٰمًا ٢٦Àyàfi ọ̀rọ̀ àlàáfíà, àlàáfíà وَأَصۡحَٰبُ ٱلۡيَمِينِ مَآ أَصۡحَٰبُ ٱلۡيَمِينِ ٢٧Àwọn èrò ọwọ́ ọtún, kí ni (ó máa ti dára tó fún) àwọn èrò ọwọ́ ọtún فِي سِدۡرٍ مَّخۡضُودٍ ٢٨(Wọn yóò wà) ní ìdí igi tí kò ní ẹ̀gún وَطَلۡحٍ مَّنضُودٍ ٢٩àti ọ̀gẹ̀dẹ̀ t’ó so jìgbìnnì وَظِلٍّ مَّمۡدُودٍ ٣٠àti ibòji t’ó gbòòrò وَمَآءٍ مَّسۡكُوبٍ ٣١àti omi t’ó ń ṣàn láì dáwọ́ dúró وَفَٰكِهَةٍ كَثِيرَةٍ ٣٢àti ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ èso لَّا مَقۡطُوعَةٍ وَلَا مَمۡنُوعَةٍ ٣٣tí kò níí já (ní ọ̀dọ̀ wọn), kò sì níí dèèwọ̀ (fún wọn) وَفُرُشٍ مَّرۡفُوعَةٍ ٣٤(Wọ́n máa wà lórí) ìtẹ́ tí wọ́n gbé sókè إِنَّآ أَنشَأۡنَٰهُنَّ إِنشَآءً ٣٥Dájúdájú Àwa tún (àwọn obìnrin wọn) dá ní ẹ̀dá ọ̀tun فَجَعَلۡنَٰهُنَّ أَبۡكَارًا ٣٦A sì ṣe wọ́n ní wúńdíá عُرُبًا أَتۡرَابًا ٣٧olólùfẹ́ ọkọ. Wọ́n sì dọ́gba ní ọjọ́ orí لِّأَصۡحَٰبِ ٱلۡيَمِينِ ٣٨(Wọ́n wà) fún àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún ثُلَّةٌ مِّنَ ٱلۡأَوَّلِينَ ٣٩Wọ́n pọ̀ nínú àwọn ẹni àkọ́kọ́ وَثُلَّةٌ مِّنَ ٱلۡأٓخِرِينَ ٤٠Wọ́n tún pọ̀ nínú àwọn ẹni Ìkẹ́yìn وَأَصۡحَٰبُ ٱلشِّمَالِ مَآ أَصۡحَٰبُ ٱلشِّمَالِ ٤١Àwọn èrò ọwọ́ òsì, kí ni (ó máa ti burú tó fún) àwọn èrò ọwọ́ òsì فِي سَمُومٍ وَحَمِيمٍ ٤٢(Wọn yóò wà) nínú atẹ́gùn gbígbóná àti omi gbígbóná وَظِلٍّ مِّن يَحۡمُومٍ ٤٣àti ní abẹ́ ibòji eléèéfín dúdú لَّا بَارِدٍ وَلَا كَرِيمٍ ٤٤kò tutù, kò sì dára إِنَّهُمۡ كَانُواْ قَبۡلَ ذَٰلِكَ مُتۡرَفِينَ ٤٥Dájúdájú wọ́n ti jẹ́ onígbẹdẹmukẹ ṣíwájú ìyẹn وَكَانُواْ يُصِرُّونَ عَلَى ٱلۡحِنثِ ٱلۡعَظِيمِ ٤٦Wọ́n sì máa ń ṣoríkunkun lórí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá وَكَانُواْ يَقُولُونَ أَئِذَا مِتۡنَا وَكُنَّا تُرَابًا وَعِظَٰمًا أَءِنَّا لَمَبۡعُوثُونَ ٤٧Wọ́n sì máa ń wí pé: "Ṣé nígbà tí a bá di òkú, tí a sì di erùpẹ̀ àti egungun, ǹjẹ́ Wọn yóò tún gbé wa dìde ni أَوَءَابَآؤُنَا ٱلۡأَوَّلُونَ ٤٨Ṣé àti àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́ قُلۡ إِنَّ ٱلۡأَوَّلِينَ وَٱلۡأٓخِرِينَ ٤٩Sọ pé: "Dájúdájú àwọn ẹni àkọ́kọ́ àti àwọn ẹni Ìkẹ́yìn لَمَجۡمُوعُونَ إِلَىٰ مِيقَٰتِ يَوۡمٍ مَّعۡلُومٍ ٥٠dájúdájú A óò kó wọn jọ papọ̀ ní àkókò ọjọ́ kan tí A ti mọ̀ ثُمَّ إِنَّكُمۡ أَيُّهَا ٱلضَّآلُّونَ ٱلۡمُكَذِّبُونَ ٥١Lẹ́yìn náà, dájúdájú ẹ̀yin olùṣìnà, olùpe-òdodo-nírọ́ لَأٓكِلُونَ مِن شَجَرٍ مِّن زَقُّومٍ ٥٢dájúdájú ẹ̀yin máa jẹ nínú igi zaƙƙūm (igi iwọ) فَمَالِـُٔونَ مِنۡهَا ٱلۡبُطُونَ ٥٣Ikùn yín sì máa kún bámúbámú fún (jíjẹ) igi náà فَشَٰرِبُونَ عَلَيۡهِ مِنَ ٱلۡحَمِيمِ ٥٤Ẹ̀yin yó sì máa mu omi gbígbóná lé e lórí فَشَٰرِبُونَ شُرۡبَ ٱلۡهِيمِ ٥٥Ẹ̀yin yóò máa mu ún ní ìmumi ràkúnmí tí òǹgbẹ ń gbẹ هَٰذَا نُزُلُهُمۡ يَوۡمَ ٱلدِّينِ ٥٦Èyí ni n̄ǹkan àlejò wọn ní Ọjọ́ ẹ̀san نَحۡنُ خَلَقۡنَٰكُمۡ فَلَوۡلَا تُصَدِّقُونَ ٥٧Àwa l’A ṣẹ̀dá yín. Kí ni kò jẹ́ kí ẹ gbàgbọ́ lódodo أَفَرَءَيۡتُم مَّا تُمۡنُونَ ٥٨Ẹ sọ fún Mi nípa àtọ̀ tí ẹ̀ ń dà jáde (sínú àpòlùkẹ́) ءَأَنتُمۡ تَخۡلُقُونَهُۥٓ أَمۡ نَحۡنُ ٱلۡخَٰلِقُونَ ٥٩ṣé ẹ̀yin lẹ ṣẹ̀dá rẹ̀ ni tàbí Àwa l’A ṣẹ̀dá rẹ̀ نَحۡنُ قَدَّرۡنَا بَيۡنَكُمُ ٱلۡمَوۡتَ وَمَا نَحۡنُ بِمَسۡبُوقِينَ ٦٠Àwa l’A yan kádàrá (ọjọ́) ikú fún gbogbo yín. Àwa kò sì lè kágara عَلَىٰٓ أَن نُّبَدِّلَ أَمۡثَٰلَكُمۡ وَنُنشِئَكُمۡ فِي مَا لَا تَعۡلَمُونَ ٦١láti fi irú yín pààrọ̀ yín, kí á sì tun yín dá sínú ohun tí ẹ kò mọ̀ وَلَقَدۡ عَلِمۡتُمُ ٱلنَّشۡأَةَ ٱلۡأُولَىٰ فَلَوۡلَا تَذَكَّرُونَ ٦٢Ẹ kúkú mọ ìṣẹ̀dá àkọ́kọ́, ẹ ò ṣe lo ìrántí أَفَرَءَيۡتُم مَّا تَحۡرُثُونَ ٦٣Ẹ sọ fún Mi nípa n̄ǹkan tí ẹ̀ ń gbìn sínú ilẹ̀ ءَأَنتُمۡ تَزۡرَعُونَهُۥٓ أَمۡ نَحۡنُ ٱلزَّٰرِعُونَ ٦٤ṣé ẹ̀yin l’ẹ̀ ń jẹ́ kí ó hù jáde ni tàbí Àwa l’À ń jẹ́ kí ó hù jáde لَوۡ نَشَآءُ لَجَعَلۡنَٰهُ حُطَٰمًا فَظَلۡتُمۡ تَفَكَّهُونَ ٦٥Tí A bá fẹ́ ni, Àwa ìbá sọ ọ́ di gbígbẹ, ẹ̀yin yó sì máa ṣèèmọ̀ (tí ẹ óò máa ká àbámọ̀) إِنَّا لَمُغۡرَمُونَ ٦٦(Ẹ̀yin yó sì wí pé:) "Dájúdájú àwa ti di onígbèsè بَلۡ نَحۡنُ مَحۡرُومُونَ ٦٧(Àwọn mìíràn yó sì wí pé:) "Rárá o! Wọ́n ṣe ìkórè oko ní èèwọ̀ fún wa ni أَفَرَءَيۡتُمُ ٱلۡمَآءَ ٱلَّذِي تَشۡرَبُونَ ٦٨Ẹ sọ fún mi nípa omi tí ẹ̀ ń mu ءَأَنتُمۡ أَنزَلۡتُمُوهُ مِنَ ٱلۡمُزۡنِ أَمۡ نَحۡنُ ٱلۡمُنزِلُونَ ٦٩ṣé ẹ̀yin l’ẹ̀ ń sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti inú ẹ̀ṣújò ni tàbí Àwa l’À ń sọ̀ ọ́ kalẹ̀ لَوۡ نَشَآءُ جَعَلۡنَٰهُ أُجَاجًا فَلَوۡلَا تَشۡكُرُونَ ٧٠Tí A bá fẹ́ ni, Àwa ìbá ṣe é ní omi t’ó móró. Ẹ ò ṣe máa dúpẹ́ أَفَرَءَيۡتُمُ ٱلنَّارَ ٱلَّتِي تُورُونَ ٧١Ẹ sọ fún Mi nípa iná tí ẹ̀ ń dá ءَأَنتُمۡ أَنشَأۡتُمۡ شَجَرَتَهَآ أَمۡ نَحۡنُ ٱلۡمُنشِـُٔونَ ٧٢ṣé ẹ̀yin l’ẹ ṣẹ̀dá igi rẹ̀ ni tàbí Àwa ni Aṣẹ̀dá نَحۡنُ جَعَلۡنَٰهَا تَذۡكِرَةً وَمَتَٰعًا لِّلۡمُقۡوِينَ ٧٣Àwa ṣe iná ayé ní ìrántí (fún Iná ọ̀run) àti n̄ǹkan èlò fún àwọn onírìn-àjò فَسَبِّحۡ بِٱسۡمِ رَبِّكَ ٱلۡعَظِيمِ ٧٤Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi ۞ فَلَآ أُقۡسِمُ بِمَوَٰقِعِ ٱلنُّجُومِ ٧٥Mò ń búra pẹ̀lú àwọn ibùsọ̀ ìràwọ̀ وَإِنَّهُۥ لَقَسَمٌ لَّوۡ تَعۡلَمُونَ عَظِيمٌ ٧٦Dájúdájú ìbúra ńlá ni, tí ẹ bá mọ̀ إِنَّهُۥ لَقُرۡءَانٌ كَرِيمٌ ٧٧Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni n̄ǹkan kíké alápọ̀n-ọ́nlé فِي كِتَٰبٍ مَّكۡنُونٍ ٧٨(t’ó wà) nínú Tírà ààbò (nínú Laohul-Mahfūṭḥ) لَّا يَمَسُّهُۥٓ إِلَّا ٱلۡمُطَهَّرُونَ ٧٩Kò sí ẹni tó lè fọwọ́ kàn án (ní ọ̀dọ̀ Allāhu) àfi àwọn ẹni mímọ́ (ìyẹn, àwọn mọlāika) تَنزِيلٌ مِّن رَّبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ ٨٠Wọ́n sọ̀ al-Ƙur’ān kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá أَفَبِهَٰذَا ٱلۡحَدِيثِ أَنتُم مُّدۡهِنُونَ ٨١Nítorí náà, ṣé ọ̀rọ̀ (al-Ƙur’ān) yìí l’ẹ̀ ń pè nírọ́ وَتَجۡعَلُونَ رِزۡقَكُمۡ أَنَّكُمۡ تُكَذِّبُونَ ٨٢Ẹ sì ń sọ ìdúpẹ́ arísìkí yín di pé dájúdájú ẹ̀ ń pe òdodo nírọ́ فَلَوۡلَآ إِذَا بَلَغَتِ ٱلۡحُلۡقُومَ ٨٣Kí ni ó máa ti rí (fun yín) nígbà tí ẹ̀mí (yín) bá dé ọ̀nà ọ̀fun وَأَنتُمۡ حِينَئِذٍ تَنظُرُونَ ٨٤tí ẹ̀yin yó sì máa wòran nígbà yẹn وَنَحۡنُ أَقۡرَبُ إِلَيۡهِ مِنكُمۡ وَلَٰكِن لَّا تُبۡصِرُونَ ٨٥Àwa sì súnmọ́ ọn ju ẹ̀yin lọ, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò ríran فَلَوۡلَآ إِن كُنتُمۡ غَيۡرَ مَدِينِينَ ٨٦Ẹ̀yin kò ṣe jẹ́ ẹni tí A ò níí gbẹ̀san lára rẹ̀ تَرۡجِعُونَهَآ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ ٨٧kí ẹ sì dá (ẹ̀mí tí ó fẹ́ bọ́) padà, tí ẹ bá jẹ́ olódodo فَأَمَّآ إِن كَانَ مِنَ ٱلۡمُقَرَّبِينَ ٨٨Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn alásùn-únmọ́ (Wa) فَرَوۡحٌ وَرَيۡحَانٌ وَجَنَّتُ نَعِيمٍ ٨٩ìsinmi, èsè t’ó dára àti Ọgbà Ìdẹ̀ra (ni tirẹ̀) وَأَمَّآ إِن كَانَ مِنۡ أَصۡحَٰبِ ٱلۡيَمِينِ ٩٠Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún فَسَلَٰمٌ لَّكَ مِنۡ أَصۡحَٰبِ ٱلۡيَمِينِ ٩١àlàáfíà ni fún ọ láààrin àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún وَأَمَّآ إِن كَانَ مِنَ ٱلۡمُكَذِّبِينَ ٱلضَّآلِّينَ ٩٢Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn olùpe-òdodo-nírọ́, àwọn olùṣìnà فَنُزُلٌ مِّنۡ حَمِيمٍ ٩٣n̄ǹkan àlejò (wọn) ni omi gbígbóná وَتَصۡلِيَةُ جَحِيمٍ ٩٤àti wíwọ inú iná Jẹhīm إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ حَقُّ ٱلۡيَقِينِ ٩٥Dájúdájú èyí, òhun ni òdodo t’ó dájú فَسَبِّحۡ بِٱسۡمِ رَبِّكَ ٱلۡعَظِيمِ ٩٦Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi

الترجمة: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.