بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
وَٱلنَّجۡمِ إِذَا هَوَىٰ ١(Allāhu búra pẹ̀lú) ìràwọ̀ nígbà tí ó bá jábọ́ مَا ضَلَّ صَاحِبُكُمۡ وَمَا غَوَىٰ ٢Ẹni yín kò ṣìnà, kò sì sọnù وَمَا يَنطِقُ عَنِ ٱلۡهَوَىٰٓ ٣Àti pé kò níí sọ̀rọ̀ ìfẹ́-inú إِنۡ هُوَ إِلَّا وَحۡيٌ يُوحَىٰ ٤Kò níí sọ ohun kan tayọ ìmísí tí A fi ránṣẹ́ sí i عَلَّمَهُۥ شَدِيدُ ٱلۡقُوَىٰ ٥Alágbára (ìyẹn, mọlāika Jibrīl) l’ó kọ́ ọ ní ìmọ̀ (al-Ƙur’ān) ذُو مِرَّةٍ فَٱسۡتَوَىٰ ٦Ó ní àlàáfíà t’ó péye. Nítorí náà, ó dúró wámúwámú وَهُوَ بِٱلۡأُفُقِ ٱلۡأَعۡلَىٰ ٧nígbà tí ó wà nínú òfurufú lókè pátápátá ثُمَّ دَنَا فَتَدَلَّىٰ ٨Lẹ́yìn náà, ó sún mọ́ (Ànábì). Ó sì sọ̀kalẹ̀ (tọ̀ ọ́ wá) فَكَانَ قَابَ قَوۡسَيۡنِ أَوۡ أَدۡنَىٰ ٩(Àlàfo ààrin àwọn méjèèjì) sì tó ìwọ̀n ọrún ọfà méjì, tàbí kí ó kéré (sí ìyẹn) فَأَوۡحَىٰٓ إِلَىٰ عَبۡدِهِۦ مَآ أَوۡحَىٰ ١٠Allāhu sì fún ẹrúsìn Rẹ̀ ní ìmísí t’Ó fún un مَا كَذَبَ ٱلۡفُؤَادُ مَا رَأَىٰٓ ١١Ọkàn (Ànábì) kò parọ́ ohun t’ó rí أَفَتُمَٰرُونَهُۥ عَلَىٰ مَا يَرَىٰ ١٢Ṣé ẹ óò jà á níyàn nípa ohun t’ó rí ni وَلَقَدۡ رَءَاهُ نَزۡلَةً أُخۡرَىٰ ١٣Àti pé dájúdájú ó rí i nígbà kejì Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ni ó rí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igun yìí fi kún un pé ọkàn l’ó fi rí Allāhu bíi ọ̀rọ̀ tí ó tọ̀dọ̀ Ọmọ ‘Abbās (rọdiyallāhu 'anhu) wá pé “Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) fi ọkàn rẹ̀ rí Allāhu ni.” Ìyẹn ni pé عِندَ سِدۡرَةِ ٱلۡمُنتَهَىٰ ١٤níbi igi sidirah al-Muntahā عِندَهَا جَنَّةُ ٱلۡمَأۡوَىٰٓ ١٥nítòsí rẹ̀ ni Ọgbà Ibùgbé (gbére) wà إِذۡ يَغۡشَى ٱلسِّدۡرَةَ مَا يَغۡشَىٰ ١٦(Rántí) nígbà tí ohun t’ó bo igi Sidirah bò ó mọ́lẹ̀ مَا زَاغَ ٱلۡبَصَرُ وَمَا طَغَىٰ ١٧Ojú (Ànábì) kò yẹ̀, kò sì tayọ ẹnu-àlà لَقَدۡ رَأَىٰ مِنۡ ءَايَٰتِ رَبِّهِ ٱلۡكُبۡرَىٰٓ ١٨Dájúdájú ó rí nínú àwọn àmì Olúwa rẹ̀, t’ó tóbi jùlọ أَفَرَءَيۡتُمُ ٱللَّٰتَ وَٱلۡعُزَّىٰ ١٩Ẹ sọ fún mi nípa òrìṣà Lāt àti òrìṣà ‘Uzzā وَمَنَوٰةَ ٱلثَّالِثَةَ ٱلۡأُخۡرَىٰٓ ٢٠àti Mọnāh, òrìṣà kẹta mìíràn أَلَكُمُ ٱلذَّكَرُ وَلَهُ ٱلۡأُنثَىٰ ٢١Ṣé ọmọkùnrin ni tiyín, ọmọbìnrin sì ni tiRẹ̀ تِلۡكَ إِذًا قِسۡمَةٌ ضِيزَىٰٓ ٢٢Ìpín àbòsí nìyẹn nígbà náà إِنۡ هِيَ إِلَّآ أَسۡمَآءٌ سَمَّيۡتُمُوهَآ أَنتُمۡ وَءَابَآؤُكُم مَّآ أَنزَلَ ٱللَّهُ بِهَا مِن سُلۡطَٰنٍۚ إِن يَتَّبِعُونَ إِلَّا ٱلظَّنَّ وَمَا تَهۡوَى ٱلۡأَنفُسُۖ وَلَقَدۡ جَآءَهُم مِّن رَّبِّهِمُ ٱلۡهُدَىٰٓ ٢٣(Àwọn orúkọ òrìṣà wọ̀nyẹn) kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àwọn orúkọ kan tí ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín fi sọ (àwọn òrìṣà yín fúnra yín). Allāhu kò sì sọ ẹ̀rí ọ̀rọ̀ kan kalẹ̀ nípa rẹ̀. Wọn kò sì tẹ̀lé kiní kan bí kò ṣe àròsọ àti ohun tí ẹ̀mí (wọn) ń fẹ́. Ìmọ̀nà kúkú ti dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn أَمۡ لِلۡإِنسَٰنِ مَا تَمَنَّىٰ ٢٤Tàbí ti ènìyàn ni n̄ǹkan t’ó bá ń fẹ́ فَلِلَّهِ ٱلۡأٓخِرَةُ وَٱلۡأُولَىٰ ٢٥Ti Allāhu sì ni ọ̀run àti ayé ۞ وَكَم مِّن مَّلَكٍ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ لَا تُغۡنِي شَفَٰعَتُهُمۡ شَيۡـًٔا إِلَّا مِنۢ بَعۡدِ أَن يَأۡذَنَ ٱللَّهُ لِمَن يَشَآءُ وَيَرۡضَىٰٓ ٢٦Àti pé mélòó mélòó nínú àwọn mọlāika t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀, tí ìṣìpẹ̀ wọn kò níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kiní kan àyàfi lẹ́yìn ìgbà tí Allāhu bá yọ̀ǹda fún ẹni tí Ó bá fẹ́, tí Ó sì yọ́nú sí إِنَّ ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡأٓخِرَةِ لَيُسَمُّونَ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةَ تَسۡمِيَةَ ٱلۡأُنثَىٰ ٢٧Dájúdájú àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, àwọn ni wọ́n ń fún àwọn mọlāika ní orúkọ obìnrin وَمَا لَهُم بِهِۦ مِنۡ عِلۡمٍۖ إِن يَتَّبِعُونَ إِلَّا ٱلظَّنَّۖ وَإِنَّ ٱلظَّنَّ لَا يُغۡنِي مِنَ ٱلۡحَقِّ شَيۡـًٔا ٢٨Kò sí ìmọ̀ kan fún wọn nípa rẹ̀. Wọn kò sì tẹ̀lé kiní kan bí kò ṣe àròsọ. Dájúdájú àròsọ kò sì níí rọrọ̀ kiní kan lára òdodo فَأَعۡرِضۡ عَن مَّن تَوَلَّىٰ عَن ذِكۡرِنَا وَلَمۡ يُرِدۡ إِلَّا ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا ٢٩Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò ní ọ̀dọ̀ ẹni t’ó kẹ̀yìn sí ìrántí Wa, tí kò sì gbèrò kiní kan àfi ìṣẹ̀mí ayé ذَٰلِكَ مَبۡلَغُهُم مِّنَ ٱلۡعِلۡمِۚ إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعۡلَمُ بِمَن ضَلَّ عَن سَبِيلِهِۦ وَهُوَ أَعۡلَمُ بِمَنِ ٱهۡتَدَىٰ ٣٠Ìyẹn ni òdíwọ̀n (àti òpin) ìmọ̀ wọn. Dájúdájú Olúwa rẹ, Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni t’ó ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà Rẹ̀. Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa ẹni t’ó mọ̀nà وَلِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِ لِيَجۡزِيَ ٱلَّذِينَ أَسَٰٓـُٔواْ بِمَا عَمِلُواْ وَيَجۡزِيَ ٱلَّذِينَ أَحۡسَنُواْ بِٱلۡحُسۡنَى ٣١Ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀ nítorí kí Ó lè san àwọn t’ó ṣe iṣẹ́ aburú ní ẹ̀san ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ àti nítorí kí Ó lè san àwọn t’ó ṣe iṣẹ́ rere ni ẹ̀san rere ٱلَّذِينَ يَجۡتَنِبُونَ كَبَٰٓئِرَ ٱلۡإِثۡمِ وَٱلۡفَوَٰحِشَ إِلَّا ٱللَّمَمَۚ إِنَّ رَبَّكَ وَٰسِعُ ٱلۡمَغۡفِرَةِۚ هُوَ أَعۡلَمُ بِكُمۡ إِذۡ أَنشَأَكُم مِّنَ ٱلۡأَرۡضِ وَإِذۡ أَنتُمۡ أَجِنَّةٌ فِي بُطُونِ أُمَّهَٰتِكُمۡۖ فَلَا تُزَكُّوٓاْ أَنفُسَكُمۡۖ هُوَ أَعۡلَمُ بِمَنِ ٱتَّقَىٰٓ ٣٢Àwọn t’ó ń jìnnà sí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ńlá àti ìwà ìbàjẹ́ àyàfi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, dájúdájú Olúwa rẹ gbòòrò ní àforíjìn. Ó nímọ̀ jùlọ nípa yín nígbà tí Ó ṣẹ̀dá yín láti inú ilẹ̀ àti nígbà tí ẹ wà ní ọlẹ̀ nínú àwọn ikùn ìyá yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe fọra yín mọ́. Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni t’ó bẹ̀rù (Rẹ̀) أَفَرَءَيۡتَ ٱلَّذِي تَوَلَّىٰ ٣٣Sọ fún mi nípa ẹni t’ó gbúnrí (kúrò níbi òdodo) وَأَعۡطَىٰ قَلِيلًا وَأَكۡدَىٰٓ ٣٤tí ó fi díẹ̀ tọrẹ, tí ó sì di ìyókù mọ́wọ́ أَعِندَهُۥ عِلۡمُ ٱلۡغَيۡبِ فَهُوَ يَرَىٰٓ ٣٥Ṣé ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ wà ní ọ̀dọ̀ rẹ, tí ó sì ń rí i (pé ẹlòmíìràn l’ó ma bá òun jìyà lọ́run) أَمۡ لَمۡ يُنَبَّأۡ بِمَا فِي صُحُفِ مُوسَىٰ ٣٦Tàbí wọn kò fún un ní ìró ohun t’ó wà nínú tírà (Ànábì) Mūsā ni وَإِبۡرَٰهِيمَ ٱلَّذِي وَفَّىٰٓ ٣٧àti (tírà Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ẹni t’ó mú (òfin Allāhu) ṣẹ أَلَّا تَزِرُ وَازِرَةٌ وِزۡرَ أُخۡرَىٰ ٣٨pé dájúdájú ẹlẹ́rù-ẹ̀ṣẹ̀ kan kò níí ru ẹrù-ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn وَأَن لَّيۡسَ لِلۡإِنسَٰنِ إِلَّا مَا سَعَىٰ ٣٩Àti pé kò sí kiní kan fún ènìyàn àfi ohun t’ó ṣe níṣẹ́ وَأَنَّ سَعۡيَهُۥ سَوۡفَ يُرَىٰ ٤٠Àti pé dájúdájú iṣẹ́ rẹ̀, láìpẹ́ wọ́n máa fi hàn án ثُمَّ يُجۡزَىٰهُ ٱلۡجَزَآءَ ٱلۡأَوۡفَىٰ ٤١Lẹ́yìn náà, wọ́n máa san án ní ẹ̀san rẹ̀, ní ẹ̀san t’ó kún jùlọ وَأَنَّ إِلَىٰ رَبِّكَ ٱلۡمُنتَهَىٰ ٤٢Àti pé dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni òpin (ìrìn-àjò ẹ̀dá) وَأَنَّهُۥ هُوَ أَضۡحَكَ وَأَبۡكَىٰ ٤٣Dájúdájú Òun l’Ó ń pa (ẹ̀dá) ní ẹ̀rín. Ó sì ń pa (ẹ̀dá) ní ẹkún وَأَنَّهُۥ هُوَ أَمَاتَ وَأَحۡيَا ٤٤Dájúdájú Òun l’Ó ń sọ (ẹ̀dá) di òkú. Ó sì ń sọ (ẹ̀dá) di alààyè وَأَنَّهُۥ خَلَقَ ٱلزَّوۡجَيۡنِ ٱلذَّكَرَ وَٱلۡأُنثَىٰ ٤٥Dájúdájú Òun l’Ó dá ẹ̀dá ní oríṣi méjì, ọkùnrin àti obìnrin مِن نُّطۡفَةٍ إِذَا تُمۡنَىٰ ٤٦láti ara àtọ̀ nígbà tí wọ́n bá dà á sínú àpòlùkẹ́ وَأَنَّ عَلَيۡهِ ٱلنَّشۡأَةَ ٱلۡأُخۡرَىٰ ٤٧Dájúdájú Òun l’Ó máa ṣe ìṣẹ̀dá ìkẹ́yìn fún àjíǹde وَأَنَّهُۥ هُوَ أَغۡنَىٰ وَأَقۡنَىٰ ٤٨Dájúdájú Òun l’Ó ń ṣe púpọ̀, Ó sì ń ṣe kékeré (oore fún ẹ̀dá) وَأَنَّهُۥ هُوَ رَبُّ ٱلشِّعۡرَىٰ ٤٩Dájúdájú Òun sì ni Olúwa ìràwọ̀ Ṣi‘rọ̄ (tí wọ́n sọ di òrìṣà) وَأَنَّهُۥٓ أَهۡلَكَ عَادًا ٱلۡأُولَىٰ ٥٠Dájúdájú Òun l’Ó pa ìran ‘Ād rẹ́, àwọn ẹni àkọ́kọ́ وَثَمُودَاْ فَمَآ أَبۡقَىٰ ٥١àti ìran Thamūd, kò sì ṣẹ́ wọn kù وَقَوۡمَ نُوحٍ مِّن قَبۡلُۖ إِنَّهُمۡ كَانُواْ هُمۡ أَظۡلَمَ وَأَطۡغَىٰ ٥٢àti ìjọ Nūh t’ó ṣíwájú (wọn), dájúdájú wọ́n jẹ́ alábòsí jùlọ, wọ́n sì tayọ ẹnu-àlà jùlọ وَٱلۡمُؤۡتَفِكَةَ أَهۡوَىٰ ٥٣àti ìlú tí wọ́n dàwó (ìlú Ànábì Lūt) t’Ó yẹ̀ lulẹ̀ (láti òkè) فَغَشَّىٰهَا مَا غَشَّىٰ ٥٤Ohun t’ó bò wọ́n mọ́lẹ̀ bò wọ́n mọ́lẹ̀ فَبِأَيِّ ءَالَآءِ رَبِّكَ تَتَمَارَىٰ ٥٥Nítorí náà, èwo nínú ìdẹ̀ra Olúwa rẹ ni ìwọ (ènìyàn) ń jà níyàn هَٰذَا نَذِيرٌ مِّنَ ٱلنُّذُرِ ٱلۡأُولَىٰٓ ٥٦Èyí ni ìkìlọ̀ kan nínú àwọn ìkìlọ̀ àkọ́kọ́ أَزِفَتِ ٱلۡأٓزِفَةُ ٥٧Ohun t’ó súnmọ́ súnmọ́ لَيۡسَ لَهَا مِن دُونِ ٱللَّهِ كَاشِفَةٌ ٥٨Lẹ́yìn Allāhu, kò sí ẹni t’ó lè ṣàfi hàn (Àkókò náà) أَفَمِنۡ هَٰذَا ٱلۡحَدِيثِ تَعۡجَبُونَ ٥٩Ṣé ọ̀rọ̀ yìí l’ó ń ṣe yín ní kàyéfì وَتَضۡحَكُونَ وَلَا تَبۡكُونَ ٦٠Ẹ̀ ń rẹ́rìn-ín, ẹ ò sì sunkún وَأَنتُمۡ سَٰمِدُونَ ٦١Afọ́nú-fọ́ra ni yín فَٱسۡجُدُواْۤ لِلَّهِۤ وَٱعۡبُدُواْ ۩ ٦٢Nítorí náà, ẹ forí kanlẹ̀ fún Allāhu, kí ẹ jọ́sìn (fún Un)