بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
وَٱلصَّٰٓفَّٰتِ صَفًّا ١(Allāhu búra pẹ̀lú) àwọn mọlāika olùtò-lọ́wọ̀ọ̀wọ́ tààrà فَٱلزَّٰجِرَٰتِ زَجۡرًا ٢àti àwọn mọlāika t’ó ń wọ́ ẹ̀ṣújò kiri tààrà فَٱلتَّٰلِيَٰتِ ذِكۡرًا ٣àti àwọn mọlāika òǹké-tírà ìrántí إِنَّ إِلَٰهَكُمۡ لَوَٰحِدٌ ٤Dájúdájú Ọlọ́hun yín, Ọ̀kan ṣoṣo ni رَّبُّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَيۡنَهُمَا وَرَبُّ ٱلۡمَشَٰرِقِ ٥Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. Òun sì ni Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn إِنَّا زَيَّنَّا ٱلسَّمَآءَ ٱلدُّنۡيَا بِزِينَةٍ ٱلۡكَوَاكِبِ ٦Dájúdájú Àwa fi àwọn ìràwọ̀ ṣe sánmọ̀ ilé ayé ní ọ̀ṣọ́ وَحِفۡظًا مِّن كُلِّ شَيۡطَٰنٍ مَّارِدٍ ٧àti ìṣọ́ níbi (aburú) gbogbo èṣù olóríkunkun لَّا يَسَّمَّعُونَ إِلَى ٱلۡمَلَإِ ٱلۡأَعۡلَىٰ وَيُقۡذَفُونَ مِن كُلِّ جَانِبٍ ٨(Àwọn èṣù) kò sì níí lè tẹ́tí sí ìjọ (mọlāika t’ó wà ní) àyè gíga jùlọ (nínú sánmọ̀). (Àwọn mọlāika) yó sì máa ku (àwọn èṣù) lókò (ẹ̀ta ìràwọ̀) ní gbogbo agbègbè (sánmọ̀) دُحُورًاۖ وَلَهُمۡ عَذَابٌ وَاصِبٌ ٩Wọ́n ń lé wọn dànù. Ìyà àìlópin sì wà fún wọn إِلَّا مَنۡ خَطِفَ ٱلۡخَطۡفَةَ فَأَتۡبَعَهُۥ شِهَابٌ ثَاقِبٌ ١٠(Wọn kò níí gbọ́ ọ̀rọ̀ ní kíkún) àyàfi ẹni tí ó bá rí ọ̀rọ̀ àjígbọ́ gbé, nígbà náà (ni mọlāika) yó sì fi ẹ̀ta ìràwọ̀ iná t’ó máa jó o tẹ̀lé e فَٱسۡتَفۡتِهِمۡ أَهُمۡ أَشَدُّ خَلۡقًا أَم مَّنۡ خَلَقۡنَآۚ إِنَّا خَلَقۡنَٰهُم مِّن طِينٍ لَّازِبِۭ ١١Bi wọ́n léèrè wò pé ṣé àwọn ni ìṣẹ̀dá wọn lágbára jùlọ ni tàbí àwọn (ènìyàn) tí A dá? Dájúdájú Àwa dá wọn láti ara erùpẹ̀ t’ó lẹ̀ mọ́ra wọn بَلۡ عَجِبۡتَ وَيَسۡخَرُونَ ١٢Rárá (kò jọra wọn); ìwọ ṣèèmọ̀ (nípa al-Ƙur’ān), àwọn sì ń ṣe yẹ̀yẹ́ وَإِذَا ذُكِّرُواْ لَا يَذۡكُرُونَ ١٣Àti pé nígbà tí wọ́n bá ṣe ìrántí fún wọn, wọn kò níí lo ìrántí وَإِذَا رَأَوۡاْ ءَايَةً يَسۡتَسۡخِرُونَ ١٤Nígbà tí wọ́n bá tún rí àmì kan, wọn yóò máa ṣe yẹ̀yẹ́ وَقَالُوٓاْ إِنۡ هَٰذَآ إِلَّا سِحۡرٌ مُّبِينٌ ١٥Wọ́n sì wí pé: "Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe idán pọ́nńbélé أَءِذَا مِتۡنَا وَكُنَّا تُرَابًا وَعِظَٰمًا أَءِنَّا لَمَبۡعُوثُونَ ١٦Ṣé nígbà tí a bá kú tán, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé dájúdájú Wọn yóò tún gbé wa dìde ni أَوَءَابَآؤُنَا ٱلۡأَوَّلُونَ ١٧Ṣé àti àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́ قُلۡ نَعَمۡ وَأَنتُمۡ دَٰخِرُونَ ١٨Sọ pé: "Bẹ́ẹ̀ ni. Ẹ̀yin yó sì di ẹni yẹpẹrẹ فَإِنَّمَا هِيَ زَجۡرَةٌ وَٰحِدَةٌ فَإِذَا هُمۡ يَنظُرُونَ ١٩Nítorí náà, igbe ẹyọ kan mà ni. Nígbà náà ni wọn yóò máa wò sùn وَقَالُواْ يَٰوَيۡلَنَا هَٰذَا يَوۡمُ ٱلدِّينِ ٢٠Wọ́n á wí pé: "Ègbé wa! Èyí ni Ọjọ́ ẹ̀san هَٰذَا يَوۡمُ ٱلۡفَصۡلِ ٱلَّذِي كُنتُم بِهِۦ تُكَذِّبُونَ ٢١Èyí ni ọjọ́ Ìdájọ́ èyí tí ẹ̀ ń pè nírọ́ ۞ ٱحۡشُرُواْ ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ وَأَزۡوَٰجَهُمۡ وَمَا كَانُواْ يَعۡبُدُونَ ٢٢Ẹ kó àwọn t’ó ṣàbòsí jọ, àwọn ìyàwó wọn àti ohun tí wọ́n ń jọ́sìn fún مِن دُونِ ٱللَّهِ فَٱهۡدُوهُمۡ إِلَىٰ صِرَٰطِ ٱلۡجَحِيمِ ٢٣lẹ́yìn Allāhu. Kí ẹ sì júwe wọn sí ojú ọ̀nà iná Jẹhīm وَقِفُوهُمۡۖ إِنَّهُم مَّسۡـُٔولُونَ ٢٤Ẹ dá wọn dúró ná, dájúdájú wọ́n máa bi wọ́n léèrè ìbéèrè مَا لَكُمۡ لَا تَنَاصَرُونَ ٢٥Kí ni kò jẹ́ kí ẹ ranra yín lọ́wọ́ بَلۡ هُمُ ٱلۡيَوۡمَ مُسۡتَسۡلِمُونَ ٢٦Rárá, wọ́n ti juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ ní òní ni وَأَقۡبَلَ بَعۡضُهُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٍ يَتَسَآءَلُونَ ٢٧Apá kan wọn yóò dojú kọ apá kan, tí wọn yóò máa bira wọn léèrè ìbéèrè قَالُوٓاْ إِنَّكُمۡ كُنتُمۡ تَأۡتُونَنَا عَنِ ٱلۡيَمِينِ ٢٨(Àwọn ènìyàn) wí pé: "Dájúdájú ẹ̀yin l’ẹ̀ ń gba ọ̀tún wọlé sí wa lára (láti ṣì wá lọ́nà) قَالُواْ بَل لَّمۡ تَكُونُواْ مُؤۡمِنِينَ ٢٩(Àwọn àlùjànnú) wí pé: "Rárá o (àwa kọ́), ẹ̀yin ni ẹ kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo وَمَا كَانَ لَنَا عَلَيۡكُم مِّن سُلۡطَٰنِۭۖ بَلۡ كُنتُمۡ قَوۡمًا طَٰغِينَ ٣٠Àti pé àwa kò ní agbára kan lórí yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ ìjọ olùtayọ-ẹnu àlà فَحَقَّ عَلَيۡنَا قَوۡلُ رَبِّنَآۖ إِنَّا لَذَآئِقُونَ ٣١Ọ̀rọ̀ Olúwa wa sì kò lé wa lórí pé dájúdájú àwa yóò tọ́ Iná wò فَأَغۡوَيۡنَٰكُمۡ إِنَّا كُنَّا غَٰوِينَ ٣٢Nítorí náà, a ṣì yín lọ́nà. Dájúdájú àwa náà sì jẹ́ olùṣìnà فَإِنَّهُمۡ يَوۡمَئِذٍ فِي ٱلۡعَذَابِ مُشۡتَرِكُونَ ٣٣Dájúdájú ní ọjọ́ yẹn, akẹgbẹ́ ni wọ́n nínú Ìyà إِنَّا كَذَٰلِكَ نَفۡعَلُ بِٱلۡمُجۡرِمِينَ ٣٤Dájúdájú báyẹn ni Àwa yóò ti ṣe pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ إِنَّهُمۡ كَانُوٓاْ إِذَا قِيلَ لَهُمۡ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا ٱللَّهُ يَسۡتَكۡبِرُونَ ٣٥Dájúdájú nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé "Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Allāhu.", wọn yóò máa ṣègbéraga وَيَقُولُونَ أَئِنَّا لَتَارِكُوٓاْ ءَالِهَتِنَا لِشَاعِرٍ مَّجۡنُونِۭ ٣٦Wọ́n sì ń wí pé: "Ṣé a máa fi àwọn òrìṣà wa sílẹ̀ nítorí eléwì wèrè kan بَلۡ جَآءَ بِٱلۡحَقِّ وَصَدَّقَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ ٣٧Kò rí bẹ́ẹ̀. Ó mú òdodo wá ni. Ó sì ń jẹ́rìí sí òdodo àwọn Òjíṣẹ́ náà إِنَّكُمۡ لَذَآئِقُواْ ٱلۡعَذَابِ ٱلۡأَلِيمِ ٣٨Dájúdájú ẹ máa tọ́ ìyà ẹlẹ́ta-eléro wò وَمَا تُجۡزَوۡنَ إِلَّا مَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ ٣٩A ò níí san yín ní ẹ̀san kan àfi ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ إِلَّا عِبَادَ ٱللَّهِ ٱلۡمُخۡلَصِينَ ٤٠Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn ẹni ẹ̀ṣà أُوْلَٰٓئِكَ لَهُمۡ رِزۡقٌ مَّعۡلُومٌ ٤١Ti àwọn wọ̀nyẹn sì ni arísìkí tí wọ́n ti mọ̀ فَوَٰكِهُ وَهُم مُّكۡرَمُونَ ٤٢àwọn èso. Àwọn sì ni alápọ̀n-ọ́nlé فِي جَنَّٰتِ ٱلنَّعِيمِ ٤٣nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra عَلَىٰ سُرُرٍ مُّتَقَٰبِلِينَ ٤٤Lórí àwọn ìtẹ́ ni wọn yóò ti kọjú síra wọn يُطَافُ عَلَيۡهِم بِكَأۡسٍ مِّن مَّعِينِۭ ٤٥Wọn yóò máa gbé ife ọtí mímọ́ káà kiri ọ̀dọ̀ wọn بَيۡضَآءَ لَذَّةٍ لِّلشَّٰرِبِينَ ٤٦Funfun ni (ọtí náà). Ó ń dùn lẹ́nu àwọn t’ó máa mu ún لَا فِيهَا غَوۡلٌ وَلَا هُمۡ عَنۡهَا يُنزَفُونَ ٤٧Kò sí ìpalára kan fún wọn nínú rẹ̀, wọn kò sì níí hunrírà lórí rẹ̀ وَعِندَهُمۡ قَٰصِرَٰتُ ٱلطَّرۡفِ عِينٌ ٤٨Àwọn obìnrin tí kì í wo ẹlòmíìràn, àwọn ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́ yó sì wà lọ́dọ̀ wọn كَأَنَّهُنَّ بَيۡضٌ مَّكۡنُونٌ ٤٩Wọ́n dà bí tinú ẹyin. ó tún jẹ́ kí á mọ̀ pé wọn kò retí ìkẹ́ kan kan lọ́run ní tiwọn. Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n ń retí ìkẹ́ kan ní ọ̀run فَأَقۡبَلَ بَعۡضُهُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٍ يَتَسَآءَلُونَ ٥٠Apá kan wọn yóò dojú kọ apá kan, tí wọn yóò máa bira wọn léèrè ìbéèrè قَالَ قَآئِلٌ مِّنۡهُمۡ إِنِّي كَانَ لِي قَرِينٌ ٥١Òǹsọ̀rọ̀ kan nínú wọn yóò sọ pé: "Dájúdájú èmi ní ọ̀rẹ́ kan يَقُولُ أَءِنَّكَ لَمِنَ ٱلۡمُصَدِّقِينَ ٥٢tí ó ń wí pé, “Ṣé dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn onígbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Àjíǹde أَءِذَا مِتۡنَا وَكُنَّا تُرَابًا وَعِظَٰمًا أَءِنَّا لَمَدِينُونَ ٥٣Ṣé nígbà tí a bá kú tán, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé dájúdájú Wọn yóò san wá ní ẹ̀san ni?” قَالَ هَلۡ أَنتُم مُّطَّلِعُونَ ٥٤Ó sọ pé: "Ṣé ẹ̀yin yóò yọjú wo (ẹni náà tí kò gbàgbọ́ nínú Ọjọ́ àjíǹde) فَٱطَّلَعَ فَرَءَاهُ فِي سَوَآءِ ٱلۡجَحِيمِ ٥٥Ó yọjú wò ó. Ó sì rí i láààrin gbùngbùn nínú iná Jẹhīm قَالَ تَٱللَّهِ إِن كِدتَّ لَتُرۡدِينِ ٥٦Ó (sì) sọ pé: "Mó fi Allāhu búra, ìwọ fẹ́ẹ̀ kó ìparun bá mi tán وَلَوۡلَا نِعۡمَةُ رَبِّي لَكُنتُ مِنَ ٱلۡمُحۡضَرِينَ ٥٧Àti pé tí kì í bá ṣe ìdẹ̀ra Olúwa mi ni, èmi náà ìbá wà nínú ẹni tí wọ́n máa mú wá sínú Iná أَفَمَا نَحۡنُ بِمَيِّتِينَ ٥٨Àwa kò sá níí kú mọ́ báyìí إِلَّا مَوۡتَتَنَا ٱلۡأُولَىٰ وَمَا نَحۡنُ بِمُعَذَّبِينَ ٥٩Àfi ikú wa àkọ́kọ́. Wọn kò sì níí jẹ àwa níyà إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡعَظِيمُ ٦٠Dájúdájú èyí, òhun ni èrèǹjẹ ńlá لِمِثۡلِ هَٰذَا فَلۡيَعۡمَلِ ٱلۡعَٰمِلُونَ ٦١Nítorí irú èyí, kí àwọn olùṣẹ̀sìn máa ṣẹ̀sìn lọ أَذَٰلِكَ خَيۡرٌ نُّزُلًا أَمۡ شَجَرَةُ ٱلزَّقُّومِ ٦٢Ǹjẹ́ ìyẹn l’ó lóore jùlọ ní ibùdésí ni tàbí igi zaƙūm (igi ẹlẹ́gùn-ún) إِنَّا جَعَلۡنَٰهَا فِتۡنَةً لِّلظَّٰلِمِينَ ٦٣Dájúdájú Àwa ṣe é ní àdánwò fún àwọn alábòsí إِنَّهَا شَجَرَةٌ تَخۡرُجُ فِيٓ أَصۡلِ ٱلۡجَحِيمِ ٦٤Dájúdájú òhun ni igi kan tí ó máa hù jáde láti ìdí iná Jẹhīm طَلۡعُهَا كَأَنَّهُۥ رُءُوسُ ٱلشَّيَٰطِينِ ٦٥Èso rẹ̀ dà bí orí àwọn èṣù فَإِنَّهُمۡ لَأٓكِلُونَ مِنۡهَا فَمَالِـُٔونَ مِنۡهَا ٱلۡبُطُونَ ٦٦Dájúdájú wọn yóò máa jẹ nínú rẹ̀. Nítorí náà, wọn yóò fi kún inú wọn bámúbámú ثُمَّ إِنَّ لَهُمۡ عَلَيۡهَا لَشَوۡبًا مِّنۡ حَمِيمٍ ٦٧Lẹ́yìn náà, dájúdájú wọn yóò mu n̄ǹkan mímu àwọyúnwẹ̀jẹ̀ gbígbóná lé e lórí ثُمَّ إِنَّ مَرۡجِعَهُمۡ لَإِلَى ٱلۡجَحِيمِ ٦٨Lẹ́yìn náà, dájúdájú ibùpadàsí wọn ni iná Jẹhīm إِنَّهُمۡ أَلۡفَوۡاْ ءَابَآءَهُمۡ ضَآلِّينَ ٦٩Dájúdájú wọ́n bá àwọn bàbá wọn ní olùṣìnà فَهُمۡ عَلَىٰٓ ءَاثَٰرِهِمۡ يُهۡرَعُونَ ٧٠Àwọn náà sì ń yára tẹ̀lé orípa wọn وَلَقَدۡ ضَلَّ قَبۡلَهُمۡ أَكۡثَرُ ٱلۡأَوَّلِينَ ٧١Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ẹni àkọ́kọ́ ti ṣìnà ṣíwájú wọn وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا فِيهِم مُّنذِرِينَ ٧٢Dájúdájú A ti rán àwọn olùkìlọ̀ sí wọn فَٱنظُرۡ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلۡمُنذَرِينَ ٧٣Nítorí náà, wo bí àtubọ̀tán àwọn ẹni-akìlọ̀-fún ti rí إِلَّا عِبَادَ ٱللَّهِ ٱلۡمُخۡلَصِينَ ٧٤Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn ẹni ẹ̀ṣà وَلَقَدۡ نَادَىٰنَا نُوحٌ فَلَنِعۡمَ ٱلۡمُجِيبُونَ ٧٥Dájúdájú (Ànábì) Nūh pè Wá. A sì dára ní olùjẹ́pè وَنَجَّيۡنَٰهُ وَأَهۡلَهُۥ مِنَ ٱلۡكَرۡبِ ٱلۡعَظِيمِ ٧٦A gba òun àti àwọn ará ilé rẹ̀ là kúrò nínú ìbànújẹ́ ńlá وَجَعَلۡنَا ذُرِّيَّتَهُۥ هُمُ ٱلۡبَاقِينَ ٧٧A dá àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ sí lẹ́yìn rẹ̀ وَتَرَكۡنَا عَلَيۡهِ فِي ٱلۡأٓخِرِينَ ٧٨A sì fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn سَلَٰمٌ عَلَىٰ نُوحٍ فِي ٱلۡعَٰلَمِينَ ٧٩Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) Nūh láààrin gbogbo ẹ̀dá إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ ٨٠Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere) إِنَّهُۥ مِنۡ عِبَادِنَا ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ٨١Dájúdájú òun wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo ثُمَّ أَغۡرَقۡنَا ٱلۡأٓخَرِينَ ٨٢Lẹ́yìn náà, A tẹ àwọn yòókù rì sínú agbami ۞ وَإِنَّ مِن شِيعَتِهِۦ لَإِبۡرَٰهِيمَ ٨٣Dájúdájú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm wà nínú ìjọ (tí ó tẹ̀lé ìlànà) rẹ̀ إِذۡ جَآءَ رَبَّهُۥ بِقَلۡبٍ سَلِيمٍ ٨٤(Ẹ rántí) nígbà tí òun náà dojú kọ Olúwa rẹ̀ pẹ̀lú ọkàn mímọ́ إِذۡ قَالَ لِأَبِيهِ وَقَوۡمِهِۦ مَاذَا تَعۡبُدُونَ ٨٥(Rántí) nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: "Kí ni ẹ̀ ń jọ́sìn fún أَئِفۡكًا ءَالِهَةً دُونَ ٱللَّهِ تُرِيدُونَ ٨٦Ṣé ẹ̀ ń gbèrò láti sọ irọ́ di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu فَمَا ظَنُّكُم بِرَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ ٨٧Kí sì ni èrò ọkàn yín sí Olúwa gbogbo ẹ̀dá?” فَنَظَرَ نَظۡرَةً فِي ٱلنُّجُومِ ٨٨Ó ṣíjú wo àwọn ìràwọ̀ gan-an فَقَالَ إِنِّي سَقِيمٌ ٨٩Ó sì sọ pé: "Dájúdájú ó rẹ̀ mí فَتَوَلَّوۡاْ عَنۡهُ مُدۡبِرِينَ ٩٠Nítorí náà, wọ́n pa á tì, wọ́n sì lọ فَرَاغَ إِلَىٰٓ ءَالِهَتِهِمۡ فَقَالَ أَلَا تَأۡكُلُونَ ٩١Nígbà náà, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn òrìṣà wọn. Ó sì sọ pé: "Ṣé ẹ ò níí jẹun ni مَا لَكُمۡ لَا تَنطِقُونَ ٩٢Kí ni ó ṣe yín tí ẹ ò sọ̀rọ̀ فَرَاغَ عَلَيۡهِمۡ ضَرۡبَۢا بِٱلۡيَمِينِ ٩٣Nígbà náà, ó dojú lílù kọ wọ́n pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún (ó sì rún wọn wómúwómú) فَأَقۡبَلُوٓاْ إِلَيۡهِ يَزِفُّونَ ٩٤(Àwọn abọ̀rìṣà) sáré wá dojú kọ ọ́ قَالَ أَتَعۡبُدُونَ مَا تَنۡحِتُونَ ٩٥Ó sọ pé: "Ṣé ẹ óò máa jọ́sìn fún n̄ǹkan tí ẹ gbẹ́ kalẹ̀ lére ni وَٱللَّهُ خَلَقَكُمۡ وَمَا تَعۡمَلُونَ ٩٦Allāhu l’Ó sì dá ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ قَالُواْ ٱبۡنُواْ لَهُۥ بُنۡيَٰنًا فَأَلۡقُوهُ فِي ٱلۡجَحِيمِ ٩٧Wọ́n wí pé: "Ẹ mọ ilé kan fún un, kí ẹ sì jù ú sínú iná فَأَرَادُواْ بِهِۦ كَيۡدًا فَجَعَلۡنَٰهُمُ ٱلۡأَسۡفَلِينَ ٩٨Wọ́n gbèrò ète sí i. A sì sọ wọ́n di ẹni yẹpẹrẹ وَقَالَ إِنِّي ذَاهِبٌ إِلَىٰ رَبِّي سَيَهۡدِينِ ٩٩Ó sọ pé: "Dájúdájú mo máa lọ sí (ìlú tí) Olúwa mi (pa mí láṣẹ láti lọ). Ó sì máa tọ́ mi sọ́nà (láti dé ibẹ̀) رَبِّ هَبۡ لِي مِنَ ٱلصَّٰلِحِينَ ١٠٠Olúwa mi, ta mí lọ́rẹ ọmọ nínú àwọn ẹni rere فَبَشَّرۡنَٰهُ بِغُلَٰمٍ حَلِيمٍ ١٠١A sì fún un ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ọmọkùnrin aláfaradà فَلَمَّا بَلَغَ مَعَهُ ٱلسَّعۡيَ قَالَ يَٰبُنَيَّ إِنِّيٓ أَرَىٰ فِي ٱلۡمَنَامِ أَنِّيٓ أَذۡبَحُكَ فَٱنظُرۡ مَاذَا تَرَىٰۚ قَالَ يَٰٓأَبَتِ ٱفۡعَلۡ مَا تُؤۡمَرُۖ سَتَجِدُنِيٓ إِن شَآءَ ٱللَّهُ مِنَ ٱلصَّٰبِرِينَ ١٠٢Nígbà tí (ọmọ náà) dàgbà, tí ó tó bá (bàbá rẹ̀) ṣe iṣẹ́, (bàbá rẹ̀) sọ pé: "Ọmọ mi, dájúdájú èmi lá àlá pé dájúdájú mò ń dúńbú rẹ. Nítorí náà, wòye sí i, kí ni o rí sí i." Ó sọ pé: "Bàbá mi, ṣe ohun tí Wọ́n pa láṣẹ fún ọ. O máa bá mi nínú àwọn onísùúrù, tí Allāhu bá fẹ́ فَلَمَّآ أَسۡلَمَا وَتَلَّهُۥ لِلۡجَبِينِ ١٠٣Nígbà tí àwọn méjèèjì juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀, tí (Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sì dojú (ọmọ) rẹ̀ bolẹ̀ وَنَٰدَيۡنَٰهُ أَن يَٰٓإِبۡرَٰهِيمُ ١٠٤A pè é (báyìí) pé, ’Ibrọ̄hīm قَدۡ صَدَّقۡتَ ٱلرُّءۡيَآۚ إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ ١٠٥o kúkú ti mú àlá náà ṣẹ. Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere) إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ ٱلۡبَلَٰٓؤُاْ ٱلۡمُبِينُ ١٠٦Dájúdájú èyí, òhun ni àdánwò pọ́nńbélé وَفَدَيۡنَٰهُ بِذِبۡحٍ عَظِيمٍ ١٠٧A sì fi àgbò ńlá ṣèràpadà rẹ̀ وَتَرَكۡنَا عَلَيۡهِ فِي ٱلۡأٓخِرِينَ ١٠٨A tún fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn سَلَٰمٌ عَلَىٰٓ إِبۡرَٰهِيمَ ١٠٩Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ ١١٠Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere) إِنَّهُۥ مِنۡ عِبَادِنَا ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ١١١Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo وَبَشَّرۡنَٰهُ بِإِسۡحَٰقَ نَبِيًّا مِّنَ ٱلصَّٰلِحِينَ ١١٢A tún fún un ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ’Ishāƙ, (ó máa jẹ́) Ànábì. (Ó sì máa wà) nínú àwọn ẹni rere وَبَٰرَكۡنَا عَلَيۡهِ وَعَلَىٰٓ إِسۡحَٰقَۚ وَمِن ذُرِّيَّتِهِمَا مُحۡسِنٌ وَظَالِمٌ لِّنَفۡسِهِۦ مُبِينٌ ١١٣Àti pé A fún òun àti ’Ishāƙ ní ìbùkún. Ẹni rere àti alábòsí pọ́nńbélé (t’ó ń ṣàbòsí sí) ẹ̀mí ara rẹ̀ wà nínú àrọ́mọdọ́mọ àwọn méjèèjì وَلَقَدۡ مَنَنَّا عَلَىٰ مُوسَىٰ وَهَٰرُونَ ١١٤Dájúdájú A ṣoore fún (Ànábì) Mūsā àti Hārūn وَنَجَّيۡنَٰهُمَا وَقَوۡمَهُمَا مِنَ ٱلۡكَرۡبِ ٱلۡعَظِيمِ ١١٥A gba àwọn méjèèjì àti ìjọ àwọn méjèèjì là kúrò nínú ìbànújẹ́ ńlá وَنَصَرۡنَٰهُمۡ فَكَانُواْ هُمُ ٱلۡغَٰلِبِينَ ١١٦A tún ṣàrànṣe fún wọn. Àwọn ni wọ́n jẹ́ olùborí (ọ̀tá wọn) وَءَاتَيۡنَٰهُمَا ٱلۡكِتَٰبَ ٱلۡمُسۡتَبِينَ ١١٧A sì fún àwọn méjèèjì ní Tírà t’ó yanjú وَهَدَيۡنَٰهُمَا ٱلصِّرَٰطَ ٱلۡمُسۡتَقِيمَ ١١٨A tún fi àwọn méjèèjì mọ̀nà tààrà وَتَرَكۡنَا عَلَيۡهِمَا فِي ٱلۡأٓخِرِينَ ١١٩A fún àwọn méjèèjì ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn سَلَٰمٌ عَلَىٰ مُوسَىٰ وَهَٰرُونَ ١٢٠Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) Mūsā àti Hārūn إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ ١٢١Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere) إِنَّهُمَا مِنۡ عِبَادِنَا ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ١٢٢Dájúdájú àwọn méjèèjì wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo وَإِنَّ إِلۡيَاسَ لَمِنَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ ١٢٣Dájúdájú (Ànábì) ’Ilyās wà nínú àwọn Òjíṣẹ́ إِذۡ قَالَ لِقَوۡمِهِۦٓ أَلَا تَتَّقُونَ ١٢٤(Ẹ rántí) nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: "Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù Allāhu ni أَتَدۡعُونَ بَعۡلًا وَتَذَرُونَ أَحۡسَنَ ٱلۡخَٰلِقِينَ ١٢٥Ṣé ẹ óò máa pe òrìṣà kan, ẹ sì máa fi Ẹni t’Ó dára jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́dàá sílẹ̀, وَهُوَ خَيْرُ ٱلْحَٰكِمِينَ Òun l’Ó sì dára jùlọ nínú àwọn olùdájọ́. (sūrah al-’A‘rọ̄f 7:87) وَهُوَ أَسْرَعُ ٱلْحَٰسِبِينَ Òun sì yára jùlọ nínú àwọn oníṣirò. (sūrah al-’Ani‘ām 6:62) olùdájọ́ aláàánú ìbáà mọ bíi ọmọ iná igún àfi kí Allāhu jẹ́ Ẹlẹ́dàá rẹ̀. Kódà àdámọ́ owó àti okòwò tí wọ́n sọ di “ọrọ̀-Ajé. Àwọn t’ó ń bọ́ ẹlòmíìràn náà ń sọra wọn di olùpèsè. Yàtọ̀ sí pé Allāhu ti fi rinlẹ̀ pé Òun nìkan ni Olùpèsè fún gbogbo ẹ̀dá Rẹ̀. Tí èyí kò bá tí ì dá àwọn kan lójú bẹ́ẹ̀ tí wọ́n sì fẹ́ gbé gbogbo ìpèsè olúkùlùkù lórí ìwọ̀n nínú àánú tí Allāhu fi sí àwọn ẹ̀dá kan lọ́kàn ni wọ́n fi di aláàánú. Nítorí náà Allāhu ni Aláàánú jùlọ nínú àwọn aláàánú ٱللَّهَ رَبَّكُمۡ وَرَبَّ ءَابَآئِكُمُ ٱلۡأَوَّلِينَ ١٢٦(ẹ̀ ń fi) Allāhu (sílẹ̀), Olúwa yín àti Olúwa àwọn bàbá yín, àwọn ẹni àkọ́kọ́ فَكَذَّبُوهُ فَإِنَّهُمۡ لَمُحۡضَرُونَ ١٢٧Wọ́n sì pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, wọ́n máa mú wọn wá sínú Iná إِلَّا عِبَادَ ٱللَّهِ ٱلۡمُخۡلَصِينَ ١٢٨Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn ẹni ẹ̀ṣà وَتَرَكۡنَا عَلَيۡهِ فِي ٱلۡأٓخِرِينَ ١٢٩A fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn سَلَٰمٌ عَلَىٰٓ إِلۡ يَاسِينَ ١٣٠Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) ’Ilyās إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ ١٣١Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere) إِنَّهُۥ مِنۡ عِبَادِنَا ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ١٣٢Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo وَإِنَّ لُوطًا لَّمِنَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ ١٣٣Dájúdájú (Ànábì) Lūt wà nínú àwọn Òjíṣẹ́ إِذۡ نَجَّيۡنَٰهُ وَأَهۡلَهُۥٓ أَجۡمَعِينَ ١٣٤(Ẹ rántí) nígbà tí A gba òun àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ là إِلَّا عَجُوزًا فِي ٱلۡغَٰبِرِينَ ١٣٥Àyàfi arúgbóbìnrin kan tí ó wà nínú àwọn t’ó ṣẹ́ kù lẹ́yìn (láààrin àwọn tí A parẹ́) ثُمَّ دَمَّرۡنَا ٱلۡأٓخَرِينَ ١٣٦Lẹ́yìn náà, A pa àwọn yòókù run وَإِنَّكُمۡ لَتَمُرُّونَ عَلَيۡهِم مُّصۡبِحِينَ ١٣٧Dájúdájú ẹ̀yin náà kúkú ń gba ọ̀dọ̀ wọn kọjá láàárọ̀-láàárọ̀ وَبِٱلَّيۡلِۚ أَفَلَا تَعۡقِلُونَ ١٣٨àti ní alaalẹ́. Ṣé ẹ ò níí ṣe làákàyè ni وَإِنَّ يُونُسَ لَمِنَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ ١٣٩Dájúdájú (Ànábì) Yūnus kúkú wà nínú àwọn Òjíṣẹ́ إِذۡ أَبَقَ إِلَى ٱلۡفُلۡكِ ٱلۡمَشۡحُونِ ١٤٠(Ẹ rántí) nígbà tí ó sá lọ sínú ọkọ̀ ojú-omi t’ó kún kẹ́kẹ́ فَسَاهَمَ فَكَانَ مِنَ ٱلۡمُدۡحَضِينَ ١٤١Ó sì bá wọn muje pọ̀. Ó sì wà nínú àwọn tí aje ṣí mọ́ lórí فَٱلۡتَقَمَهُ ٱلۡحُوتُ وَهُوَ مُلِيمٌ ١٤٢Nítorí náà, ẹja gbé e mì; ó sì ń dá ara rẹ̀ lẹ́bi فَلَوۡلَآ أَنَّهُۥ كَانَ مِنَ ٱلۡمُسَبِّحِينَ ١٤٣Nítorí náà, tí kò bá jẹ́ pé ó wà nínú àwọn olùṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu لَلَبِثَ فِي بَطۡنِهِۦٓ إِلَىٰ يَوۡمِ يُبۡعَثُونَ ١٤٤dájúdájú ìbá wà nínú ẹja títí di ọjọ́ tí wọn yóò gbé ẹ̀dá dìde ۞ فَنَبَذۡنَٰهُ بِٱلۡعَرَآءِ وَهُوَ سَقِيمٌ ١٤٥Nítorí náà, A jù ú sí orí ilẹ́ gban̄sasa létí omi. Ó sì jẹ́ aláìlera وَأَنۢبَتۡنَا عَلَيۡهِ شَجَرَةً مِّن يَقۡطِينٍ ١٤٦A sì mú igi Yẹƙtīn hù jáde láti ṣíji bò ó وَأَرۡسَلۡنَٰهُ إِلَىٰ مِاْئَةِ أَلۡفٍ أَوۡ يَزِيدُونَ ١٤٧A tún rán an níṣẹ́ sí ọ̀kẹ́ márùn-ún (ènìyàn) tàbí kí wọ́n lékún sí i فَـَٔامَنُواْ فَمَتَّعۡنَٰهُمۡ إِلَىٰ حِينٍ ١٤٨Wọ́n gbàgbọ́ ní òdodo. A sì fún wọn ní ìgbádùn títí di ìgbà díẹ̀ فَٱسۡتَفۡتِهِمۡ أَلِرَبِّكَ ٱلۡبَنَاتُ وَلَهُمُ ٱلۡبَنُونَ ١٤٩Bi wọ́n léèrè wò pé: "Ṣé Olúwa rẹ l’ó ni àwọn ọmọbìnrin, tiwọn sì ni ọmọkùnrin أَمۡ خَلَقۡنَا ٱلۡمَلَٰٓئِكَةَ إِنَٰثًا وَهُمۡ شَٰهِدُونَ ١٥٠Tàbí A dá àwọn mọlāika ní obìnrin, tí àwọn sì jẹ́ ẹlẹ́rìí أَلَآ إِنَّهُم مِّنۡ إِفۡكِهِمۡ لَيَقُولُونَ ١٥١Gbọ́, nínú irọ́ wọn ni pé dájúdájú wọ́n ń wí pé وَلَدَ ٱللَّهُ وَإِنَّهُمۡ لَكَٰذِبُونَ ١٥٢Allāhu bímọ." Dájúdájú òpùrọ́ ni wọ́n أَصۡطَفَى ٱلۡبَنَاتِ عَلَى ٱلۡبَنِينَ ١٥٣Ṣé (Allāhu) ṣẹ̀ṣà àwọn ọmọbìnrin lórí àwọn ọmọkùnrin ni مَا لَكُمۡ كَيۡفَ تَحۡكُمُونَ ١٥٤Kí l’ó ń ṣe yín tí ẹ fi ń dájọ́ báyìí أَفَلَا تَذَكَّرُونَ ١٥٥Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni أَمۡ لَكُمۡ سُلۡطَٰنٌ مُّبِينٌ ١٥٦Tàbí ẹ ní ẹ̀rí t’ó yanjú lọ́wọ́ ni فَأۡتُواْ بِكِتَٰبِكُمۡ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ ١٥٧Ẹ mú tírà yín wà nígbà náà tí ẹ bá jẹ́ olódodo وَجَعَلُواْ بَيۡنَهُۥ وَبَيۡنَ ٱلۡجِنَّةِ نَسَبًاۚ وَلَقَدۡ عَلِمَتِ ٱلۡجِنَّةُ إِنَّهُمۡ لَمُحۡضَرُونَ ١٥٨Wọ́n tún fi ìbátan sáààrin (Allāhu) àti àlùjànnú! Àwọn àlùjànnú sì ti mọ̀ pé dájúdájú wọ́n kúkú máa mú àwọn wá sínú Iná ni سُبۡحَٰنَ ٱللَّهِ عَمَّا يَصِفُونَ ١٥٩Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀) إِلَّا عِبَادَ ٱللَّهِ ٱلۡمُخۡلَصِينَ ١٦٠Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn ẹni ẹ̀ṣà فَإِنَّكُمۡ وَمَا تَعۡبُدُونَ ١٦١Dájúdájú ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún (lẹ́yìn Allāhu) مَآ أَنتُمۡ عَلَيۡهِ بِفَٰتِنِينَ ١٦٢ẹ ò lè fi ṣi ẹnì kan kan lọ́nà إِلَّا مَنۡ هُوَ صَالِ ٱلۡجَحِيمِ ١٦٣àfi ẹni tí ó bá fẹ́ wọ inú iná Jẹhīm وَمَا مِنَّآ إِلَّا لَهُۥ مَقَامٌ مَّعۡلُومٌ ١٦٤Kò sí ẹnì kan nínú àwa (mọlāika) àfi kí ó ní ibùdúró tí wọ́n ti mọ̀ وَإِنَّا لَنَحۡنُ ٱلصَّآفُّونَ ١٦٥Dájúdájú àwa, a kúkú wà ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ وَإِنَّا لَنَحۡنُ ٱلۡمُسَبِّحُونَ ١٦٦Àti pé dájúdájú àwa, àwa kúkú ni olùṣàfọ̀mọ́ (fún Allāhu) وَإِن كَانُواْ لَيَقُولُونَ ١٦٧Wọ́n kúkú ń wí pé لَوۡ أَنَّ عِندَنَا ذِكۡرًا مِّنَ ٱلۡأَوَّلِينَ ١٦٨Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú a bá ní (tírà) ìrántí kan nínú (àwọn tírà) àwọn ẹni àkọ́kọ́ لَكُنَّا عِبَادَ ٱللَّهِ ٱلۡمُخۡلَصِينَ ١٦٩dájúdájú àwa ìbá jẹ́ ẹrúsìn Allāhu, àwọn ẹni ẹ̀ṣà فَكَفَرُواْ بِهِۦۖ فَسَوۡفَ يَعۡلَمُونَ ١٧٠Ṣùgbọ́n wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú (Allāhu). Láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀ وَلَقَدۡ سَبَقَتۡ كَلِمَتُنَا لِعِبَادِنَا ٱلۡمُرۡسَلِينَ ١٧١Dájúdájú ọ̀rọ̀ Wa ti ṣíwájú fún àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn Òjíṣẹ́ إِنَّهُمۡ لَهُمُ ٱلۡمَنصُورُونَ ١٧٢Dájúdájú àwọn, àwọn l’a kúkú máa ṣàrànṣe fún وَإِنَّ جُندَنَا لَهُمُ ٱلۡغَٰلِبُونَ ١٧٣Àti pé dájúdájú àwọn ọmọ ogun Wa, àwọn kúkú ni olùborí فَتَوَلَّ عَنۡهُمۡ حَتَّىٰ حِينٍ ١٧٤Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn fún ìgbà díẹ̀ وَأَبۡصِرۡهُمۡ فَسَوۡفَ يُبۡصِرُونَ ١٧٥Àti pé máa wò wọ́n níran ná, àwọn náà ń bọ̀ wá ríran wò أَفَبِعَذَابِنَا يَسۡتَعۡجِلُونَ ١٧٦Ṣé ìyà Wa ni wọ́n ń wá pẹ̀lú ìkánjú فَإِذَا نَزَلَ بِسَاحَتِهِمۡ فَسَآءَ صَبَاحُ ٱلۡمُنذَرِينَ ١٧٧Nígbà tí ó bá sọ̀kalẹ̀ sí agboolé wọn, òwúrọ̀ ọjọ́ náà yó sì burú fún àwọn ẹni-akìlọ̀-fún وَتَوَلَّ عَنۡهُمۡ حَتَّىٰ حِينٍ ١٧٨Kúrò lọ́dọ̀ wọn títí di ìgbà kan ná وَأَبۡصِرۡ فَسَوۡفَ يُبۡصِرُونَ ١٧٩Àti pé máa wò wọ́n níran ná, àwọn náà ń bọ̀ wá ríran wò سُبۡحَٰنَ رَبِّكَ رَبِّ ٱلۡعِزَّةِ عَمَّا يَصِفُونَ ١٨٠Mímọ́ ni fún Olúwa rẹ, Olúwa agbára, tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀) وَسَلَٰمٌ عَلَى ٱلۡمُرۡسَلِينَ ١٨١Kí àlàáfíà máa bá àwọn Òjíṣẹ́ وَٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ ١٨٢Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá