بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
وَٱلسَّمَآءِ وَٱلطَّارِقِ ١(Allāhu) búra pẹ̀lú sánmọ̀ àti Tọ̄riƙ وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا ٱلطَّارِقُ ٢Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Tọ̄riƙ ٱلنَّجۡمُ ٱلثَّاقِبُ ٣Ìràwọ̀ tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ń tàn ròrò (ní alẹ́ ni) إِن كُلُّ نَفۡسٍ لَّمَّا عَلَيۡهَا حَافِظٌ ٤Kò sí ẹ̀mí kan àfi kí ẹ̀ṣọ́ kan wà fún un (nínú àwọn mọlāika) فَلۡيَنظُرِ ٱلۡإِنسَٰنُ مِمَّ خُلِقَ ٥Nítorí náà, kí ènìyàn wòye sí ohun tí A fi ṣẹ̀dá rẹ̀ خُلِقَ مِن مَّآءٍ دَافِقٍ ٦Wọ́n ṣẹ̀dá rẹ̀ láti inú omi t’ó ń tú jáde kọ̀ọ́kọ̀ọ́ يَخۡرُجُ مِنۢ بَيۡنِ ٱلصُّلۡبِ وَٱلتَّرَآئِبِ ٧Ó ń jáde láti ààrin ìbàdí ọkùnrin àti àwọn ẹfọ́nhà igbá-àyà obìnrin إِنَّهُۥ عَلَىٰ رَجۡعِهِۦ لَقَادِرٌ ٨Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lóri ìdápadà rẹ̀ يَوۡمَ تُبۡلَى ٱلسَّرَآئِرُ ٩ní ọjọ́ tí wọ́n máa ṣe àyẹ̀wò àwọn (iṣẹ́) àṣepamọ́ فَمَا لَهُۥ مِن قُوَّةٍ وَلَا نَاصِرٍ ١٠Nígbà náà, kò níí sí agbára tàbí alárànṣe kan fún un وَٱلسَّمَآءِ ذَاتِ ٱلرَّجۡعِ ١١Allāhu búra pẹ̀lú sánmọ̀ t’ó ń rọ òjò ní ọdọọdún وَٱلۡأَرۡضِ ذَاتِ ٱلصَّدۡعِ ١٢Ó tún búra pẹ̀lú ilẹ̀ t’ó ń sán kànkàn (fún híhùjáde èso) إِنَّهُۥ لَقَوۡلٌ فَصۡلٌ ١٣Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ọ̀rọ̀-ìpínyà (láààrin òdodo àti irọ́) وَمَا هُوَ بِٱلۡهَزۡلِ ١٤Kì í sì ṣe àwàdà إِنَّهُمۡ يَكِيدُونَ كَيۡدًا ١٥Dájúdájú wọ́n ń déte gan-an وَأَكِيدُ كَيۡدًا ١٦Èmi náà sì ń déte gan-an فَمَهِّلِ ٱلۡكَٰفِرِينَ أَمۡهِلۡهُمۡ رُوَيۡدَۢا ١٧Nítorí náà, lọ́ra fún àwọn aláìgbàgbọ́. Lọ́ wọn lára sẹ́ fún ìgbà díẹ̀