ملة الإسلام

السورة 43 · 89 آية · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

سورة الزخرف باللغة اليوروبا

السورة بالعربية مع التفسير استمع إلى سورة الزخرف (1,181 قارئاً)
مكيةسورة الزخرف٨٩ آية

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

حمٓ ١Hā mīm وَٱلۡكِتَٰبِ ٱلۡمُبِينِ ٢(Allāhu) fi Tírà t’ó yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá búra إِنَّا جَعَلۡنَٰهُ قُرۡءَٰنًا عَرَبِيًّا لَّعَلَّكُمۡ تَعۡقِلُونَ ٣Dájúdájú Àwa sọ ọ́ ní al-Ƙur’ān. (A sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ní) èdè Lárúbáwá nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè وَإِنَّهُۥ فِيٓ أُمِّ ٱلۡكِتَٰبِ لَدَيۡنَا لَعَلِيٌّ حَكِيمٌ ٤Àti pé dájúdájú nínú Tírà Ìpìlẹ̀ t’ó wà lọ́dọ̀ Wa, al-Ƙur’ān ga, ó kún fún ọgbọ́n أَفَنَضۡرِبُ عَنكُمُ ٱلذِّكۡرَ صَفۡحًا أَن كُنتُمۡ قَوۡمًا مُّسۡرِفِينَ ٥Ṣé kí Á ká Tírà Ìrántí (al-Ƙur’ān) kúrò nílẹ̀ fun yín, kí Á máa wò yín níran nítorí pé ẹ jẹ́ ìjọ alákọyọ وَكَمۡ أَرۡسَلۡنَا مِن نَّبِيٍّ فِي ٱلۡأَوَّلِينَ ٦Mélòó mélòó nínú àwọn Ànábì tí A ti rán sí àwọn ẹni àkọ́kọ́ وَمَا يَأۡتِيهِم مِّن نَّبِيٍّ إِلَّا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ ٧Kò sí Ànábì kan tí ó wá bá wọn àyàfi kí wọ́n máa fi ṣe yẹ̀yẹ́ فَأَهۡلَكۡنَآ أَشَدَّ مِنۡهُم بَطۡشًا وَمَضَىٰ مَثَلُ ٱلۡأَوَّلِينَ ٨Nítorí náà, A ti pa àwọn t’ó ní agbára ju àwọn (wọ̀nyí) rẹ́. Àpèjúwe (ìparun) àwọn ẹni àkọ́kọ́ sì ti ṣíwájú وَلَئِن سَأَلۡتَهُم مَّنۡ خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ لَيَقُولُنَّ خَلَقَهُنَّ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡعَلِيمُ ٩Tí o bá bi wọ́n léèrè pé: "Ta ni Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?", dájúdájú wọ́n á wí pé: "Ẹni t’ó dá wọn ni Alágbára, Onímọ̀ ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُمُ ٱلۡأَرۡضَ مَهۡدًا وَجَعَلَ لَكُمۡ فِيهَا سُبُلًا لَّعَلَّكُمۡ تَهۡتَدُونَ ١٠Ẹni tí Ó ṣe ilẹ̀ ní ìtẹ́ fun yín. Ó sì fi àwọn ojú ọ̀nà sínú rẹ̀ fun yín nítorí kí ẹ lè mọ̀nà وَٱلَّذِي نَزَّلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءَۢ بِقَدَرٍ فَأَنشَرۡنَا بِهِۦ بَلۡدَةً مَّيۡتًاۚ كَذَٰلِكَ تُخۡرَجُونَ ١١Ẹni tí Ó ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀ níwọ̀n-níwọ̀n. Ó sì ń fi sọ òkú ilẹ̀ di àyè ilẹ̀. Báyẹn náà ni wọn yóò ṣe mu yín jáde وَٱلَّذِي خَلَقَ ٱلۡأَزۡوَٰجَ كُلَّهَا وَجَعَلَ لَكُم مِّنَ ٱلۡفُلۡكِ وَٱلۡأَنۡعَٰمِ مَا تَرۡكَبُونَ ١٢Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá gbogbo n̄ǹkan ní oríṣiríṣi. Ó sì ṣe n̄ǹkan tí ẹ̀ ń gùn fun yín láti ara àwọn ọkọ̀ ojú-omi àti àwọn ẹran-ọ̀sìn لِتَسۡتَوُۥاْ عَلَىٰ ظُهُورِهِۦ ثُمَّ تَذۡكُرُواْ نِعۡمَةَ رَبِّكُمۡ إِذَا ٱسۡتَوَيۡتُمۡ عَلَيۡهِ وَتَقُولُواْ سُبۡحَٰنَ ٱلَّذِي سَخَّرَ لَنَا هَٰذَا وَمَا كُنَّا لَهُۥ مُقۡرِنِينَ ١٣Nítorí kí ẹ lè jókòó dáadáa sẹ́yìn rẹ̀, lẹ́yìn náà kí ẹ lè ṣe ìrántí ìdẹ̀ra Olúwa yín nígbà tí ẹ bá jókòó dáadáa tán sórí rẹ̀, kí ẹ sì sọ pé: "Mímọ́ ni fún Ẹni tí Ó rọ èyí fún wa, kì í ṣe pé a jẹ́ alágbára lórí rẹ̀ وَإِنَّآ إِلَىٰ رَبِّنَا لَمُنقَلِبُونَ ١٤Àti pé dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa wa ni àwa yóò padà sí وَجَعَلُواْ لَهُۥ مِنۡ عِبَادِهِۦ جُزۡءًاۚ إِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ لَكَفُورٌ مُّبِينٌ ١٥Wọ́n fi ìpín kan nínú àwọn ẹrúsìn (Allāhu) tì sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ (ní ti ọmọ bíbí). Dájúdájú ènìyàn ni aláìmoore pọ́nńbélé أَمِ ٱتَّخَذَ مِمَّا يَخۡلُقُ بَنَاتٍ وَأَصۡفَىٰكُم بِٱلۡبَنِينَ ١٦Tàbí (ẹ̀yin ń wí pé): "Ó mú nínú n̄ǹkan tí Ó dá ní ọmọbìnrin (fúnra Rẹ̀). Ó sì fi àwọn ọmọkùnrin ṣa ẹ̀yin lẹ́ṣà وَإِذَا بُشِّرَ أَحَدُهُم بِمَا ضَرَبَ لِلرَّحۡمَٰنِ مَثَلًا ظَلَّ وَجۡهُهُۥ مُسۡوَدًّا وَهُوَ كَظِيمٌ ١٧Nígbà tí wọ́n bá fún ẹnì kan nínú wọn ní ìró ìdùnnú ohun tí ó fi ṣe àpẹẹrẹ fún Àjọkẹ́-ayé (pé onítọ̀ún bí ọmọbìnrin), ojú rẹ̀ máa ṣókùnkùn wá. Ó sì máa kún fún ìbànújẹ́ أَوَمَن يُنَشَّؤُاْ فِي ٱلۡحِلۡيَةِ وَهُوَ فِي ٱلۡخِصَامِ غَيۡرُ مُبِينٍ ١٨Ṣé ẹni tí wọ́n ń tọ́ nínú ọ̀ṣọ́ (tí ó ń to ọ̀ṣọ́ mọ́ra), tí kò sì lè bọ́ sí gban̄gba níbi ìjà (ni ẹ̀ ń pè ní ọmọ Àjọkẹ́-ayé) وَجَعَلُواْ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةَ ٱلَّذِينَ هُمۡ عِبَٰدُ ٱلرَّحۡمَٰنِ إِنَٰثًاۚ أَشَهِدُواْ خَلۡقَهُمۡۚ سَتُكۡتَبُ شَهَٰدَتُهُمۡ وَيُسۡـَٔلُونَ ١٩Àwọn mọlāika, àwọn t’ó jẹ́ ẹrúsìn Àjọkẹ́-ayé, wọ́n tún sọ wọ́n di ọmọbìnrin! Ṣé wọ́n fojú rí ìṣẹ̀dá wọn ni? Wọ́n máa ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n fojú rí. Wọ́n sì máa bi wọ́n léèrè (nípa rẹ̀) وَقَالُواْ لَوۡ شَآءَ ٱلرَّحۡمَٰنُ مَا عَبَدۡنَٰهُمۗ مَّا لَهُم بِذَٰلِكَ مِنۡ عِلۡمٍۖ إِنۡ هُمۡ إِلَّا يَخۡرُصُونَ ٢٠Wọ́n tún wí pé: "Tí Àjọkẹ́-ayé bá fẹ́, àwa ìbá tí jọ́sìn fún wọn." Kò sí ìmọ̀ kan fún wọn nípa ìyẹn. Wọn kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe pé wọ́n ń parọ́ أَمۡ ءَاتَيۡنَٰهُمۡ كِتَٰبًا مِّن قَبۡلِهِۦ فَهُم بِهِۦ مُسۡتَمۡسِكُونَ ٢١Tàbí A ti fún wọn ní Tírà kan ṣíwájú al-Ƙur’ān, tí wọ́n ń lò ní ẹ̀rí بَلۡ قَالُوٓاْ إِنَّا وَجَدۡنَآ ءَابَآءَنَا عَلَىٰٓ أُمَّةٍ وَإِنَّا عَلَىٰٓ ءَاثَٰرِهِم مُّهۡتَدُونَ ٢٢Rárá. Wọ́n wí pé: "Dájúdájú àwa bá àwọn bàbá wa lórí ẹ̀sìn kan. Dájúdájú àwa sì ni olùmọ̀nà lórí orípa wọn وَكَذَٰلِكَ مَآ أَرۡسَلۡنَا مِن قَبۡلِكَ فِي قَرۡيَةٍ مِّن نَّذِيرٍ إِلَّا قَالَ مُتۡرَفُوهَآ إِنَّا وَجَدۡنَآ ءَابَآءَنَا عَلَىٰٓ أُمَّةٍ وَإِنَّا عَلَىٰٓ ءَاثَٰرِهِم مُّقۡتَدُونَ ٢٣Bákan náà, Àwa kò rán olùkìlọ̀ kan sí ìlú kan ṣíwájú rẹ, àyàfi kí àwọn onígbẹdẹmukẹ ìlú náà wí pé: "Dájúdájú àwa bá àwọn bàbá wa lórí ẹ̀sìn kan. Dájúdájú àwa sì ni olùtẹ̀lé wọn lórí orípa wọn ۞ قَٰلَ أَوَلَوۡ جِئۡتُكُم بِأَهۡدَىٰ مِمَّا وَجَدتُّمۡ عَلَيۡهِ ءَابَآءَكُمۡۖ قَالُوٓاْ إِنَّا بِمَآ أُرۡسِلۡتُم بِهِۦ كَٰفِرُونَ ٢٤(Olùkìlọ̀) sì sọ pé: "Ǹjẹ́ èmi kò ti mú wá fun yín ohun tí ó jẹ́ ìmọ̀nà jùlọ sí ohun tí ẹ bá àwọn bàbá yín lórí rẹ̀?" Wọ́n wí pé: "Dájúdájú àwa jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n fi ran yín níṣẹ́ فَٱنتَقَمۡنَا مِنۡهُمۡۖ فَٱنظُرۡ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلۡمُكَذِّبِينَ ٢٥Nítorí náà, A gbẹ̀san lára wọn. Wo bí ìkángun àwọn olùpe-òdodo-nírọ́ ti rí وَإِذۡ قَالَ إِبۡرَٰهِيمُ لِأَبِيهِ وَقَوۡمِهِۦٓ إِنَّنِي بَرَآءٌ مِّمَّا تَعۡبُدُونَ ٢٦(Rántí) nígbà tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: "Dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú ohun tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún إِلَّا ٱلَّذِي فَطَرَنِي فَإِنَّهُۥ سَيَهۡدِينِ ٢٧Àfi Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá mi. Dájúdájú Òun l’Ó máa fi ọ̀nà tààrà mọ̀ mí وَجَعَلَهَا كَلِمَةَۢ بَاقِيَةً فِي عَقِبِهِۦ لَعَلَّهُمۡ يَرۡجِعُونَ ٢٨Allāhu sì ṣe é ní ọ̀rọ̀ kan t’ó máa wà títí láéláé láààrin àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo) بَلۡ مَتَّعۡتُ هَٰٓؤُلَآءِ وَءَابَآءَهُمۡ حَتَّىٰ جَآءَهُمُ ٱلۡحَقُّ وَرَسُولٌ مُّبِينٌ ٢٩Ṣùgbọ́n Mo fún àwọn wọ̀nyí àti àwọn bàbá wọn ní ìgbádùn ayé títí òdodo àti Òjíṣẹ́ pọ́nńbélé fi dé bá wọn وَلَمَّا جَآءَهُمُ ٱلۡحَقُّ قَالُواْ هَٰذَا سِحۡرٌ وَإِنَّا بِهِۦ كَٰفِرُونَ ٣٠Nígbà tí òdodo dé bá wọn, wọ́n wí pé: "Idán ni èyí; dájúdájú àwa kò sì níí gbà á gbọ́ وَقَالُواْ لَوۡلَا نُزِّلَ هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانُ عَلَىٰ رَجُلٍ مِّنَ ٱلۡقَرۡيَتَيۡنِ عَظِيمٍ ٣١Wọ́n tún wí pé: "Kí ni kò jẹ́ kí Wọ́n sọ al-Ƙur’ān yìí kalẹ̀ fún ọkùnrin pàtàkì kan nínú àwọn ìlú méjèèjì أَهُمۡ يَقۡسِمُونَ رَحۡمَتَ رَبِّكَۚ نَحۡنُ قَسَمۡنَا بَيۡنَهُم مَّعِيشَتَهُمۡ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۚ وَرَفَعۡنَا بَعۡضَهُمۡ فَوۡقَ بَعۡضٍ دَرَجَٰتٍ لِّيَتَّخِذَ بَعۡضُهُم بَعۡضًا سُخۡرِيًّاۗ وَرَحۡمَتُ رَبِّكَ خَيۡرٌ مِّمَّا يَجۡمَعُونَ ٣٢Ṣé àwọn ni wọn máa pín ìkẹ́ Olúwa rẹ ni? Àwa l’A pín n̄ǹkan ìṣẹ̀mí wọn fún wọn nínú ìgbésí ayé. A sì fi àwọn ipò gíga gbé apá kan wọn ga ju apá kan lọ nítorí kí apá kan wọn lè máa ṣiṣẹ́ fún apá kan. Ìkẹ́ Olúwa rẹ sì lóore jùlọ sí ohun tí wọ́n ń kó jọ وَلَوۡلَآ أَن يَكُونَ ٱلنَّاسُ أُمَّةً وَٰحِدَةً لَّجَعَلۡنَا لِمَن يَكۡفُرُ بِٱلرَّحۡمَٰنِ لِبُيُوتِهِمۡ سُقُفًا مِّن فِضَّةٍ وَمَعَارِجَ عَلَيۡهَا يَظۡهَرُونَ ٣٣Àti pé tí kì í bá ṣe pé àwọn ènìyàn máa jẹ́ ìjọ kan ṣoṣo (lórí àìgbàgbọ́ ni), A ìbá ṣe àwọn òrùlé àti àwọn àkàbà tí wọn yóò fi máa gùnkè nínú ilé ní fàdákà fún ẹni t’ó ń ṣàì gbàgbọ́ nínú Àjọkẹ́-ayé وَلِبُيُوتِهِمۡ أَبۡوَٰبًا وَسُرُرًا عَلَيۡهَا يَتَّكِـُٔونَ ٣٤(A ìbá tún ṣe) àwọn ẹnu ọ̀nà ilé wọn àti àwọn ibùsùn tí wọn yóò máa rọ̀gbọ̀kú lé lórí (ní fàdákà) وَزُخۡرُفًاۚ وَإِن كُلُّ ذَٰلِكَ لَمَّا مَتَٰعُ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۚ وَٱلۡأٓخِرَةُ عِندَ رَبِّكَ لِلۡمُتَّقِينَ ٣٥àti góòlù. Gbogbo n̄ǹkan wọ̀nyí kò jẹ́ n̄ǹkan kan bí kò ṣe ìgbádùn ìṣẹ̀mí ayé lásán. (Ọgbà Ìdẹ̀ra) Ọ̀run sì wà ní ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) وَمَن يَعۡشُ عَن ذِكۡرِ ٱلرَّحۡمَٰنِ نُقَيِّضۡ لَهُۥ شَيۡطَٰنًا فَهُوَ لَهُۥ قَرِينٌ ٣٦Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbúnrí kúrò níbi ìrántí Àjọké-ayé, A máa yan èṣù kan fún un. Òun sì ni alábàárìn rẹ̀ وَإِنَّهُمۡ لَيَصُدُّونَهُمۡ عَنِ ٱلسَّبِيلِ وَيَحۡسَبُونَ أَنَّهُم مُّهۡتَدُونَ ٣٧Dájúdájú àwọn èṣù náà yóò máa ṣẹ́rí wọn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn Allāhu). Wọn yó sì máa lérò pé dájúdájú àwọn ni olùmọ̀nà حَتَّىٰٓ إِذَا جَآءَنَا قَالَ يَٰلَيۡتَ بَيۡنِي وَبَيۡنَكَ بُعۡدَ ٱلۡمَشۡرِقَيۡنِ فَبِئۡسَ ٱلۡقَرِينُ ٣٨Títí di ìgbà tí ó fi máa wá bá Wa, ó sì máa wí pé: "Háà! Kí ó sì jẹ́ pé (ìtakété bí) ìtakété ibùyọ-òòrùn àti ibùwọ̀ rẹ̀ sì wà láààrin èmi àti ìwọ (èṣù alábàárìn yìí, ìbá dára); alábàárìn burúkú sì ni وَلَن يَنفَعَكُمُ ٱلۡيَوۡمَ إِذ ظَّلَمۡتُمۡ أَنَّكُمۡ فِي ٱلۡعَذَابِ مُشۡتَرِكُونَ ٣٩(Àbámọ̀ yín) kò níí ṣe yín ní àǹfààní ní Òní nígbà tí ẹ ti ṣàbòsí. (Àti pé) dájúdájú ẹ̀yin (àti òrìṣà yín) ni akẹ́gbẹ́ nínú ìyà أَفَأَنتَ تُسۡمِعُ ٱلصُّمَّ أَوۡ تَهۡدِي ٱلۡعُمۡيَ وَمَن كَانَ فِي ضَلَٰلٍ مُّبِينٍ ٤٠Ṣé ìwọ l’o máa fún àwọn adití ní ọ̀rọ̀ gbọ́ tàbí o máa fún àwọn afọ́jú ní ìmọ̀nà àti ẹni tí ó wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé فَإِمَّا نَذۡهَبَنَّ بِكَ فَإِنَّا مِنۡهُم مُّنتَقِمُونَ ٤١Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kí Á ti mú ọ kúrò (lórí ilẹ̀ ayé ṣíwájú àsìkò ìyà wọn), dájúdájú Àwa yóò gbẹ̀san (ìyà) lára wọn أَوۡ نُرِيَنَّكَ ٱلَّذِي وَعَدۡنَٰهُمۡ فَإِنَّا عَلَيۡهِم مُّقۡتَدِرُونَ ٤٢Tàbí kí Á fi ohun tí A ṣe ní ìlérí fún wọn hàn ọ́, dájúdájú Àwa jẹ́ Alágbára lórí wọn فَٱسۡتَمۡسِكۡ بِٱلَّذِيٓ أُوحِيَ إِلَيۡكَۖ إِنَّكَ عَلَىٰ صِرَٰطٍ مُّسۡتَقِيمٍ ٤٣Nítorí náà, di ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ mú ṣinṣin. Dájúdájú ìwọ wà lójú ọ̀nà tààrà (’Islām) وَإِنَّهُۥ لَذِكۡرٌ لَّكَ وَلِقَوۡمِكَۖ وَسَوۡفَ تُسۡـَٔلُونَ ٤٤Dájúdájú al-Ƙur’ān ni tírà ìrántí fún ìwọ àti ìjọ rẹ. Láìpẹ́ Wọ́n máa bi yín léèrè (nípa rẹ̀) وَسۡـَٔلۡ مَنۡ أَرۡسَلۡنَا مِن قَبۡلِكَ مِن رُّسُلِنَآ أَجَعَلۡنَا مِن دُونِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ءَالِهَةً يُعۡبَدُونَ ٤٥Bèèrè wò lọ́wọ́ àwọn tí A rán níṣẹ́ ṣíwájú rẹ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Wa (pé): "Ǹjẹ́ A sọ àwọn kan di ọlọ́hun tí wọn yóò máa jọ́sìn fún lẹ́yìn Àjọkẹ́-ayé bí وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا مُوسَىٰ بِـَٔايَٰتِنَآ إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ وَمَلَإِيْهِۦ فَقَالَ إِنِّي رَسُولُ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ ٤٦A kúkú fi àwọn àmì Wa rán (Ànábì) Mūsā níṣẹ́ sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Ó sì sọ pé: "Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ Olúwa gbogbo ẹ̀dá فَلَمَّا جَآءَهُم بِـَٔايَٰتِنَآ إِذَا هُم مِّنۡهَا يَضۡحَكُونَ ٤٧Ṣùgbọ́n nígbà tí ó mú àwọn àmì Wa wá bá wọn, ńṣe ni wọ́n ń fi àwọn àmì náà rẹ́rìn-ín nígbà náà وَمَا نُرِيهِم مِّنۡ ءَايَةٍ إِلَّا هِيَ أَكۡبَرُ مِنۡ أُخۡتِهَاۖ وَأَخَذۡنَٰهُم بِٱلۡعَذَابِ لَعَلَّهُمۡ يَرۡجِعُونَ ٤٨A ò sì níí fi àmì kan hàn wọ́n àyàfi kí ó tóbi ju irú rẹ̀ (t’ó ṣíwájú). A sì fi ìyà jẹ wọ́n nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo) وَقَالُواْ يَٰٓأَيُّهَ ٱلسَّاحِرُ ٱدۡعُ لَنَا رَبَّكَ بِمَا عَهِدَ عِندَكَ إِنَّنَا لَمُهۡتَدُونَ ٤٩Wọ́n sì wí pé: "Ìwọ òpìdán, pe Olúwa rẹ fún wa nítorí àdéhùn tí Ó ṣe pẹ̀lú rẹ. Dájúdájú àwa máa tẹ̀lé ìmọ̀nà Rẹ̀ فَلَمَّا كَشَفۡنَا عَنۡهُمُ ٱلۡعَذَابَ إِذَا هُمۡ يَنكُثُونَ ٥٠Ṣùgbọ́n nígbà tí A mú ìyà kúrò fún wọn, nígbà náà ni wọ́n tún ń yẹ àdéhùn وَنَادَىٰ فِرۡعَوۡنُ فِي قَوۡمِهِۦ قَالَ يَٰقَوۡمِ أَلَيۡسَ لِي مُلۡكُ مِصۡرَ وَهَٰذِهِ ٱلۡأَنۡهَٰرُ تَجۡرِي مِن تَحۡتِيٓۚ أَفَلَا تُبۡصِرُونَ ٥١Fir‘aon sì pèpè láààrin àwọn ènìyàn rẹ̀, ó wí pé: "Ẹ̀yin ènìyàn mi, ṣé tèmi kọ́ ni ìjọba Misrọ àti àwọn odò wọ̀nyí t’ó ń ṣàn nísàlẹ̀ (ọ̀dọ̀) mi? Ṣé ẹ ò ríran ni أَمۡ أَنَا۠ خَيۡرٌ مِّنۡ هَٰذَا ٱلَّذِي هُوَ مَهِينٌ وَلَا يَكَادُ يُبِينُ ٥٢Tàbí ṣé èmi kò lóore jùlọ sí èyí tí ó jẹ́ ọ̀lẹ yẹpẹrẹ, tí ó fẹ́ẹ̀ má lè dá ọ̀rọ̀ sọ yanjú فَلَوۡلَآ أُلۡقِيَ عَلَيۡهِ أَسۡوِرَةٌ مِّن ذَهَبٍ أَوۡ جَآءَ مَعَهُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ مُقۡتَرِنِينَ ٥٣Kí ni kò jẹ́ kí Wọ́n fún un ní àwọn ẹ̀gbà-ọwọ́ góòlù tàbí (kí ni kò jẹ́ kí) àwọn mọlāika wá pẹ̀lú rẹ̀, kí wọ́n jẹ́ alábàárìn (tí wọn yóò máa jẹ́rìí rẹ̀) فَٱسۡتَخَفَّ قَوۡمَهُۥ فَأَطَاعُوهُۚ إِنَّهُمۡ كَانُواْ قَوۡمًا فَٰسِقِينَ ٥٤Nítorí náà, ó sọ àwọn ènìyàn rẹ̀ dòpè. Wọ́n sì tẹ̀lé e. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́ فَلَمَّآ ءَاسَفُونَا ٱنتَقَمۡنَا مِنۡهُمۡ فَأَغۡرَقۡنَٰهُمۡ أَجۡمَعِينَ ٥٥Nígbà tí wọ́n wá ìbínú Wa, A gba ẹ̀san (ìyà) lára wọn. Nítorí náà, A tẹ gbogbo wọn rì (sínú agbami odò) فَجَعَلۡنَٰهُمۡ سَلَفًا وَمَثَلًا لِّلۡأٓخِرِينَ ٥٦A sì ṣe wọ́n ní ìjọ aṣíwájú (nínú ìparun) àti àpẹẹrẹ (fèyíkọ́gbọ́n) fún àwọn ẹni ìkẹ́yìn ۞ وَلَمَّا ضُرِبَ ٱبۡنُ مَرۡيَمَ مَثَلًا إِذَا قَوۡمُكَ مِنۡهُ يَصِدُّونَ ٥٧Nígbà tí àwọn ọ̀ṣẹbọ fi ọmọ Mọryam ṣe àpẹẹrẹ (fún òrìṣà wọn), nígbà náà ni àwọn ènìyàn rẹ bá ń fi (àpẹẹrẹ náà) rẹ́rìn-ín وَقَالُوٓاْ ءَأَٰلِهَتُنَا خَيۡرٌ أَمۡ هُوَۚ مَا ضَرَبُوهُ لَكَ إِلَّا جَدَلَۢاۚ بَلۡ هُمۡ قَوۡمٌ خَصِمُونَ ٥٨Wọ́n sì wí pé: "Ṣé àwọn òrìṣà wa l’ó lóore jùlọ ni tàbí òun? Wọn kò wulẹ̀ fi ṣàpẹẹrẹ fún ọ bí kò ṣe (fún) àtakò. Àní sẹ́, ìjọ oníyànjíjà ni wọ́n إِنۡ هُوَ إِلَّا عَبۡدٌ أَنۡعَمۡنَا عَلَيۡهِ وَجَعَلۡنَٰهُ مَثَلًا لِّبَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ ٥٩Kí ni òun bí kò ṣe ẹrúsìn kan tí A ṣe ìdẹ̀ra fún. A sì ṣe é ní àpẹẹrẹ rere fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl وَلَوۡ نَشَآءُ لَجَعَلۡنَا مِنكُم مَّلَٰٓئِكَةً فِي ٱلۡأَرۡضِ يَخۡلُفُونَ ٦٠Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́, A ìbá máa fi àwọn mọlāika rọ́pò yín lórí ilẹ̀ وَإِنَّهُۥ لَعِلۡمٌ لِّلسَّاعَةِ فَلَا تَمۡتَرُنَّ بِهَا وَٱتَّبِعُونِۚ هَٰذَا صِرَٰطٌ مُّسۡتَقِيمٌ ٦١Dájúdájú òun ni ìmọ̀ (tàbí àmì fún ìsúnmọ́) Àkókò náà. Nítorí náà, ẹ ò gbọdọ̀ ṣeyèméjì nípa rẹ̀. Kí ẹ sì tẹ̀lé mi. Èyí ni ọ̀nà tààrà وَلَا يَصُدَّنَّكُمُ ٱلشَّيۡطَٰنُۖ إِنَّهُۥ لَكُمۡ عَدُوٌّ مُّبِينٌ ٦٢Ẹ má ṣe jẹ́ kí Èṣù ṣẹ yín lórí; dájúdájú òun ni ọ̀tá pọ́nńbélé fun yín وَلَمَّا جَآءَ عِيسَىٰ بِٱلۡبَيِّنَٰتِ قَالَ قَدۡ جِئۡتُكُم بِٱلۡحِكۡمَةِ وَلِأُبَيِّنَ لَكُم بَعۡضَ ٱلَّذِي تَخۡتَلِفُونَ فِيهِۖ فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ ٦٣Nígbà tí (Ànábì) ‘Īsā dé pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú, ó sọ pé: "Dájúdájú mo dé wá ba yín pẹ̀lú ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n. (Mo sì dé) nítorí kí n̄g lè ṣe àlàyé apá kan èyí tí ẹ̀ ń yapa ẹnu nípa rẹ̀ fun yín. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi إِنَّ ٱللَّهَ هُوَ رَبِّي وَرَبُّكُمۡ فَٱعۡبُدُوهُۚ هَٰذَا صِرَٰطٌ مُّسۡتَقِيمٌ ٦٤Dájúdájú Allāhu ni Olúwa mi àti Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Èyí ni ọ̀nà tààrà فَٱخۡتَلَفَ ٱلۡأَحۡزَابُ مِنۢ بَيۡنِهِمۡۖ فَوَيۡلٌ لِّلَّذِينَ ظَلَمُواْ مِنۡ عَذَابِ يَوۡمٍ أَلِيمٍ ٦٥Àwọn ìjọ (rẹ̀) sì yapa (ẹ̀sìn ’Islām) láààrin ara wọn. Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn t’ó ṣàbòsí ní ọjọ́ ìyà ẹlẹ́ta-eléro هَلۡ يَنظُرُونَ إِلَّا ٱلسَّاعَةَ أَن تَأۡتِيَهُم بَغۡتَةً وَهُمۡ لَا يَشۡعُرُونَ ٦٦Ṣé wọ́n ń retí kiní kan bí kò ṣe Àkókò náà; tí ó máa dé bá wọn ní òjijì; wọn kò sì níí fura ٱلۡأَخِلَّآءُ يَوۡمَئِذِۭ بَعۡضُهُمۡ لِبَعۡضٍ عَدُوٌّ إِلَّا ٱلۡمُتَّقِينَ ٦٧Àwọn ọ̀rẹ́ àyò ní ọjọ́ yẹn, apá kan wọn yóò jẹ́ ọ̀tá fún apá kan àyàfi àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) يَٰعِبَادِ لَا خَوۡفٌ عَلَيۡكُمُ ٱلۡيَوۡمَ وَلَآ أَنتُمۡ تَحۡزَنُونَ ٦٨Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi, kò sí ìbẹ̀rù fun yín ní òní. Ẹ̀yin kò sì níí banújẹ́ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ بِـَٔايَٰتِنَا وَكَانُواْ مُسۡلِمِينَ ٦٩(Àwọn ni) àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, tí wọ́n sì jẹ́ mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀ sílẹ̀ fún Allāhu) ٱدۡخُلُواْ ٱلۡجَنَّةَ أَنتُمۡ وَأَزۡوَٰجُكُمۡ تُحۡبَرُونَ ٧٠Ẹ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, ẹ̀yin àti àwọn ìyàwó yín; kí ẹ máa dunnú يُطَافُ عَلَيۡهِم بِصِحَافٍ مِّن ذَهَبٍ وَأَكۡوَابٍۖ وَفِيهَا مَا تَشۡتَهِيهِ ٱلۡأَنفُسُ وَتَلَذُّ ٱلۡأَعۡيُنُۖ وَأَنتُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ ٧١Wọn yóò máa gbé àwọn àwo góòlù àti àwọn ife ìmumi káà kiri ọ̀dọ̀ wọn. Ohun tí ẹ̀mí ń fẹ́ àti (ohun tí) ojú yóò máa dúnnú sí wà nínú rẹ̀. Olùṣegbére sì ni yín nínú rẹ̀ وَتِلۡكَ ٱلۡجَنَّةُ ٱلَّتِيٓ أُورِثۡتُمُوهَا بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ ٧٢Ìyẹn ni Ọgbà Ìdẹ̀ra tí A jogún rẹ̀ fun yín nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ لَكُمۡ فِيهَا فَٰكِهَةٌ كَثِيرَةٌ مِّنۡهَا تَأۡكُلُونَ ٧٣Èso púpọ̀ wà fun yín nínú rẹ̀. Ẹ̀yin yó sì máa jẹ nínú rẹ̀ إِنَّ ٱلۡمُجۡرِمِينَ فِي عَذَابِ جَهَنَّمَ خَٰلِدُونَ ٧٤Dájúdájú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni olùṣegbére nínú ìyà iná Jahanamọ لَا يُفَتَّرُ عَنۡهُمۡ وَهُمۡ فِيهِ مُبۡلِسُونَ ٧٥A ò níí gbé e fúyẹ́ fún wọn. Wọn yó sì sọ̀rètí nù nínú Iná وَمَا ظَلَمۡنَٰهُمۡ وَلَٰكِن كَانُواْ هُمُ ٱلظَّٰلِمِينَ ٧٦A ò ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n àwọn ni wọ́n jẹ́ alábòsí وَنَادَوۡاْ يَٰمَٰلِكُ لِيَقۡضِ عَلَيۡنَا رَبُّكَۖ قَالَ إِنَّكُم مَّٰكِثُونَ ٧٧Wọn yóò pe (mọlāika kan) pé: "Mọ̄lik (ẹ̀ṣọ́ Iná), jẹ́ kí Olúwa rẹ pa wá ráúráú." (Mọ̄lik) yóò sọ pé: "Dájúdájú ẹ̀yin yóò máa gbé inú rẹ̀ ni لَقَدۡ جِئۡنَٰكُم بِٱلۡحَقِّ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَكُمۡ لِلۡحَقِّ كَٰرِهُونَ ٧٨Dájúdájú A ti mú òdodo wá ba yín, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ yin kórira òdodo أَمۡ أَبۡرَمُوٓاْ أَمۡرًا فَإِنَّا مُبۡرِمُونَ ٧٩Tàbí àwọn (aláìgbàgbọ́) ti pinnu ọ̀rọ̀ kan ni? Dájúdájú Àwa náà ń pinnu ọ̀rọ̀ أَمۡ يَحۡسَبُونَ أَنَّا لَا نَسۡمَعُ سِرَّهُمۡ وَنَجۡوَىٰهُمۚ بَلَىٰ وَرُسُلُنَا لَدَيۡهِمۡ يَكۡتُبُونَ ٨٠Tàbí wọ́n ń lérò pé Àwa kò gbọ́ ọ̀rọ̀ àṣírí wọn àti ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ wọn? Rárá (À ń gbọ́); àwọn Òjíṣẹ́ Wa wà ní ọ̀dọ̀ wọn, tí wọ́n ń ṣe àkọsílẹ̀ (ọ̀rọ̀ wọn) قُلۡ إِن كَانَ لِلرَّحۡمَٰنِ وَلَدٌ فَأَنَا۠ أَوَّلُ ٱلۡعَٰبِدِينَ ٨١Sọ pé: "Kò sí ọmọ kan fún Àjọké ayé. Nítorí náà, èmi ni ẹni àkọ́kọ́ nínú àwọn olùjọ́sìn (fún Allāhu ní àsìkò tèmi) سُبۡحَٰنَ رَبِّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ رَبِّ ٱلۡعَرۡشِ عَمَّا يَصِفُونَ ٨٢Mímọ́ ni fún Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, Olúwa Ìtẹ́-ọlá tayọ irọ́ tí wọ́n ń pa (mọ́ Ọn) فَذَرۡهُمۡ يَخُوضُواْ وَيَلۡعَبُواْ حَتَّىٰ يُلَٰقُواْ يَوۡمَهُمُ ٱلَّذِي يُوعَدُونَ ٨٣Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa sọ ìsọkúsọ (wọn), kí wọ́n sì máa ṣeré wọn lọ títí wọn yóò fi pàdé ọjọ́ wọn, tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn وَهُوَ ٱلَّذِي فِي ٱلسَّمَآءِ إِلَٰهٌ وَفِي ٱلۡأَرۡضِ إِلَٰهٌۚ وَهُوَ ٱلۡحَكِيمُ ٱلۡعَلِيمُ ٨٤(Allāhu) Òun ni Ọlọ́hun Ẹni tí ìjọ́sìn tọ́ sí nínú sánmọ̀. Òun náà sì ni Ọlọ́hun Ẹni tí ìjọ́sìn tọ́ sí lórí ilẹ̀. Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀ وَتَبَارَكَ ٱلَّذِي لَهُۥ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَيۡنَهُمَا وَعِندَهُۥ عِلۡمُ ٱلسَّاعَةِ وَإِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ ٨٥Ìbùkún ni fún Ẹni tí Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun t’ó wà láààrin méjèèjì. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni ìmọ̀ Àkókò náà wà. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọ́n máa da yín padà sí وَلَا يَمۡلِكُ ٱلَّذِينَ يَدۡعُونَ مِن دُونِهِ ٱلشَّفَٰعَةَ إِلَّا مَن شَهِدَ بِٱلۡحَقِّ وَهُمۡ يَعۡلَمُونَ ٨٦Àwọn tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò kápá ìṣìpẹ̀ àyàfi ẹni tí ó bá jẹ́rìí sí òdodo (kalmọtuṣ-ṣahaadah), tí wọ́n sì nímọ̀ (rẹ̀) وَلَئِن سَأَلۡتَهُم مَّنۡ خَلَقَهُمۡ لَيَقُولُنَّ ٱللَّهُۖ فَأَنَّىٰ يُؤۡفَكُونَ ٨٧Àti pé tí o bá bi wọ́n léèrè pé: "Ta ni Ó dá wọn?", dájúdájú wọn á wí pé: "Allāhu ni." Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo وَقِيلِهِۦ يَٰرَبِّ إِنَّ هَٰٓؤُلَآءِ قَوۡمٌ لَّا يُؤۡمِنُونَ ٨٨Ọ̀rọ̀ (tí Ànábì ń sọ fún Allāhu ni pé): "Olúwa Mi, dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni ìjọ tí kò gbàgbọ́.” فَٱصۡفَحۡ عَنۡهُمۡ وَقُلۡ سَلَٰمٌۚ فَسَوۡفَ يَعۡلَمُونَ ٨٩Nítorí náà, ṣàmójú kúrò fún wọn, kí ó sì sọ pé: "Àlàáfíà!" Láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀

الترجمة: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.