ملة الإسلام

السورة 40 · 85 آية · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

سورة غافر باللغة اليوروبا

السورة بالعربية مع التفسير استمع إلى سورة غافر (1,259 قارئاً)
مكيةسورة غافر٨٥ آية

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

حمٓ ١Hā mīm تَنزِيلُ ٱلۡكِتَٰبِ مِنَ ٱللَّهِ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡعَلِيمِ ٢Tírà náà sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Allāhu, Alágbára, Onímọ̀ غَافِرِ ٱلذَّنۢبِ وَقَابِلِ ٱلتَّوۡبِ شَدِيدِ ٱلۡعِقَابِ ذِي ٱلطَّوۡلِۖ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ إِلَيۡهِ ٱلۡمَصِيرُ ٣Aláforíjìn-ẹ̀ṣẹ̀, Olùgba-ìronúpìwàdà, Ẹni líle níbi ìyà, Ọlọ́rẹ, kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni àbọ̀ ẹ̀dá مَا يُجَٰدِلُ فِيٓ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ إِلَّا ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ فَلَا يَغۡرُرۡكَ تَقَلُّبُهُمۡ فِي ٱلۡبِلَٰدِ ٤Kò sí ẹni tí ó máa ṣe àtakò sí àwọn āyah Allāhu àfi àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí ìgbòkègbodò wọn nínú ìlú kó ẹ̀tàn bá ọ كَذَّبَتۡ قَبۡلَهُمۡ قَوۡمُ نُوحٍ وَٱلۡأَحۡزَابُ مِنۢ بَعۡدِهِمۡۖ وَهَمَّتۡ كُلُّ أُمَّةِۭ بِرَسُولِهِمۡ لِيَأۡخُذُوهُۖ وَجَٰدَلُواْ بِٱلۡبَٰطِلِ لِيُدۡحِضُواْ بِهِ ٱلۡحَقَّ فَأَخَذۡتُهُمۡۖ فَكَيۡفَ كَانَ عِقَابِ ٥Ìjọ (Ànábì) Nūh pe òdodo nírọ́ ṣíwájú wọn. Àwọn ìjọ (mìíràn) lẹ́yìn wọn (náà ṣe bẹ́ẹ̀). Ìjọ kọ̀ọ̀kan ló gbèrò láti ki Òjíṣẹ́ wọn mọ́lẹ̀. Wọ́n fi irọ́ ja òdodo níyàn nítorí kí wọ́n lè fi wó òdodo lulẹ̀. Mo sì gbá wọn mú. Nítorí náà, báwo ni ìyà (tí mo fi jẹ wọ́n) ti rí (lára wọn ná) وَكَذَٰلِكَ حَقَّتۡ كَلِمَتُ رَبِّكَ عَلَى ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ أَنَّهُمۡ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِ ٦Àti pé báyẹn ni ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ ṣe kò lórí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ pé: "Dájúdájú àwọn ni èrò inú Iná ٱلَّذِينَ يَحۡمِلُونَ ٱلۡعَرۡشَ وَمَنۡ حَوۡلَهُۥ يُسَبِّحُونَ بِحَمۡدِ رَبِّهِمۡ وَيُؤۡمِنُونَ بِهِۦ وَيَسۡتَغۡفِرُونَ لِلَّذِينَ ءَامَنُواْۖ رَبَّنَا وَسِعۡتَ كُلَّ شَيۡءٍ رَّحۡمَةً وَعِلۡمًا فَٱغۡفِرۡ لِلَّذِينَ تَابُواْ وَٱتَّبَعُواْ سَبِيلَكَ وَقِهِمۡ عَذَابَ ٱلۡجَحِيمِ ٧Àwọn t’ó gbé Ìtẹ́-ọlá náà rù àti àwọn t’ó wà ní àyíká rẹ̀, wọ́n ń ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa wọn. Wọ́n gba Allāhu gbọ́. Wọ́n sì ń tọrọ àforíjìn fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo (báyìí pé): "Olúwa wa, ìkẹ́ àti ìmọ̀ (Rẹ) gbòòrò ju gbogbo n̄ǹkan lọ, nítorí náà, ṣàforíjìn fún àwọn t’ó ronú pìwàdà, tí wọ́n sì tẹ̀lé ojú-ọ̀nà Rẹ. Kí O sì ṣọ́ wọn nínú ìyà iná Jẹhīm رَبَّنَا وَأَدۡخِلۡهُمۡ جَنَّٰتِ عَدۡنٍ ٱلَّتِي وَعَدتَّهُمۡ وَمَن صَلَحَ مِنۡ ءَابَآئِهِمۡ وَأَزۡوَٰجِهِمۡ وَذُرِّيَّٰتِهِمۡۚ إِنَّكَ أَنتَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ ٨Olúwa wa, fi wọ́n sínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra tí Ó ṣe ní àdéhùn fún àwọn àti ẹni t’ó ṣe iṣẹ́ rere nínú àwọn bàbá wọn, àwọn aya wọn àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn. Dájúdájú Ìwọ ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n وَقِهِمُ ٱلسَّيِّـَٔاتِۚ وَمَن تَقِ ٱلسَّيِّـَٔاتِ يَوۡمَئِذٍ فَقَدۡ رَحِمۡتَهُۥۚ وَذَٰلِكَ هُوَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡعَظِيمُ ٩Ṣọ́ wọn nínú àwọn aburú. Ẹnikẹ́ni tí O bá ṣọ́ níbi àwọn aburú (ìyà) ní ọjọ́ yẹn, dájúdájú O ti kẹ́ ẹ. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ يُنَادَوۡنَ لَمَقۡتُ ٱللَّهِ أَكۡبَرُ مِن مَّقۡتِكُمۡ أَنفُسَكُمۡ إِذۡ تُدۡعَوۡنَ إِلَى ٱلۡإِيمَٰنِ فَتَكۡفُرُونَ ١٠Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, wọn yóò pè wọ́n (láti sọ fún wọn nínú Iná pé): " Dájúdájú ìbínú ti Allāhu tóbi ju ìbínú tí ẹ̀ ń bí síra yín (nínú Iná, ṣebí) nígbà tí wọ́n ń pè yín síbi ìgbàgbọ́ òdodo, ńṣe ni ẹ̀ ń ṣàì gbàgbọ́ قَالُواْ رَبَّنَآ أَمَتَّنَا ٱثۡنَتَيۡنِ وَأَحۡيَيۡتَنَا ٱثۡنَتَيۡنِ فَٱعۡتَرَفۡنَا بِذُنُوبِنَا فَهَلۡ إِلَىٰ خُرُوجٍ مِّن سَبِيلٍ ١١Wọ́n wí pé: "Olúwa wa, O pa wá ní ẹ̀ẹ̀ méjì. O sì ji wá ní ẹ̀ẹ̀ méjì. Nítorí náà, a sì jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ǹjẹ́ ọ̀nà kan wà láti jáde (padà sí ilé ayé) bí ذَٰلِكُم بِأَنَّهُۥٓ إِذَا دُعِيَ ٱللَّهُ وَحۡدَهُۥ كَفَرۡتُمۡ وَإِن يُشۡرَكۡ بِهِۦ تُؤۡمِنُواْۚ فَٱلۡحُكۡمُ لِلَّهِ ٱلۡعَلِيِّ ٱلۡكَبِيرِ ١٢(Ẹ wà nínú Iná) yẹn nítorí pé dájúdájú nígbà tí wọ́n bá pe Allāhu nìkan ṣoṣo, ẹ̀yin ṣàì gbàgbọ́. Nígbà tí wọ́n bá ṣẹbọ sí I, ẹ sì máa gbàgbọ́ (nínú ẹbọ). Nítorí náà, ìdájọ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Ó ga, Ó tóbi هُوَ ٱلَّذِي يُرِيكُمۡ ءَايَٰتِهِۦ وَيُنَزِّلُ لَكُم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ رِزۡقًاۚ وَمَا يَتَذَكَّرُ إِلَّا مَن يُنِيبُ ١٣Òun ni Ẹni t’Ó ń fi àwọn àmì Rẹ̀ hàn yín. Ó sì ń sọ arísìkí kalẹ̀ fun yín láti sánmọ̀. Kò sí ẹni t’ó ń lo ìrántí àfi ẹni t’ó ń ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípasẹ̀ ìronúpìwàdà) فَٱدۡعُواْ ٱللَّهَ مُخۡلِصِينَ لَهُ ٱلدِّينَ وَلَوۡ كَرِهَ ٱلۡكَٰفِرُونَ ١٤Nítorí náà, ẹ pe Allāhu ní ti olùṣàfọ̀mọ́-ẹ̀sìn fún Un, àwọn aláìgbàgbọ́ ìbáà kórira Rẹ̀ رَفِيعُ ٱلدَّرَجَٰتِ ذُو ٱلۡعَرۡشِ يُلۡقِي ٱلرُّوحَ مِنۡ أَمۡرِهِۦ عَلَىٰ مَن يَشَآءُ مِنۡ عِبَادِهِۦ لِيُنذِرَ يَوۡمَ ٱلتَّلَاقِ ١٥(Allāhu) Ẹni t’Ó ni gbogbo ipò àjùlọ, Olúwa Ìtẹ́-ọlá, Ó ń fi ìmísí (al-Ƙur’ān) ránṣẹ́ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀ sí ẹni tí Ó fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ nítorì kí ó lè fi ṣèkìlọ̀ nípa Ọjọ́ ìpàdé náà يَوۡمَ هُم بَٰرِزُونَۖ لَا يَخۡفَىٰ عَلَى ٱللَّهِ مِنۡهُمۡ شَيۡءٌۚ لِّمَنِ ٱلۡمُلۡكُ ٱلۡيَوۡمَۖ لِلَّهِ ٱلۡوَٰحِدِ ٱلۡقَهَّارِ ١٦Ní ọjọ́ tí wọn yóò yọ jáde (láti inú sàréè), kiní kan kò sì níí pamọ́ nípa wọn fún Allāhu. (Allāhu yó sì sọ pé): "Ti ta ni ìjọba ní ọjọ́ òní? Ti Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí ni ٱلۡيَوۡمَ تُجۡزَىٰ كُلُّ نَفۡسِۭ بِمَا كَسَبَتۡۚ لَا ظُلۡمَ ٱلۡيَوۡمَۚ إِنَّ ٱللَّهَ سَرِيعُ ٱلۡحِسَابِ ١٧Ní òní ni A óò san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́. Kò sì sí àbòsí kan ní òní. Dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́ وَأَنذِرۡهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡأٓزِفَةِ إِذِ ٱلۡقُلُوبُ لَدَى ٱلۡحَنَاجِرِ كَٰظِمِينَۚ مَا لِلظَّٰلِمِينَ مِنۡ حَمِيمٍ وَلَا شَفِيعٍ يُطَاعُ ١٨Àti pé ṣèkìlọ̀ ọjọ́ tí ó súnmọ́ fún wọn. Nígbà tí àwọn ọkàn bá ga dé gògòńgò, tí ó máa kún fún ìbànújẹ́, kò níí sí ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ àti olùṣìpẹ̀ kan tí wọ́n máa tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ̀ lórí (ọ̀rọ̀) àwọn alábòsí يَعۡلَمُ خَآئِنَةَ ٱلۡأَعۡيُنِ وَمَا تُخۡفِي ٱلصُّدُورُ ١٩(Allāhu) mọ ojú ìjàǹbá àti ohun tí àwọn ọkàn fi pamọ́ وَٱللَّهُ يَقۡضِي بِٱلۡحَقِّۖ وَٱلَّذِينَ يَدۡعُونَ مِن دُونِهِۦ لَا يَقۡضُونَ بِشَيۡءٍۗ إِنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡبَصِيرُ ٢٠Àti pé Allāhu l’Ó máa fi òdodo dájọ́. Àwọn tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò lè ṣe ìdájọ́ kan kan. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Olùríran ۞ أَوَلَمۡ يَسِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَيَنظُرُواْ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلَّذِينَ كَانُواْ مِن قَبۡلِهِمۡۚ كَانُواْ هُمۡ أَشَدَّ مِنۡهُمۡ قُوَّةً وَءَاثَارًا فِي ٱلۡأَرۡضِ فَأَخَذَهُمُ ٱللَّهُ بِذُنُوبِهِمۡ وَمَا كَانَ لَهُم مِّنَ ٱللَّهِ مِن وَاقٍ ٢١Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn t’ó ṣíwájú wọn ṣe rí? Wọ́n ní agbára jù wọ́n lọ. Wọ́n sì lo ilẹ̀ (fún oko dídá jù wọ́n lọ). Síbẹ̀síbẹ̀ Allāhu mú wọn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Kò sì sí olùṣọ́ kan fún wọn (níbi ìyà) Allāhu ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ كَانَت تَّأۡتِيهِمۡ رُسُلُهُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِ فَكَفَرُواْ فَأَخَذَهُمُ ٱللَّهُۚ إِنَّهُۥ قَوِيٌّ شَدِيدُ ٱلۡعِقَابِ ٢٢Ìyẹn nítorí pé àwọn Òjíṣẹ́ wọn ń wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú, ṣùgbọ́n wọ́n ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, Allāhu mú wọn. Dájúdájú Òun ni Alágbára, Ẹni líle níbi ìyà وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا مُوسَىٰ بِـَٔايَٰتِنَا وَسُلۡطَٰنٍ مُّبِينٍ ٢٣Dájúdájú A fi àwọn àmì Wa àti ẹ̀rí t’ó yanjú rán (Ànábì) Mūsā níṣẹ́ إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ وَهَٰمَٰنَ وَقَٰرُونَ فَقَالُواْ سَٰحِرٌ كَذَّابٌ ٢٤sí Fir‘aon, Hāmọ̄n àti Ƙọ̄rūn. Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé: "Òpìdán, òpùrọ́ ni (Ànábì Mūsā) فَلَمَّا جَآءَهُم بِٱلۡحَقِّ مِنۡ عِندِنَا قَالُواْ ٱقۡتُلُوٓاْ أَبۡنَآءَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مَعَهُۥ وَٱسۡتَحۡيُواْ نِسَآءَهُمۡۚ وَمَا كَيۡدُ ٱلۡكَٰفِرِينَ إِلَّا فِي ضَلَٰلٍ ٢٥Nígbà tí ó mú òdodo náà dé ọ̀dọ̀ wọn láti ọ̀dọ̀ Wa, wọ́n wí pé: "Ẹ pa àwọn ọmọkùnrin àwọn t’ó gbàgbọ́ pẹ̀lú rẹ̀, kí ẹ sì fi àwọn ọmọbìnrin wọn sílẹ̀." Ète àwọn aláìgbàgbọ́ kò sí nínú kiní kan bí kò ṣe nínú òfò وَقَالَ فِرۡعَوۡنُ ذَرُونِيٓ أَقۡتُلۡ مُوسَىٰ وَلۡيَدۡعُ رَبَّهُۥٓۖ إِنِّيٓ أَخَافُ أَن يُبَدِّلَ دِينَكُمۡ أَوۡ أَن يُظۡهِرَ فِي ٱلۡأَرۡضِ ٱلۡفَسَادَ ٢٦Fir‘aon wí pé: "Ẹ fi mí sílẹ̀ kí n̄g pa Mūsā, kí ó sì pe Olúwa rẹ̀ (wò bóyá Ó máa gbà á sílẹ̀). Dájúdájú èmi ń bẹ̀rù pé ó máa yí ẹ̀sìn yín padà tàbí pé ó máa ṣàfi hàn ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀ وَقَالَ مُوسَىٰٓ إِنِّي عُذۡتُ بِرَبِّي وَرَبِّكُم مِّن كُلِّ مُتَكَبِّرٍ لَّا يُؤۡمِنُ بِيَوۡمِ ٱلۡحِسَابِ ٢٧(Ànábì) Mūsā sọ pé: "Dájúdájú èmi sá di Olúwa mi àti Olúwa yín kúrò lọ́wọ́ gbogbo onígbèéraga, tí kò gba Ọjọ́ ìṣírò-iṣẹ́ gbọ́ وَقَالَ رَجُلٌ مُّؤۡمِنٌ مِّنۡ ءَالِ فِرۡعَوۡنَ يَكۡتُمُ إِيمَٰنَهُۥٓ أَتَقۡتُلُونَ رَجُلًا أَن يَقُولَ رَبِّيَ ٱللَّهُ وَقَدۡ جَآءَكُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِ مِن رَّبِّكُمۡۖ وَإِن يَكُ كَٰذِبًا فَعَلَيۡهِ كَذِبُهُۥۖ وَإِن يَكُ صَادِقًا يُصِبۡكُم بَعۡضُ ٱلَّذِي يَعِدُكُمۡۖ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي مَنۡ هُوَ مُسۡرِفٌ كَذَّابٌ ٢٨Ọkùnrin onígbàgbọ́ òdodo kan t’ó ń fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ pamọ́ nínú àwọn ènìyàn Fir‘aon sọ pé: "Ṣé ẹ máa pa ọkùnrin kan nítorí pé ó ń sọ pé, ‘Allāhu ni Olúwa mi.’ Ó sì kúkú ti mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Tí ó bá jẹ́ òpùrọ́, (ìyà) irọ́ rẹ̀ wà lórí rẹ̀. Tí ó bá sì jẹ́ olódodo, apá kan èyí tí ó ṣe ní ìlérí fun yín yó sì kò le yín lórí. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó jẹ́ aláṣejù, òpùrọ́ يَٰقَوۡمِ لَكُمُ ٱلۡمُلۡكُ ٱلۡيَوۡمَ ظَٰهِرِينَ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَمَن يَنصُرُنَا مِنۢ بَأۡسِ ٱللَّهِ إِن جَآءَنَاۚ قَالَ فِرۡعَوۡنُ مَآ أُرِيكُمۡ إِلَّا مَآ أَرَىٰ وَمَآ أَهۡدِيكُمۡ إِلَّا سَبِيلَ ٱلرَّشَادِ ٢٩Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ̀yin l’ẹ ni ìjọba lónìí, ẹ̀yin sì ni alásẹ lórí ilẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n ta ni ó máa ràn wá lọ́wọ́ tí ìyà Allāhu bá dé bá wa?" Fir‘aon wí pé: "Èmi kò fi n̄ǹkan kan hàn yín bí kò ṣe ohun tí mo rí (nínú òye mi). Èmi kò sì tọ yín sí ọ̀nà kan bí kò ṣe ojú ọ̀nà ìmọ̀nà وَقَالَ ٱلَّذِيٓ ءَامَنَ يَٰقَوۡمِ إِنِّيٓ أَخَافُ عَلَيۡكُم مِّثۡلَ يَوۡمِ ٱلۡأَحۡزَابِ ٣٠Ẹni t’ó gbàgbọ́ ní òdodo tún sọ pé: "Ẹ̀yin ènìyàn mi, dájúdájú irú ọjọ́ (ẹ̀san ìyà t’ó ṣẹlẹ̀ sí) àwọn ọmọ-ogun oníjọ ni èmi ń páyà lórí yín مِثۡلَ دَأۡبِ قَوۡمِ نُوحٍ وَعَادٍ وَثَمُودَ وَٱلَّذِينَ مِنۢ بَعۡدِهِمۡۚ وَمَا ٱللَّهُ يُرِيدُ ظُلۡمًا لِّلۡعِبَادِ ٣١Irú ìṣe (ìparun t’ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn) ènìyàn Nūh, ‘Ād, Thamūd àti àwọn t’ó tẹ̀lé wọn. Allāhu kò sì gbèrò àbòsí sí àwọn ẹrúsìn náà وَيَٰقَوۡمِ إِنِّيٓ أَخَافُ عَلَيۡكُمۡ يَوۡمَ ٱلتَّنَادِ ٣٢Ẹ̀yin ènìyàn mi, dájúdájú èmi ń páyà Ọjọ́ ìpè fun yín يَوۡمَ تُوَلُّونَ مُدۡبِرِينَ مَا لَكُم مِّنَ ٱللَّهِ مِنۡ عَاصِمٍۗ وَمَن يُضۡلِلِ ٱللَّهُ فَمَا لَهُۥ مِنۡ هَادٍ ٣٣Ọjọ́ tí ẹ máa pẹ̀yìndà láti sá lọ; kò sì níí sí aláàbò kan fun yín lọ́dọ̀ Allāhu. Àti pé ẹni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò lè sí afinimọ̀nà kan fún un وَلَقَدۡ جَآءَكُمۡ يُوسُفُ مِن قَبۡلُ بِٱلۡبَيِّنَٰتِ فَمَا زِلۡتُمۡ فِي شَكٍّ مِّمَّا جَآءَكُم بِهِۦۖ حَتَّىٰٓ إِذَا هَلَكَ قُلۡتُمۡ لَن يَبۡعَثَ ٱللَّهُ مِنۢ بَعۡدِهِۦ رَسُولًاۚ كَذَٰلِكَ يُضِلُّ ٱللَّهُ مَنۡ هُوَ مُسۡرِفٌ مُّرۡتَابٌ ٣٤Àti pé dájúdájú (Ànábì) Yūsuf ti tọ̀ yín wá ṣíwájú pẹ̀lú àwọn àlàyé ọ̀rọ̀ t’ó yanjú, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò yé wà nínú iyèméjì nípa ohun tí ó mú wá ba yín títí di ìgbà tí ó fi kú, tí ẹ fi wí pé: "Allāhu kò níí gbé Òjíṣẹ́ kan dìde mọ́ lẹ́yìn rẹ̀." Báyẹn ni Allāhu ṣe ń sọ ẹni tí ó jẹ́ aláṣejù, oníyèméjì nù ٱلَّذِينَ يُجَٰدِلُونَ فِيٓ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ بِغَيۡرِ سُلۡطَٰنٍ أَتَىٰهُمۡۖ كَبُرَ مَقۡتًا عِندَ ٱللَّهِ وَعِندَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْۚ كَذَٰلِكَ يَطۡبَعُ ٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ قَلۡبِ مُتَكَبِّرٍ جَبَّارٍ ٣٥Àwọn t’ó ń jiyàn nípa àwọn āyah Allāhu láìsí ẹ̀rí kan tí ó dé bá wọn. Ẹ̀ṣẹ̀ ńlá sì ni ní ọ̀dọ̀ Allāhu àti ní ọ̀dọ̀ àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń fi èdídí bo gbogbo ọkàn onígbèéraga, ajẹninípá.” وَقَالَ فِرۡعَوۡنُ يَٰهَٰمَٰنُ ٱبۡنِ لِي صَرۡحًا لَّعَلِّيٓ أَبۡلُغُ ٱلۡأَسۡبَٰبَ ٣٦Fir‘aon wí pé: "Hāmọ̄n, mọ ilé gíga fíofío kan fún mi nítorí kí èmi lè dé àwọn ojú ọ̀nà náà أَسۡبَٰبَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ فَأَطَّلِعَ إِلَىٰٓ إِلَٰهِ مُوسَىٰ وَإِنِّي لَأَظُنُّهُۥ كَٰذِبًاۚ وَكَذَٰلِكَ زُيِّنَ لِفِرۡعَوۡنَ سُوٓءُ عَمَلِهِۦ وَصُدَّ عَنِ ٱلسَّبِيلِۚ وَمَا كَيۡدُ فِرۡعَوۡنَ إِلَّا فِي تَبَابٍ ٣٧Àwọn ojú ọ̀nà (inú) sánmọ̀ ni, nítorí kí èmi lè yọjú wo Ọlọ́hun Mūsā nítorí pé dájúdájú èmi ń rò ó sí òpùrọ́." Báyẹn ni wọ́n ṣe iṣẹ́ aburú (ọwọ́) Fir‘aon ní ọ̀ṣọ́ fún un. Wọ́n sì ṣẹ́rí rẹ̀ kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn Allāhu). Ète Fir‘aon kò sì wà nínú kiní kan bí kò ṣe nínú òfò وَقَالَ ٱلَّذِيٓ ءَامَنَ يَٰقَوۡمِ ٱتَّبِعُونِ أَهۡدِكُمۡ سَبِيلَ ٱلرَّشَادِ ٣٨Ẹni t’ó gbàgbọ́ ní òdodo tún sọ pé: "Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ tẹ̀lé mi, mo máa júwe yín sí ojú ọ̀nà ìmọ̀nà يَٰقَوۡمِ إِنَّمَا هَٰذِهِ ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَا مَتَٰعٌ وَإِنَّ ٱلۡأٓخِرَةَ هِيَ دَارُ ٱلۡقَرَارِ ٣٩Ẹ̀yin ènìyàn mi, ìṣẹ̀mí ilé ayé yìí jẹ́ ìgbádùn lásán. Dájúdájú ọ̀run sì ni ilé gbére مَنۡ عَمِلَ سَيِّئَةً فَلَا يُجۡزَىٰٓ إِلَّا مِثۡلَهَاۖ وَمَنۡ عَمِلَ صَٰلِحًا مِّن ذَكَرٍ أَوۡ أُنثَىٰ وَهُوَ مُؤۡمِنٌ فَأُوْلَٰٓئِكَ يَدۡخُلُونَ ٱلۡجَنَّةَ يُرۡزَقُونَ فِيهَا بِغَيۡرِ حِسَابٍ ٤٠Ẹni tí ó bá ṣe aburú kan, Wọn kò níí san án ní ẹ̀san kan àyàfi irú rẹ̀. Ẹni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ rere ní ọkùnrin tàbí ní obìnrin, tí ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Wọn yóò máa pèsè àrísìkí fún wọn nínú rẹ̀ láì la ìṣírò lọ ۞ وَيَٰقَوۡمِ مَا لِيٓ أَدۡعُوكُمۡ إِلَى ٱلنَّجَوٰةِ وَتَدۡعُونَنِيٓ إِلَى ٱلنَّارِ ٤١Ẹ̀yin ènìyàn mi, kí ló mú yín tí mò ń pè yín síbi ìgbàlà, tí ẹ̀yin sì ń pè mí síbi Iná تَدۡعُونَنِي لِأَكۡفُرَ بِٱللَّهِ وَأُشۡرِكَ بِهِۦ مَا لَيۡسَ لِي بِهِۦ عِلۡمٌ وَأَنَا۠ أَدۡعُوكُمۡ إِلَى ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡغَفَّٰرِ ٤٢Ẹ̀ ń pè mí pé kí n̄g ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu, kí n̄g sì sọ n̄ǹkan tí èmi kò nímọ̀ nípa rẹ̀ di akẹgbẹ́ fún Un. Èmi sì ń pè yín sí ọ̀dọ̀ Alágbára, Aláforíjìn لَا جَرَمَ أَنَّمَا تَدۡعُونَنِيٓ إِلَيۡهِ لَيۡسَ لَهُۥ دَعۡوَةٌ فِي ٱلدُّنۡيَا وَلَا فِي ٱلۡأٓخِرَةِ وَأَنَّ مَرَدَّنَآ إِلَى ٱللَّهِ وَأَنَّ ٱلۡمُسۡرِفِينَ هُمۡ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِ ٤٣Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, dájúdájú n̄ǹkan tí ẹ̀ ń pè mí sí, kò ní ẹ̀tọ́ sí ìpè kan ní ayé àti ní ọ̀run. Àti pé dájúdájú ọ̀dọ̀ Allāhu ni àbọ̀ wa. Dájúdájú àwọn olùtayọ-ẹnu-àlà, àwọn ni èrò inú Iná فَسَتَذۡكُرُونَ مَآ أَقُولُ لَكُمۡۚ وَأُفَوِّضُ أَمۡرِيٓ إِلَى ٱللَّهِۚ إِنَّ ٱللَّهَ بَصِيرُۢ بِٱلۡعِبَادِ ٤٤Nítorí náà, ẹ máa rántí ohun tí mò ń sọ fun yín. Mo sì ń fi ọ̀rọ̀ mi tì sí ọ̀dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn فَوَقَىٰهُ ٱللَّهُ سَيِّـَٔاتِ مَا مَكَرُواْۖ وَحَاقَ بِـَٔالِ فِرۡعَوۡنَ سُوٓءُ ٱلۡعَذَابِ ٤٥Allāhu sì ṣọ́ ọ níbi àwọn aburú tí wọ́n dète rẹ̀. Ìyà burúkú sì yí àwọn ènìyàn Fir‘aon po ٱلنَّارُ يُعۡرَضُونَ عَلَيۡهَا غُدُوًّا وَعَشِيًّاۚ وَيَوۡمَ تَقُومُ ٱلسَّاعَةُ أَدۡخِلُوٓاْ ءَالَ فِرۡعَوۡنَ أَشَدَّ ٱلۡعَذَابِ ٤٦Iná ni Wọ́n yóò máà ṣẹ́rí wọn sí ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́. Àti pé ní ọjọ́ tí Àkókò náà bá dé (A máa sọ pé): "Ẹ mú àwọn ènìyàn Fir‘aon wọ inú ìyà Iná t’ó le jùlọ وَإِذۡ يَتَحَآجُّونَ فِي ٱلنَّارِ فَيَقُولُ ٱلضُّعَفَٰٓؤُاْ لِلَّذِينَ ٱسۡتَكۡبَرُوٓاْ إِنَّا كُنَّا لَكُمۡ تَبَعًا فَهَلۡ أَنتُم مُّغۡنُونَ عَنَّا نَصِيبًا مِّنَ ٱلنَّارِ ٤٧(Rántí) nígbà tí wọ́n bá ń bá ara wọn ṣe àríyànjiyàn nínú Iná. Àwọn ọ̀lẹ yóò wí fún àwọn tí wọ́n ṣègbéraga pé: “Dájúdájú àwa jẹ́ ọmọlẹ́yìn fun yín, ǹjẹ́ ẹ̀yin lè gbé ìpín kan kúrò fún wa nínú ìyà Iná?” قَالَ ٱلَّذِينَ ٱسۡتَكۡبَرُوٓاْ إِنَّا كُلٌّ فِيهَآ إِنَّ ٱللَّهَ قَدۡ حَكَمَ بَيۡنَ ٱلۡعِبَادِ ٤٨Àwọn t’ó ṣègbéraga wí pé: "Dájúdájú gbogbo wa l’a wà nínú rẹ̀.” Dájúdájú Allāhu kúkú ti dájọ́ láààrin àwọn ẹrú náà وَقَالَ ٱلَّذِينَ فِي ٱلنَّارِ لِخَزَنَةِ جَهَنَّمَ ٱدۡعُواْ رَبَّكُمۡ يُخَفِّفۡ عَنَّا يَوۡمًا مِّنَ ٱلۡعَذَابِ ٤٩Àwọn t’ó wà nínú Iná tún wí fún àwọn ẹ̀ṣọ́-Iná pé: "Ẹ bá wa pe Olúwa yín, kí Ó ṣe ìyà ní fífúyẹ́ fún wa fún ọjọ́ kan قَالُوٓاْ أَوَلَمۡ تَكُ تَأۡتِيكُمۡ رُسُلُكُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِۖ قَالُواْ بَلَىٰۚ قَالُواْ فَٱدۡعُواْۗ وَمَا دُعَٰٓؤُاْ ٱلۡكَٰفِرِينَ إِلَّا فِي ضَلَٰلٍ ٥٠Wọ́n yóò sọ pé: "Ǹjẹ́ àwọn Òjísẹ́ yín kì í mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá ba yín bí?" Wọ́n wí pé: “Rárá, (wọ́n ń mú un wá).” Wọ́n sọ pé: “Ẹ ṣàdúà wò.” Àdúà àwọn aláìgbàgbọ́ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe sínú ìṣìnà. ọ̀nà wo ni àwọn aláìgbàgbọ́ ń gbà rí oore láyé? Kò sí oore ayé kan tí ó lè tẹ aláìgbàgbọ́ lọ́wọ́ bí kò ṣe ìpín rẹ̀ nínú kádàrá. Àmọ́ ní ti onígbàgbọ́ òdodo oore inú kádàrá àti oore àdúà l’ó wà fún un níwọ̀n ìgbà tí àdúà rẹ̀ bá ti bá sunnah Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) mu إِنَّا لَنَنصُرُ رُسُلَنَا وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا وَيَوۡمَ يَقُومُ ٱلۡأَشۡهَٰدُ ٥١Dájúdájú Àwa kúkú máa ṣàrànṣe fún àwọn Òjíṣẹ́ Wa àti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo nínú ìgbésí ayé yìí àti ní ọjọ́ tí àwọn ẹlẹ́rìí yó dìde (ní Ọjọ́ Àjíǹde) يَوۡمَ لَا يَنفَعُ ٱلظَّٰلِمِينَ مَعۡذِرَتُهُمۡۖ وَلَهُمُ ٱللَّعۡنَةُ وَلَهُمۡ سُوٓءُ ٱلدَّارِ ٥٢Ní ọjọ́ tí àwáwí àwọn alábòsí kò níí ṣe wọ́n ní àǹfààní; ègún ń bẹ fún wọn, ilé (ìyà) burúkú sì wà fún wọn وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡهُدَىٰ وَأَوۡرَثۡنَا بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ ٱلۡكِتَٰبَ ٥٣Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní ìmọ̀nà. A sì jogún Tírà fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl هُدًى وَذِكۡرَىٰ لِأُوْلِي ٱلۡأَلۡبَٰبِ ٥٤(Ó jẹ́) ìmọ̀nà àti ìrántí fún àwọn onílàákàyè فَٱصۡبِرۡ إِنَّ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقٌّ وَٱسۡتَغۡفِرۡ لِذَنۢبِكَ وَسَبِّحۡ بِحَمۡدِ رَبِّكَ بِٱلۡعَشِيِّ وَٱلۡإِبۡكَٰرِ ٥٥Nítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Kí o sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa rẹ ní àṣálẹ́ àti ní òwúrọ̀ kùtùkùtù. àwọn tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) tú sílẹ̀ wọ̀nyí àwọn ni olórí àwọn ọ̀ṣẹbọ nínú ìlú Mọkkah. Wọ́n sì ti pa àwọn mùsùlùmí kan nípakúpa ṣíwájú kí ọwọ́ tó tẹ àwọn náà lójú ogun Badr. Àmọ́ ohun tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) rò t’ó fi tú wọn sílẹ̀ ni pé ‘Ó gba ìyàwó lọ́wọ́ ọmọ rẹ̀ ó sì fi ṣaya!’. Ọ̀rọ̀ kò sì rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé a ò gbọ́dọ̀ fojú bín-íntín wo èyíkéyìí àṣìṣe tàbí ẹ̀ṣẹ̀. A gbọ́dọ̀ kún fún títọrọ àforíjìn ni lọ́dọ̀ Allāhu Aláforíjìn. Kò sí ohun t’ó dára tó rírí àforíjìn gbà lọ́dọ̀ Allāhu lórí gbogbo àṣìṣe wa ṣíwájú ọjọ́ ikú wa إِنَّ ٱلَّذِينَ يُجَٰدِلُونَ فِيٓ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ بِغَيۡرِ سُلۡطَٰنٍ أَتَىٰهُمۡ إِن فِي صُدُورِهِمۡ إِلَّا كِبۡرٌ مَّا هُم بِبَٰلِغِيهِۚ فَٱسۡتَعِذۡ بِٱللَّهِۖ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡبَصِيرُ ٥٦Dájúdájú àwọn t’ó ń jiyàn nípa àwọn āyah Allāhu láìní ẹrí kan (lọ́wọ́) tí ó wá bá wọn (láti ọ̀dọ̀ Allāhu), kò sí kiní kan nínú igbá-àyà wọn àyàfi ọkàn-gíga. Wọn kò sì lè dé ibi gíga (pẹ̀lú ọkàn gíga). Nítorí náà, sá di Allāhu. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Olùríran لَخَلۡقُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ أَكۡبَرُ مِنۡ خَلۡقِ ٱلنَّاسِ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ ٥٧Dájúdájú ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ tóbi ju ìṣẹ̀dá àwọn ènìyàn; ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn ni kò mọ̀ وَمَا يَسۡتَوِي ٱلۡأَعۡمَىٰ وَٱلۡبَصِيرُ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ وَلَا ٱلۡمُسِيٓءُۚ قَلِيلًا مَّا تَتَذَكَّرُونَ ٥٨Afọ́jú àti olùríran kò dọ́gba. Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere àti oníṣẹ́-aburú (kò dọ́gba). Díẹ̀ l’ẹ̀ ń lò nínú ìrántí إِنَّ ٱلسَّاعَةَ لَأٓتِيَةٌ لَّا رَيۡبَ فِيهَا وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يُؤۡمِنُونَ ٥٩Dájúdájú Àkókò náà ń bọ̀, kò sì sí iyèméjì nínú rẹ̀. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn ni kò gbàgbọ́ وَقَالَ رَبُّكُمُ ٱدۡعُونِيٓ أَسۡتَجِبۡ لَكُمۡۚ إِنَّ ٱلَّذِينَ يَسۡتَكۡبِرُونَ عَنۡ عِبَادَتِي سَيَدۡخُلُونَ جَهَنَّمَ دَاخِرِينَ ٦٠Olúwa yín sọ pé: "Ẹ pè Mí, kí N̄g jẹ́pè yín. Dájúdájú àwọn t’ó ń ṣègbéraga nípa jíjọ́sìn fún Mi, wọn yóò wọ inú iná Jahanamọ ní ẹni yẹpẹrẹ ٱللَّهُ ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُمُ ٱلَّيۡلَ لِتَسۡكُنُواْ فِيهِ وَٱلنَّهَارَ مُبۡصِرًاۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَذُو فَضۡلٍ عَلَى ٱلنَّاسِ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَشۡكُرُونَ ٦١Allāhu ni Ẹni tí Ó ṣe òru fun yín nítorí kí ẹ lè sinmi nínú rẹ̀. (Ó sì ṣe) ọ̀sán (nítorí kí ẹ lè fi) ríran. Dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́lá-jùlọ lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kì í dúpẹ́ (fún Un) ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبُّكُمۡ خَٰلِقُ كُلِّ شَيۡءٍ لَّآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ فَأَنَّىٰ تُؤۡفَكُونَ ٦٢Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín, Ẹlẹ́dàá gbogbo n̄ǹkan. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ yín lórí kúrò níbi òdodo كَذَٰلِكَ يُؤۡفَكُ ٱلَّذِينَ كَانُواْ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ يَجۡحَدُونَ ٦٣Báyẹn náà ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́ àwọn t’ó ń tako àwọn āyah Allāhu lórí kúrò níbi òdodo (ṣíwájú tiwọn) ٱللَّهُ ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُمُ ٱلۡأَرۡضَ قَرَارًا وَٱلسَّمَآءَ بِنَآءً وَصَوَّرَكُمۡ فَأَحۡسَنَ صُوَرَكُمۡ وَرَزَقَكُم مِّنَ ٱلطَّيِّبَٰتِۚ ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبُّكُمۡۖ فَتَبَارَكَ ٱللَّهُ رَبُّ ٱلۡعَٰلَمِينَ ٦٤Allāhu ni Ẹni tí Ó ṣe ilẹ̀ fun yín ní ibùgbé. Ó mọ sánmọ̀ (le yín lórí). Ó ya àwòrán yín. Ó sì ya àwòrán yín dáradára. Ó pèsè arísìkí fun yín nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa. Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín. Nítorí náà, mímọ́ ni fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá هُوَ ٱلۡحَيُّ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ فَٱدۡعُوهُ مُخۡلِصِينَ لَهُ ٱلدِّينَۗ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ ٦٥Òun ni Alààyè. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Nítorí náà, ẹ pè É ní ti olùṣàfọ̀mọ́-ẹ̀sìn fún Un. Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá ۞ قُلۡ إِنِّي نُهِيتُ أَنۡ أَعۡبُدَ ٱلَّذِينَ تَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ لَمَّا جَآءَنِيَ ٱلۡبَيِّنَٰتُ مِن رَّبِّي وَأُمِرۡتُ أَنۡ أُسۡلِمَ لِرَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ ٦٦Sọ pé: "Dájúdájú Wọ́n kọ̀ fún mi pé kí n̄g jọ́sìn fún àwọn tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, nígbà tí àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú ti dé bá mi láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi, tí wọ́n sì pa mí ní àṣẹ pé kí n̄g juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ (kí n̄g jẹ́ mùsùlùmí) fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá هُوَ ٱلَّذِي خَلَقَكُم مِّن تُرَابٍ ثُمَّ مِن نُّطۡفَةٍ ثُمَّ مِنۡ عَلَقَةٍ ثُمَّ يُخۡرِجُكُمۡ طِفۡلًا ثُمَّ لِتَبۡلُغُوٓاْ أَشُدَّكُمۡ ثُمَّ لِتَكُونُواْ شُيُوخًاۚ وَمِنكُم مَّن يُتَوَفَّىٰ مِن قَبۡلُۖ وَلِتَبۡلُغُوٓاْ أَجَلًا مُّسَمًّى وَلَعَلَّكُمۡ تَعۡقِلُونَ ٦٧Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín láti inú erùpẹ̀, lẹ́yìn náà láti inú àtọ̀, lẹ́yìn náà láti inú ẹ̀jẹ̀ dídì, lẹ́yìn náà Ó mu yín jáde ní òpóǹló. Lẹ́yìn náà, (Ó da yín sí) nítorí kí ẹ lè sánn̄gun dópin agbára yín. Lẹ́yìn náà (Ó tún da yín sí) nítorí kí ẹ lè di àgbàlágbà. Ó wà nínú yín ẹni tí A óò ti gba ẹ̀mí rẹ̀ ṣíwájú (ipò àgbà). Àti pé (Ó da yín sí) nítorí kí ẹ lè dàgbà dé gbèdéke àkókò kan àti nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè هُوَ ٱلَّذِي يُحۡيِۦ وَيُمِيتُۖ فَإِذَا قَضَىٰٓ أَمۡرًا فَإِنَّمَا يَقُولُ لَهُۥ كُن فَيَكُونُ ٦٨Òun ni Ẹni tí ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Nígbà tí Ó bá sì pèbùbù kiní kan, Ó kàn máa sọ fún un pé: "Jẹ́ bẹ́ẹ̀." Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀ أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ يُجَٰدِلُونَ فِيٓ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ أَنَّىٰ يُصۡرَفُونَ ٦٩Ṣé o ò rí àwọn tí ń ṣàríyànjiyàn nípa àwọn āyah Allāhu bí wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بِٱلۡكِتَٰبِ وَبِمَآ أَرۡسَلۡنَا بِهِۦ رُسُلَنَاۖ فَسَوۡفَ يَعۡلَمُونَ ٧٠Àwọn t’ó pe Tírà náà àti ohun tí A fi rán àwọn Òjíṣẹ́ Wa nírọ́, láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀ إِذِ ٱلۡأَغۡلَٰلُ فِيٓ أَعۡنَٰقِهِمۡ وَٱلسَّلَٰسِلُ يُسۡحَبُونَ ٧١Nígbà tí àwọn sẹ́kẹ́sẹkẹ̀ àti ẹ̀wọ̀n bá wà ní ọrùn wọn, tí wọn yóò fi máa wọ́ wọn فِي ٱلۡحَمِيمِ ثُمَّ فِي ٱلنَّارِ يُسۡجَرُونَ ٧٢sínú omi gbígbóná. Lẹ́yìn náà, wọn yóò fi wọ́n ko Iná ثُمَّ قِيلَ لَهُمۡ أَيۡنَ مَا كُنتُمۡ تُشۡرِكُونَ ٧٣Lẹ́yìn náà, Wọ́n máa sọ fún wọn pé: "Ibo ni ohun tí ẹ sọ di òrìṣà wà مِن دُونِ ٱللَّهِۖ قَالُواْ ضَلُّواْ عَنَّا بَل لَّمۡ نَكُن نَّدۡعُواْ مِن قَبۡلُ شَيۡـًٔاۚ كَذَٰلِكَ يُضِلُّ ٱللَّهُ ٱلۡكَٰفِرِينَ ٧٤(Ohun tí ẹ jọ́sìn fún) lẹ́yìn Allāhu (dà)?" Wọ́n á wí pé: "Wọ́n ti di òfò mọ́ wa lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ kọ́, àwa kì í pe n̄ǹkan kan tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀." Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣi àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́nà ذَٰلِكُم بِمَا كُنتُمۡ تَفۡرَحُونَ فِي ٱلۡأَرۡضِ بِغَيۡرِ ٱلۡحَقِّ وَبِمَا كُنتُمۡ تَمۡرَحُونَ ٧٥Ìyẹn nítorí pé ẹ̀ ń yọ lórí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́ àti nítorí pé ẹ̀ ń ṣe fáàrí (lórí àìgbàgbọ́) ٱدۡخُلُوٓاْ أَبۡوَٰبَ جَهَنَّمَ خَٰلِدِينَ فِيهَاۖ فَبِئۡسَ مَثۡوَى ٱلۡمُتَكَبِّرِينَ ٧٦Ẹ wọ àwọn ẹnu ọ̀na iná Jahanamọ; olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ó sì burú ní ibùgbé fún àwọn onígbèéraga فَٱصۡبِرۡ إِنَّ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقٌّۚ فَإِمَّا نُرِيَنَّكَ بَعۡضَ ٱلَّذِي نَعِدُهُمۡ أَوۡ نَتَوَفَّيَنَّكَ فَإِلَيۡنَا يُرۡجَعُونَ ٧٧Nítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Ó ṣeé ṣe kí A fi apá kan èyí tí A ṣe ní ìlérí fún wọn hàn ọ́ tàbí kí A ti gba ẹ̀mí rẹ (ṣíwájú àsìkò náà). Ọ̀dọ̀ Wa kúkú ni wọ́n máa dá wọn padà sí وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا رُسُلًا مِّن قَبۡلِكَ مِنۡهُم مَّن قَصَصۡنَا عَلَيۡكَ وَمِنۡهُم مَّن لَّمۡ نَقۡصُصۡ عَلَيۡكَۗ وَمَا كَانَ لِرَسُولٍ أَن يَأۡتِيَ بِـَٔايَةٍ إِلَّا بِإِذۡنِ ٱللَّهِۚ فَإِذَا جَآءَ أَمۡرُ ٱللَّهِ قُضِيَ بِٱلۡحَقِّ وَخَسِرَ هُنَالِكَ ٱلۡمُبۡطِلُونَ ٧٨Àti pé A kúkú ti rán àwọn Òjísẹ́ níṣẹ́ ṣíwájú rẹ. Àwọn tí A sọ ìtàn wọn fún ọ wà nínú wọn. Àwọn tí A ò sì sọ ìtàn wọn fún ọ wà nínú wọn. Àti pé kò tọ́ fún Òjísẹ́ kan láti mú àmì kan wá àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Nígbà tí àṣẹ Allāhu bá sì dé, A máa fi òdodo dájọ́. Àwọn òpùrọ́ sì máa ṣòfò dànù níbẹ̀ yẹn ٱللَّهُ ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُمُ ٱلۡأَنۡعَٰمَ لِتَرۡكَبُواْ مِنۡهَا وَمِنۡهَا تَأۡكُلُونَ ٧٩Allāhu ni Ẹni tí Ó dá àwọn ẹran-ọ̀sìn fun yín nítorí kí ẹ lè máa gùn nínú wọn. Ẹ ó sì máa jẹ nínú wọn وَلَكُمۡ فِيهَا مَنَٰفِعُ وَلِتَبۡلُغُواْ عَلَيۡهَا حَاجَةً فِي صُدُورِكُمۡ وَعَلَيۡهَا وَعَلَى ٱلۡفُلۡكِ تُحۡمَلُونَ ٨٠Àwọn àǹfààní (mìíràn) wà fun yín lára ẹran-ọ̀sìn. Àti nítorí kí ẹ lè dé ọ̀nà jíjìn t’ó wà lọ́kàn yín lórí (gígùn) wọ́n (kiri). Ẹ ó sì máa fi àwọn (ẹran-ọ̀sìn) àti ọkọ̀ ojú-omi gbé àwọn ẹrù وَيُرِيكُمۡ ءَايَٰتِهِۦ فَأَيَّ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ تُنكِرُونَ ٨١(Allāhu) ń fi àwọn àmì Rẹ̀ hàn yín. Nítorí náà, èwo nínú àwọn àmì Allāhu l’ẹ máa takò أَفَلَمۡ يَسِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَيَنظُرُواْ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۚ كَانُوٓاْ أَكۡثَرَ مِنۡهُمۡ وَأَشَدَّ قُوَّةً وَءَاثَارًا فِي ٱلۡأَرۡضِ فَمَآ أَغۡنَىٰ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ ٨٢Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn t’ó ṣíwájú wọn ṣe rí? Wọ́n pọ̀ (ní òǹkà) jù wọ́n lọ. Wọ́n ní agbára jù wọ́n lọ. Wọ́n sì lo ilẹ̀ (fún oko dídá jù wọ́n lọ). Síbẹ̀síbẹ̀ ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ (níbi ìyà) فَلَمَّا جَآءَتۡهُمۡ رُسُلُهُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِ فَرِحُواْ بِمَا عِندَهُم مِّنَ ٱلۡعِلۡمِ وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ ٨٣Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá bá wọn, wọ́n yọ àyọ̀pọ̀rọ́ nítorí ohun t’ó wà lọ́dọ̀ wọn nínú ìmọ̀ (ayé). Ohun tí wọ́n sì ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà t’ó yí wọn po فَلَمَّا رَأَوۡاْ بَأۡسَنَا قَالُوٓاْ ءَامَنَّا بِٱللَّهِ وَحۡدَهُۥ وَكَفَرۡنَا بِمَا كُنَّا بِهِۦ مُشۡرِكِينَ ٨٤Nígbà tí wọ́n rí ìyà Wa, wọ́n wí pé: "A gbàgbọ́ nínú Allāhu, Òun nìkan ṣoṣo. A sì lòdì sí n̄ǹkan tí a sọ di akẹgbẹ́ fún Un فَلَمۡ يَكُ يَنفَعُهُمۡ إِيمَٰنُهُمۡ لَمَّا رَأَوۡاْ بَأۡسَنَاۖ سُنَّتَ ٱللَّهِ ٱلَّتِي قَدۡ خَلَتۡ فِي عِبَادِهِۦۖ وَخَسِرَ هُنَالِكَ ٱلۡكَٰفِرُونَ ٨٥Ìgbàgbọ́ wọn kò ṣe wọ́n ní àǹfààní nígbà tí wọ́n rí ìyà Wa. Ìṣe Allāhu, èyí tí ó ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú sí àwọn ẹrú Rẹ̀ (ni èyí). Àwọn aláìgbàgbọ́ sì ṣòfò dànù níbẹ̀ yẹn

الترجمة: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.