بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
عَبَسَ وَتَوَلَّىٰٓ ١(Ànábì s.a.w.) fajú ro, ó sì pẹ̀yìn dà أَن جَآءَهُ ٱلۡأَعۡمَىٰ ٢nítorí pé afọ́jú wá bá a وَمَا يُدۡرِيكَ لَعَلَّهُۥ يَزَّكَّىٰٓ ٣Kí sì l’ó máa fi mọ̀ ọ́ pé ó ṣeé ṣe kí ó ṣàfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú àìgbàgbọ́) أَوۡ يَذَّكَّرُ فَتَنفَعَهُ ٱلذِّكۡرَىٰٓ ٤tàbí kí ó gbọ́ ìrántí, kí ìrántí náà sì ṣe é ní àǹfààní أَمَّا مَنِ ٱسۡتَغۡنَىٰ ٥Ní ti ẹni tí ó ka ara rẹ̀ kún ọlọ́rọ̀ فَأَنتَ لَهُۥ تَصَدَّىٰ ٦òun ni ìwọ tẹ́tí sí وَمَا عَلَيۡكَ أَلَّا يَزَّكَّىٰ ٧Kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ bí kò bá ṣe àfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú àìgbàgbọ́) وَأَمَّا مَن جَآءَكَ يَسۡعَىٰ ٨Ní ti ẹni tí ó sì wá bá ọ, t’ó ń yára gágá (sí ìrántí, ìyẹn afọ́jú) وَهُوَ يَخۡشَىٰ ٩tí ó sì ń páyà (Allāhu) فَأَنتَ عَنۡهُ تَلَهَّىٰ ١٠ìwọ kò sì kọbi ara sí i كـَلَّآ إِنَّهَا تَذۡكِرَةٌ ١١Rárá (kò tọ́ bẹ́ẹ̀). Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ìrántí فَمَن شَآءَ ذَكَرَهُۥ ١٢Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó rántí rẹ̀ فِي صُحُفٍ مُّكَرَّمَةٍ ١٣(Al-Ƙur’ān) wà nínú àwọn tàkádà alápọ̀n-ọ́nlé مَّرۡفُوعَةٍ مُّطَهَّرَةِۭ ١٤A gbé e ga, A sì ṣe é ní mímọ́ بِأَيۡدِي سَفَرَةٍ ١٥ní ọwọ́ àwọn òǹkọtíà (ìyẹn, àwọn mọlāika) كِرَامِۭ بَرَرَةٍ ١٦àwọn alápọ̀n-ọ́nlé, àwọn ẹni rere قُتِلَ ٱلۡإِنسَٰنُ مَآ أَكۡفَرَهُۥ ١٧Wọ́n ti fi ènìyàn gégùn-ún (nípa) bí ó ṣe jẹ́ aláìmoore jùlọ مِنۡ أَيِّ شَيۡءٍ خَلَقَهُۥ ١٨Kí sì ni Allāhu fi ṣẹ̀dá rẹ̀ مِن نُّطۡفَةٍ خَلَقَهُۥ فَقَدَّرَهُۥ ١٩Nínú àtọ̀ l’Ó ti ṣẹ̀dá rẹ̀. Ó sì pèbùbù (ẹ̀yà-ara) rẹ̀ ثُمَّ ٱلسَّبِيلَ يَسَّرَهُۥ ٢٠Lẹ́yìn náà, Ó ṣe ọ̀nà àtiwáyé ní ìrọ̀rùn fún un ثُمَّ أَمَاتَهُۥ فَأَقۡبَرَهُۥ ٢١Lẹ́yìn náà, Ó máa pa á. Ó sì máa fi sínú sàréè ثُمَّ إِذَا شَآءَ أَنشَرَهُۥ ٢٢Lẹ́yìn náà, nígbà tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa gbé e dìde كـَلَّا لَمَّا يَقۡضِ مَآ أَمَرَهُۥ ٢٣Ẹ gbọ́, ènìyàn kò tí ì ṣe n̄ǹkan tí Allāhu pa láṣẹ fún un فَلۡيَنظُرِ ٱلۡإِنسَٰنُ إِلَىٰ طَعَامِهِۦٓ ٢٤Nítorí náà, kí ènìyàn wòye sí oúnjẹ rẹ̀ أَنَّا صَبَبۡنَا ٱلۡمَآءَ صَبًّا ٢٥Dájúdájú Àwa ń rọ òjò ní púpọ̀ ثُمَّ شَقَقۡنَا ٱلۡأَرۡضَ شَقًّا ٢٦Lẹ́yìn náà, A mú ilẹ̀ sán kànkàn فَأَنۢبَتۡنَا فِيهَا حَبًّا ٢٧A sì mú kóró èso hù jáde láti inú rẹ̀ وَعِنَبًا وَقَضۡبًا ٢٨àti èso àjàrà àti kànnáfùrù وَزَيۡتُونًا وَنَخۡلًا ٢٩àti igi òróró Zaetūn àti dàbínù وَحَدَآئِقَ غُلۡبًا ٣٠àti àwọn ọgbà t’ó kún fún igi وَفَٰكِهَةً وَأَبًّا ٣١àti àwọn èso (mìíràn) pẹ̀lú ewé tí ẹranko ń jẹ, (A mú wọn hù jáde) مَّتَٰعًا لَّكُمۡ وَلِأَنۡعَٰمِكُمۡ ٣٢(Wọ́n jẹ́ n̄ǹkan) ìgbádùn fún ẹ̀yin àti àwọn ẹran-ọ̀sìn yín فَإِذَا جَآءَتِ ٱلصَّآخَّةُ ٣٣Nígbà tí fífọn sínú ìwo nígbà kejì bá ṣẹlẹ̀ يَوۡمَ يَفِرُّ ٱلۡمَرۡءُ مِنۡ أَخِيهِ ٣٤ní ọjọ́ tí ènìyàn yóò sá fún arákùnrin rẹ̀ وَأُمِّهِۦ وَأَبِيهِ ٣٥àti ìyá rẹ̀ pẹ̀lú bàbá rẹ̀ وَصَٰحِبَتِهِۦ وَبَنِيهِ ٣٦àti ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ لِكُلِّ ٱمۡرِيٍٕ مِّنۡهُمۡ يَوۡمَئِذٍ شَأۡنٌ يُغۡنِيهِ ٣٧Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ní ọjọ́ yẹn l’ó ti ní ọ̀ràn t’ó máa tó o ó rán وُجُوهٌ يَوۡمَئِذٍ مُّسۡفِرَةٌ ٣٨Àwọn ojú kan lọ́jọ́ yẹn yóò mọ́lẹ̀ ضَاحِكَةٌ مُّسۡتَبۡشِرَةٌ ٣٩Wọn yó máa rẹ́rìn-ín, wọn yó sì máa dunnú وَوُجُوهٌ يَوۡمَئِذٍ عَلَيۡهَا غَبَرَةٌ ٤٠Àwọn ojú kan lọ́jọ́ yẹn ni eruku yó sì bò mọ́lẹ̀ تَرۡهَقُهَا قَتَرَةٌ ٤١Òkùnkùn yó sì bò wọ́n mọ́lẹ̀ أُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡكَفَرَةُ ٱلۡفَجَرَةُ ٤٢Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni aláìgbàgbọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀