Millat al-Islam

Chapter 79 · 46 verses · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Surah An-Naziat in Yoruba

Arabic with tafsir Listen to Surah An-Naziat (1339 reciters)

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

وَٱلنَّٰزِعَٰتِ غَرۡقًا ١Allāhu búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó ń fi ọ̀nà èle gba ẹ̀mí àwọn aláìgbàgbọ́ وَٱلنَّٰشِطَٰتِ نَشۡطًا ٢Ó tún búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó ń fi ọ̀nà ẹ̀rọ̀ gba ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo وَٱلسَّٰبِحَٰتِ سَبۡحًا ٣Ó tún búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó ń yára gágá níbi àṣẹ Rẹ̀ فَٱلسَّٰبِقَٰتِ سَبۡقًا ٤Ó tún búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó máa ṣíwájú ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo wọnú Ọgbà Ìdẹ̀ra tààrà فَٱلۡمُدَبِّرَٰتِ أَمۡرًا ٥Ó tún búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó ń ṣètò ilé ayé يَوۡمَ تَرۡجُفُ ٱلرَّاجِفَةُ ٦Ní ọjọ́ tí ìfọn àkọ́kọ́ fún òpin ayé máa mi gbogbo ayé tìtì pẹ̀lú ohùn igbe تَتۡبَعُهَا ٱلرَّادِفَةُ ٧Ìfọn kejì fún Àjíǹde sì máa tèlé e قُلُوبٌ يَوۡمَئِذٍ وَاجِفَةٌ ٨Àwọn ọkàn yóò máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ ní ọjọ́ yẹn أَبۡصَٰرُهَا خَٰشِعَةٌ ٩Ojú wọn yó sì wálẹ̀ ní ti ìyẹpẹrẹ يَقُولُونَ أَءِنَّا لَمَرۡدُودُونَ فِي ٱلۡحَافِرَةِ ١٠Wọn yóò wí pé: "Ṣé Wọ́n tún máa dá wa padà sí ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀mí (bíi tayé ni) أَءِذَا كُنَّا عِظَٰمًا نَّخِرَةً ١١Ṣé nígbà tí a ti di eegun t’ó kẹfun tán قَالُواْ تِلۡكَ إِذًا كَرَّةٌ خَاسِرَةٌ ١٢Wọ́n wí pé: "Ìdápadà òfò nìyẹn nígbà náà (fún ẹni t’ó pè é nírọ́) فَإِنَّمَا هِيَ زَجۡرَةٌ وَٰحِدَةٌ ١٣Nítorí náà, igbe ẹyọ kan sì ni فَإِذَا هُم بِٱلسَّاهِرَةِ ١٤Nígbà náà ni wọn yóò bára wọn lórí ilẹ̀ gban̄sasa هَلۡ أَتَىٰكَ حَدِيثُ مُوسَىٰٓ ١٥Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ (Ànábì) Mūsā ti dé ọ̀dọ̀ rẹ إِذۡ نَادَىٰهُ رَبُّهُۥ بِٱلۡوَادِ ٱلۡمُقَدَّسِ طُوًى ١٦(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ̀ pè é ní àfonífojì mímọ́, Tuwā ٱذۡهَبۡ إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ إِنَّهُۥ طَغَىٰ ١٧Lọ bá Fir‘aon, dájúdájú ó ti tayọ ẹnu-àlà فَقُلۡ هَل لَّكَ إِلَىٰٓ أَن تَزَكَّىٰ ١٨Kí o sì sọ pé: "Ǹjẹ o máa ṣàfọ̀mọ́ ara rẹ (kúrò nínú àìgbàgbọ́) bí وَأَهۡدِيَكَ إِلَىٰ رَبِّكَ فَتَخۡشَىٰ ١٩Kí èmi sì fi ọ̀nà mọ̀ ọ́ dé ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, kí o páyà (Rẹ̀) فَأَرَىٰهُ ٱلۡأٓيَةَ ٱلۡكُبۡرَىٰ ٢٠Ó sì fi àmì t’ó tóbi hàn án فَكَذَّبَ وَعَصَىٰ ٢١(Àmọ́) ó pè é lópùrọ́. Ó sì yapa rẹ̀ ثُمَّ أَدۡبَرَ يَسۡعَىٰ ٢٢Lẹ́yìn náà, ó kẹ̀yìn sí i. Ó sì ń ṣiṣẹ́ (takò ó) فَحَشَرَ فَنَادَىٰ ٢٣Ó kó (àwọn ènìyàn) jọ, ó sì ké gbàjarì فَقَالَ أَنَا۠ رَبُّكُمُ ٱلۡأَعۡلَىٰ ٢٤Ó sì wí pé: "Èmi ni olúwa yín, ẹni gíga jùlọ فَأَخَذَهُ ٱللَّهُ نَكَالَ ٱلۡأٓخِرَةِ وَٱلۡأُولَىٰٓ ٢٥Nítorí náà, Allāhu gbá a mú pẹ̀lú ìyà ìkẹ́yìn àti àkọ́kọ́ (nípa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ ìkẹ́yìn yìí àti àkọ́kọ́) إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَعِبۡرَةً لِّمَن يَخۡشَىٰٓ ٢٦Dájúdájú àríwòye wà nínú ìyẹn fún ẹni t’ó ń páyà (Allāhu) ءَأَنتُمۡ أَشَدُّ خَلۡقًا أَمِ ٱلسَّمَآءُۚ بَنَىٰهَا ٢٧Ṣé ẹ̀yin lẹ lágbára jùlọ ní ìṣẹ̀dá ni tàbí sánmọ̀ tí Allāhu mọ رَفَعَ سَمۡكَهَا فَسَوَّىٰهَا ٢٨Allāhu gbé àjà rẹ̀ ga sókè. Ó sì ṣe é ní pípé t’ó gún régé وَأَغۡطَشَ لَيۡلَهَا وَأَخۡرَجَ ضُحَىٰهَا ٢٩Ó ṣe òru rẹ̀ ní dúdú. Ó sì fa ìyálẹ̀ta rẹ̀ yọ jáde وَٱلۡأَرۡضَ بَعۡدَ ذَٰلِكَ دَحَىٰهَآ ٣٠Àti ilẹ̀, Ó tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ lẹ́yìn ìyẹn أَخۡرَجَ مِنۡهَا مَآءَهَا وَمَرۡعَىٰهَا ٣١Ó mú omi rẹ̀ àti irúgbìn rẹ̀ jáde láti inú rẹ̀ وَٱلۡجِبَالَ أَرۡسَىٰهَا ٣٢Àti àwọn àpáta, Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ ṣinṣin مَتَٰعًا لَّكُمۡ وَلِأَنۡعَٰمِكُمۡ ٣٣Ìgbádùn ni fun yín àti fún àwọn ẹran-ọ̀sìn yín فَإِذَا جَآءَتِ ٱلطَّآمَّةُ ٱلۡكُبۡرَىٰ ٣٤Ṣùgbọ́n nígbà tí ìparun ńlá bá dé يَوۡمَ يَتَذَكَّرُ ٱلۡإِنسَٰنُ مَا سَعَىٰ ٣٥ní ọjọ́ tí ènìyàn yóò rántí ohun t’ó ṣe níṣẹ́ وَبُرِّزَتِ ٱلۡجَحِيمُ لِمَن يَرَىٰ ٣٦Wọ́n sì máa fi Iná hàn kedere fún (gbogbo) ẹni t’ó ríran فَأَمَّا مَن طَغَىٰ ٣٧Nítorí náà, ní ti ẹni t’ó bá tayọ ẹnu-àlà وَءَاثَرَ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا ٣٨tí ó tún gbé àjùlọ fún ìṣẹ̀mí ayé فَإِنَّ ٱلۡجَحِيمَ هِيَ ٱلۡمَأۡوَىٰ ٣٩dájúdájú iná Jẹhīm, òhun ni ibùgbé (rẹ̀) وَأَمَّا مَنۡ خَافَ مَقَامَ رَبِّهِۦ وَنَهَى ٱلنَّفۡسَ عَنِ ٱلۡهَوَىٰ ٤٠Ní ti ẹni tí ó bá páyà ìdúró níwájú Olúwa rẹ̀, tí ó tún kọ ìfẹ́-inú fún ẹ̀mí (ara rẹ̀) فَإِنَّ ٱلۡجَنَّةَ هِيَ ٱلۡمَأۡوَىٰ ٤١dájúdájú Ọgbà Ìdẹ̀ra, òhun ni ibùgbé (rẹ̀) يَسۡـَٔلُونَكَ عَنِ ٱلسَّاعَةِ أَيَّانَ مُرۡسَىٰهَا ٤٢Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa Àkókò náà pé: "Ìgbà wo l’ó máa ṣẹlẹ̀ فِيمَ أَنتَ مِن ذِكۡرَىٰهَآ ٤٣Ọ̀nà wo ni ìwọ lè fi ní (ìmọ̀) ìrántí rẹ̀ ná إِلَىٰ رَبِّكَ مُنتَهَىٰهَآ ٤٤Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni òpin ìmọ̀ nípa rẹ̀ wà إِنَّمَآ أَنتَ مُنذِرُ مَن يَخۡشَىٰهَا ٤٥Ìwọ kúkú ni olùkìlọ̀ fún ẹni t’ó ń páyà rẹ̀ كَأَنَّهُمۡ يَوۡمَ يَرَوۡنَهَا لَمۡ يَلۡبَثُوٓاْ إِلَّا عَشِيَّةً أَوۡ ضُحَىٰهَا ٤٦Ní ọjọ́ tí wọ́n máa rí i, wọn máa dà bí ẹni pé wọn kò lò tayọ ìrọ̀lẹ́ tàbí ìyálẹ̀ta (ọjọ́) kan lọ (nílé ayé)

Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.