Millat al-Islam

Chapter 92 · 21 verses · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Surah Al-Lail in Yoruba

Arabic with tafsir Listen to Surah Al-Lail (1283 reciters)
Meccanسورة الليل21 verses

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

وَٱلَّيۡلِ إِذَا يَغۡشَىٰ ١(Allāhu) búra pẹ̀lú alẹ́ nígbà tí (ilẹ̀) bá ṣú وَٱلنَّهَارِ إِذَا تَجَلَّىٰ ٢Ó tún búra pẹ̀lú ọ̀sán nígbà tí (ọ̀sán) bá pọ́n وَمَا خَلَقَ ٱلذَّكَرَ وَٱلۡأُنثَىٰٓ ٣Ó tún búra pẹ̀lú Ẹni tí Ó dá akọ àti abo إِنَّ سَعۡيَكُمۡ لَشَتَّىٰ ٤Dájúdájú iṣẹ́ yín, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni فَأَمَّا مَنۡ أَعۡطَىٰ وَٱتَّقَىٰ ٥Ní ti ẹni tí ó bá tọrẹ, tí ó sì bẹ̀rù (Allāhu) وَصَدَّقَ بِٱلۡحُسۡنَىٰ ٦(tí) ó tún pe ẹ̀san rere ní òdodo فَسَنُيَسِّرُهُۥ لِلۡيُسۡرَىٰ ٧A sì máa ṣe iṣẹ́ rere ní ìrọ̀rùn fún un وَأَمَّا مَنۢ بَخِلَ وَٱسۡتَغۡنَىٰ ٨Ní ti ẹni tí ó bá yahun, tí ó sì rí ara rẹ̀ lẹ́ni t’ó rọrọ̀ tayọ ẹ̀san ọ̀run وَكَذَّبَ بِٱلۡحُسۡنَىٰ ٩(tí) ó tún pe ẹ̀san rere ní irọ́ فَسَنُيَسِّرُهُۥ لِلۡعُسۡرَىٰ ١٠A sì máa ṣe iṣẹ́ aburú ní ìrọ̀rùn fún un وَمَا يُغۡنِي عَنۡهُ مَالُهُۥٓ إِذَا تَرَدَّىٰٓ ١١Dúkìá rẹ̀ kò sì níí rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ nígbà tí ó bá já bọ́ (sínú Iná) إِنَّ عَلَيۡنَا لَلۡهُدَىٰ ١٢Dájúdájú tiWa ni (láti ṣàlàyé) ìmọ̀nà وَإِنَّ لَنَا لَلۡأٓخِرَةَ وَٱلۡأُولَىٰ ١٣Àti pé dájúdájú tiWa ni ọ̀run àti ayé فَأَنذَرۡتُكُمۡ نَارًا تَلَظَّىٰ ١٤Nítorí náà, Mo ti fi Iná eléjò fòfò kìlọ̀ fun yín لَا يَصۡلَىٰهَآ إِلَّا ٱلۡأَشۡقَى ١٥Kò sí ẹni tí ó máa wọ inú rẹ̀ àfi olórí burúkú ٱلَّذِي كَذَّبَ وَتَوَلَّىٰ ١٦ẹni tí ó pe òdodo nírọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i وَسَيُجَنَّبُهَا ٱلۡأَتۡقَى ١٧Wọ́n sì máa gbé (Iná) jìnnà sí olùbẹ̀rù (Allāhu) ٱلَّذِي يُؤۡتِي مَالَهُۥ يَتَزَكَّىٰ ١٨ẹni t’ó ń fi dúkìá rẹ̀ tọrẹ, tí ó ń ṣàfọ̀mọ́ (rẹ̀) وَمَا لِأَحَدٍ عِندَهُۥ مِن نِّعۡمَةٍ تُجۡزَىٰٓ ١٩Kò sì sí oore ìdẹ̀ra kan tí (ó ní lọ́kàn) láti gbà ní ẹ̀san ní ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni إِلَّا ٱبۡتِغَآءَ وَجۡهِ رَبِّهِ ٱلۡأَعۡلَىٰ ٢٠bí kò ṣe pé láti fi wá ojú rere Olúwa rẹ̀, Ẹni Gíga jùlọ وَلَسَوۡفَ يَرۡضَىٰ ٢١Láìpẹ́ ó sì máa yọ́nú (sí ẹ̀san rẹ̀)

Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.