Millat al-Islam

Chapter 91 · 15 verses · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Surah Ash-Shams in Yoruba

Arabic with tafsir Listen to Surah Ash-Shams (1346 reciters)
Meccanسورة الشمس15 verses

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

وَٱلشَّمۡسِ وَضُحَىٰهَا ١(Allāhu) búra pẹ̀lú òòrùn àti ìyálẹ̀ta rẹ̀ وَٱلۡقَمَرِ إِذَا تَلَىٰهَا ٢Ó tún búra pẹ̀lú òṣùpá nígbà tí ó bá (yọ) tẹ̀lé (òòrùn) وَٱلنَّهَارِ إِذَا جَلَّىٰهَا ٣Ó tún búra pẹ̀lú ọ̀sán nígbà tí ó bá mú ìmọ́lẹ̀ bá òkùnkùn òru وَٱلَّيۡلِ إِذَا يَغۡشَىٰهَا ٤Ó tún búra pẹ̀lú alẹ́ nígbà tí ó bá bo ọ̀sán mọ́lẹ̀ وَٱلسَّمَآءِ وَمَا بَنَىٰهَا ٥Ó tún búra pẹ̀lú sánmọ̀ àti Ẹni tí Ó mọ ọ́n وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا طَحَىٰهَا ٦Ó tún búra pẹ̀lú ilẹ̀ àti Ẹni tí Ó tẹ́ ẹ kalẹ̀ وَنَفۡسٍ وَمَا سَوَّىٰهَا ٧Ó tún búra pẹ̀lú ẹ̀mí (ènìyàn) àti Ẹni tí Ó ṣe (oríkèé rẹ̀) dọ́gba فَأَلۡهَمَهَا فُجُورَهَا وَتَقۡوَىٰهَا ٨Ó sì fi ẹ̀ṣẹ̀ (tí ẹ̀mí lè dá) àti ìbẹ̀rù rẹ̀ mọ̀ ọ́n قَدۡ أَفۡلَحَ مَن زَكَّىٰهَا ٩Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàfọ̀mọ́ (ẹ̀mí ara) rẹ̀ (níbi ẹ̀ṣẹ̀), ó mà ti jèrè وَقَدۡ خَابَ مَن دَسَّىٰهَا ١٠Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi (ìwà ẹ̀ṣẹ̀) ba ẹ̀mí (ara) rẹ̀ jẹ́, ó mà ti pàdánù كَذَّبَتۡ ثَمُودُ بِطَغۡوَىٰهَآ ١١Ìjọ Thamūd pe òdodo nírọ́ nípa ìtayọ ẹnu-àlà wọn إِذِ ٱنۢبَعَثَ أَشۡقَىٰهَا ١٢(Rántí) nígbà tí ẹni tí orí rẹ̀ burú jùlọ nínú wọn sáré dìde (láti gún ràkúnmí pa) فَقَالَ لَهُمۡ رَسُولُ ٱللَّهِ نَاقَةَ ٱللَّهِ وَسُقۡيَٰهَا ١٣Nígbà náà, Òjíṣẹ́ Allāhu sọ fún wọn pé: "(Ẹ fi) abo ràkúnmí Allāhu àti omi rẹ̀ (sílẹ̀) فَكَذَّبُوهُ فَعَقَرُوهَا فَدَمۡدَمَ عَلَيۡهِمۡ رَبُّهُم بِذَنۢبِهِمۡ فَسَوَّىٰهَا ١٤Wọ́n pè é nírọ́. Wọ́n sì gún (ràkúnmí) pa. Nítorí náà, Olúwa wọn pa wọ́n rẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ó sì fi ìparun náà kárí wọn وَلَا يَخَافُ عُقۡبَٰهَا ١٥(Ẹni t’ó gún ràkúnmí pa) kò sì páyà ìkángun ọ̀rọ̀ wọn

Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.