بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
أَرَءَيۡتَ ٱلَّذِي يُكَذِّبُ بِٱلدِّينِ ١Sọ fún mi nípa ẹni t’ó ń pe Ọjọ́ Ẹ̀san nírọ́ فَذَٰلِكَ ٱلَّذِي يَدُعُّ ٱلۡيَتِيمَ ٢Ìyẹn ni ẹni t’ó ń lé ọmọ-òrukàn dànù وَلَا يَحُضُّ عَلَىٰ طَعَامِ ٱلۡمِسۡكِينِ ٣Kò sì níí gbìyànjú láti bọ́ mẹ̀kúnnù فَوَيۡلٌ لِّلۡمُصَلِّينَ ٤Ègbé ni fún àwọn (mùnááfìkí) t’ó ń kírun; kò túmọ̀ sí “ohun t’ó ń run ènìyàn”. Àmọ́ ìtúmọ̀ “ìrun” ni “ohun t’ó ń run ẹ̀ṣẹ̀ olùkírun” nítorí pé tí olùkírun bá ti ṣe àlùwàlá ni ó ti ṣan gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wẹẹrẹ tí ó ti fi àwọn oríkèé ara rẹ̀ ṣe ṣíwájú. Bákan náà ٱلَّذِينَ هُمۡ عَن صَلَاتِهِمۡ سَاهُونَ ٥àwọn t’ó ń gbàgbé láti kírun wọn ní àsìkò rẹ̀ ٱلَّذِينَ هُمۡ يُرَآءُونَ ٦àwọn t’ó ń ṣe ṣekárími وَيَمۡنَعُونَ ٱلۡمَاعُونَ ٧àti pé wọ́n ń hánnà ohun èlò (fún àwọn ènìyàn)