Millat al-Islam

Chapter 101 · 11 verses · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Surah Al-Qaria in Yoruba

Arabic with tafsir Listen to Surah Al-Qaria (1290 reciters)

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

ٱلۡقَارِعَةُ ١Àkókò ìjáyà مَا ٱلۡقَارِعَةُ ٢Kí ni Àkókò ìjáyà وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا ٱلۡقَارِعَةُ ٣Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Àkókò ìjáyà يَوۡمَ يَكُونُ ٱلنَّاسُ كَٱلۡفَرَاشِ ٱلۡمَبۡثُوثِ ٤(Òhun ni) ọjọ́ tí ènìyàn yó dà bí àfòpiná tí wọ́n fọ́nká síta وَتَكُونُ ٱلۡجِبَالُ كَٱلۡعِهۡنِ ٱلۡمَنفُوشِ ٥àwọn àpáta yó sì dà bí òwú tí wọ́n gbọ̀n dànù فَأَمَّا مَن ثَقُلَتۡ مَوَٰزِينُهُۥ ٦Nítorí náà, ní ti ẹni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá tẹ̀ wọ̀n فَهُوَ فِي عِيشَةٍ رَّاضِيَةٍ ٧ó sì máa wà nínú ìṣẹ̀mí t’ó yọ́nú sí وَأَمَّا مَنۡ خَفَّتۡ مَوَٰزِينُهُۥ ٨Ní ti ẹni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá sì fúyẹ́ فَأُمُّهُۥ هَاوِيَةٌ ٩Hāwiyah sì ni ibùgbé rẹ̀ وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا هِيَهۡ ١٠Kí sì ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀ نَارٌ حَامِيَةُۢ ١١(Òhun ni) Iná gbígbóná gan-an

Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.