Millat al-Islam

Chapter 102 · 8 verses · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Surah At-Takathur in Yoruba

Arabic with tafsir Listen to Surah At-Takathur (1265 reciters)

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

أَلۡهَىٰكُمُ ٱلتَّكَاثُرُ ١Wíwá oore ayé ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ fún ìyanràn ṣíṣe ti kó àìrójú fẹ́sìn ba yín حَتَّىٰ زُرۡتُمُ ٱلۡمَقَابِرَ ٢títí ẹ fi wọ inú sàréè كـَلَّا سَوۡفَ تَعۡلَمُونَ ٣Rárá (kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀, àmọ́) láìpẹ́ ẹ máa mọ̀ ثُمَّ كـَلَّا سَوۡفَ تَعۡلَمُونَ ٤Lẹ́yìn náà, ní òdodo láìpẹ́ ẹ máa mọ̀ كـَلَّا لَوۡ تَعۡلَمُونَ عِلۡمَ ٱلۡيَقِينِ ٥Bẹ́ẹ̀ ni, tí ó bá jẹ́ pé ẹ ni ìmọ̀ àmọ̀dájú ni (ẹ̀yin ìbá tí ṣe bẹ́ẹ̀) لَتَرَوُنَّ ٱلۡجَحِيمَ ٦Dájúdájú ẹ máa rí iná Jẹhīm ثُمَّ لَتَرَوُنَّهَا عَيۡنَ ٱلۡيَقِينِ ٧Lẹ́yìn náà, dájúdájú ẹ máa rí i ní àrídájú ثُمَّ لَتُسۡـَٔلُنَّ يَوۡمَئِذٍ عَنِ ٱلنَّعِيمِ ٨Lẹ́yìn náà, dájúdájú ní ọjọ́ yẹn wọ́n máa bi yín léèrè nípa ìgbádùn (ayé yìí)

Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.