Millat al-Islam

Chapter 78 · 40 verses · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Surah An-Naba in Yoruba

Arabic with tafsir Listen to Surah An-Naba (1413 reciters)
Meccanسورة النبأ40 verses

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

عَمَّ يَتَسَآءَلُونَ ١Nípa kí ni wọ́n ń bíra wọn léèrè ná عَنِ ٱلنَّبَإِ ٱلۡعَظِيمِ ٢Nípa ìró ìkọ̀kọ̀ ńlá ni ٱلَّذِي هُمۡ فِيهِ مُخۡتَلِفُونَ ٣èyí tí wọ́n ń yapa ẹnu sí كـَلَّا سَيَعۡلَمُونَ ٤Rárá! Wọ́n ń bọ̀ wá mọ̀ ثُمَّ كـَلَّا سَيَعۡلَمُونَ ٥Lẹ́yìn náà, ní ti òdodo wọ́n ń bọ̀ wá mọ̀ أَلَمۡ نَجۡعَلِ ٱلۡأَرۡضَ مِهَٰدًا ٦Ǹjẹ́ Àwa kò ṣe ilẹ̀ ní ìtẹ́ bí وَٱلۡجِبَالَ أَوۡتَادًا ٧àti àwọn àpáta ní èèkàn (fún ilẹ̀) وَخَلَقۡنَٰكُمۡ أَزۡوَٰجًا ٨A sì ṣẹ̀dá yín ní oríṣiríṣi (akọ àti abo) وَجَعَلۡنَا نَوۡمَكُمۡ سُبَاتًا ٩A ṣe oorun yín ní ìsinmi وَجَعَلۡنَا ٱلَّيۡلَ لِبَاسًا ١٠A tún ṣe alẹ́ ní ìbora وَجَعَلۡنَا ٱلنَّهَارَ مَعَاشًا ١١A tún ṣe ọ̀sán ní (àsìkò fún) wíwá ìjẹ-ìmu وَبَنَيۡنَا فَوۡقَكُمۡ سَبۡعًا شِدَادًا ١٢A tún mọ sánmọ̀ méje t’ó lágbára sókè yín وَجَعَلۡنَا سِرَاجًا وَهَّاجًا ١٣A tún ṣe òòrùn ní ìmọ́lẹ̀ t’ó ń tàn gbòlà وَأَنزَلۡنَا مِنَ ٱلۡمُعۡصِرَٰتِ مَآءً ثَجَّاجًا ١٤Àti pé A sọ omi t’ó ń bọ́ tẹ̀léra wọn kalẹ̀ láti inú àwọn ẹ̀ṣújò لِّنُخۡرِجَ بِهِۦ حَبًّا وَنَبَاتًا ١٥nítorí kí Á lè fi mú kóró èso àti irúgbìn jáde وَجَنَّٰتٍ أَلۡفَافًا ١٦pẹ̀lú àwọn ọgbà t’ó kún digbí fún n̄ǹkan oko إِنَّ يَوۡمَ ٱلۡفَصۡلِ كَانَ مِيقَٰتًا ١٧Dájúdájú ọjọ́ ìpínyà, ó ní gbèdéke àkókò kan يَوۡمَ يُنفَخُ فِي ٱلصُّورِ فَتَأۡتُونَ أَفۡوَاجًا ١٨(Ìyẹn ni) ọjọ́ tí wọ́n á fọn fèrè oníwo fún àjíǹde. Ẹ̀yin yó sì máa wá níjọ-níjọ وَفُتِحَتِ ٱلسَّمَآءُ فَكَانَتۡ أَبۡوَٰبًا ١٩Wọ́n sì máa ṣí sánmọ̀ sílẹ̀. Ó sì máa di àwọn ìlẹ̀kùn وَسُيِّرَتِ ٱلۡجِبَالُ فَكَانَتۡ سَرَابًا ٢٠Wọ́n máa mú àwọn àpáta rìn (bọ́ sí àyè mìíràn). Ó sì máa di ahúnpeéná إِنَّ جَهَنَّمَ كَانَتۡ مِرۡصَادًا ٢١Dájúdájú iná Jahanamọ, ó lúgọ sílẹ̀ lójú ọ̀nà لِّلطَّٰغِينَ مَـَٔابًا ٢٢(Ó jẹ́) ibùgbé fún àwọn alákọyọ لَّٰبِثِينَ فِيهَآ أَحۡقَابًا ٢٣Wọn yóò máa gbé inú rẹ̀ fún ìgbà gbọọrọ لَّا يَذُوقُونَ فِيهَا بَرۡدًا وَلَا شَرَابًا ٢٤Wọn kò níí rí ìtura tàbí ohun mímu kan tọ́wò nínú rẹ̀ إِلَّا حَمِيمًا وَغَسَّاقًا ٢٥àyàfi omi gbígbóná àti àwọyúnwẹ̀jẹ̀ جَزَآءً وِفَاقًا ٢٦(Ó jẹ́) ẹ̀san t’ó ṣe wẹ́kú (iṣẹ́ wọn) إِنَّهُمۡ كَانُواْ لَا يَرۡجُونَ حِسَابًا ٢٧Dájúdájú wọn kì í retí ìṣírò-iṣẹ́ وَكَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَا كِذَّابًا ٢٨Wọ́n sì pe àwọn āyah Wa nírọ́ gan-an وَكُلَّ شَيۡءٍ أَحۡصَيۡنَٰهُ كِتَٰبًا ٢٩Gbogbo n̄ǹkan sì ni A ti ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú Tírà kan فَذُوقُواْ فَلَن نَّزِيدَكُمۡ إِلَّا عَذَابًا ٣٠Nítorí náà, ẹ tọ́ (ìyà) wò. A ò sì níí ṣe àlékún kan fun yín bí kò ṣe ìyà إِنَّ لِلۡمُتَّقِينَ مَفَازًا ٣١Dájúdájú ìgbàlà wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) حَدَآئِقَ وَأَعۡنَٰبًا ٣٢Àwọn ọgbà àti èso àjàrà وَكَوَاعِبَ أَتۡرَابًا ٣٣àti àwọn ọlọ́mọge, tí wọn kò júra wọn lọ lọ́jọ́-orí وَكَأۡسًا دِهَاقًا ٣٤àti ife ọtí t’ó kún dẹnu (ni ẹ̀san wọn) لَّا يَسۡمَعُونَ فِيهَا لَغۡوًا وَلَا كِذَّٰبًا ٣٥Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ àti ọ̀rọ̀ irọ́ nínú rẹ̀ جَزَآءً مِّن رَّبِّكَ عَطَآءً حِسَابًا ٣٦(Ó jẹ́) ẹ̀san láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, (ó sì jẹ́) ọrẹ ní ìbámu sí ìṣírò-iṣẹ́ (wọn) رَّبِّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَيۡنَهُمَا ٱلرَّحۡمَٰنِۖ لَا يَمۡلِكُونَ مِنۡهُ خِطَابًا ٣٧(Ẹsan náà wá láti ọ̀dọ̀) Olúwa àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohun t’ó wà láààrin méjèèjì, Àjọkẹ́-ayé. Wọn kò sì ní ìkápá ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Rẹ̀ يَوۡمَ يَقُومُ ٱلرُّوحُ وَٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ صَفًّاۖ لَّا يَتَكَلَّمُونَ إِلَّا مَنۡ أَذِنَ لَهُ ٱلرَّحۡمَٰنُ وَقَالَ صَوَابًا ٣٨Ọjọ́ tí mọlāika Jibrīl àti àwọn mọlāika (mìíràn) yóò dúró ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Wọn kò sì níí sọ̀rọ̀ àfi ẹni tí Àjọké-ayé bá yọ̀ǹda fún. Onítọ̀ún sì máa sọ̀rọ̀ t’ó ṣe wẹ́kú ذَٰلِكَ ٱلۡيَوۡمُ ٱلۡحَقُّۖ فَمَن شَآءَ ٱتَّخَذَ إِلَىٰ رَبِّهِۦ مَـَٔابًا ٣٩Ìyẹn ni ọjọ́ òdodo. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó mú ọ̀nà tó máa gbà ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ pọ̀n (ní ti ìronúpìwàdà) إِنَّآ أَنذَرۡنَٰكُمۡ عَذَابًا قَرِيبًا يَوۡمَ يَنظُرُ ٱلۡمَرۡءُ مَا قَدَّمَتۡ يَدَاهُ وَيَقُولُ ٱلۡكَافِرُ يَٰلَيۡتَنِي كُنتُ تُرَٰبَۢا ٤٠Dájúdájú A fi ìyà t’ó súnmọ́ ṣe ìkìlọ̀ fun yín. Ọjọ́ tí ènìyàn yóò máa wo ohun tí ó tì síwájú, aláìgbàgbọ́ yó sì wí pé: "Yéè, èmi ìbá sì jẹ́ erùpẹ̀, (èmi ìbá là nínú ìyà)

Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.