Millat al-Islam

Chapter 95 · 8 verses · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Surah At-Tin in Yoruba

Arabic with tafsir Listen to Surah At-Tin (1299 reciters)
Meccanسورة التين8 verses

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

وَٱلتِّينِ وَٱلزَّيۡتُونِ ١Allāhu búra pẹ̀lú èso tīn àti èso zaetūn وَطُورِ سِينِينَ ٢Ó tún búra pẹ̀lú àpáta Sīnīn وَهَٰذَا ٱلۡبَلَدِ ٱلۡأَمِينِ ٣Ó tún búra pẹ̀lú ìlú ìfàyàbalẹ̀ yìí لَقَدۡ خَلَقۡنَا ٱلۡإِنسَٰنَ فِيٓ أَحۡسَنِ تَقۡوِيمٍ ٤Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn pẹ̀lú ìrísí t’ó dára jùlọ ثُمَّ رَدَدۡنَٰهُ أَسۡفَلَ سَٰفِلِينَ ٥Lẹ́yìn náà, A máa dá a padà sí ìsàlẹ̀ pátápátá (nínú Iná) إِلَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ فَلَهُمۡ أَجۡرٌ غَيۡرُ مَمۡنُونٍ ٦Àyàfi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Nítorí náà, ẹ̀san tí kò níí pin (tí kò níí pẹ̀dín) ń bẹ fún wọn فَمَا يُكَذِّبُكَ بَعۡدُ بِٱلدِّينِ ٧Ta l’ó tún ń pè ọ́ ní òpùrọ́ nípa Ọjọ́ ẹ̀san lẹ́yìn (ọ̀rọ̀ yìí) أَلَيۡسَ ٱللَّهُ بِأَحۡكَمِ ٱلۡحَٰكِمِينَ ٨Ṣé Allāhu kọ́ ni Ẹni t’Ó mọ ẹ̀jọ́ dá jùlọ nínú àwọn adájọ́ ni

Translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.