ملة الإسلام

السورة 84 · 25 آية · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

سورة الانشقاق باللغة اليوروبا

السورة بالعربية مع التفسير استمع إلى سورة الانشقاق (1,276 قارئاً)
مكيةسورة الانشقاق٢٥ آية

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

إِذَا ٱلسَّمَآءُ ٱنشَقَّتۡ ١Nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ وَأَذِنَتۡ لِرَبِّهَا وَحُقَّتۡ ٢ó gbọ́, ó sì tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ̀ ni. Ó sì di dandan fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ – وَإِذَا ٱلۡأَرۡضُ مُدَّتۡ ٣àti nígbà tí A bá fẹ ilẹ̀ lójú وَأَلۡقَتۡ مَا فِيهَا وَتَخَلَّتۡ ٤ó máa ju ohun tí ó wà nínú rẹ̀ síta, ó sì máa pa sófo وَأَذِنَتۡ لِرَبِّهَا وَحُقَّتۡ ٥– ó gbọ́, ó sì tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ̀ ni. Ó sì di dandan fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ – (ní ọjọ́ yẹn ni ẹ̀dá máa rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀) يَٰٓأَيُّهَا ٱلۡإِنسَٰنُ إِنَّكَ كَادِحٌ إِلَىٰ رَبِّكَ كَدۡحًا فَمُلَٰقِيهِ ٦Ìwọ ènìyàn dájúdájú ìwọ ń ṣe iṣẹ́ kárakára ní iṣẹ́ àṣepàdé Olúwa rẹ. O sì máa mú un pàdé Rẹ̀ فَأَمَّا مَنۡ أُوتِيَ كِتَٰبَهُۥ بِيَمِينِهِۦ ٧Nítorí náà, ní ti ẹni tí wọ́n bá fún ní ìwé iṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ فَسَوۡفَ يُحَاسَبُ حِسَابًا يَسِيرًا ٨láìpẹ́ A máa ṣe ìṣírò-iṣẹ́ (rẹ̀) ní ìṣírò ìrọ̀rùn وَيَنقَلِبُ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِۦ مَسۡرُورًا ٩Ó sì máa padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra) lẹ́ni ìdùnnú وَأَمَّا مَنۡ أُوتِيَ كِتَٰبَهُۥ وَرَآءَ ظَهۡرِهِۦ ١٠Ní ti ẹni tí wọ́n bá sì fún ní ìwé iṣẹ́ rẹ̀ láti ẹ̀yìn rẹ̀ فَسَوۡفَ يَدۡعُواْ ثُبُورًا ١١láìpẹ́ ó máa kígbe ìparun وَيَصۡلَىٰ سَعِيرًا ١٢Ó sì máa wọ inú Iná t’ó ń jò fòfò إِنَّهُۥ كَانَ فِيٓ أَهۡلِهِۦ مَسۡرُورًا ١٣Dájúdájú ó ti wà láààrin àwọn ènìyàn rẹ̀ lẹ́ni ìdùnnú (sí àìgbàgbọ́ nílé ayé) إِنَّهُۥ ظَنَّ أَن لَّن يَحُورَ ١٤Dájúdájú ó lérò pé òun kò níí padà (sí ọ̀dọ̀ Allāhu ni) بَلَىٰٓۚ إِنَّ رَبَّهُۥ كَانَ بِهِۦ بَصِيرًا ١٥Rárá (ó máa padà). Dájúdájú Olúwa rẹ̀ jẹ́ Olùríran nípa rẹ̀ فَلَآ أُقۡسِمُ بِٱلشَّفَقِ ١٦Nítorí náà, Èmi (Allāhu) ń búra pẹ̀lú àwòǹpapa وَٱلَّيۡلِ وَمَا وَسَقَ ١٧Mo tún búra pẹ̀lú òru àti ohun tí ó kó jọ sínú rẹ̀ وَٱلۡقَمَرِ إِذَا ٱتَّسَقَ ١٨Mo tún búra pẹ̀lú òṣùpá nígbà tí ó bá dégbá (pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀) لَتَرۡكَبُنَّ طَبَقًا عَن طَبَقٍ ١٩Dájúdájú ẹ̀yin yóò máa bọ́ sínú wàhálà kan láti inú wàhálà kan فَمَا لَهُمۡ لَا يُؤۡمِنُونَ ٢٠Kí l’ó ṣe wọ́n ná tí wọn kò fi gbàgbọ́ ní òdodo وَإِذَا قُرِئَ عَلَيۡهِمُ ٱلۡقُرۡءَانُ لَا يَسۡجُدُونَۤ ۩ ٢١Nígbà tí wọ́n bá sì ké al-Ƙur’ān fún wọn, wọn kò níí forí kanlẹ̀ بَلِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ يُكَذِّبُونَ ٢٢Rárá, ńṣe ni àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ń pè é nírọ́ وَٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِمَا يُوعُونَ ٢٣Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ (sínú ọkàn wọn) فَبَشِّرۡهُم بِعَذَابٍ أَلِيمٍ ٢٤Nítorí náà, fún wọn ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro إِلَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ لَهُمۡ أَجۡرٌ غَيۡرُ مَمۡنُونِۭ ٢٥Àyàfi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, ẹ̀san tí kò níí pin ń bẹ fún wọn

الترجمة: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.