ملة الإسلام

السورة 83 · 36 آية · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

سورة المطففين باللغة اليوروبا

السورة بالعربية مع التفسير استمع إلى سورة المطففين (1,318 قارئاً)
مكيةسورة المطففين٣٦ آية

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

وَيۡلٌ لِّلۡمُطَفِّفِينَ ١Ègbé ni fún àwọn olùdín-òṣùwọ̀n-kù ٱلَّذِينَ إِذَا ٱكۡتَالُواْ عَلَى ٱلنَّاسِ يَسۡتَوۡفُونَ ٢àwọn (òǹtajà) t’ó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá wọn n̄ǹkan lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn, wọ́n á gbà á ní ẹ̀kún وَإِذَا كَالُوهُمۡ أَو وَّزَنُوهُمۡ يُخۡسِرُونَ ٣nígbà tí àwọn (òǹtajà náà) bá sì lo ìwọ̀n fún àwọn (òǹrajà) tàbí lo òṣùwọ̀n fún wọn, wọn yóò dín in kù أَلَا يَظُنُّ أُوْلَٰٓئِكَ أَنَّهُم مَّبۡعُوثُونَ ٤Ṣé àwọn wọ̀nyẹn kò mọ̀ dájú pé dájúdájú A máa gbé wọn dìde لِيَوۡمٍ عَظِيمٍ ٥ní Ọjọ́ ńlá kan يَوۡمَ يَقُومُ ٱلنَّاسُ لِرَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ ٦Ní ọjọ́ tí àwọn ènìyàn yóò dìde nàró fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá كـَلَّآ إِنَّ كِتَٰبَ ٱلۡفُجَّارِ لَفِي سِجِّينٍ ٧Bẹ́ẹ̀ ni, dájúdájú ìwé iṣẹ́ àwọn ẹni ibi kúkú wà nínú Sijjīn وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا سِجِّينٌ ٨Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Sijjīn كِتَٰبٌ مَّرۡقُومٌ ٩Ìwé tí wọ́n ti kọ iṣẹ́ aburú ẹ̀dá sínú rẹ̀ (tí wọ́n sì fi pamọ́ sínú ilẹ̀ keje ni Sijjīn) وَيۡلٌ يَوۡمَئِذٍ لِّلۡمُكَذِّبِينَ ١٠Ní ọjọ́ yẹn, ègbé ni fún àwọn olùpe-òdodo- nírọ́ ٱلَّذِينَ يُكَذِّبُونَ بِيَوۡمِ ٱلدِّينِ ١١àwọn t’ó ń pe Ọjọ́ ẹ̀san nírọ́ وَمَا يُكَذِّبُ بِهِۦٓ إِلَّا كُلُّ مُعۡتَدٍ أَثِيمٍ ١٢Kò sì sí ẹni t’ó ń pè é nírọ́ àfi gbogbo alákọyọ, ẹlẹ́ṣẹ̀ إِذَا تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِ ءَايَٰتُنَا قَالَ أَسَٰطِيرُ ٱلۡأَوَّلِينَ ١٣Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa fún un, ó máa wí pé: "Àwọn àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́ (nìwọ̀nyí) كـَلَّاۖ بَلۡۜ رَانَ عَلَىٰ قُلُوبِهِم مَّا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ ١٤Rárá kò rí bẹ́ẹ̀, àmọ́ ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ ibi l’ó jọba lórí ọkàn wọn كـَلَّآ إِنَّهُمۡ عَن رَّبِّهِمۡ يَوۡمَئِذٍ لَّمَحۡجُوبُونَ ١٥Ní ti òdodo, dájúdájú wọn yóò wà nínú gàgá, wọn kò sì níí rí Olúwa wọn ní ọjọ́ yẹn ثُمَّ إِنَّهُمۡ لَصَالُواْ ٱلۡجَحِيمِ ١٦Lẹ́yìn náà, dájúdájú wọn yóò wọ inú iná Jẹhīm ثُمَّ يُقَالُ هَٰذَا ٱلَّذِي كُنتُم بِهِۦ تُكَذِّبُونَ ١٧Lẹ́yìn náà, wọ́n máa sọ (fún wọn) pe: "Èyí ni ohun tí ẹ̀ ń pè nírọ́ كـَلَّآ إِنَّ كِتَٰبَ ٱلۡأَبۡرَارِ لَفِي عِلِّيِّينَ ١٨Bẹ́ẹ̀ ni. Dájúdájú ìwé iṣẹ́ àwọn ẹni rere wà nínú ‘illiyyūn وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا عِلِّيُّونَ ١٩Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ ‘illiyyūn كِتَٰبٌ مَّرۡقُومٌ ٢٠Ìwé tí wọ́n ti kọ iṣẹ́ rere ẹ̀dá sínú rẹ̀ (tí wọ́n sì fi pamọ́ sí òkè sánmọ̀ ni ‘illiyyūn) يَشۡهَدُهُ ٱلۡمُقَرَّبُونَ ٢١Àwọn (mọlāika) tí wọ́n súnmọ́ Allāhu ń jẹ́rìí sí i إِنَّ ٱلۡأَبۡرَارَ لَفِي نَعِيمٍ ٢٢Dájúdájú àwọn ẹni rere máa wà nínú ìgbádùn عَلَى ٱلۡأَرَآئِكِ يَنظُرُونَ ٢٣Wọn yóò máa wòran lórí àwọn ibùsùn تَعۡرِفُ فِي وُجُوهِهِمۡ نَضۡرَةَ ٱلنَّعِيمِ ٢٤Ìwọ yóò dá ìtutù ojú ìgbádùn mọ̀ nínú ojú wọn يُسۡقَوۡنَ مِن رَّحِيقٍ مَّخۡتُومٍ ٢٥Wọn yóò máa fún wọn mu nínú ọtí onídèérí خِتَٰمُهُۥ مِسۡكٌۚ وَفِي ذَٰلِكَ فَلۡيَتَنَافَسِ ٱلۡمُتَنَٰفِسُونَ ٢٦Àlùmísìkí ni (òórùn) ìparí rẹ̀. Kí àwọn alápàáǹtètè ṣàpáǹtètè nínú ìyẹn وَمِزَاجُهُۥ مِن تَسۡنِيمٍ ٢٧Tẹsnīm ni wọ́n yóò máa pòpọ̀ (mọ́ ọtí náà) عَيۡنًا يَشۡرَبُ بِهَا ٱلۡمُقَرَّبُونَ ٢٨(Tẹsnīm ni) omi ìṣẹ́lẹ̀rú kan, tí àwọn olùsúnmọ́ (Allāhu) yóò máa mu إِنَّ ٱلَّذِينَ أَجۡرَمُواْ كَانُواْ مِنَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ يَضۡحَكُونَ ٢٩Dájúdájú àwọn t’ó dẹ́ṣẹ̀, wọ́n máa ń fi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo rẹ́rìn-ín وَإِذَا مَرُّواْ بِهِمۡ يَتَغَامَزُونَ ٣٠Nígbà tí wọ́n bá gba ẹ̀gbẹ́ wọn kọjá, (àwọn adẹ́ṣẹ̀) yóò máa ṣẹ́jú síra wọn ní ti yẹ̀yẹ́ وَإِذَا ٱنقَلَبُوٓاْ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِمُ ٱنقَلَبُواْ فَكِهِينَ ٣١Nígbà tí wọ́n bá sì padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wọn, wọ́n á padà tí wọn yóò máa ṣe fáàrí وَإِذَا رَأَوۡهُمۡ قَالُوٓاْ إِنَّ هَٰٓؤُلَآءِ لَضَآلُّونَ ٣٢Àti pé nígbà tí wọ́n bá rí (àwọn onígbàgbọ́ òdodo) wọ́n á wí pé: "Dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni olùṣìnà وَمَآ أُرۡسِلُواْ عَلَيۡهِمۡ حَٰفِظِينَ ٣٣Àwa kò sì rán wọn níṣẹ́ olùṣọ́ sí wọn فَٱلۡيَوۡمَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مِنَ ٱلۡكُفَّارِ يَضۡحَكُونَ ٣٤Nítorí náà, ní òní àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo yóò fi àwọn aláìgbàgbọ́ rẹ́rìn-ín عَلَى ٱلۡأَرَآئِكِ يَنظُرُونَ ٣٥Wọn yóò máa wòran lórí àwọn ibùsùn هَلۡ ثُوِّبَ ٱلۡكُفَّارُ مَا كَانُواْ يَفۡعَلُونَ ٣٦Ṣebí wọ́n ti fi ohun tí àwọn aláìgbàgbọ́ ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n lẹ́san (báyìí)

الترجمة: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.