ملة الإسلام

السورة 70 · 44 آية · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

سورة المعارج باللغة اليوروبا

السورة بالعربية مع التفسير استمع إلى سورة المعارج (1,289 قارئاً)
مكيةسورة المعارج٤٤ آية

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

سَأَلَ سَآئِلُۢ بِعَذَابٍ وَاقِعٍ ١Oníbèéèrè kan bèèrè nípa ìyà t’ó máa ṣẹlẹ̀ لِّلۡكَٰفِرِينَ لَيۡسَ لَهُۥ دَافِعٌ ٢sí àwọn aláìgbàgbọ́. Kò sì sí ẹni tí ó máa dí i lọ́wọ́ مِّنَ ٱللَّهِ ذِي ٱلۡمَعَارِجِ ٣lọ́dọ̀ Allāhu, Onípò-àyè gíga تَعۡرُجُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ وَٱلرُّوحُ إِلَيۡهِ فِي يَوۡمٍ كَانَ مِقۡدَارُهُۥ خَمۡسِينَ أَلۡفَ سَنَةٍ ٤Àwọn mọlāika àti mọlāika Jibrīl ń gùnkè wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nínú ọjọ́ kan tí òdiwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ (tí ẹ bá fẹ́ rìn ín) فَٱصۡبِرۡ صَبۡرًا جَمِيلًا ٥Nítorí náà, ṣe sùúrù ní sùúrù t’ó rẹwà إِنَّهُمۡ يَرَوۡنَهُۥ بَعِيدًا ٦Dájúdájú wọ́n ń wo (ìyà náà) ní ohun t’ó jìnnà وَنَرَىٰهُ قَرِيبًا ٧A sì ń wò ó ní ohun t’ó súnmọ́ يَوۡمَ تَكُونُ ٱلسَّمَآءُ كَٱلۡمُهۡلِ ٨(Ọjọ́ náà ni) ọjọ́ tí sánmọ̀ yó dà bí idẹ t’ó yọ́ وَتَكُونُ ٱلۡجِبَالُ كَٱلۡعِهۡنِ ٩àwọn àpáta yó sì dà bí ẹ̀gbọ̀n òwú-irun وَلَا يَسۡـَٔلُ حَمِيمٌ حَمِيمًا ١٠ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan kò sì níí bèèrè ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ (rẹ̀) يُبَصَّرُونَهُمۡۚ يَوَدُّ ٱلۡمُجۡرِمُ لَوۡ يَفۡتَدِي مِنۡ عَذَابِ يَوۡمِئِذِۭ بِبَنِيهِ ١١Wọ́n máa rí ara wọn (wọ́n sì máa dára wọn mọ̀). Ẹlẹ́ṣẹ̀ sì máa fẹ́ kí òun fi àwọn ọmọ rẹ̀ ṣèràpadà ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Ìyà ní ọjọ́ yẹn وَصَٰحِبَتِهِۦ وَأَخِيهِ ١٢Ìyàwó rẹ̀ àti arákùnrin rẹ̀ وَفَصِيلَتِهِ ٱلَّتِي تُـٔۡوِيهِ ١٣àti àwọn ẹbí rẹ̀ t’ó pa tì, tí àwọn sì ń gbà á sọ́dọ̀ nílé ayé وَمَن فِي ٱلۡأَرۡضِ جَمِيعًا ثُمَّ يُنجِيهِ ١٤àti gbogbo ẹni t’ó wà lórí ilẹ̀ ayé pátápátá, (ó máa fẹ́ fi wọ́n ṣèràpadà ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Ìyà). Lẹ́yìn náà, (ó máa fẹ́) kí Allāhu gba òun là (nínú ìyà Iná) كـَلَّآۖ إِنَّهَا لَظَىٰ ١٥Rárá! Dájúdájú (ó máa wọ) iná Laṭḥọ̄ (iná t’ó ń jò fòfò) نَزَّاعَةً لِّلشَّوَىٰ ١٦Ó máa bó awọ orí tòró تَدۡعُواْ مَنۡ أَدۡبَرَ وَتَوَلَّىٰ ١٧(Iná) yó máa ké sí ẹni t’ó kẹ̀yìn sí (ìgbágbọ́ òdodo), tí ó sì takété sí i وَجَمَعَ فَأَوۡعَىٰٓ ١٨ó kó (ọrọ̀) jọ, ó sì fi pamọ́ (kò ná an fún ẹ̀sìn) ۞ إِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ خُلِقَ هَلُوعًا ١٩Dájúdájú ènìyàn, A ṣẹ̀dá rẹ̀ ní aláìlọ́kàn, ọ̀kánjúà إِذَا مَسَّهُ ٱلشَّرُّ جَزُوعًا ٢٠Nígbà tí aburú bá fọwọ́ bà á, ó máa kanra gógó وَإِذَا مَسَّهُ ٱلۡخَيۡرُ مَنُوعًا ٢١Nígbà tí ọwọ́ rẹ̀ bá sì tẹ oore, ó máa yahun إِلَّا ٱلۡمُصَلِّينَ ٢٢Àyàfi àwọn olùkírun ٱلَّذِينَ هُمۡ عَلَىٰ صَلَاتِهِمۡ دَآئِمُونَ ٢٣àwọn olùdúnnímọ́ ìrun wọn وَٱلَّذِينَ فِيٓ أَمۡوَٰلِهِمۡ حَقٌّ مَّعۡلُومٌ ٢٤àwọn t’ó mọ ojúṣe (wọn) nínú dúkìá wọn لِّلسَّآئِلِ وَٱلۡمَحۡرُومِ ٢٥sí alágbe àti ẹni tí A ṣe arísìkí ní èèwọ̀ fún وَٱلَّذِينَ يُصَدِّقُونَ بِيَوۡمِ ٱلدِّينِ ٢٦àwọn t’ó ń gba ọjọ́ ẹ̀san gbọ́ ní òdodo وَٱلَّذِينَ هُم مِّنۡ عَذَابِ رَبِّهِم مُّشۡفِقُونَ ٢٧àwọn t’ó ń páyà ìyà Olúwa wọn إِنَّ عَذَابَ رَبِّهِمۡ غَيۡرُ مَأۡمُونٍ ٢٨dájúdájú ìyà Olúwa wọn kò ṣeé fàyàbalẹ̀ sí وَٱلَّذِينَ هُمۡ لِفُرُوجِهِمۡ حَٰفِظُونَ ٢٩àwọn t’ó ń ṣọ́ abẹ́ wọn إِلَّا عَلَىٰٓ أَزۡوَٰجِهِمۡ أَوۡ مَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُهُمۡ فَإِنَّهُمۡ غَيۡرُ مَلُومِينَ ٣٠àyàfi lọ́dọ̀ àwọn ìyàwó wọn tàbí ẹrúbìnrin wọn ni wọn kò ti lè jẹ́ ẹni-èébú فَمَنِ ٱبۡتَغَىٰ وَرَآءَ ذَٰلِكَ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡعَادُونَ ٣١nítorí náà, ẹni kẹ́ni t’ó bá ń wá n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olùtayọ-ẹnu àlà وَٱلَّذِينَ هُمۡ لِأَمَٰنَٰتِهِمۡ وَعَهۡدِهِمۡ رَٰعُونَ ٣٢àwọn t’ó ń ṣọ́ àgbàfipamọ́ wọn àti àdéhùn wọn وَٱلَّذِينَ هُم بِشَهَٰدَٰتِهِمۡ قَآئِمُونَ ٣٣àwọn t’ó ń dúró ti ìjẹ́rìí wọn وَٱلَّذِينَ هُمۡ عَلَىٰ صَلَاتِهِمۡ يُحَافِظُونَ ٣٤àti àwọn t’ó ń ṣọ́ àwọn ìrun wọn أُوْلَٰٓئِكَ فِي جَنَّٰتٍ مُّكۡرَمُونَ ٣٥Àwọn wọ̀nyẹn ni alápọ̀n-ọ́nlé nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra فَمَالِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ قِبَلَكَ مُهۡطِعِينَ ٣٦Kí ló mú àwọn tí kò gbàgbọ́ tí ara wọn kò balẹ̀ níwájú rẹ عَنِ ٱلۡيَمِينِ وَعَنِ ٱلشِّمَالِ عِزِينَ ٣٧tí wọ́n sì jókòó ní ìsọ̀rí ìsọ̀rí sí ọwọ́ ọ̀tún àti ọwọ́ òsì (rẹ) أَيَطۡمَعُ كُلُّ ٱمۡرِيٍٕ مِّنۡهُمۡ أَن يُدۡخَلَ جَنَّةَ نَعِيمٍ ٣٨Ṣé ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú wọn ń jẹ̀rankàn pé A óò mú òun wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra ni كـَلَّآۖ إِنَّا خَلَقۡنَٰهُم مِّمَّا يَعۡلَمُونَ ٣٩Rárá o! Dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá wọn láti inú ohun tí wọ́n mọ̀ فَلَآ أُقۡسِمُ بِرَبِّ ٱلۡمَشَٰرِقِ وَٱلۡمَغَٰرِبِ إِنَّا لَقَٰدِرُونَ ٤٠Nítorí náà, Èmi ń búra pẹ̀lú Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn àti àwọn ibùwọ̀ òòrùn , dájúdájú Àwa ni Alágbára عَلَىٰٓ أَن نُّبَدِّلَ خَيۡرًا مِّنۡهُمۡ وَمَا نَحۡنُ بِمَسۡبُوقِينَ ٤١láti lè fi àwọn t’ó dára jù wọ́n lọ pààrọ̀ wọn. Kò sì sí ẹni t’ó lè kó agara bá Wa فَذَرۡهُمۡ يَخُوضُواْ وَيَلۡعَبُواْ حَتَّىٰ يُلَٰقُواْ يَوۡمَهُمُ ٱلَّذِي يُوعَدُونَ ٤٢Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa sọ ìsọkúsọ (wọn), kí wọ́n sì máa ṣeré títí wọn yóò fi pàdé ọjọ́ wọn tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn يَوۡمَ يَخۡرُجُونَ مِنَ ٱلۡأَجۡدَاثِ سِرَاعًا كَأَنَّهُمۡ إِلَىٰ نُصُبٍ يُوفِضُونَ ٤٣Ọjọ́ tí wọn yóò sáré jáde wéréwéré láti inú àwọn sàréè, wọn yó sì dà bí ẹni pé wọ́n ń yára lọ sídìí ohun àfojúsùn kan خَٰشِعَةً أَبۡصَٰرُهُمۡ تَرۡهَقُهُمۡ ذِلَّةٌۚ ذَٰلِكَ ٱلۡيَوۡمُ ٱلَّذِي كَانُواْ يُوعَدُونَ ٤٤Ojú wọn yóò wálẹ̀. Ìyẹpẹrẹ máa bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ọjọ́ yẹn ni èyí tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn

الترجمة: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.