بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
ٱلۡحَآقَّةُ ١Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo مَا ٱلۡحَآقَّةُ ٢Kí ni Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا ٱلۡحَآقَّةُ ٣Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo كَذَّبَتۡ ثَمُودُ وَعَادُۢ بِٱلۡقَارِعَةِ ٤Àwọn ìjọ Thamūd àti ìjọ ‘Ād pe Ìpáyà nírọ́ فَأَمَّا ثَمُودُ فَأُهۡلِكُواْ بِٱلطَّاغِيَةِ ٥Ní ti ìjọ Thamūd, wọ́n fi igbe t’ó tayọ ẹnu-àlà pa wọ́n rẹ́ وَأَمَّا عَادٌ فَأُهۡلِكُواْ بِرِيحٍ صَرۡصَرٍ عَاتِيَةٍ ٦Ní ti ìjọ ‘Ād, wọ́n fi atẹ́gùn líle t’ó tayọ ẹnu-àlà pa wọ́n rẹ́ سَخَّرَهَا عَلَيۡهِمۡ سَبۡعَ لَيَالٍ وَثَمَٰنِيَةَ أَيَّامٍ حُسُومًاۖ فَتَرَى ٱلۡقَوۡمَ فِيهَا صَرۡعَىٰ كَأَنَّهُمۡ أَعۡجَازُ نَخۡلٍ خَاوِيَةٍ ٧Ó dẹ ẹ́ sí wọn fún òru méje àti ọ̀sán mẹ́jọ láì dáwọ́ dúró. O sì máa rí ìjọ náà tí wọ́n ti kú sínú rẹ̀ bí ẹni pé kùkùté igi dàbínù t’ó ti luhò nínú ni wọ́n فَهَلۡ تَرَىٰ لَهُم مِّنۢ بَاقِيَةٍ ٨Ǹjẹ́ o rí ẹnì kan nínú wọn t’ó ṣẹ́ kù bí وَجَآءَ فِرۡعَوۡنُ وَمَن قَبۡلَهُۥ وَٱلۡمُؤۡتَفِكَٰتُ بِٱلۡخَاطِئَةِ ٩Fir‘aon àti àwọn t’ó ṣíwájú rẹ̀ àti àwọn ìlú tí wọ́n dojú rẹ̀ bolẹ̀ dé pẹ̀lú àwọn àṣìṣe فَعَصَوۡاْ رَسُولَ رَبِّهِمۡ فَأَخَذَهُمۡ أَخۡذَةً رَّابِيَةً ١٠Wọ́n yapa Òjíṣẹ́ Olúwa wọn. Ó sì gbá wọn mú ní ìgbámú àlékún إِنَّا لَمَّا طَغَا ٱلۡمَآءُ حَمَلۡنَٰكُمۡ فِي ٱلۡجَارِيَةِ ١١Dájúdájú nígbà tí omi tayọ ẹnu-àlà. A gbe yín gun ọkọ̀ ojú-omi لِنَجۡعَلَهَا لَكُمۡ تَذۡكِرَةً وَتَعِيَهَآ أُذُنٌ وَٰعِيَةٌ ١٢Nítorí kí Á lè fi ṣe ìrántí fun yín àti nítorí kí etí t’ó ń ṣọ́ n̄ǹkan lè ṣọ́ ọ فَإِذَا نُفِخَ فِي ٱلصُّورِ نَفۡخَةٌ وَٰحِدَةٌ ١٣Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún ikú ní fífọn ẹyọ kan وَحُمِلَتِ ٱلۡأَرۡضُ وَٱلۡجِبَالُ فَدُكَّتَا دَكَّةً وَٰحِدَةً ١٤tí wọ́n gbé ilẹ̀ àti àpáta sókè, tí wọ́n sì rún méjèèjì wómúwómú ní rírún ẹ̀ẹ̀ kan فَيَوۡمَئِذٍ وَقَعَتِ ٱلۡوَاقِعَةُ ١٥ní ọjọ́ yẹn ni Ìṣẹ̀lẹ̀ máa ṣẹlẹ̀ وَٱنشَقَّتِ ٱلسَّمَآءُ فَهِيَ يَوۡمَئِذٍ وَاهِيَةٌ ١٦Àti pé sánmọ̀ yó fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Ó sì máa fúyẹ́ gẹgẹ ní ọjọ́ yẹn وَٱلۡمَلَكُ عَلَىٰٓ أَرۡجَآئِهَاۚ وَيَحۡمِلُ عَرۡشَ رَبِّكَ فَوۡقَهُمۡ يَوۡمَئِذٍ ثَمَٰنِيَةٌ ١٧Àwọn mọlāika sì máa wà ní àwọn ẹ̀gbẹ́ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àti pé ní ọjọ́ yẹn, lókè wọn, àwọn (mọlāika) mẹ́jọ ni wọ́n máa ru Ìtẹ́ Olúwa rẹ يَوۡمَئِذٍ تُعۡرَضُونَ لَا تَخۡفَىٰ مِنكُمۡ خَافِيَةٌ ١٨Ní ọjọ́ yẹn, wọn yóò máa ṣẹ́rí yín wá (fún ìṣírò-iṣẹ́). Kò sì níí sí àṣírí yín kan t’ó máa pamọ́ (fún Wa) فَأَمَّا مَنۡ أُوتِيَ كِتَٰبَهُۥ بِيَمِينِهِۦ فَيَقُولُ هَآؤُمُ ٱقۡرَءُواْ كِتَٰبِيَهۡ ١٩Nítorí náà, ní ti ẹni tí wọ́n bá fún ní tírà rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ó máa sọ pé: "Ẹ gbà, ẹ ka tírà mi إِنِّي ظَنَنتُ أَنِّي مُلَٰقٍ حِسَابِيَهۡ ٢٠Dájúdájú èmi ti mọ àmọ̀dájú pé dájúdájú èmi yóò bá ìṣírò-iṣẹ́ mi pàdé فَهُوَ فِي عِيشَةٍ رَّاضِيَةٍ ٢١Nítorí náà, ó máa wà nínú ìṣẹ̀mí t’ó máa yọ́nú sí فِي جَنَّةٍ عَالِيَةٍ ٢٢nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra gíga قُطُوفُهَا دَانِيَةٌ ٢٣Àwọn èso rẹ̀ (sì) wà ní àrọ́wọ́tó كُلُواْ وَٱشۡرَبُواْ هَنِيٓـَٔۢا بِمَآ أَسۡلَفۡتُمۡ فِي ٱلۡأَيَّامِ ٱلۡخَالِيَةِ ٢٤Ẹ jẹ, kí ẹ sì mu pẹ̀lú ìgbàdún nítorí ohun tí ẹ tì síwájú nínú àwọn ọjọ́ tí ó ti ré kọjá وَأَمَّا مَنۡ أُوتِيَ كِتَٰبَهُۥ بِشِمَالِهِۦ فَيَقُولُ يَٰلَيۡتَنِي لَمۡ أُوتَ كِتَٰبِيَهۡ ٢٥Ní ti ẹni tí wọ́n bá sì fún ní tírà rẹ̀ ní ọwọ́ òsì rẹ̀, ó máa wí pé: "Háà! Kí wọ́n sì má fún mi ni tírà mi! méjéèjì ló máa ṣẹlẹ̀ sí wọn nítorí pé ọwọ́ òsì ni aláìgbàgbọ́ máa tì bọ inú igbá-àyà rẹ̀ bọ́ sí ẹ̀yìn rẹ̀ láti fi gba ìwé iṣẹ́ rẹ̀ وَلَمۡ أَدۡرِ مَا حِسَابِيَهۡ ٢٦Àti pé èmi kò mọ ohun tí ìṣírò-iṣẹ́ mi jẹ́ يَٰلَيۡتَهَا كَانَتِ ٱلۡقَاضِيَةَ ٢٧Háà! Kí ikú sì jẹ́ òpin (ọ̀rọ̀ ẹ̀dá) مَآ أَغۡنَىٰ عَنِّي مَالِيَهۡۜ ٢٨Dúkìá mi kò sì rọ̀ mí lọ́rọ̀ هَلَكَ عَنِّي سُلۡطَٰنِيَهۡ ٢٩Agbára mi sì ti parun خُذُوهُ فَغُلُّوهُ ٣٠Ẹ mú un, kí ẹ dè é ní ọwọ́ mọ́ ọrùn ثُمَّ ٱلۡجَحِيمَ صَلُّوهُ ٣١Lẹ́yìn náà, inú iná Jẹhīm ni kí ẹ mú un wọ̀ ثُمَّ فِي سِلۡسِلَةٍ ذَرۡعُهَا سَبۡعُونَ ذِرَاعًا فَٱسۡلُكُوهُ ٣٢Lẹ́yìn náà, inú ẹ̀wọ̀n tí gígùn rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin gígùn thar‘u ni kí ẹ kì í sí إِنَّهُۥ كَانَ لَا يُؤۡمِنُ بِٱللَّهِ ٱلۡعَظِيمِ ٣٣Dájúdájú òun kì í gbàgbọ́ nínú Allāhu, Atóbi وَلَا يَحُضُّ عَلَىٰ طَعَامِ ٱلۡمِسۡكِينِ ٣٤Kì í sì gba ènìyàn níyànjú láti bọ́ àwọn mẹ̀kúnnù فَلَيۡسَ لَهُ ٱلۡيَوۡمَ هَٰهُنَا حَمِيمٌ ٣٥Nítorí náà, kò níí sí ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan fún un níbí yìí ní òní وَلَا طَعَامٌ إِلَّا مِنۡ غِسۡلِينٍ ٣٦Kò sì níí sí oúnjẹ kan (fún un) bí kò ṣe (oúnjẹ) àwọyúnwẹ̀jẹ̀ لَّا يَأۡكُلُهُۥٓ إِلَّا ٱلۡخَٰطِـُٔونَ ٣٧Kò sí ẹni tí ó máa jẹ ẹ́ bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ فَلَآ أُقۡسِمُ بِمَا تُبۡصِرُونَ ٣٨Nítorí náà, Èmi ń búra pẹ̀lú ohun tí ẹ̀ ń fojú rí وَمَا لَا تُبۡصِرُونَ ٣٩àti ohun tí ẹ ò fojú rí إِنَّهُۥ لَقَوۡلُ رَسُولٍ كَرِيمٍ ٤٠Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ọ̀rọ̀ (tí A fi rán) Òjíṣẹ́, alápọ̀n-ọ́nlé وَمَا هُوَ بِقَوۡلِ شَاعِرٍۚ قَلِيلًا مَّا تُؤۡمِنُونَ ٤١Kì í ṣe ọ̀rọ̀ eléwì. Ohun tí ẹ gbàgbọ́ kéré púpọ̀ وَلَا بِقَوۡلِ كَاهِنٍۚ قَلِيلًا مَّا تَذَكَّرُونَ ٤٢Kì í sì ṣe ọ̀rọ̀ adábigba. Díẹ̀ lẹ̀ ń lò nínú ìrántí تَنزِيلٌ مِّن رَّبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ ٤٣Wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá وَلَوۡ تَقَوَّلَ عَلَيۡنَا بَعۡضَ ٱلۡأَقَاوِيلِ ٤٤Tí ó bá jẹ́ pé (Ànábì) dá àdápa apá kan ọ̀rọ̀ náà mọ́ Wa ni لَأَخَذۡنَا مِنۡهُ بِٱلۡيَمِينِ ٤٥Àwa ìbá gbá a mú lọ́wọ́ ọ̀tún ثُمَّ لَقَطَعۡنَا مِنۡهُ ٱلۡوَتِينَ ٤٦Lẹ́yìn náà, Àwa ìbá já isan ọrùn rẹ̀ فَمَا مِنكُم مِّنۡ أَحَدٍ عَنۡهُ حَٰجِزِينَ ٤٧Kò sì sí ẹnì kan nínú yín tí ó máa gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ (Wa) وَإِنَّهُۥ لَتَذۡكِرَةٌ لِّلۡمُتَّقِينَ ٤٨Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni ìrántí fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) وَإِنَّا لَنَعۡلَمُ أَنَّ مِنكُم مُّكَذِّبِينَ ٤٩Dájúdájú Àwa sì mọ̀ pé àwọn t’ó ń pe al-Ƙur’ān nírọ́ wà nínú yín وَإِنَّهُۥ لَحَسۡرَةٌ عَلَى ٱلۡكَٰفِرِينَ ٥٠Dájúdájú al-Ƙur’ān máa jẹ́ àbámọ̀ fún àwọn aláìgbàgbọ́ وَإِنَّهُۥ لَحَقُّ ٱلۡيَقِينِ ٥١Dájúdájú al-Ƙur’ān ni òdodo t’ó dájú فَسَبِّحۡ بِٱسۡمِ رَبِّكَ ٱلۡعَظِيمِ ٥٢Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa Rẹ, Atóbi