ملة الإسلام

السورة 74 · 56 آية · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

سورة المدثر باللغة اليوروبا

السورة بالعربية مع التفسير استمع إلى سورة المدثر (1,220 قارئاً)
مكيةسورة المدثر٥٦ آية

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

يَٰٓأَيُّهَا ٱلۡمُدَّثِّرُ ١Ìwọ olùdaṣọbora قُمۡ فَأَنذِرۡ ٢Dìde kí o ṣèkìlọ̀ وَرَبَّكَ فَكَبِّرۡ ٣Olúwa rẹ sì ni kí o gbé títóbi fún وَثِيَابَكَ فَطَهِّرۡ ٤Aṣọ rẹ ni kí o fọ̀ mọ́ وَٱلرُّجۡزَ فَٱهۡجُرۡ ٥Òrìṣà ni kí o jìnnà sí وَلَا تَمۡنُن تَسۡتَكۡثِرُ ٦Má ṣe tọrẹ nítorí kí o lè rí púpọ̀ gbà وَلِرَبِّكَ فَٱصۡبِرۡ ٧Olúwa rẹ ni kí o ṣe sùúrù fún فَإِذَا نُقِرَ فِي ٱلنَّاقُورِ ٨Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún àjíǹde فَذَٰلِكَ يَوۡمَئِذٍ يَوۡمٌ عَسِيرٌ ٩ìyẹn, ní ọjọ́ yẹn, ni ọjọ́ ìnira عَلَى ٱلۡكَٰفِرِينَ غَيۡرُ يَسِيرٍ ١٠tí kò níí rọrùn fún àwọn aláìgbàgbọ́ ذَرۡنِي وَمَنۡ خَلَقۡتُ وَحِيدًا ١١Fi Mí dá ẹni tí Mo dá ní òun nìkan وَجَعَلۡتُ لَهُۥ مَالًا مَّمۡدُودًا ١٢Mo sì fún un ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ dúkìá وَبَنِينَ شُهُودًا ١٣àti àwọn ọmọkúnrin t’ó ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ وَمَهَّدتُّ لَهُۥ تَمۡهِيدًا ١٤Mo sì ṣe ayé nírọ̀rùn fún un gan-an ثُمَّ يَطۡمَعُ أَنۡ أَزِيدَ ١٥Lẹ́yìn náà, ó tún ń jẹ̀rankàn pé kí N̄g ṣe àlékún كـَلَّآۖ إِنَّهُۥ كَانَ لِأٓيَٰتِنَا عَنِيدًا ١٦Rárá o! Dájúdájú ó jẹ́ alátakò sí àwọn āyah Wa سَأُرۡهِقُهُۥ صَعُودًا ١٧Èmi yóò la ìyà pọ́nkèpọ́nkè bọ̀ ọ́ lọ́rùn (nínú Iná) إِنَّهُۥ فَكَّرَ وَقَدَّرَ ١٨Dájúdájú ó ronú (lódì nípa al-Ƙur’ān). Ó sì pinnu (ọ̀rọ̀ kan nínú ẹ̀mí rẹ̀) فَقُتِلَ كَيۡفَ قَدَّرَ ١٩Wọ́n sì ṣẹ́bi lé e nípa bí ó ṣe pinnu ثُمَّ قُتِلَ كَيۡفَ قَدَّرَ ٢٠Lẹ́yìn náà, Wọ́n tún ṣẹ́bi lé e nípa bí ó ṣe pinnu ثُمَّ نَظَرَ ٢١Lẹ́yìn náà, ó wò sùn ثُمَّ عَبَسَ وَبَسَرَ ٢٢Lẹ́yìn náà, ó fajú ro, ó sì dijú mágbárí ثُمَّ أَدۡبَرَ وَٱسۡتَكۡبَرَ ٢٣Lẹ́yìn náà, ó pẹ̀yìn dà, ó sì ṣègbéraga فَقَالَ إِنۡ هَٰذَآ إِلَّا سِحۡرٌ يُؤۡثَرُ ٢٤Ó sì wí pé: "Kí ni èyí bí kò ṣe idán àtọwọ́dọ́wọ́ إِنۡ هَٰذَآ إِلَّا قَوۡلُ ٱلۡبَشَرِ ٢٥Kí ni èyí bí kò ṣe ọ̀rọ̀ abara سَأُصۡلِيهِ سَقَرَ ٢٦Èmi yóò fi sínú iná Saƙọr وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا سَقَرُ ٢٧Kí l’ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ iná Saƙọr لَا تُبۡقِي وَلَا تَذَرُ ٢٨(Saƙọr) kò níí ṣẹ́ ẹ kù, kò sì níí pa á tì لَوَّاحَةٌ لِّلۡبَشَرِ ٢٩Ó máa jó awọ ara di dúdú عَلَيۡهَا تِسۡعَةَ عَشَرَ ٣٠(Àwọn mọlāika) mọ́kàndínlógún ni ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ وَمَا جَعَلۡنَآ أَصۡحَٰبَ ٱلنَّارِ إِلَّا مَلَٰٓئِكَةًۖ وَمَا جَعَلۡنَا عِدَّتَهُمۡ إِلَّا فِتۡنَةً لِّلَّذِينَ كَفَرُواْ لِيَسۡتَيۡقِنَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ وَيَزۡدَادَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِيمَٰنًا وَلَا يَرۡتَابَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡمُؤۡمِنُونَ وَلِيَقُولَ ٱلَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٌ وَٱلۡكَٰفِرُونَ مَاذَآ أَرَادَ ٱللَّهُ بِهَٰذَا مَثَلًاۚ كَذَٰلِكَ يُضِلُّ ٱللَّهُ مَن يَشَآءُ وَيَهۡدِي مَن يَشَآءُۚ وَمَا يَعۡلَمُ جُنُودَ رَبِّكَ إِلَّا هُوَۚ وَمَا هِيَ إِلَّا ذِكۡرَىٰ لِلۡبَشَرِ ٣١Àwa kò ṣe ẹnì kan ní ẹ̀ṣọ́ Iná àfi àwọn mọlāika. Àwa kò sì ṣe òǹkà wọn (bẹ́ẹ̀) bí kò ṣe (nítorí kí ó lè jẹ́) àdánwò fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, àti nítorí kí àwọn tí A fún ní Tírà lè ní àmọ̀dájú àti nítorí kí àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ ní òdodo lè lékún ní ìgbàgbọ́ òdodo. (Ó rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí àwọn tí A fún ní Tírà àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo má baà ṣeyèméjì àti nítorí kí àwọn tí àrùn wà nínú ọkàn wọn àti àwọn aláìgbàgbọ́ lè wí pé: "Kí ni Allāhu gbà lérò pẹ̀lú àpèjúwe yìí?" Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà, Ó sì ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sọ́nà. Kò sì sí ẹni tí ó mọ àwọn ọmọ ogun Olúwa rẹ̀ àfi Òun náà. (Iná Saƙọr) kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ìrántí fún abara كـَلَّا وَٱلۡقَمَرِ ٣٢Ẹ gbọ́! Allāhu búra pẹ̀lú òṣùpá وَٱلَّيۡلِ إِذۡ أَدۡبَرَ ٣٣Ó tún búra pẹ̀lú alẹ́ nígbà tí ó bá lọ وَٱلصُّبۡحِ إِذَآ أَسۡفَرَ ٣٤Ó tún búra pẹ̀lú òwúrọ̀ nígbà tí ojúmọ́ bá mọ́ إِنَّهَا لَإِحۡدَى ٱلۡكُبَرِ ٣٥Dájúdájú (iná Saƙọr) ni ọ̀kan nínú (àwọn àdánwò) t’ó tóbi نَذِيرًا لِّلۡبَشَرِ ٣٦(Ó jẹ́) ìkìlọ̀ fún abara لِمَن شَآءَ مِنكُمۡ أَن يَتَقَدَّمَ أَوۡ يَتَأَخَّرَ ٣٧Fún ẹni tí ó bá fẹ́ nínú yín láti tẹ̀ síwájú tàbí láti fà sẹ́yìn كُلُّ نَفۡسِۭ بِمَا كَسَبَتۡ رَهِينَةٌ ٣٨Ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ni onídùúró fún ohun t’ó ṣe níṣẹ́ إِلَّآ أَصۡحَٰبَ ٱلۡيَمِينِ ٣٩Àyàfi àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún فِي جَنَّٰتٍ يَتَسَآءَلُونَ ٤٠Wọn yóò máa bira wọn léèrè ọ̀rọ̀ nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra عَنِ ٱلۡمُجۡرِمِينَ ٤١nípa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pé مَا سَلَكَكُمۡ فِي سَقَرَ ٤٢Kí ni ó mu yín wọ inú iná Saƙọr قَالُواْ لَمۡ نَكُ مِنَ ٱلۡمُصَلِّينَ ٤٣Wọn yóò wí pé: "Àwa kò sí nínú àwọn olùkírun ni وَلَمۡ نَكُ نُطۡعِمُ ٱلۡمِسۡكِينَ ٤٤Àwa kò sì sí nínú àwọn t’ó ń bọ́ àwọn mẹ̀kúnnù وَكُنَّا نَخُوضُ مَعَ ٱلۡخَآئِضِينَ ٤٥Àwa sì máa ń sọ ìsọkúsọ pẹ̀lú àwọn onísọkúsọ وَكُنَّا نُكَذِّبُ بِيَوۡمِ ٱلدِّينِ ٤٦Àti pé àwa máa ń pe Ọjọ́ ẹ̀san nírọ́ حَتَّىٰٓ أَتَىٰنَا ٱلۡيَقِينُ ٤٧títí ikú fi dé bá wa فَمَا تَنفَعُهُمۡ شَفَٰعَةُ ٱلشَّٰفِعِينَ ٤٨Ìpẹ̀ àwọn olùṣìpẹ̀ kò sì níí ṣe wọ́n ní àǹfààní فَمَا لَهُمۡ عَنِ ٱلتَّذۡكِرَةِ مُعۡرِضِينَ ٤٩Kí ló mú wọn ná tí wọ́n ń gbúnrí kúrò níbi ìrántí كَأَنَّهُمۡ حُمُرٌ مُّسۡتَنفِرَةٌ ٥٠bí ẹni pé àwọn ni kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ t’ó ń sá lọ فَرَّتۡ مِن قَسۡوَرَةِۭ ٥١t’ó sá fún kìnìhún بَلۡ يُرِيدُ كُلُّ ٱمۡرِيٍٕ مِّنۡهُمۡ أَن يُؤۡتَىٰ صُحُفًا مُّنَشَّرَةً ٥٢Rárá, ńṣe ni ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú wọn ń fẹ́ kí Á fún òun náà ní Tírà tí ó máa ṣeé tẹ́ han àwọn ènìyàn (bíi ti al-Ƙur’ān) كـَلَّاۖ بَل لَّا يَخَافُونَ ٱلۡأٓخِرَةَ ٥٣Rárá. Wọn kò páyà ọ̀run ni كـَلَّآ إِنَّهُۥ تَذۡكِرَةٌ ٥٤Ẹ gbọ́! Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ìrántí فَمَن شَآءَ ذَكَرَهُۥ ٥٥Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kó rántí rẹ̀ وَمَا يَذۡكُرُونَ إِلَّآ أَن يَشَآءَ ٱللَّهُۚ هُوَ أَهۡلُ ٱلتَّقۡوَىٰ وَأَهۡلُ ٱلۡمَغۡفِرَةِ ٥٦Wọn kò sì níí rántí (al-Ƙur’ān) àfi tí Allāhu bá fẹ́. (Allāhu) Òun l’a gbọ́dọ̀ bẹ̀rù. Òun l’ó sì làforíjìn

الترجمة: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.