ملة الإسلام

السورة 75 · 40 آية · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

سورة القيامة باللغة اليوروبا

السورة بالعربية مع التفسير استمع إلى سورة القيامة (1,389 قارئاً)
مكيةسورة القيامة٤٠ آية

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

لَآ أُقۡسِمُ بِيَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِ ١Èmi (Allāhu) ń búra pẹ̀lú Ọjọ́ Àjíǹde وَلَآ أُقۡسِمُ بِٱلنَّفۡسِ ٱللَّوَّامَةِ ٢Mo tún ń búra pẹ̀lú ẹ̀mí t’ó máa dára rẹ̀ lẹ́bi أَيَحۡسَبُ ٱلۡإِنسَٰنُ أَلَّن نَّجۡمَعَ عِظَامَهُۥ ٣Ṣé ènìyàn lérò pé A ò níí kó àwọn eegun rẹ̀ jọ ni بَلَىٰ قَٰدِرِينَ عَلَىٰٓ أَن نُّسَوِّيَ بَنَانَهُۥ ٤Rárá o. A lágbára láti to eegun ọmọníka rẹ̀ dọ́gba بَلۡ يُرِيدُ ٱلۡإِنسَٰنُ لِيَفۡجُرَ أَمَامَهُۥ ٥Ṣùgbọ́n ènìyàn gbèrò láti pe (Ọjọ́ Àjíǹde) t’ó ń bẹ níwájú rẹ̀ nírọ́ يَسۡـَٔلُ أَيَّانَ يَوۡمُ ٱلۡقِيَٰمَةِ ٦Ó ń bèèrè pé: "Ìgbà wo ni Ọjọ́ Àjíǹde فَإِذَا بَرِقَ ٱلۡبَصَرُ ٧Nígbà tí ojú bá kọ mọ̀nà وَخَسَفَ ٱلۡقَمَرُ ٨àti (nígbà) tí òṣùpá bá wọ̀ọ̀kùn وَجُمِعَ ٱلشَّمۡسُ وَٱلۡقَمَرُ ٩àti (nígbà) tí A bá pa òòrùn àti òṣùpá pọ̀ mọ́ra wọn يَقُولُ ٱلۡإِنسَٰنُ يَوۡمَئِذٍ أَيۡنَ ٱلۡمَفَرُّ ١٠ènìyàn yóò wí ní ọjọ́ yẹn pé: "Níbo ni ibùsásí wà كـَلَّا لَا وَزَرَ ١١Rárá, kò sí ibùsásí إِلَىٰ رَبِّكَ يَوۡمَئِذٍ ٱلۡمُسۡتَقَرُّ ١٢Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni ibùdúró ní ọjọ́ yẹn يُنَبَّؤُاْ ٱلۡإِنسَٰنُ يَوۡمَئِذِۭ بِمَا قَدَّمَ وَأَخَّرَ ١٣Wọ́n máa fún ènìyàn ní ìró ní ọjọ́ yẹn nípa ohun t’ó tì síwájú (nínú iṣẹ́ rẹ̀) àti ohun t’ó fi kẹ́yìn (nínú orípa iṣẹ́ rẹ̀) بَلِ ٱلۡإِنسَٰنُ عَلَىٰ نَفۡسِهِۦ بَصِيرَةٌ ١٤Ṣebí ènìyàn dá ara rẹ̀ mọ̀ وَلَوۡ أَلۡقَىٰ مَعَاذِيرَهُۥ ١٥ìbáà mú àwọn àwáwí rẹ̀ wá لَا تُحَرِّكۡ بِهِۦ لِسَانَكَ لِتَعۡجَلَ بِهِۦٓ ١٦Má ṣe gbé ahọ́n rẹ sí ìmísí láti kánjú ké e إِنَّ عَلَيۡنَا جَمۡعَهُۥ وَقُرۡءَانَهُۥ ١٧Dájúdájú Àwa l’A máa ṣe ìkójọ rẹ̀ (sínú ọkàn rẹ) àti kíké rẹ̀ فَإِذَا قَرَأۡنَٰهُ فَٱتَّبِعۡ قُرۡءَانَهُۥ ١٨Nígbà tí A bá ń ké e (fún ọ), kí o sì máa tẹ̀lé kíké rẹ̀ ثُمَّ إِنَّ عَلَيۡنَا بَيَانَهُۥ ١٩Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa l’A máa ṣe àlàyé rẹ̀ fún ọ كـَلَّا بَلۡ تُحِبُّونَ ٱلۡعَاجِلَةَ ٢٠Ẹ gbọ́! Ńṣe l’ẹ nífẹ̀ẹ́ ayé وَتَذَرُونَ ٱلۡأٓخِرَةَ ٢١Ẹ sì ń pa ọ̀run tì وُجُوهٌ يَوۡمَئِذٍ نَّاضِرَةٌ ٢٢Àwọn ojú kan ní ọjọ́ yẹn yóò tutù (fún ìdùnnú) إِلَىٰ رَبِّهَا نَاظِرَةٌ ٢٣Olúwa wọn ni wọn yóò máa wò وَوُجُوهٌ يَوۡمَئِذِۭ بَاسِرَةٌ ٢٤Àwọn ojú kan ní ọjọ́ yẹn sì máa bàjẹ́ تَظُنُّ أَن يُفۡعَلَ بِهَا فَاقِرَةٌ ٢٥(Ojú náà) yóò mọ̀ dájú pé Wọ́n máa fi aburú kan òhun كـَلَّآ إِذَا بَلَغَتِ ٱلتَّرَاقِيَ ٢٦Ẹ gbọ́! Nígbà tí ẹ̀mí bá dé gògòńgò وَقِيلَ مَنۡۜ رَاقٍ ٢٧A sì máa sọ pé: "Ǹjẹ́ ọlọ́fọ̀ pípè kan wà bí (tí ó máa gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú) وَظَنَّ أَنَّهُ ٱلۡفِرَاقُ ٢٨Ó sì máa dá a lójú pé dájúdájú ìpínyà ayé ti dé وَٱلۡتَفَّتِ ٱلسَّاقُ بِٱلسَّاقِ ٢٩Ojúgun yó sì lọ́mọ́ ojúgun إِلَىٰ رَبِّكَ يَوۡمَئِذٍ ٱلۡمَسَاقُ ٣٠Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sì ni wíwa ẹ̀dá lọ ní ọjọ́ yẹn فَلَا صَدَّقَ وَلَا صَلَّىٰ ٣١Kò kúkú gba òdodo gbọ́, kò sì kírun وَلَٰكِن كَذَّبَ وَتَوَلَّىٰ ٣٢Ṣùgbọ́n ó pe òdodo nírọ́. Ó sì kẹ̀yìn sí i ثُمَّ ذَهَبَ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِۦ يَتَمَطَّىٰٓ ٣٣Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì ń ṣe fáàrí أَوۡلَىٰ لَكَ فَأَوۡلَىٰ ٣٤Ègbé ni fún ọ, ègbé ni sẹ́ ثُمَّ أَوۡلَىٰ لَكَ فَأَوۡلَىٰٓ ٣٥Lẹ́yìn náà, ègbé ni fún ọ, ègbé sì sẹ́ أَيَحۡسَبُ ٱلۡإِنسَٰنُ أَن يُتۡرَكَ سُدًى ٣٦Ṣé ènìyàn lérò pé A máa fi òun sílẹ̀ lásán ni أَلَمۡ يَكُ نُطۡفَةً مِّن مَّنِيٍّ يُمۡنَىٰ ٣٧Ṣé kò ti jẹ́ àtọ̀ mọnī tí wọ́n dà jáde sínú àpòlùkẹ́ ni ثُمَّ كَانَ عَلَقَةً فَخَلَقَ فَسَوَّىٰ ٣٨Lẹ́yìn náà, ó di ẹ̀jẹ̀ dídì. (Allāhu) sì ṣẹ̀dá (rẹ̀). Ó sì ṣe é t’ó dọ́gba jálẹ̀ léèyàn فَجَعَلَ مِنۡهُ ٱلزَّوۡجَيۡنِ ٱلذَّكَرَ وَٱلۡأُنثَىٰٓ ٣٩(Allāhu) sì ṣe ìran méjì jáde láti inú rẹ̀, akọ àti abo أَلَيۡسَ ذَٰلِكَ بِقَٰدِرٍ عَلَىٰٓ أَن يُحۡـِۧيَ ٱلۡمَوۡتَىٰ ٤٠Ǹjẹ́ Ẹni tí Ó ṣe ìyẹn kò níí ní agbára láti jí àwọn òkú dìde bí

الترجمة: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.