ملة الإسلام

السورة 68 · 52 آية · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

سورة القلم باللغة اليوروبا

السورة بالعربية مع التفسير استمع إلى سورة القلم (1,276 قارئاً)
مكيةسورة القلم٥٢ آية

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

نٓۚ وَٱلۡقَلَمِ وَمَا يَسۡطُرُونَ ١Nūn. (Allāhu búra pẹ̀lú) gègé ìkọ̀wé àti ohun tí àwọn mọlāika ń kọ sílẹ̀ مَآ أَنتَ بِنِعۡمَةِ رَبِّكَ بِمَجۡنُونٍ ٢Ìwọ kì í ṣe wèrè nípa ìdẹ̀ra Olúwa rẹ وَإِنَّ لَكَ لَأَجۡرًا غَيۡرَ مَمۡنُونٍ ٣Àti pé dájúdájú ẹ̀san tí kò níí dáwọ́ dúró ti wà fún ọ وَإِنَّكَ لَعَلَىٰ خُلُقٍ عَظِيمٍ ٤Dájúdájú ìwọ sì wà lórí ìwà àpọ́nlé فَسَتُبۡصِرُ وَيُبۡصِرُونَ ٥Láìpẹ́ ìwọ yóò rí i, àwọn náà yó sì rí i بِأَييِّكُمُ ٱلۡمَفۡتُونُ ٦èwo nínú yín ni wèrè إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعۡلَمُ بِمَن ضَلَّ عَن سَبِيلِهِۦ وَهُوَ أَعۡلَمُ بِٱلۡمُهۡتَدِينَ ٧Dájúdájú Olúwa rẹ, Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni t’ó ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà Rẹ̀. Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùmọ̀nà فَلَا تُطِعِ ٱلۡمُكَذِّبِينَ ٨Nítorí náà, má ṣe tẹ̀lé àwọn olùpe-òdodo-nírọ́ وَدُّواْ لَوۡ تُدۡهِنُ فَيُدۡهِنُونَ ٩Àti pé wọ́n fẹ́ kí o dẹwọ́, kí àwọn náà sì dẹwọ́ وَلَا تُطِعۡ كُلَّ حَلَّافٍ مَّهِينٍ ١٠Má ṣe tẹ̀lé gbogbo ẹni tí ìbúra rẹ̀ pọ̀, ẹni yẹpẹrẹ هَمَّازٍ مَّشَّآءِۭ بِنَمِيمٍ ١١abúni, alárìnká t’ó ń sòfófó kiri مَّنَّاعٍ لِّلۡخَيۡرِ مُعۡتَدٍ أَثِيمٍ ١٢olùdènà iṣẹ́ rere, alákọyọ, ẹlẹ́ṣẹ̀ عُتُلِّۭ بَعۡدَ ذَٰلِكَ زَنِيمٍ ١٣ọ̀dájú. Lẹ́yìn ìyẹn, àsáwọ̀ ni أَن كَانَ ذَا مَالٍ وَبَنِينَ ١٤Nítorí pé ó ní dúkìá àti àwọn ọmọkùnrin إِذَا تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِ ءَايَٰتُنَا قَالَ أَسَٰطِيرُ ٱلۡأَوَّلِينَ ١٥nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa fún un, ó máa wí pé: “Àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́ (nìwọ̀nyí)” سَنَسِمُهُۥ عَلَى ٱلۡخُرۡطُومِ ١٦A máa fi àmì sí i ní góńgórí imú إِنَّا بَلَوۡنَٰهُمۡ كَمَا بَلَوۡنَآ أَصۡحَٰبَ ٱلۡجَنَّةِ إِذۡ أَقۡسَمُواْ لَيَصۡرِمُنَّهَا مُصۡبِحِينَ ١٧Dájúdájú Àwa dán wọn wò gẹ́gẹ́ bí A ṣe dán àwọn ọlọ́gbà wò nígbà tí wọ́n búra pé dájúdájú àwọn yóò ká gbogbo èso ọgbà náà ní òwúrọ̀ kùtùkùtù وَلَا يَسۡتَثۡنُونَ ١٨Wọn kò sì ṣe àyàfi pé "tí Allāhu bá fẹ́ فَطَافَ عَلَيۡهَا طَآئِفٌ مِّن رَّبِّكَ وَهُمۡ نَآئِمُونَ ١٩Àdánwò t’ó ń yí n̄ǹkan po láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sì yí ọgbà náà po, nígbà tí wọ́n sùn lọ فَأَصۡبَحَتۡ كَٱلصَّرِيمِ ٢٠Ó sì dà bí oko àgédànù (tí wọ́n ti résun) فَتَنَادَوۡاْ مُصۡبِحِينَ ٢١Wọ́n ń pera wọn ní òwúrọ̀ kùtùkùtù أَنِ ٱغۡدُواْ عَلَىٰ حَرۡثِكُمۡ إِن كُنتُمۡ صَٰرِمِينَ ٢٢pé ẹ jí lọ sí oko yín tí ẹ bá fẹ́ ká èso فَٱنطَلَقُواْ وَهُمۡ يَتَخَٰفَتُونَ ٢٣Wọ́n lọ, wọ́n sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ bára wọn sọ̀rọ̀ أَن لَّا يَدۡخُلَنَّهَا ٱلۡيَوۡمَ عَلَيۡكُم مِّسۡكِينٌ ٢٤pé ní òní mẹ̀kúnnù kan kò gbọdọ̀ wọnú rẹ̀ wá ba yín وَغَدَوۡاْ عَلَىٰ حَرۡدٍ قَٰدِرِينَ ٢٥Wọ́n jí lọ lórí èrò-ọkàn kan (pé) àwọn lágbára فَلَمَّا رَأَوۡهَا قَالُوٓاْ إِنَّا لَضَآلُّونَ ٢٦Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n wí pé: "Dájúdájú àwa ti ṣìnà بَلۡ نَحۡنُ مَحۡرُومُونَ ٢٧Rárá o, wọ́n ṣe ìkórè oko léèwọ̀ fún wa ni قَالَ أَوۡسَطُهُمۡ أَلَمۡ أَقُل لَّكُمۡ لَوۡلَا تُسَبِّحُونَ ٢٨Ẹni t’ó dúró déédé jùlọ nínú wọn sọ pé: "Ṣé èmi kò sọ fun yín pé ẹ̀yin kò ṣe ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu (pé "a máa kórè oko wa, ’in ṣā ’Allāhu) قَالُواْ سُبۡحَٰنَ رَبِّنَآ إِنَّا كُنَّا ظَٰلِمِينَ ٢٩Wọ́n wí pé: "Mímọ́ ni fún Olúwa wa, dájúdájú àwa jẹ́ alábòsí فَأَقۡبَلَ بَعۡضُهُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٍ يَتَلَٰوَمُونَ ٣٠Apá kan wọn kọjú sí apá kan; wọ́n sì ń dára wọn lẹ́bi قَالُواْ يَٰوَيۡلَنَآ إِنَّا كُنَّا طَٰغِينَ ٣١Wọ́n wí pé: "Ègbé wa ò! Dájúdájú àwa jẹ́ olùtayọ-ẹnu àlà عَسَىٰ رَبُّنَآ أَن يُبۡدِلَنَا خَيۡرًا مِّنۡهَآ إِنَّآ إِلَىٰ رَبِّنَا رَٰغِبُونَ ٣٢Ó ṣeé ṣe kí Olúwa wa fi èyí t’ó dára ju èyí lọ pààrọ̀ rẹ̀ fún wa. Dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa wa ni àwa ń rokàn oore sí كَذَٰلِكَ ٱلۡعَذَابُۖ وَلَعَذَابُ ٱلۡأٓخِرَةِ أَكۡبَرُۚ لَوۡ كَانُواْ يَعۡلَمُونَ ٣٣Báyẹn ni ìyà náà ṣe rí (fún wọn). Ìyà ọ̀run sì tóbi jùlọ, tí ó bá jẹ́ pé wọ́n mọ̀ إِنَّ لِلۡمُتَّقِينَ عِندَ رَبِّهِمۡ جَنَّٰتِ ٱلنَّعِيمِ ٣٤Dájúdájú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra wà fún àwọn olùbẹ̀rù lọ́dọ̀ Olúwa wọn أَفَنَجۡعَلُ ٱلۡمُسۡلِمِينَ كَٱلۡمُجۡرِمِينَ ٣٥Ṣé A máa ṣe àwọn mùsùlùmí bí (A ṣe máa ṣe) àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bí مَا لَكُمۡ كَيۡفَ تَحۡكُمُونَ ٣٦Kí l’ó ń ṣe yín tí ẹ fi ń dájọ́ báyìí ná أَمۡ لَكُمۡ كِتَٰبٌ فِيهِ تَدۡرُسُونَ ٣٧Tàbí tírà kan wà fun yín tí ẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀ إِنَّ لَكُمۡ فِيهِ لَمَا تَخَيَّرُونَ ٣٨pé dájúdájú ẹ̀yin lẹ ni ohun tí ẹ bá ń ṣà lẹ́ṣà nínú ìdájọ́ أَمۡ لَكُمۡ أَيۡمَٰنٌ عَلَيۡنَا بَٰلِغَةٌ إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِ إِنَّ لَكُمۡ لَمَا تَحۡكُمُونَ ٣٩Ǹjẹ́ ẹ ni àwọn àdéhùn kan lọ́dọ̀ wa tí ó máa wà títí di Ọjọ́ Àjíǹde pé: "Dájúdájú tiyín ni ìdájọ́ tí ẹ bá ti mú wá سَلۡهُمۡ أَيُّهُم بِذَٰلِكَ زَعِيمٌ ٤٠Bi wọ́n léèrè wò pé èwo nínú wọn l’ó lè fọwọ́ ìyẹn sọ̀yà أَمۡ لَهُمۡ شُرَكَآءُ فَلۡيَأۡتُواْ بِشُرَكَآئِهِمۡ إِن كَانُواْ صَٰدِقِينَ ٤١Tàbí wọ́n ní àwọn òrìṣà kan? Kí wọ́n mú àwọn òrìṣà wọn wá nígbà náà tí wọ́n bá jẹ́ olódodo يَوۡمَ يُكۡشَفُ عَن سَاقٍ وَيُدۡعَوۡنَ إِلَى ٱلسُّجُودِ فَلَا يَسۡتَطِيعُونَ ٤٢Ní ọjọ́ tí A máa ṣí ojúgun sílẹ̀, A sì máa pè wọ́n síbi ìforíkanlẹ̀, wọn kò sì níí lè ṣe é خَٰشِعَةً أَبۡصَٰرُهُمۡ تَرۡهَقُهُمۡ ذِلَّةٌۖ وَقَدۡ كَانُواْ يُدۡعَوۡنَ إِلَى ٱلسُّجُودِ وَهُمۡ سَٰلِمُونَ ٤٣Ojú wọn yóò wálẹ̀. Ìyẹpẹrẹ máa bò wọ́n mọ́lẹ̀. Wọ́n kúkú ti pè wọ́n síbi ìforíkanlẹ̀ nígbà tí wọ́n ní àlàáfíà (wọn kò sì kírun) فَذَرۡنِي وَمَن يُكَذِّبُ بِهَٰذَا ٱلۡحَدِيثِۖ سَنَسۡتَدۡرِجُهُم مِّنۡ حَيۡثُ لَا يَعۡلَمُونَ ٤٤Nítorí náà, fi Èmi àti ẹni t’ó ń pe ọ̀rọ̀ yìí nírọ́ sílẹ̀. A óò máa dẹ wọ́n lẹ́kẹ láti jẹ wọ́n níyà ní àyè tí wọn kò mọ̀ وَأُمۡلِي لَهُمۡۚ إِنَّ كَيۡدِي مَتِينٌ ٤٥Mò ń lọ́ra fún wọn ni. Dájúdájú ète Mi lágbára أَمۡ تَسۡـَٔلُهُمۡ أَجۡرًا فَهُم مِّن مَّغۡرَمٍ مُّثۡقَلُونَ ٤٦Tàbí ò ń bèèrè owó-ọ̀yà kan lọ́dọ̀ wọn, ni gbèsè fi wọ̀ wọ́n lọ́rùn أَمۡ عِندَهُمُ ٱلۡغَيۡبُ فَهُمۡ يَكۡتُبُونَ ٤٧Tàbí lọ́dọ̀ wọn ni (wàláà) ìkọ̀kọ̀ wà ni wọ́n bá ń kọ ọ́ (síta) فَٱصۡبِرۡ لِحُكۡمِ رَبِّكَ وَلَا تَكُن كَصَاحِبِ ٱلۡحُوتِ إِذۡ نَادَىٰ وَهُوَ مَكۡظُومٌ ٤٨Nítorí náà, ṣe sùúrù fún ìdájọ́ Olúwa rẹ. Kí ìwọ má sì ṣe dà bí ẹlẹ́ja (ìyẹn, Ànábì Yūnus) nígbà tí ó pe (Allāhu) pẹ̀lú ìbànújẹ́ لَّوۡلَآ أَن تَدَٰرَكَهُۥ نِعۡمَةٌ مِّن رَّبِّهِۦ لَنُبِذَ بِٱلۡعَرَآءِ وَهُوَ مَذۡمُومٌ ٤٩Tí kò bá jẹ́ pé ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ lé e bá, wọn ìbá jù ú sórí ilẹ̀ gban̄sasa (láti inú ẹja) ní ẹni-èébú فَٱجۡتَبَٰهُ رَبُّهُۥ فَجَعَلَهُۥ مِنَ ٱلصَّٰلِحِينَ ٥٠Nítorí náà, Olúwa rẹ̀ ṣà á lẹ́ṣà. Ó sì ṣe é ní ara àwọn ẹni rere وَإِن يَكَادُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَيُزۡلِقُونَكَ بِأَبۡصَٰرِهِمۡ لَمَّا سَمِعُواْ ٱلذِّكۡرَ وَيَقُولُونَ إِنَّهُۥ لَمَجۡنُونٌ ٥١Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ fẹ́ẹ̀ fi ojú wọn gbé ọ ṣubú nígbà tí wọ́n gbọ́ ìrántí náà. Wọ́n sì ń wí pé: "Dájúdájú wèrè mà ni وَمَا هُوَ إِلَّا ذِكۡرٌ لِّلۡعَٰلَمِينَ ٥٢Kí sì ni al-Ƙur’ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá

الترجمة: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.