ملة الإسلام

السورة 81 · 29 آية · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

سورة التكوير باللغة اليوروبا

السورة بالعربية مع التفسير استمع إلى سورة التكوير (1,316 قارئاً)
مكيةسورة التكوير٢٩ آية

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

إِذَا ٱلشَّمۡسُ كُوِّرَتۡ ١Nígbà tí Wọ́n bá ká òòrùn kóróbójó dànù وَإِذَا ٱلنُّجُومُ ٱنكَدَرَتۡ ٢àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri وَإِذَا ٱلۡجِبَالُ سُيِّرَتۡ ٣àti nígbà tí Wọ́n bá mú àwọn àpáta rìn (kúrò ní àyè wọn, tí wọ́n kù wọ́n dànù) وَإِذَا ٱلۡعِشَارُ عُطِّلَتۡ ٤àti nígbà tí wọ́n bá pa àwọn ràkúnmí aboyún tì وَإِذَا ٱلۡوُحُوشُ حُشِرَتۡ ٥àti nígbà tí Wọ́n bá ko àwọn ẹranko jọ وَإِذَا ٱلۡبِحَارُ سُجِّرَتۡ ٦àti nígbà tí Wọ́n bá mú àwọn agbami odò gbiná وَإِذَا ٱلنُّفُوسُ زُوِّجَتۡ ٧àti nígbà tí Wọ́n bá so àwọn ẹ̀mí pọ̀ mọ́ra wọn, (ẹni rere pẹ̀lú ẹni rere, ẹni ibi pẹ̀lú ẹni ibi) وَإِذَا ٱلۡمَوۡءُۥدَةُ سُئِلَتۡ ٨àti nígbà tí ọmọbìnrin tí wọ́n bò mọ́lẹ̀ láàyè bá bèèrè pé بِأَيِّ ذَنۢبٍ قُتِلَتۡ ٩ẹ̀ṣẹ̀ wo ni wọ́n pa òun fún وَإِذَا ٱلصُّحُفُ نُشِرَتۡ ١٠àti nígbà tí Wọ́n bá ṣí àwọn tákàdá (iṣẹ́ ẹ̀dá) sílẹ̀ وَإِذَا ٱلسَّمَآءُ كُشِطَتۡ ١١àti nígbà tí Wọ́n bá ká sánmọ̀ kúrò lókè وَإِذَا ٱلۡجَحِيمُ سُعِّرَتۡ ١٢àti nígbà tí wọ́n bá mú iná Jẹhīm jò fòfò وَإِذَا ٱلۡجَنَّةُ أُزۡلِفَتۡ ١٣àti nígbà tí Wọ́n bá sún Ọgbà Ìdẹ̀ra mọ́ (àwọn onígbàgbọ́ òdodo) عَلِمَتۡ نَفۡسٌ مَّآ أَحۡضَرَتۡ ١٤(nígbà náà ni) ẹ̀mí (kọ̀ọ̀kan) yóò mọ ohun tí ó mú wá (nínú iṣẹ́ ire àti iṣẹ́ ibi) فَلَآ أُقۡسِمُ بِٱلۡخُنَّسِ ١٥Nítorí náà, Èmi (Allāhu) ń búra pẹ̀lú àwọn ìràwọ̀ t’ó ń yọ ní alẹ́, t’ó ń wọ̀ọ̀kùn ní ọ̀sán ٱلۡجَوَارِ ٱلۡكُنَّسِ ١٦(ìyẹn) àwọn ìràwọ̀ t’ó ń rìn lọ rìn bọ̀, t’ó ń wọ̀ọ̀kùn sí ibùwọ̀ wọn وَٱلَّيۡلِ إِذَا عَسۡعَسَ ١٧Mo tún búra pẹ̀lú alẹ́ nígbà tí ó bá lọ وَٱلصُّبۡحِ إِذَا تَنَفَّسَ ١٨Mo tún búra pẹ̀lú òwúrọ̀ nígbà tí ó bá mọ́lẹ̀ إِنَّهُۥ لَقَوۡلُ رَسُولٍ كَرِيمٍ ١٩Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni ọ̀rọ̀ (tí A fi rán Jibrīl) Òjíṣẹ́, alápọ̀n-ọ́nlé ذِي قُوَّةٍ عِندَ ذِي ٱلۡعَرۡشِ مَكِينٍ ٢٠alágbára, ẹni pàtàkì ní ọ̀dọ̀ Ẹni t’Ó ni Ìtẹ́-ọlá مُّطَاعٍ ثَمَّ أَمِينٍ ٢١ẹni tí wọ́n ń tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ níbẹ̀ yẹn (nínú sánmọ̀), olùfọkàntán وَمَا صَاحِبُكُم بِمَجۡنُونٍ ٢٢Àti pé ẹni yín (Ànábì Muhammad s.a.w.) kì í ṣe wèrè وَلَقَدۡ رَءَاهُ بِٱلۡأُفُقِ ٱلۡمُبِينِ ٢٣Ó kúkú rí i nínú òfurufú kedere وَمَا هُوَ عَلَى ٱلۡغَيۡبِ بِضَنِينٍ ٢٤Àti pé kì í ṣe ahun (tàbí ẹni-afurasí) lórí ìró ìkọ̀kọ̀ (tí A fi ránṣẹ́ sí i) وَمَا هُوَ بِقَوۡلِ شَيۡطَٰنٍ رَّجِيمٍ ٢٥Al-Ƙur’ān kì í sì ṣe ọ̀rọ̀ (tí A fi rán) Èṣù, ẹni ẹ̀kọ̀ فَأَيۡنَ تَذۡهَبُونَ ٢٦Nítorí náà, ibo l’ẹ̀ ń lọ إِنۡ هُوَ إِلَّا ذِكۡرٌ لِّلۡعَٰلَمِينَ ٢٧Kí sì ni al-Ƙur’ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá لِمَن شَآءَ مِنكُمۡ أَن يَسۡتَقِيمَ ٢٨(Ó wà) fún ẹni tí ó bá fẹ́ nínú yín láti dúró déédé وَمَا تَشَآءُونَ إِلَّآ أَن يَشَآءَ ٱللَّهُ رَبُّ ٱلۡعَٰلَمِينَ ٢٩Ẹ̀yin kò sì níí fẹ́ (láti dúró déédé) àyàfi tí Allāhu bá fẹ́, Olúwa gbogbo ẹ̀dá

الترجمة: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.