ملة الإسلام

السورة 82 · 19 آية · Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

سورة الانفطار باللغة اليوروبا

السورة بالعربية مع التفسير استمع إلى سورة الانفطار (1,366 قارئاً)
مكيةسورة الانفطار١٩ آية

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

إِذَا ٱلسَّمَآءُ ٱنفَطَرَتۡ ١Nígbà tí sánmọ̀ bá fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ وَإِذَا ٱلۡكَوَاكِبُ ٱنتَثَرَتۡ ٢àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri وَإِذَا ٱلۡبِحَارُ فُجِّرَتۡ ٣àti nígbà tí àwọn ibúdò bá ṣàn jára wọn وَإِذَا ٱلۡقُبُورُ بُعۡثِرَتۡ ٤àti (nígbà tí A bá ta ilẹ̀ sókè), tí A sì mú àwọn òkú jáde (láàyè) láti inú àwọn sàréè عَلِمَتۡ نَفۡسٌ مَّا قَدَّمَتۡ وَأَخَّرَتۡ ٥(nígbà náà ni) ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò mọ ohun tí ó tì síwájú (nínú iṣẹ́ rẹ̀) àti ohun tí ó fi sẹ́yìn (nínú orípa iṣẹ́ rẹ̀) يَٰٓأَيُّهَا ٱلۡإِنسَٰنُ مَا غَرَّكَ بِرَبِّكَ ٱلۡكَرِيمِ ٦Ìwọ ènìyàn, kí ni ó tàn ọ́ jẹ nípa Olúwa rẹ, Alápọ̀n-ọ́nlé ٱلَّذِي خَلَقَكَ فَسَوَّىٰكَ فَعَدَلَكَ ٧Ẹni t’Ó ṣẹ̀dá rẹ? Ó ṣẹ̀dá rẹ̀ ní pípé. Ó sì mú ọ dọ́gba jalẹ̀ léèyàn فِيٓ أَيِّ صُورَةٍ مَّا شَآءَ رَكَّبَكَ ٨Ó to ẹ̀yà ara rẹ papọ̀ sínú èyíkéyìí àwòrán tí Ó fẹ́ كـَلَّا بَلۡ تُكَذِّبُونَ بِٱلدِّينِ ٩Ní ti òdodo, ńṣe l’ẹ̀ ń pe Ọjọ́ ẹ̀san nírọ́ وَإِنَّ عَلَيۡكُمۡ لَحَٰفِظِينَ ١٠Dájúdájú àwọn ẹ̀ṣọ́ sì wà ní ọ̀dọ̀ yín كِرَامًا كَٰتِبِينَ ١١(Wọ́n jẹ́) alápọ̀n-ọ́nlé, òǹkọ̀wé-iṣẹ́ ẹ̀dá يَعۡلَمُونَ مَا تَفۡعَلُونَ ١٢Wọ́n mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ إِنَّ ٱلۡأَبۡرَارَ لَفِي نَعِيمٍ ١٣Dájúdájú àwọn ẹni rere yóò kúkú wà nínú ìgbádùn وَإِنَّ ٱلۡفُجَّارَ لَفِي جَحِيمٍ ١٤Dájúdájú àwọn ẹni ibi yó sì kúkú wà nínú iná Jẹhīm يَصۡلَوۡنَهَا يَوۡمَ ٱلدِّينِ ١٥Wọn yóò wọ inú rẹ̀ ní Ọjọ́ ẹ̀san وَمَا هُمۡ عَنۡهَا بِغَآئِبِينَ ١٦Wọn kò sì níí kúrò nínú rẹ̀ وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا يَوۡمُ ٱلدِّينِ ١٧Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san ثُمَّ مَآ أَدۡرَىٰكَ مَا يَوۡمُ ٱلدِّينِ ١٨Lẹ́yìn náà, kí ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san يَوۡمَ لَا تَمۡلِكُ نَفۡسٌ لِّنَفۡسٍ شَيۡـًٔاۖ وَٱلۡأَمۡرُ يَوۡمَئِذٍ لِّلَّهِ ١٩(Ọjọ́ ẹ̀san ni) ọjọ́ tí ẹ̀mí kan kò níí kápá kiní kan fún ẹ̀mí kan. Gbogbo àṣẹ ọjọ́ yẹn sì ń jẹ́ ti Allāhu

الترجمة: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni.